ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/1 ojú ìwé 15-20
  • Ibi Ìsádi Wọn—Irọ́ Ni!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibi Ìsádi Wọn—Irọ́ Ni!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Majẹmu Pẹlu Iku”
  • Ṣíṣá “Okuta Ti A Danwo” Tì
  • Awọn Ireti Asán fun Alaafia
  • ‘Ọlọrun Ni Ibi Isadi Wa’
  • Kristẹndọm “Ibi Itẹmọlẹ”
  • Orukọ Jehofa “Ile-iṣọ Agbara”
  • Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Ẹ Maa Baa Niṣo Ni Ṣiṣekilọ Àràmàǹdà Iṣẹ Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • “Sá Di Orúkọ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ọwọ́ Jèhófà Kò Kúrú
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/1 ojú ìwé 15-20

Ibi Ìsádi Wọn—Irọ́ Ni!

“Awa ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa ninu eke sì ni awa fi ara wa pamọ níkọ̀kọ̀.”—AISAYA 28:15, NW.

1, 2. (a) Eto-ajọ wo lonii ni o nilati kiyesi ohun ti o ṣẹlẹ si ijọba Juda igbaani? (b) Igbọkanle ninu ohun aitọna wo ni Juda ni?

NJẸ awọn ọrọ wọnni kan Kristẹndọm lonii gẹgẹ bi wọn ṣe kan ijọba ẹya meji Juda igbaani? Dajudaju, ó kàn wọ́n! Ibadọgba yẹn sì jẹ ami ibi fun Kristẹndọm ode oni. O tumọsi pe àjálù ibi yoo sáré lé eto-ajọ isin ti o jẹ apẹhinda yẹn bá laipẹ.

2 Ni apa ariwa Juda ni ijọba ẹlẹya mẹwaa ti Isirẹli. Nigba ti Isirẹli di alainigbagbọ, Jehofa yọnda ki a ṣẹgun rẹ̀ lati ọwọ Asiria ni 740 B.C.E. Ijọba Juda ti o jẹ ọmọ iya rẹ̀, ṣẹlẹrii iṣẹlẹ ọlọran ibanujẹ yii ṣugbọn ni kedere ó rò pe iru nǹkan bẹẹ ki yoo ṣẹlẹ si oun lae. Awọn aṣaaju rẹ̀ fọ́nnu pe, ‘Họ́wù, tẹmpili Jehofa ko ha ṣì wà ni Jerusalẹmu? Awa kii ha ṣe awọn eniyan ti Ọlọrun ṣe ojurere si? Awọn wolii ati alufaa wa ko ha nsọrọ ni orukọ Jehofa bi?’ (Fiwe Jeremaya 7:4, 8-11.) Awọn aṣaaju isin wọnni ni igbọkanle pe awọn wà láàbò. Ṣugbọn wọn kò tọna! Wọn jẹ alaini igbagbọ gan-an gẹgẹ bi awọn ibatan wọn ọkunrin ti iha ariwa. Nitori naa, ohun ti o ṣẹlẹ si Samaria yoo tun ṣẹlẹ si Jerusalẹmu pẹlu.

3. Eeṣe ti Kristẹndọm fi nimọlara igbọkanle nipa ọjọ-ọla, ṣugbọn idi rere ha wà fun igbọkanle rẹ̀ bi?

3 Ni ọna ti o farajọra, Kristẹndọm sọ pe oun ni ipo ibatan akanṣe pẹlu Ọlọrun. Oun fọ́nnu pe, ‘Eeṣe, awa ni awọn ṣọọṣi ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa mẹwaa ati awujọ alufaa amọṣẹ́dunjú, ati pẹlu araadọta ọkẹ lọna ọgọrọọrun awọn ọmọlẹhin. Awa tun ni Bibeli, a si nlo orukọ Jesu ninu ijọsin wa. Dajudaju, a ṣojú rere si wa lati ọdọ Ọlọrun!’ Ṣugbọn ohun ti o ṣẹlẹ si Jerusalẹmu igbaani duro gẹgẹ bi ikilọ alaigboju bọ̀rọ̀ kan. Laika awọn idagbasoke ara ọtọ ti oṣelu ní lọwọ lọwọ yii si, awa mọ pe Jehofa yoo gbegbeesẹ tipinnu tipinnu lodisi Kristẹndọm ati gbogbo awọn isin eke miiran laipẹ.

“Majẹmu Pẹlu Iku”

4. Majẹmu wo ni Juda ronu pe oun ti ṣe?

4 Ni igba laelae, Jerusalẹmu alaiṣotitọ gba ọpọlọpọ ikilọ nipasẹ awọn wolii tootọ ti Ọlọrun, ṣugbọn oun ko gbà wọn gbọ. Kaka bẹẹ, oun fọ́nnu pe iku ki yoo mu oun lọ lae sinu Sheol, saare, gẹgẹ bi o ti mu ijọba ariwa ti Isirẹli lọ. Wolii Aisaya ni a mi si lati sọ fun Juda pe: “Nitori naa ẹ gbọ ọrọ Jehofa, ẹyin afọ́nnu, ẹyin alakooso awọn eniyan wọnyi ti wọn wa ni Jerusalẹmu: Nitori pe ẹyin eniyan yii ti wipe: ‘Awa ti dá majẹmu pẹlu Iku; ati pẹlu Sheol ni awa ti mu iran ṣẹ; ikun omi ayaluni lojiji, boya o le kọja, ko ni wa sọdọ wa, nitori awa ti fi irọ ṣe ibi isadi wa ninu eke si ni awa ti fi ara wa pamọ nikọkọ.’”—Aisaya 28:14, 15, NW.

5. (a) Ki ni majẹmu ti Juda ronu pe oun ti ṣe pẹlu iku? (b) Ikilọ ti a fi fun Ọba Asa wo ni Juda ti gbagbe?

5 Bẹẹni, awọn aṣaaju Jerusalẹmu ronu pe awọn ni àdéhùn, ki a sọ ọ́ lọna bẹẹ, pẹlu iku ati Sheol ki o le jẹ pe ilu wọn ni a o pamọ. Ṣugbọn njẹ ohun ti Jerusalẹmu lero pe o jẹ majẹmu pẹlu iku ha tumọsi pe oun ti ronupiwada kuro ninu awọn ẹṣẹ rẹ ti oun si ti nigbẹkẹle ninu Jehofa fun igbala nisinsinyi? (Jeremaya 8:6, 7) Bẹẹkọ rara! Kaka bẹẹ, oun yiju si awọn alakooso oṣelu ti eniyan fun iranlọwọ. Ṣugbọn gbigbe ti o gbarale awọn alajọṣepọ aye jẹ́ itanjẹ, ati irọ kan. Awọn ẹni aye ti oun gbọkanle ko le gba a la. Ati niwọn bi oun ti pa Jehofa tì, Jehofa pa Jerusalẹmu tì. O ṣẹlẹ gẹgẹ bi wolii Asaraya ti kilọ fun Ọba Asa: “Oluwa [“Jehofa,” NW] wà pẹlu yin, nitori ti ẹyin ti wà pẹlu rẹ̀; bi ẹyin ba si ṣàfẹ́rí rẹ̀ ẹyin yoo ri; ṣugbọn bi ẹyin ba kọ̀ ọ́, oun yoo si kọ̀ yin.”—2 Kironika 15:2.

6, 7. Awọn igbesẹ wo ni Juda gbe lati mu aabo rẹ daju, ṣugbọn pẹlu iyọrisi ikẹhin wo?

6 Pẹlu igbọkanle ninu awọn ajọṣepọ oṣelu wọn, awọn aṣaaju Jerusalẹmu ni idaniloju pe ko si “ìkun omi ayaluni lojiji” ti awọn ọmọ-ogun ti yoo sunmọ ọdọ wọn lati yọ alaafia ati aabo wọn lẹnu. Nigba ti a halẹ mọ ọ nipasẹ ajọṣepọ Isirẹli ati Siria, Juda yiju si Asiria fun iranlọwọ. (2 Ọba 16:5-9) Lẹhin naa, nigba ti a dẹru bà wọ́n nipasẹ awọn agbo ologun Babiloni, oun fi taratara bẹ Ijibiti fun itilẹhin tí Farao si dahun pada, ni riran ẹgbẹ ọmọ-ogun kan lati ṣeranlọwọ.—Jeremaya 37:5-8; Esekiẹli 17:11-15.

7 Ṣugbọn awọn ọmọ-ogun Babiloni lagbara ju, awọn ọ̀wọ́ ogun Ijibiti si nilati fà sẹhin. Gbigbe ti Jerusalẹmu gbọkanle Ijibiti jasi aṣiṣe kan, ati ni 607 B.C.E., Jehofa kọ ọ silẹ fun iparun ti o ti sọtẹlẹ. Nitori naa awọn alakooso ati alufaa Jerusalẹmu ko tọna! Igbẹkẹle wọn ninu awọn ajọṣepọ aye fun alaafia ati aabo jẹ “irọ́” ti a ti gbá lọ nipasẹ ìkún omi awọn ọmọ-ogun Babiloni.

Ṣíṣá “Okuta Ti A Danwo” Tì

8. Bawo ni Kristẹndọm ṣe mu ipo ti o dabi ti Juda igbaani gan an?

8 Ipo ti o baradọgba ha wà lonii bi? Bẹẹni, o wà. Awujọ alufaa Kristẹndọm bakan naa nimọlara pe ko si ìjábá kankan ti yoo ba awọn. Nipa bayii, wọn sọ gẹgẹ bi Aisaya ti sọtẹlẹ pe: “Awa ti dá majẹmu pẹlu Iku; ati pẹlu Sheol ni awa ti mu iran ṣẹ; ìkún omi ayaluni lojiji, bi o ba kọja, ko ni de ọdọ wa, nitori awa ti fi irọ ṣe ibi isadi wa ninu èké si ni awa fi ara wa pamọ níkọ̀kọ̀.” (Aisaya 28:15) Bi Jerusalẹmu igbaani, awujọ alufaa Kristẹndọm nwo awọn ajọṣe ti aye fun aabo, wọn si kọ̀ lati wa ibi isadi lọdọ Jehofa. Eeṣe, wọn kò tilẹ lo orukọ rẹ̀, wọn si nfi awọn wọnni ti wọn nbọla fun orukọ yẹn ṣẹlẹya wọn si nṣe inúnibíni si wọn. Kristẹndọm ati awujọ alufaa rẹ̀ ti ṣe ohun naa gan-an ti awọn alufaa awọn agba Juu ni ọgorun un ọdun kin-inni ṣe nigba ti wọn ṣá Kristi tì. Wọn ti wi, nitootọ pe, “awa ko ni ọba bikoṣe Kesari.”—Johanu 19:15.

9. (a) Awọn wo ni wọn nkilọ fun Kristẹndọm lonii lọna kan naa ti Aisaya gba kilọ fun Juda? (b) Ta ni Kristẹndọm nilati yiju si?

9 Lonii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kilọ pe ìkún omi ọmọ ogun amúdajọ ṣẹ yoo ya bori Kristẹndọm laipẹ. Ju bẹẹ lọ, wọn tọka si ibi isadi tootọ kuro lọwọ ìkún omi yẹn. Wọn fa ọrọ Aisaya 28:16 yọ ti o wi pe: “Nitori naa bayii ni Oluwa Jehofa wi, pe, Kiyesi, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dánwo, okuta igun ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹni ti o gbagbọ ki yoo sá.” Ta ni ‘okuta igun ile iyebiye’ yii? Apọsteli Peteru fa awọn ọrọ wọnyi yọ o si lo wọn fun Jesu Kristi. (1 Peteru 2:6) Bi Kristẹndọm ba ti wa alaafia pẹlu Ọba Jehofa, Jesu Kristi ni, nigba naa oun iba ti yẹra fun ìkún omi ayalaluni lojiji ti nbọ.—Fiwe Luuku 19:42-44.

10. Awọn ilọwọsi wo ni Kristẹndọm ti mu dagba?

10 Bi o ti wu ki o ri, oun ko tíì ṣe bẹẹ. Kaka bẹẹ, ninu iwakiri rẹ̀ fun alaafia ati aabo, oun fọgbọn fi ara rẹ̀ sinu ojurere awọn aṣaaju oṣelu awọn orilẹ-ede—eyi laika ikilọ Bibeli pe ibatan aye jẹ iṣọta pẹlu Ọlọrun si. (Jakọbu 4:4) Ju bẹẹ lọ, lọna ti o lagbara oun ṣalagbawi Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ni 1919 gẹgẹ bi ireti didara julọ fun alaafia eniyan. Lati 1945 oun ti fi ireti rẹ sinu Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. (Fiwe Iṣipaya 17:3, 11.) Bawo ni ikowọnu rẹ̀ pẹlu eto-ajọ yii ti gbooro to?

11. Oju wo ni isin ni ninu Iparapọ Awọn Orilẹ-ede?

11 Iwe lọ́ọ́lọ́ọ́ kan funni ni oye nigba ti o wi pe: “Awọn eto-ajọ Katoliki ti a ṣoju fun ni Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ko din ni mẹrinlelogun. Awọn aṣaaju isin aye melookan ti bẹ eto-ajọ jakejado aye naa wo. Manigbagbe julọ ni awọn ibẹwo Ẹni Mimọ Pope Paul Kẹfa lakooko Apejọ Gbogboogbo ni 1965 ati ti Pope John Paul Keji ni 1979. Ọpọlọpọ isin ni awọn akanṣe ọrọ ijirẹẹbẹ, awọn adura, orin ati isin fun Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Awọn apẹẹrẹ ti o ṣe pataki julọ ni awọn wọnni ti Katoliki, Ijọ Onigbagbọ ninu Igbala gbogbo araye ati Omininra Isin, Ijọ Onitẹbọmi ati igbagbọ Bahai.”

Awọn Ireti Asán fun Alaafia

12, 13. Laika awọn ireti ti ó tànkálẹ̀ pe alaafia ni ọwọ le tẹ̀, eeṣe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi nigbọkanle pe awọn ikilọ wọn jẹ otitọ?

12 Ọkan lara awọn aṣaaju oṣelu aye ti o lagbara julọ gbé ireti ọpọlọpọ eniyan jade nigba ti o wi pe: “Iran eniyan yii lori ilẹ-aye le ri dide sáà alaafia alaiṣee yipada kan ninu itan ọ̀làjú.” Oun ha tọna bi? Njẹ awọn ìṣẹlẹ lọ́ọ́lọ́ọ́ ha tumọ si pe awọn ikilọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nsọ jade nipa imudajọ ṣẹ Jehofa lori awọn orilẹ-ede ki yoo ṣẹ bi? Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ha ṣaitọna bi?

13 Bẹẹkọ, wọn ko ṣaitọna. Wọn mọ pe awọn nsọ otitọ nitori pe wọn fi igbẹkẹle wọn sinu Jehofa ati sinu Bibeli, eyi ti o jẹ Ọrọ otitọ Ọlọrun funraarẹ. Titu 1:2 wi pe: “Ọlọrun . . . ko le ṣeke.” Nitori naa wọn ni igbọkanle kikun pe nigba ti akọsilẹ Bibeli kan ba wi pe ohun kan yoo ṣẹlẹ, yoo ni imuṣẹ laikuna. Jehofa funraarẹ wi pe: “Bẹẹ ni ọrọ mi ti o ti ẹnu mi jade yoo ri: ki yoo pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yoo ṣe eyi ti o wu mi, yoo si maa ṣe rere ninu ohun ti mo rán an.”—Aisaya 55:11.

14, 15. (a) Ki ni awọn aṣaaju Juda npokiki kete ṣaaju iparun Jerusalẹmu ni 607 B.C.E.? (b) Ki ni Pọọlu sọtẹlẹ pe a o pòkìkí rẹ̀ ki iparun òjiji to wa sori aye yii? (c) Ki ni a le reti ni òtéńté ìpolongo ti a sọtẹlẹ ni 1 Tẹsalonika 5:3?

14 Ni awọn ọdun ṣaaju iparun Jerusalẹmu ni 607 B.C.E., Jeremaya rohin pe awọn aṣaaju nkigbe pe, “Alaafia wà! Alaafia wà!” (Jeremaya 8:11, NW) Bi o ti wu ki o ri, iyẹn jẹ irọ́ kan. Jerusalẹmu ni a parun ni imuṣẹ ikilọ onimiisi ti awọn wolii tootọ ti Jehofa. Apọsteli Pọọlu kilọ pe ohun kan ti o farajọra yoo ṣelẹ ni ọjọ wa. Oun wipe awọn eniyan yoo maa ké pe “Alaafia ati ailewu!” Sugbọn nigba naa, oun wi pe, “iparun ojiji yoo dé lọgan sori wọn.”—1 Tẹsalonika 5:3, NW.

