ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/1 ojú ìwé 10-15
  • Awọn Ọmutipara Nipa Tẹmi—Ta ni Wọn Íṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ọmutipara Nipa Tẹmi—Ta ni Wọn Íṣe?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Awọn Ọmutipara Efuraimu”
  • ‘Alufaa ati Wolii Ti Ṣìnà’
  • Awọn Ọmutipara Lonii
  • “Àṣẹ Lé Àṣẹ”
  • Iṣeṣiro Naa
  • Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Bàbá Kan Àtàwọn Ọlọ̀tẹ̀ Ọmọ Rẹ̀
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Ibi Ìsádi Wọn—Irọ́ Ni!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/1 ojú ìwé 10-15

Awọn Ọmutipara Nipa Tẹmi—Ta ni Wọn Íṣe?

“Ègbé ni fun adé ọlọla ògo awọn ọmutipara Efuraimu.”—AISAYA 28:1, NW.

1. Ẹmi nǹkan yoo dara wo ni ọpọlọpọ ti nimọlara rẹ, ṣugbọn awọn ireti wọn ni a o ha muṣẹ bi?

ANGBE ni awọn akoko ti ntaniji pẹ́pẹ́. Ọpọlọpọ awọn eniyan ni a ti ru soke nipasẹ awọn iyipada amunijigiri ti oṣelu yika aye ati ni rírí bi Iparapọ awọn orilẹ-ede ti nkowọnu rẹ lọna pupọ sii. Ni December 1989 Detroit Free Press wi pe: “Bi planẹti yii ti nwọnu awọn ọdun 1990, alaafia ni a ti bẹrẹ sii rí.” Iwe irohin Soviet kan kede pe: “Awa nmura silẹ lati fi awọn ọ̀kọ̀ wa rọ ohun eelo ìtulẹ̀,” nigba ti akọwe gbogbogboo ti Iparapọ awọn Orilẹ-ede polongo pe: “Awa kò sí ninu ogun tutu mọ́.” Bẹẹni, awọn ireti ti ga, ati laisi iyemeji, iran aye ti nyipada. Lẹ aipẹ yii, ogun Gulf ti ṣakawe bi awọn iyipada ti lè yarakankan tó. Ṣugbọn njẹ ọwọ́ aye isinsinyi yoo ha tẹ akoko alaafia ati aabo gidi kan, pẹlu gbogbo awọn anfaani ti nbaarin lae bi? Idahun naa ni bẹẹkọ. Nitootọ, yanpọnyanrin lilekoko kan ngbarajọ ti yoo mi aye tìtì de awọn ipilẹ rẹ̀! O jẹ yanpọnyanrin kan ninu eyi ti o mu isin lọwọ lọna jijinlẹ.

2. Bawo ni ipo ti oni ṣe ba ti Isirẹli ati Juda igbaani dọgba?

2 Yanpọnyanrin yii ni a ṣapẹẹrẹ ṣaaju nipa awọn iṣẹlẹ ni Isirẹli ati Juda igbaani laaarin ọrundun kẹjọ ati keje B.C.E. Nigba naa lọhun-un, pẹlu, awọn eniyan ronu pe ọwọ́ awọn lè tẹ alaafia. Ṣugbọn Ọlọrun, nipasẹ wolii rẹ̀ Aisaya, kilọ pe ireti wọn fun alaafia jẹ́ ìtànjẹ kan, eyi ti a o túdìí aṣiri rẹ̀ laipẹ. Ni ọna ti o farajọra lonii, Jehofa, nipasẹ awọn Ẹlẹrii rẹ̀, nkilọ fun araye pe a ti tan wọn jẹ bi wọn ba reti lati nawọ́gán alaafia pipẹtiti kan nipasẹ awọn isapa eniyan. Ẹ jẹ ki a ka ikilọ alasọtẹlẹ Jehofa ki a sì ríi bi o ti ṣee fisilo lonii. A ríi ninu Aisaya ori kejidinlọgbọn a sì kọ ọ́ ṣaaju 740 B.C.E., o ṣeeṣe ki o jẹ lakooko ijọba Peka Ọba buburu ti Isirẹli ati Ọba Ahasi aṣetinu ẹni ti Juda.

“Awọn Ọmutipara Efuraimu”

3. Ibawi amunitagiri wo ni Aisaya sọ jade?

3 Ni ori 28 ẹsẹ 1 (NW), a gbò wá jìgìjìgì nipasẹ gbolohun ọrọ amunitagiri kan pe: “Ègbé ni fun adé ọlọla ògo awọn ọmutipara Efuraimu, ati ìtànná rírọ iṣeloge ẹwa rẹ̀ ti o wà ni ori afonifoji ẹlẹ́tùlójú awọn wọnni ti ọti waini bori!” Bawo ni a ti gbọdọ ti mu awọn Isirẹli gbọnriri to lati gbọ́ idalẹbi mimuna yẹn! Awọn wo ni “awọn ọmutipara Efuraimu” wọnyi? Ki ni “adé ọlọla ògo” wọn? Ki si ni ‘ori afonifoji ẹlẹ́tùlójú’? Ni pataki ju, ki ni awọn ọrọ wọnyi tumọsi fun wa lonii?

4. (a) Ki ni Efuraimu ati ori afonifoji ẹlẹtuloju? (b) Eeṣe ti Isirẹli fi nimọlara aabo?

4 Niwọn bi Efuraimu ti jẹ ẹ̀yà ti o tobi julọ laaarin awọn ẹ̀yà mẹwaa Isirẹli, èdè isọrọ naa “Efuraimu” nigba miiran tọka si gbogbo ijọba iha ariwa. Nitori naa “awọn ọmutipara Efuraimu” jẹ awọn ọmutipara Isirẹli niti gidi. Olu ilu Isirẹli ni Samaria, eyi ti o wà ni ibi giga apàfiyèsí kan lori afonifoji ẹlẹ́tùlójú kan. Nitori naa ọrọ naa “ori afonifoji ẹlẹ́tùlójú” tọkasi Samaria. Nigba ti a kọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi silẹ, ijọba Isirẹli dibajẹ gan-an bi a ba sọ niti isin. Ju bẹẹ lọ, oun ti kówọnú ajọṣepọ oloṣelu pẹlu Siria lodisi Juda o sì nimọlara aabo gan-an nisinsinyi. (Aisaya 7:1-9) Iyẹn ni o fẹrẹẹ yipada laipẹ. Yanpọnyanrin kan nsunmọ tosi, eyi ti o jẹ idi ti Jehofa fi sọrọ ikede pe “ègbé ni fun ade ọlọla ogo awọn ọmutipara Efuraimu.”

5. (a) Ki ni ade ọlọla ogo Isirẹli? (b) Awọn wo ni ọmutipara Efuraimu?

5 Ki ni “ade ọlọla ogo”? Ade jẹ àmì aṣẹ kabiyesi. Lọna ti o han gbangba, “ade ọlọla ogo” jẹ ipo Isirẹli gẹgẹ bi ijọba ti o da duro, lai kò gbarale Juda. Ohun kan yoo ṣẹlẹ lati pa idaduro lominira kabiyesi Isirẹli run. Awọn wo ni, nigba naa, ni “awọn ọmutipara Efuraimu”? Laiṣe iyemeji, awọn ọmutipara tootọ wà ni Isirẹli, niwọn bi Samaria ti jẹ ibi iran ijọsin oloriṣa oniwa palapala. Sibẹ, Bibeli sọrọ nipa iru imutipara ti o buru ju kan. Ni Aisaya 29:9, a kà pe: “Wọn mu amupara; ṣugbọn kii ṣe fun ọti waini, wọn nta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n ṣugbọn kii ṣe fun ohun mimu lile.” Eyi jẹ imutipara tẹmi kan, imutiyo aláìmọ́, ati aṣekupani. Awọn aṣaaju Isirẹli—ni pataki awọn aṣaaju isin rẹ̀—ni kedere jiya lọwọ iru imutiyo nipa tẹmi bẹẹ.

6. Ki ni o mu ki Isirẹli igbaani mutipara?

6 Ki ni okunfa imutipara tẹmi Isirẹli igbaani? Ni ipilẹ, o jẹ ajọṣepọ rẹ̀ pẹlu Siria lodisi Juda, eyi ti o fun awọn aṣaaju orilẹ-ede naa ni imọlara rere ati aabo. Imutipara tẹmi yii ra Isirẹli ni iyè. Gẹgẹ bi ọmutipara gidi kan, oun lẹmii nǹkan yoo dara bi o tilẹ jẹ pe ko si idi lati ṣe bẹẹ. Ju bẹẹ lọ, Isirẹli gbe ajọṣepọ apani bi ọti rẹ̀ pẹlu Siria wọ̀ lọna igberaga, bi òdòdó itanna afiṣẹwà . Ṣugbọn, gẹgẹ bi Aisaya ti wi, o jẹ iṣupọ òdòdó ti nrọ ti ki yoo wà pẹ lọ titi.

7, 8. Laika imọlara daradara rẹ̀ si, ki ni Isirẹli igbaani yoo niriiri rẹ̀ laipẹ?

7 Aisaya tẹnumọ eyi ni ori 28, ẹsẹ 2: “Kiyesi i, [“Jehofa,” NW] ní ẹni kan alagbara ati onípá, bii ẹfuufu lile yìnyín, ati ìjì iparun, bii ìṣàn omi nla akunya, yoo fi ọwọ́ bì í ṣubu sori ilẹ̀.” Ta ni “ẹni kan alagbara ati onipa” yii? Ni akoko Isirẹli igbaani, o jẹ Ilẹ-ọba Asiria alagbara. Agbara aye oniwa ika, asánjú yii yoo wá sori Isirẹli gẹgẹ bi ìjì iparun, bii ìṣàn omi nla akunya. Pẹlu iyọrisi wo?

8 Aisaya nbaa lọ lati wipe: “Adé igberaga [“ọlọla ogo,” NW] awọn ọmuti Efuraimu, ni a o fi ẹsẹ tẹ mọlẹ: Ati ògo ẹwa ti o wà lori afonifoji ọlọraa [“ẹlẹtuloju,” NW] yoo jẹ itanna rírọ, gẹgẹ bi eso [“ajara,” NW] ti o yara ṣaaju igba ikore; eyi nigba ti ẹni ti o ba nwo o ba rii, nigba ti o wà ni ọwọ́ rẹ̀ sibẹ, o gbé e mì.” (Aisaya 28:3, 4) Olu ilu Isirẹli, Samaria, dabi ọ̀pọ̀tọ́ pípọ́n kan si Asiria, ti o ti wà ni sẹpẹ́ fun kíká lati gbé mì. Ajọṣepọ Isirẹli pẹlu Siria ti o dabi iṣupọ òdòdó ni a o fi ẹsẹ tẹ mọlẹ. Kò ni niyelori kankan nigba ti ọjọ́ ìjihin ba de. Eyi ti o tilẹ tun buru jù, ògo idaduro lominira rẹ̀ ni a o tẹ̀ rẹ́ labẹ ẹsẹ awọn ara Asiria ọta. Iru ajalu ibi wo ni eyi jẹ́!

‘Alufaa ati Wolii Ti Ṣìnà’

9. Eeṣe ti Juda fi lè ti reti ihin iṣẹ ti ó sàn lati ọ̀dọ̀ Jehofa ju eyi ti Isirẹli igbaani gbà?

9 Bẹẹni, iṣeṣiro bibanilẹru nduro de Isirẹli, ati gan-an gẹgẹ bi Jehofa Ọlọrun ti kilọ, iṣeṣiro yẹn de ni ọdun 740 B.C.E. nigba ti a pa Samaria run lati ọwọ́ Asiria tí ijọba iha ariwa sì ṣíwọ́ lati wà gẹgẹ bi orilẹ ede olominira kan. Ohun ti o ṣẹlẹ si Isirẹli igbaani duro gẹgẹ bi ikilọ alaidapaara fun isin eke alaiṣootọ lonii, gẹgẹ bi awa yoo ti rii. Ṣugbọn ki ni niti ijọba ọmọ iya Isirẹli ni ìhà guusu, Juda? Ni akoko Aisaya tẹmpili Jehofa ṣì wa lẹnu iṣẹ ni Jerusalẹmu, olu ilu Juda. Ẹgbẹ alufáà ṣi ngbe iṣẹ ṣe nibẹ, awọn wolii iru bii Aisaya, Hosea, ati Mika si nsọrọ ni orukọ Jehofa. Nigba naa, ihin iṣẹ wo, ni Jehofa ni fun Juda?

10, 11. Ki ni ipo ti nsuni fun irira ti o wà ni Juda?

10 Aisaya nbaa lọ lati sọ fun wa pe: “Ṣugbọn awọn [eyiini ni, awọn alufaa ati awọn wolii Jerusalẹmu] pẹlu ti ti ipa ọti waini ṣìnà, ati nipa ọti lile wọn ti ṣáko; alufaa ati wolii ti ṣìnà nipa ọti lile.” (Aisaya 28:7a) Lọna ti o han gbangba, awọn aṣaaju isin Juda ti mutipara pẹlu. Gẹgẹ bi ni Isirẹli, o ṣeeṣe ki awọn kan ti jẹ ọmutipara ni itumọ gidi, bi o ba sì ri bẹẹ, eyi jẹ ojútì. Ofin Ọlọrun ni pato ka mimu ọti lile leewọ fun awọn alufaa nigba ti wọn ba nṣiṣẹsin ninu tẹmpili. (Lefitiku 10:8-11) Imutipara gidi ninu ile Ọlọrun yoo ti jẹ iwa riru ofin Ọlọrun ti o buru jáì.

11 Eyi ti o tun wuwo ju bẹẹ lọ, bi o ti wu ki o ri, ni imutipara tẹmi ti o wa ni Juda. Gan-an gẹgẹ bi Isirẹli ti jumọ so ara rẹ̀ pọ̀ mọ Siria lodisi Juda, bẹẹ ni Juda wá aabo nipasẹ ajọṣepọ pẹlu Asiria. (2 Ọba 16:5-9) Laika wiwa nibẹ tẹmpili Ọlọrun ati awọn wolii rẹ̀ sí, Juda fi igbagbọ sinu awọn eniyan nigba ti o yẹ ki o ni igbẹkẹle ninu Jehofa. Ju bẹẹ lọ, nigba ti o ti ṣe iru ajọṣepọ alailọgbọn ninu bẹẹ, awọn aṣaaju rẹ̀ nimọlara aibikita gẹgẹ bi ti awọn aladuugbo wọn ti wọn jẹ ọmutipara nipa tẹmi ni iha ariwa. Ẹmi ironu alaimọgbọndani wọn kó Jehofa nírìíra.

12. Ki ni yoo jẹ abayọri imutipara tẹmi Juda?

12 Aisaya nbaa lọ lati wipe: “Ọti waini da wọn loju ru (NW) wọn di aṣáko nipa ọti lile, wọn ṣìnà ninu iran, wọn kọsẹ̀ ni idajọ. Nitori gbogbo tabili ni o kun fun èébì ati ẹ̀gbin, ko si ibi ti o mọ́.” (Aisaya 28:7b, 8) O ṣeeṣe pe, ninu ipò imutipara wọn, awọn kan bì niti tààràtà sinu tẹmpili. Ṣugbọn eyi ti o buru ju ni pe, awọn alufaa ati wolii ti o yẹ ki wọn funni ni itọsọna lọna ti isin ni wọn nbi èébì ọ̀bùn tẹmi jade. Ju bẹẹ lọ, yatọ si awọn oluṣotitọ kereje kan, idajọ awọn wolii jẹ eyi ti a yipo, wọn sì ri awọn ohun aritẹlẹ eleke fun orilẹ ede naa. Jehofa yoo fiya jẹ Juda fun àìmọ́ tẹmi yii.

Awọn Ọmutipara Lonii

13. Ibadọgba wo si ipo ti o wà ni Isirẹli ati Juda ni o wà ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní C.E., ibadọgba wo ni o sì wa lonii?

13 Awọn asọtẹlẹ Aisaya ha ṣẹ̀ kìkì lori Isirẹli ati Juda igbaani bi? Bẹẹ kọ rara. Jesu ati apọsteli Pọọlu pẹlu fa awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nipa imutipara tẹmi wọn si lo wọn fun awọn aṣaaju isin ti igba ti wọn. (Aisaya 29:10, 13; Matiu 15:8, 9; Roomu 11:8) Lonii, pẹlu, ipo kan ti o dabi ti akoko Aisaya ti dide—ni akoko yii ninu Kristẹndọm, eto-ajọ onisin kari aye ti o jẹwọ pe oun nṣoju fun Ọlọrun. Dipo mimu iduro gbọnyingbọnyin fun otitọ ati gbigbarale Jehofa, Kristẹndọm, Katoliki ati Protẹstanti, fi igbagbọ tirẹ sinu aye. Oun tipa bayii nta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n kiri laiduro si oju kan, bi awọn ọmutipara Isirẹli ati Juda. Awọn ọmutipara tẹmi ti awọn orilẹ ede igbaani wọnyẹn jẹ òjìji iṣaaju didara kan fun awọn aṣaaju tẹmi ti Kristẹndọm lonii. Ẹ jẹ ki a wò ó bi o ti jẹ bẹẹ gan an.

14. Bawo ni awọn aṣaaju isin Kristẹndọm ṣe jẹ ọmuti gẹgẹ bi awọn aṣaaju Samaria ati Jerusalẹmu igbaani?

14 Gẹgẹ bii Samaria ati Jerusalẹmu, Kristẹndọm ti mutiyo kẹ́ri nipasẹ ọti waini ajọṣepọ iṣelu. Ni 1919 oun wà laaarin awọn oluṣagbatẹru Imulẹ awọn Orilẹ-Ede. Nigba ti Jesu sọ pe awọn Kristian ki yoo jẹ apakan aye, awọn aṣaaju Kristẹndọm mu awọn ipo ibatan dàgba pẹlu awọn aṣaaju iṣelu. (Johanu 17:14-16) Waini iṣapẹẹrẹ iru ti igbokegbodo bẹẹ nru awọn awujọ alufaa soke. (Fiwe Iṣipaya 17:4.) Wọn gbadun ki awọn oṣelu maa kàn si wọn ki wọn sì maa kẹgbẹ pẹlu awọn eniyan jàn-ǹkànjàn-ǹkàn inu aye yii. Gẹgẹ bi iyọrisi eyi, wọn kò ni itọsọna tẹmi tootọ lati fi funni. Wọn ńbì àìmọ́ jade dipo sisọ ihin iṣẹ mimọgaara ti otitọ. (Sẹfanaya 3:9) Pẹlu iriran wọn ti o si ti di bàìbàì, wọn kii ṣe amọna alailewu kankan fun araye.—Matiu 15:14.

“Àṣẹ Lé Àṣẹ”

15, 16. Bawo ni awọn alajọgbaye Aisaya ṣe dahun pada si awọn ikilọ rẹ̀?

15 Ni ọrundun kẹjọ B.C.E., Aisaya ni pataki tudii aṣiiri ipa ọna aláìtọ́ ti awọn aṣaaju tẹmi Juda. Bawo ni wọn ti dahun pada? Wọn koriira rẹ̀! Nigba ti Aisaya tẹpẹlẹ mọ́ ọn ninu pipokiki awọn ikilọ Ọlọrun, awọn aṣaaju isin naa dá a lohun pe: “Ta ni oun yoo kọ́ ni ìmọ̀? Ati ta ni oun yoo fi òye ẹ̀kọ́ yé? Awọn ẹni ti a wọ́n ni ẹnu ọmu ti a sì ja ni ẹnu ọyàn?” (Aisaya 28:9) Bẹẹni, njẹ Aisaya ha ronu pe oun nba awọn ọmọ ọwọ́ sọ̀rọ̀ bi? Awọn aṣaaju isin Jerusalẹmu ka araawọn si awọn ọkunrin ti wọn ti dagba di gende, ti wọn lè ṣe ipinnu funraawọn lẹkun-unrẹrẹ. Wọn kò nilo fifetisilẹ si awọn irannileti aláròyé ti Aisaya.

16 Awọn onisin wọnni tilẹ fi iṣẹ iwaasu Aisaya ṣe yẹ̀yẹ́. Wọn sín in jẹ pe: “Nitori o jẹ́ ‘àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ le àṣẹ, okun iwọn lé okun iwọn, okun iwọn lé okun iwọn, diẹ nihin-in, diẹ lọhun-un.’” (Aisaya 28:10, NW) Wọn sọ pe, ‘Aisaya nbaa lọ ni sisọ asọtunsọ ṣaa. Oun nbaa lọ ni wiwi pe: “Eyi ni ohun ti Jehofa palaṣẹ! Eyi ni ohun ti Jehofa palaṣẹ! Eyi ni ọpa idiwọn Jehofa! Eyi ni ọpa idiwọn Jehofa!”’ Ninu èdè Heberu ti ipilẹṣẹ, Aisaya 28:10 jẹ ọrọ adúnbárajọ alasọtunsọ, gẹgẹ bi ewí alakọsọri ti awọn ọmọ ile ẹkọ ògowẹẹrẹ. Bẹẹ sì ni wolii naa jọ loju awọn aṣaaju isin, alasọtunsọ ti nṣe bi ọmọde.

17. Bawo ni ọpọlọpọ lonii ṣe huwa pada si awọn ihin iṣẹ onikilọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pokiki?

17 Ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní C.E., iwaasu Jesu ati awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ dún bakan naa bii ti alasọtunsọ ati òpè. Awọn wọnni ti wọn tẹle Jesu ni awọn aṣaaju isin Juu wò gẹgẹ bi ẹni ìfibú òpè eniyan lasan, awọn ọkunrin alaimọwe ati púrúǹtù. (Johanu 7:47-49; Iṣe 4:13) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii ni a nwo niye igba ni ọna kan naa. Wọn kò lọ si awọn sẹ̀mínárì Kristẹndọm wọn kii sii lò awọn orukọ oyè jàn-ǹkànjàn-ǹkàn tabi èdè isọrọ ẹlẹkọọ isin gẹgẹ bi awọn awujọ alufaa ti ṣe. Nitori naa awọn ẹni nlanla ninu Kristẹndọm foju kere wọn, ni rírò pe wọn nilati mọ àyè wọn ki wọn sì fun awọn aṣaaju isin wọnyi ni ọ̀wọ̀ pupọ sii.

18. Ki ni awọn aṣaaju isin lonii gboju fò dá?

18 Bi o ti wu ki o ri, ohun kan wà ti awọn aṣaaju isin wọnni gbójú fòdá. Ani bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹni jàn-ǹkànjàn-ǹkàn ọjọ Aisaya kọ̀ ihin iṣẹ rẹ̀, oun sọ otitọ, awọn ikilọ rẹ̀ sì jásí òótọ́! Lọna ti o farajọra, ikilọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nsọ jade lonii jẹ otitọ, ti a fìdí rẹ̀ mulẹ gbọnyingbọnyin lori Ọrọ Ọlọrun ti otitọ, Bibeli. (Johanu 17:17) Fun idi yii, wọn yoo ni imuṣẹ.

Iṣeṣiro Naa

19. Bawo ni a ṣe fi ipa mu Juda lati ṣegbọran si awọn ajeji ti wọn nsọ èdè akólòlò?

19 Ni Aisaya 28:11, a kà pe: “Nitori nipa ètè (“akololo,” NW) ati ni èdè miiran ni oun yoo fi ba eniyan wọnyii sọrọ.” Ikọnilẹkọọ Aisaya dún bii atatantoto ajeji si Juda. Bi o tilẹ jẹ pe Juda la iyọlẹnu awọn Asiria ti o bo Isirẹli mọlẹ já, nigba ti o yá Jehofa ba Juda lo nipasẹ ajeji miiran, Nebukadinesari. (Jeremaya 5:15-17) Èdè Babiloni dún bi eyi ti o lekoko ati bii akólòlò si awọn Heberu wọnni. Ṣugbọn a fi ipa mu wọn lati fetisilẹ si i nigba ti a pa Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ̀ run ni 607 B.C.E. ti a sì wọ́ awọn olùgbé rẹ̀ lọ sinu igbekun ni Babiloni. Ni ọna kan naa lonii, Kristẹndọm yoo nilati jiya laipẹ nitori pe, bii Juda atijọ, oun ṣaifiyesi awọn igbani niyanju Jehofa.

20, 21. Ki ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa npokiki laidabọ, ṣugbọn ki ni awọn aṣaaju Kristẹndọm kọ̀ lati ṣe?

20 Asọtẹlẹ naa sọ nipa iru awọn ẹni bẹẹ pe: ‘Si ẹni ti oun wipe, eyi ni isinmi, ẹyin iba mu awọn alaaarẹ sinmi, eyi sì ni itura: sibẹ wọn ki yoo gbọ́. Nitori ọrọ Jehofa jẹ àṣẹ le àṣẹ, àṣẹ le àṣẹ fun wọn: okun iwọn lé okun iwọn, okun iwọn lé okun iwọn; diẹ nihin-in diẹ lọhun-un: ki wọn baa le lọ, ki wọn sì ṣubu sẹhin, ki wọn sì ṣẹ́, ki a sì dẹ wọn, ki a sì mu wọn.’—Aisaya 28:12, 13.

21 Laidabọ, gan-an gẹgẹ bi Aisaya ti sọ ihin iṣẹ Ọlọrun, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sọ fun Kristẹndọm pe oun nilati fi ireti rẹ̀ sinu ọrọ Jehofa. Ṣugbọn oun kọ̀ lati fetisilẹ. Si i, awọn Ẹlẹrii dabii awọn ti nṣe atatantoto ni èdè ahọ́n ajeji. Wọn nsọ èdè ti oun kò lè loye. Kristẹndọm kọ̀ lati fi isinmi fun ẹni ti nṣaarẹ nipa sisọ nipa Ijọba Ọlọrun ati aye titun ti nbọ. Kaka bẹẹ, oun ti mutipara nipasẹ ọti waini ipo ibatan rẹ̀ pẹlu aye yii. Oun yàn lati ṣetilẹhin fun awọn ojutuu iṣelu fun awọn iṣoro araye. Bii awọn Juu ọjọ Jesu, oun kò wa ibi isinmi Ijọba naa, oun kò si ni sọ fun awọn ẹlomiran nipa rẹ̀.—Matiu 23:13.

22. Ki ni Jehofa fi si afiyesi awọn aṣaaju Kristẹndọm?

22 Fun idi yii, awọn ọrọ alasọtẹlẹ Aisaya fi tó awujọ alufaa leti pe Jehofa ki yoo maa fi igbagbogbo sọrọ nipasẹ awọn Ẹlẹrii Rẹ̀ alaile panilara. Laipẹ, Jehofa yoo jẹ ki “àṣẹ le àṣẹ, okun iwọn lé okun iwọn” wa si imuṣẹ, iyọrisi naa yoo sì jẹ àjálù ibi fun Kristẹndọm. Awọn aṣaaju isin rẹ̀ ati awọn agbo rẹ̀ ni a o “ṣẹ́, ki a sì dẹ wọn, ki a sì mu wọn.” Bẹẹni, bii Jerusalẹmu atijọ, awọn eto isin Kristẹndọm ni a o parun raurau. Ẹ wo idagbasoke amunigbọnriri ti a kò reti ti iyẹn yoo jẹ! Ẹ sì wo abajade abanilẹru ti o jẹ fun awujọ alufaa ti wọn yàn imutipara tẹmi si awọn irannileti Jehofa!

Iwọ Ha Le Ṣalaye?

◻ Awọn wo ni awọn ọmutipara Efuraimu, ki ni o sì mu wọn mutipara?

◻ Bawo ni a ṣe tẹ adé ọlọla ogo awọn ọmutipara Efuraimu mọlẹ?

◻ Ipo atiniloju wo ní Juda ni Aisaya tudii aṣiri rẹ̀?

◻ Nibo lonii ni a ti ri imutipara tẹmi?

◻ Eeṣe ti Kristẹndọm fi nilati kọbiara si ohun ti ó ṣẹlẹ si orilẹ-ede Juda igbaani?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́