ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/1 ojú ìwé 4-6
  • Bibeli O Ha Ti Ọdọ Ọlọrun Wa Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bibeli O Ha Ti Ọdọ Ọlọrun Wa Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kii Ṣe Itan Lasan
  • Ẹru-Iṣẹ Wa
  • Kí Ni Bíbélì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìwé Náà Tí Ó Ṣí Ìmọ̀ Ọlọrun Payá
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Orisun Àrà-ọ̀tọ̀ Ti Ọgbọn Ti O Ga Ju
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/1 ojú ìwé 4-6

Bibeli O Ha Ti Ọdọ Ọlọrun Wa Bi?

DAJUDAJU Jehofa, Ọlọrun alagbara ati alaṣẹ ti ko láàlà, ni ẹtọ naa lati jumọ sọrọpọ pẹlu eniyan iṣẹda rẹ̀ ni ọna eyikeyi ti oun fẹ. Bi oun ba yan lati bani sọrọ nipasẹ ọrọ ti a kọ silẹ, oun yoo tun nilati pa ihin iṣẹ rẹ mọ la awọn sanmani kọja. Eyi ha ti ri bẹẹ pẹlu Bibeli bi?

Ni nǹkan bi 1,500 ọdun ṣaaju Kristi, nigba ti kikọ Bibeli bẹrẹ, ọpọlọpọ awọn akọsilẹ isin miiran ni wọn wà. Bi o ti wu ki o ri, gbogbo iwọnyi di ohun ti a kò lò mọ́ ó si wulẹ poora nigbẹhingbẹhin. Diẹ ninu wọn ni a ti hu jade nipasẹ awọn awalẹpitan ti wọn si jẹ iṣẹ ọna ti a patẹ rẹ̀ bayii ninu ile akojọ ohun iṣẹmbaye. Ni ọwọ keji ẹwẹ, awọn apakan Bibeli ti a ti kọ silẹ fun eyi ti o ju ẹgbẹrun ọdun sẹhin ni a ko tii gbagbe, ti awọn ẹda si ti laaja titi di ọjọ wa. Eyi yẹ fun afiyesi, paapaa julọ nigba ti a ba ṣagbeyẹwọ iṣọta ti a ti gbe dide lodisi Bibeli jalẹjalẹ ọrọ itan. Ko tii si iwe miiran ti o ti jẹ ayansọju fun ikoriira ati atako riroro bẹẹ. Kika Bibeli tabi pipin-in kiri ni a ti jẹni niya le lori pẹlu owo itanran, ifisẹwọn, idaloro, ati lọpọ igba iku.

Bawo ni iwe kan lásán làsàn ṣe le la iru awọn ipo bẹẹ já? Bibeli funraarẹ sọ fun wa pe: “Ọrọ Oluwa [“Jehofa,” NW] duro titi lae.” (1 Peteru 1:25) Wiwa sibẹ ati aiṣeeparun Bibeli ṣeranwọ lati dá a mọ̀ gẹgẹ bi Ọrọ mimọ Ọlọrun.

Ni afikun sii, awa nilati reti lọna ti o ba ọgbọn mu pe ihin iṣẹ Ọlọrun si araye yoo wa larọọwọto yika aye. Eyi ha ri bẹẹ pẹlu Bibeli bi? Dajudaju bẹẹ ni! Ko si iwe miiran ninu itan ti o tii sunmọ Bibeli ninu eyi paapaa. Ipinkiri Bibeli ni a ti diwọn pe o ti de gongo 3,000,000,000. Ju bẹẹ lọ, ko si iwe miiran ti a tii tumọ si ọpọlọpọ ede bii tirẹ. Bibeli ni a le ka bayii lodidi tabi ni apakan, ni eyi ti o ju 1,900 oriṣiriṣi awọn ede. American Bible Society rohin pe o ti wà larọwọọto nisinsinyi fun ipin 98 ninu ọgọrun un awọn eniyan olugbaye. The New Encyclopædia Britannica pe Bibeli ni “boya akojọpọ awọn iwe ti o tii nipa lori ẹni julọ ninu ọrọ itan eniyan.” Kii ṣe iwa ọyaju, nigba naa lati ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi iwe ti o tayọ julọ lori ilẹ-aye.

Iṣọkan inu Bibeli lati ibẹrẹ de opin ninu ara rẹ jẹ ẹri alagbara pe a mí sii nitootọ lati ọdọ Ọlọrun. Yoo ha jẹ ohun ti o ṣee gbagbọ lati reti pe awọn ikọwe 40 eniyan ọtọọtọ fun akoko ti o ju 1,600 ọdun le jásí eyi ti o wà ni iṣọkan latokedelẹ ti o si ni ipilẹ ẹṣin ọrọ kanṣoṣo? Eyi ki yoo ṣeeṣe bi a ba ti fi silẹ sọwọ eeṣi tabi itọsọna eniyan lasan. Sibẹ, bayii ni ọran ri pẹlu awọn iwe 66 ti o papọ di Bibeli. Kiki ẹda alagbara, ọlọgbọnloye ti o ti wa tipẹtipẹ ni o le mu iru ipese ayanilẹnu bayii ṣẹlẹ.

Kii Ṣe Itan Lasan

Awọn itan inu Bibeli pẹtẹri. Ṣugbọn ihin iṣẹ kan lati ọdọ Ọlọrun ti o jẹ kiki itolẹsẹẹsẹ itan latokedelẹ yoo jasi eyi ti ko ni iniyelori pupọ fun wa. Awa nilo itọsọna ati ọgbọn ti o ṣee mulo, iru iwọnyi ni a si le ri ninu Bibeli. Fun apẹẹrẹ, Bibeli fun wa niṣiiri lati mu “ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwapẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijaanu” dagba—awọn koko ẹkọ eyi ti a kọ ọpọlọpọ ọrọ nipa rẹ jalẹjalẹ awọn oju-ewe rẹ. (Galatia 5:22, 23; Kolose 3:12-14) Bibeli damọran akitiyan iṣẹ, ìmọ́ tónítóní, ailabosi, iṣotitọ ninu igbeyawo, ọwọ ati ifẹ fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ ẹni; o si ni ọpọ yanturu imọran lori ihuwa eniyan laaarin idile ati awujọ ninu.

Nigba ti a ba fi silo, imọran Bibeli tayọ gẹgẹ bi eyi ti o ṣanfaani nitootọ. O dá wa silẹ lominira kuro lọwọ aimọkan ati igbagbọ ninu ohun asan. (Johanu 8:32) Ọgbọn gbigbeṣẹ rẹ jẹ alailẹgbẹ. Nitootọ, laiṣiyemeji, o ni ọgbọn atọrunwa ninu.

Ijẹwọ naa pe “ọrọ Ọlọrun yè o si ni agbara” wa ni iṣọkan ni kikun pẹlu ọna ti Bibeli gba nyi awọn eniyan pada niti gidi. (Heberu 4:12) Araadọta ọkẹ loni ti bori animọ ajogunba apanilara ti wọn si ti yi ipa ọna apanirun wọn ti atijọ pada si eyi ti o san ju gẹgẹ bi iyọrisi fifi awọn ilana Bibeli sọkan.—Efesu 4:22.

Ki ni ohun ti o nṣẹlẹ nigba ti awọn ilana Bibeli ba di eyi ti a gboju foda? Iyọrisi rẹ jẹ ailayọ ati ibanujẹ, ogun, ipo oṣi, awọn aisan tí ibalopọ takọtabo ńta látaré, ati awọn idile ti o tuka. Iru awọn nǹkan bẹẹ ni a le reti nitori pe ṣiṣaika Bibeli Mimọ si tumọsi kíkọ idari Ọlọrun, ẹni ti o dá eniyan ti o si mọ awọn aini rẹ.

Bibeli tun sọ asọtẹlẹ ọjọ iwaju, ohun kan ti ko ṣeeṣe fun eniyan lati ṣe. Idide awọn agbara aye lati Babiloni jalẹjalẹ si awọn ọrundun titi de ọjọ wa lonii ni a ti kede lọna asọtẹlẹ ninu Bibeli. (Daniẹli, ori 2, 7, 8) Ni afikun sii, ni eyi ti o fẹrẹ to ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, a kọ apejuwe apejuwe pipe perepere nipa awọn ipo aye ninu ọrundun lọna ogun yii silẹ ninu Bibeli. (Matiu, ori 24, 25; Maaku, ori 13; Luuku, ori 21; 2 Timoti 3:1-5; 2 Peteru 3:3, 4; Iṣipaya 6:1-8) Akọsilẹ gigun ti awọn imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli fi dá wa loju pe ifojusọna naa fun ọjọ ọla alayọ gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ ninu awọn oju-ewe rẹ jẹ ojulowo.

Ẹru-Iṣẹ Wa

Gbogbo eyi jẹ ẹri ti nbonimọlẹ pe Ọlọrun nitootọ ti ba araye sọrọ. Nitootọ, Ọlọrun ta àtaré ihin iṣẹ rẹ̀ nipasẹ ọwọ awọn eniyan alaipe. Ṣugbọn eyi kii ṣe idi eyikeyi lati gbagbọ pe Bibeli dinkù lọna eyikeyi niti ijotitọ gidi ju bi yoo ti jẹ ihin iṣẹ ọrọ ẹnu lati ọdọ Ọlọrun, tabi eyi ti a fi funni nipasẹ awọn angẹli, tabi eyi ti a kọ lọna iṣẹ iyanu ninu ọrun ti a si fi fun awọn eniyan lori ilẹ-aye.