15 Gẹgẹ bi a ti wọnu awọn ọdun 1990, awọn iwe agberohin jade ati iwe irohin nibi gbogbo nsọ pe Ogun Tutu ti pari ati pe alaafia aye wà ti sunmọtosi nígbẹ̀hìn gbẹ́hín. Ṣugbọn lẹhin naa afòkò ọta ogun ranṣẹ bẹ́ silẹ ni Agbedemeji Ila-oorun. Bi o ti wu ki o ri, ó pẹ́ ni ó yá ni ipo aye yoo gberu dori ibi ti igbe “Alaafia ati Ailewu!” ti a sọ tẹlẹ ni 1 Tẹsalonika 5:2, 3 yoo ti lọ soke sii de òtéńté kan. Bi a ti so ireti wa mọ Ọrọ Ọlọrun gbọnyingbọnyin, awa mọ pe, bi o ba ti dori òtéńté yẹn, idajọ Ọlọrun ni a o mú ṣẹ pẹlu iyara kánkán làìsi àṣìṣe. Ko si ikede alaafia ati aabo alawuruju kan ti o nilati mu wa ronu pe iparun ti Ọlọrun sọtẹlẹ ki yoo de. Awọn idajọ Jehofa ni a ti kọ silẹ laiṣee yipada ninu Ọrọ rẹ Bibeli. Kristẹndọm, papọ pẹlu gbogbo isin eke miiran, ni a o parun. Ati lẹhin naa awọn idajọ apanirun ti Jehofa ni a o fihan jade lodisi iyooku aye Satani. (2 Tẹsalonika 1:6-8; 2:8; Iṣipaya 18:21; 19:19-21) Niwọn bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nigbọkanle pe Jehofa yoo mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ, wọn nbaa lọ lati maa ṣọna labẹ itọsọna ẹgbẹ ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu wọn si nfarabalẹ kiyesi bi awọn iṣelẹ aye ti nṣi paya. (Matiu 24:45-47) Dajudaju, ko si awọn isapa kankan fun wiwa alaafia ni iha ọdọ eniyan ti o nilati mu wa ronu pe Jehofa ti pa ete rẹ tì lati mu ìkún omi ayaluni lojiji ti iparun wa sori Kristẹndọm ti ẹru ẹṣẹ ti pa.

‘Ọlọrun Ni Ibi Isadi Wa’

16, 17. Bawo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ndahun pada bi awọn kan ba binu si ihin-iṣẹ wọn ti ko ni ifọrọ sabẹ ahọn ninu?

16 Awọn kan le gbà aifọrọ sabẹ ahọn ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni pipokiki eyi si ibinu. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti wọn ba sọ pe awọn alakooso isin Kristẹndọm ti wa ibi isadi sinu iṣeto irọ, wọn wulẹ nsọ ohun ti Bibeli wi ni. Nigba ti wọn ba sọ pe Kristẹndọm lẹtọọ si ijiya nitori pe oun ti di apakan aye, wọn wulẹ nrohin ohun ti Ọlọrun funraarẹ sọ ninu Bibeli ni. (Filipi 3:18, 19) Ju bẹẹ lọ, nitori pe Kristẹndọm fi igbọkanle rẹ sinu awọn ìpète tí aye yii hùmọ̀, oun niti gasikiya ti ọlọrun aye yii, Satani Eṣu lẹhin, ẹni ti Jesu sọ pe o jẹ baba eke.—Johanu 8:44; 2 Kọrinti 4:4.

17 Nitori naa, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa polongo pe: Niti wa o, awa ko fun awọn ireti eke ti alaafia aye niṣiiri nitori iran oṣelu tí nyipada. Kaka bẹẹ, awa tun awọn ọrọ onisaamu naa sọ pe: “Ọlọrun ni ibi isadi fun wa. . . . Awọn ọmọkunrin eniyan olugbe laye jẹ asan, awọn ọmọkunrin araye jẹ irọ́. Nigba ti a gbé wọn ka ori iwọn gbogbo wọn lapapọ fuyẹ ju atẹgun lọ.” (Saamu 62:8, 9, NW) Awọn ìpète eniyan lati ṣagbatẹru ki o si pa Kristẹndọm ati iyooku eto igbekalẹ awọn nǹkan yii mọ jẹ eke, irọ kan! Gbogbo wọn lapapọ ko lagbara lati ṣedilọwọ fun awọn ete Jehofa gan-an gẹgẹ bi atẹgun gbigbona ti a dì sẹnu ko ti le ṣe bẹẹ!

