ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/1 ojú ìwé 20-25
  • Ẹ Maa Baa Niṣo Ni Ṣiṣekilọ Àràmàǹdà Iṣẹ Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Maa Baa Niṣo Ni Ṣiṣekilọ Àràmàǹdà Iṣẹ Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Akete Kuru Ju”
  • Iṣe Ajeji Ti Jehofa
  • Ikilọ Nipa Iṣe Jehofa
  • “Ẹ Ti Inu Rẹ Jade”
  • ‘Lori Rẹ Ni Ẹmi Jehofa Yoo Bà Lé’
  • Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Ibi Ìsádi Wọn—Irọ́ Ni!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣé Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ni Ìlú Jerúsálẹ́mù Ṣàpẹẹrẹ?
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Ọwọ́ Jèhófà Kò Kúrú
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/1 ojú ìwé 20-25

Ẹ Maa Baa Niṣo Ni Ṣiṣekilọ Àràmàǹdà Iṣẹ Jehofa

“Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo dide bii ti oke Perasimu, yoo si binu gẹgẹ bi ti afonifoji Gibioni.”—AISAYA 28:21.

1, 2. Ki ni iṣẹ àràmàǹdà ti Jehofa muṣe fun awọn eniyan Rẹ ni ọjọ Dafidi?

IṢE ajeji kan! Iṣẹ kan ti o ṣàràmàǹdà julọ! Ohun ti Jehofa mu ṣe niyẹn fun awọn eniyan rẹ ni awọn akoko igbaani pada sẹhin lọhun un ni ọrundun kọkanla B.C.E. Iṣẹ ajeji yii si jẹ awokọṣe kan fun eyi ti o tilẹ tubọ jẹ iṣẹ àràmàǹdà ti oun yoo muṣe ni ọjọ iwaju ti ko jinna. Ki ni ohun ti iṣẹ akoko igbaani yẹn jẹ? Ko pẹ lẹhin ti a fi Dafidi sori oye gẹgẹ bi ọba ni Jerusalẹmu, awọn ara Filisitini ti wọn wa nitosi gbe ija kò ó, ti eyi si tanna ran iṣe ajeji ti Jehofa. Lakọọkọ, awọn ara Filisitini bẹrẹ sii gbogunti wọn si ńpiyẹ́ ni pẹtẹlẹ titẹju ti Refeimu. Dafidi beere lọwọ Jehofa ohun ti o yẹ ki oun ṣe a si fun ni itọni lati gbéjà dide sí i. Ni ṣiṣegbọran si ọrọ Jehofa, Dafidi ṣẹgun ẹgbẹ ọmọ-ogun Filisitini alagbara naa ni delẹdelẹ ni Baali-Perasimu. Ṣugbọn awọn Filisitini ko gba pe a ṣẹgun wọn. Laipẹ wọn pada wa lati ṣeparun ti wọn si piyẹ́ pupọ sii ni pẹtẹlẹ titẹju ti Refeimu, Dafidi lẹẹkan sii beere fun itọsọna lọdọ Jehofa.

2 Lọ́tẹ̀ yii a sọ fun pe ki o kó ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ lọ si apa-ẹhin awọn Filisitini. Jehofa sọ pe: “Nigba ti iwọ ba gbọ iro ẹsẹ lori awọn [“igbo,” NW] bákà naa, nigba naa ni iwọ yoo si yara, nitori pe nigba naa ni Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo jade lọ ni iwaju rẹ, lati kọ lu ogun awọn Filisitini.” Iyẹn si ni ohun ti o ṣẹlẹ. Dafidi duro titi ti Jehofa fi pese iro ẹsẹ lori awọn igbo bákà—boya nipasẹ ìjì lile kan. Lẹsẹkẹsẹ, Dafidi ati ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ tọ kúṣọ́ jade lati ibi ti wọn fara pamọ si wọn si kọlu awọn Filisitini ti wọn ti ni ipinya ọkan, ni ṣiṣẹgun wọn pẹlu ìpakúpa ńláǹlà. Awọn oriṣa isin tí awọn ara Filisitini naa fi silẹ gbalaja lori pápá ija ogun naa ni wọn kojọ papọ ti wọn si parun.—2 Samuẹli 5:17-25; 1 Kironika 14:8-17.

3. Eeṣe ti iