Bibeli O Ha Jẹ Mimọ Nitootọ Bi?
AWỌN eniyan meloo lonii ni wọn ka Bibeli si Ọrọ Ọlọrun, ti o jẹ mimọ? Ninu sanmani oniyemeji yii, ọpọlọpọ kà á si alaibagba ati alaiṣe pataki, ni ṣiṣiyemeji pe o jẹ mimọ nitootọ. Koda diẹ ninu awọn asaaju isin Kristẹndọm paapaa kọni pe Bibeli kun fun ọpọlọpọ itan arosọ atọwọdọwọ ati alọ. Wọn gbé ibeere dide ‘boya ọna ti Bibeli gba tumọ itan jẹ eyi ti oloye eniyan le fohun ṣọkan lé lori.’—The Interpreter’s Dictionary of the Bible, Idipọ 2, oju-iwe 611.
Awọn akẹkọọ jinlẹ ayọriọla ngbin irugbin iyemeji nipa bi o ti tọna tó lati tọka si Bibeli gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun. Ọkan wipe “bi ẹnikan ba fẹ lati lo iru ede Ọrọ Ọlọrun, ede isọrọ ti o bojumu fun Bibeli yoo jẹ Ọrọ Isirẹli, Ọrọ awọn aṣiwaju Kristian kan ni ijimiji.” (The Bible in the Modern World, lati ọwọ James Barr) Ki ni iwọ ro? Bibeli ha jẹ Ọrọ Ọlọrun bi? O ha jẹ mimọ nitootọ bi?
Ta Ni O Kọ Bibeli?
Akọsilẹ Jẹnẹsisi, iwe akọkọ Bibeli, ni a kà si ti Mose lọna aṣa, ara Heberu kan ti o gbé ni nǹkan bi 3,500 ọdun sẹhin. Ni ibamu pẹlu Bibeli funraarẹ, nǹkan bi 40 eniyan lati oniruuru ipo igbesi-aye ni wọn ṣalabaapin ninu kikọ apa yooku Iwe mimọ, ti o yọrisi akojọpọ 66 iwe, tabi awọn ipin si kekeke tí o jẹ ti Bibeli. Bi o ti wu ki o ri, awọn eniyan wọnyi ko ka ara wọn si onkọwe Bibeli niti gidi. Onkọwe kan wipe: “Gbogbo iwe mimọ ni o ní imisi Ọlọrun.” (2 Timoti 3:16, New World Translation) Ẹlomiran kọwe nipa onkọwe Bibeli: “Awọn eniyan nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ Ẹmi Mimọ wa.”—2 Peteru 1:21.
Eyi fi awọn onkọwe naa si ìsọ̀rí awọn ọkunrin onígègé, tabi awọn akọwe, ti a dari, tabi tọsọna lati ọdọ Ọlọrun. Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, onkọwe naa ni a saba maa ngbalaaye lati yan awọn ọrọ tirẹ funraarẹ ninu ṣiṣakọsilẹ awọn isọfunni atọrunwa ti a pese naa. (Habakuku 2:2) Idi niyẹn ti ọpọlọpọ ọna ikọwe fi wa jalẹ gbogbo Bibeli. Ṣugbọn ikọwe naa ni a maa nfigba gbogbo tọsọna nipasẹ Ọlọrun.
Lọna ti o ṣee tẹwọgba, sisọ ti awọn onkọwe wọnyi sọ pe awọn ni imisi atọrunwa ninu ara wọn kii ṣe ẹri pe Bibeli jẹ ihin iṣẹ atọrunwa Ẹlẹdaa si iran araye. Bi o ti wu ki o ri, yala ẹni Giga Julọ naa jẹ Onṣewe Bibeli tabi bẹẹkọ ni a nilati ri kedere lori ayẹwo ti a fi iṣọra ati ailẹtanu ṣe lori iwe naa funraarẹ. Bibeli ha funni ni ẹri orisun ikọwe ti o jẹ atọrunwa bi? Nitootọ, awa ha le sọ pẹlu idaniloju pe Bibeli jẹ mimọ bi?