18. Ikilọ onisaamu wo ni o bá a mu lonii?

18 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tun lo ọrọ Saamu 33, ẹsẹ 17 si 19, eyi ti o polongo pe: “Ohun asan ni ẹṣin [Ijibiti ti o ṣapẹẹrẹ ogun jíjà] fun igbala: bẹẹ ni ki yoo fi agbara nla rẹ gbani silẹ. Kiyesi, oju Oluwa [“Jehofa,” NW] nbẹ lara wọn ti o bẹru rẹ, lara awọn ẹni ti nreti ninu aanu rẹ; lati gba ọkan wọn là kuro lọwọ iku, ati lati pa wọn mọ laaye nigba iyan.” Lonii, awọn Kristian tootọ nigbẹkẹle ninu Jehofa ati ninu Ijọba ọrun rẹ, iṣeto kanṣoṣo ti o le mu alaafia pipẹ titi wa.

Kristẹndọm “Ibi Itẹmọlẹ”

19. Eeṣe ti igbiyele awọn eto-ajọ oṣelu lati mu alaafia aye wa fi jẹ itanjẹ kan?

19 Lati gbẹkẹle afidipo eyikeyi ti eniyan fun Ijọba Ọlọrun sọ ifidipo yẹn di ère kan, ohun ajọsin fun kan. (Iṣipaya 13:14, 15) Nipa bayii, fífun gbigbiye le awọn eto igbekalẹ oṣelu niṣiiri, iru bii Iparapọ Awọn Orilẹ-ede, fun alaafia ati aabo jẹ itanjẹ, irọ kan. Nipa iru awọn ohun ireti eke bẹẹ, Jeremaya wi pe: “Nitori ere dida rẹ eke ni, ko sì sí ẹmi ninu rẹ̀. Asan ni wọn, ati iṣẹ iṣina: Nigba ibẹwo wọn wọn o ṣegbe.” (Jeremaya 10:14, 15) Nitori naa, awọn ẹṣin ogun Ijibiti amapẹẹrẹ ṣẹ, iyẹn ni pe, agbara nla iṣelu-òun-ologun ti awọn orilẹ-ede lonii, ki yoo daabo bo ilẹ akoso isin ti Kristẹndọm ni ọjọ yánpọnyánrin rẹ̀. Ajọṣepọ awọn isin Kristẹndọm pẹlu aye yii yoo kuna lati daabo bo wọn dajudaju.

20, 21. (a) Ki ni o ṣẹlẹ si Imulẹ Awọn Orilẹ-ede, eesitiṣe ti Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ko fi san ju lọnakọna? (b) Bawo ni Aisaya ṣe ti fihan pe awọn ajọṣepọ Kristẹndọm pẹlu aye ki yoo gbà á là?

20 Kristẹndọm gbé ireti rẹ ka Imulẹ Awọn Orilẹ-ede, ṣugbọn a soju rẹ̀ de ani láì tíì si dídé Amagẹdọn paapaa. Nisinsinyi oun ti gbe ajọṣepọ rẹ̀ lọ sọdọ Iparapọ Awọn Orile-ede. Ṣugbọn oun laipẹ yoo dojukọ “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare,” ki yoo si laaja. (Iṣipaya 16:14) Ani Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ti a mu sọji paapaa ko le mu alaafia ati aabo wa laelae. Ọrọ alasọtẹlẹ Ọlọrun fihan pe eto-ajọ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede pẹlu awọn orilẹ-ede mẹmba rẹ “yoo si ma ba Ọdọ Agutan [Kristi ninu agbara Ijọba] jagun, Ọdọ Agutan naa yoo si ṣẹ́gun wọn: nitori oun ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba.”—Iṣipaya 17:14.

21 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi igbọkanle wi pe ko si igbala fun Kristẹndọm ninu awọn ajọṣepọ rẹ̀ pẹlu aye Satani. Nigba ti wọn ba si sọ eyi wọn wulẹ ntọka jade si ohun ti Bibeli funraarẹ sọ ni. Aisaya 28:17, 18 (NW) ṣayọlo ọrọ Jehofa ni wiwi pe: “Emi yoo fi idajọ-ododo ṣe okùn iwọn ati ododo ohun eelo imutẹju dọgba; yinyin si gbọdọ gba aabo isadi irọ kuro, awọn omi funraawọn yoo si kún ibi ipamọ ikọkọ naa gan an. Majẹmu rẹ pẹlu Iku ni a o si mu opin de ba dajudaju, iran ifihan rẹ yẹn pẹlu Sheol ki yoo si duro. Ìkún omi ayaluni lojiji naa, nigba ti o ba kọja—iwọ pẹlu gbọdọ di ibi itẹmọlẹ fún un.”