Bi o ti wu ki o ri, jijẹwọ ipilẹṣẹ Bibeli pe o jẹ mimọ, tabi atọrunwa gbe ẹru iṣẹ kan kà wá lori. Jehofa lọna ẹtọ reti pe ki a maa ka Ọrọ rẹ deedee. (Saamu 1:1, 2) Bibeli kika ti o mu eso wa nbeere fun ẹmi ironu bibojumu. Ẹnikan gbọdọ fi sọkan pe Bibeli kii ṣe eyi ti a nilati kà bi ẹni pe o wulẹ jẹ iwe itan eyikeyii lasan. Ẹnikan gbọdọ gbé e yẹwo, “kii ṣe gẹgẹ bi ọrọ eniyan, ṣugbọn gan an gẹgẹ bi o ti jẹ nitootọ gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun.”—1 Tẹsalonika 2:13.

Awọn nǹkan diẹ le ṣoro lati loye ninu Bibeli. Ṣugbọn nipa kika a deedee, ẹnikan yoo ma dagba ninu oye ti yoo si ni oye ti o tubọ pé perepere nipa ifẹ inu Ọlọrun ati awọn ete rẹ. (Heberu 5:14) Boya iwọ sibẹsibẹ ni a ko tii yi lọkan pada ni kikun pe Bibeli jẹ Ọrọ mimọ Ọlọrun. Ṣugbọn, lọna ṣiṣe deedee, bawo ni iwọ ṣe le sọrọ nipa igbagbọ tabi ainigbagbọ ninu Bibeli bi iwọ ko ba tii farabalẹ kẹkọọ rẹ?

Laika iyemeji ode oni si nipa ipilẹṣẹ atọrunwa rẹ, ayẹwo ti a farabalẹ ṣe kan nipa Bibeli Mimọ ti mu ki ọpọlọpọ onironu eniyan kigbe jade pẹlu awọn ọrọ apọsteli Pọọlu pe: “Ki a rí Ọlọrun ni olootọ, bi a tilẹ rí olukuluku eniyan ni òpùrọ́”!—Roomu 3:4, NW.

[Graph tó wà ní ojú ìwé 4]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Bibeli ti wà larọwọọto nisinsinyi fun ipin 98 ninu ọgọrun un awọn olugbaye

Ko si iwe miiran ninu itan ti o tíì sunmọ idiwọn ipinkiri Bibeli ti 3,000,000,000. The New Encyclopædia Britannica pe é ni “boya akojọpọ awọn iwe ti o tii nipa lori ẹni julọ ninu itan eniyan”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bibeli ṣi wà sibẹ, nigba ti awọn akọsilẹ ti isin miiran ti di iṣẹ-ọna ile akojọ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé lasan

Loke: Akọsilẹ Asiria nipa ikun omi

Ni apa ọtun: Awọn adura si ọlọrun Ra ti Ijibiti

[Credit Line]

Mejeeji: Courtesy of the Trustees of The British Museum

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

A kọ ọ́ nipasẹ 40 eniyan ọtọọtọ ni akoko ti o ju 1,600 ọdun, Bibeli tẹle ẹṣin ọrọ ipilẹ kan lati ibẹrẹ titi de opin. Kiki ẹda ọlọgbọnloye kan ti o ju eniyan lọ, ti o ti walaaye tipẹtipẹ ni o le mu iru imujade pipẹtẹri bẹẹ jade

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Idide awọn agbara aye lati ori Babiloni jalẹ awọn ọrundun titi di ọjọ wa ni a ti kede lọna asọtẹlẹ ninu Bibeli. (Daniẹli 2, 7, 8)

Ni apa ọtun: Kesari Ọgọsitọsi

[Credit Line]

Museo della Civiltà Romana, Roma

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ni eyi ti o fẹrẹẹ to ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, Bibeli sọ asọtẹlẹ awọn ipo aye lonii lọna pipe pere. (Matiu 24, 25; Maaku 13; Luuku 21; 2 Timoti 3:1-5; 2 Peteru 3:3, 4; Iṣipaya 6:1-8)  Ìpé pérépéré aláìtàsé ti asọtẹlẹ Bibeli fi dá wa loju pe ileri Ọlọrun fun paradise ilẹ-aye daju pe yoo ni imuṣẹ

[Credit Line]

Reuter/Bettmann Newsphotos

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́