22. Nigba ti a ba lo idajọ-ododo pipe fun Kristẹndọm, ki ni yoo yọrisi?

22 Nigba ti a ba gbe ipinnu idajọ Jehofa jade, yoo jẹ ni ibamu pẹlu idajo-ododo pipe. Ati ipilẹ fun igbọkanle Kristẹndọm, ‘majẹmu rẹ́ pẹlu Iku’ ni a o gbá kuro patapata bi ẹni pe nipasẹ ìkún omi kan. Aisaya nbaa lọ lati wi pe: “Nitori ni gbogbo owurọ ni yoo rekọja, ni ọsan ati ni oru: kiki igburo rẹ yoo si di ijaya [“ki awọn ẹlomiran le loye ohun ti wọn ti gbọ,” NW].” (Aisaya 28:19) Bawo ni yoo ti bani lẹru to fun awọn òǹwòran lati ṣẹlẹrii ẹ̀kún rẹ́rẹ́ agbara idajọ Jehofa! Bawo ni yoo ti buru jai to fun awujọ alufaa Kristẹndọm ati awọn ọmọlẹhin wọn lati wá rí i pe o ti pẹ ju, pe wọn ti nigbẹkẹle ninu irọ!

Orukọ Jehofa “Ile-iṣọ Agbara”

23, 24. Dipo wiwa aabo sinu aye yii, ki ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo ṣe?

23 Ṣugbọn ki ni niti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? Ani loju ikoriira ati inunibini jakejado awọn orilẹ-ede paapaa, wọn tẹpẹlẹ mọ́ ọn ni yiya ara wọn sọtọ kuro ninu aye. Wọn ko gbagbe lae pe Jesu sọ nipa awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Wọn kii ṣe ti aye, gẹgẹ bi emi kìí tii ṣe ti aye.” (Johanu 17:16) Lati ibẹrẹ de opin awọn ọjọ ikẹhin wọnyii, wọn ti fi igbẹkẹle wọn sinu Ijọba Jehofa, kìí ṣe ninu awọn ìpète eniyan. Nitori naa, ajalu ibi Kristẹndọm ki yoo mu ki awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹru jìnnìnjìnnìn. Gẹgẹ bi Aisaya ti sọtẹlẹ: “Ẹni ti o gbagbọ ki yoo sa.”—Aisaya 28:16.

24 Owe 18:10 wi pe: “Orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW], ilé-ìṣọ́ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ, o si là.” Nitori naa a ké si gbogbo awọn ẹni bi agutan lati wa ibi isadi lọdọ Jehofa ati Ijọba rẹ̀ nipasẹ Kristi. Gẹgẹ bi ibi ipamọ ikọkọ, Jehofa kii ṣe eke! Ijọba Rẹ nipasẹ Kristi kii ṣe irọ! Ibi isadi Kristẹndọm ni o jẹ irọ, ṣugbọn ibi isadi awọn Kristian tootọ jẹ otitọ.

Iwọ Ha Le Ṣalaye Bi?

◻ Bawo ni Juda igbaani ṣe fi irọ́ ṣe ibi isadi wọn?

◻ Ọna wo ni Kristẹndọm gba gbiyanju lati fi ara rẹ pamọ nikọkọ ninu eke?

◻ Bawo ni Aisaya ṣe kilọ fun Juda, bawo si ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe sọ ikilọ ti o farajọra jade lonii?

◻ Bawo ni Kristẹndọm yoo ṣe ri pe oun ti fi igbọkanle sinu ohun aitọna?

◻ Ni odikeji si Kristẹndọm, iduro wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dimu?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

AWỌN IRETI GIGA TI A SỌ JADE FUN IPARAPỌ AWỌN ORILẸ-EDE

“Fun igba akọkọ lati igba Ogun Agbaye Keji awujọ jakejado awọn orilẹ-ede jakejado wà ni iṣọkan. Ipo aṣaaju Iparapọ Awọn Orilẹ-ede, ti o wulẹ jẹ apẹẹrẹ pipe ohun ti a nreti nigba kan ri, ti nmu àlá awọn oludasilẹ rẹ̀ daju nisinsinyi. . . . nitori naa aye le lo anfaani yii lati mu ileri eto aye titun kan ṣẹ.”—Aarẹ Bush ti United States ninu ọrọ rẹ ti ibẹrẹ ijokoo Igbimọ Aṣofin fun orilẹ-ede yẹn, January 29, 1991

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́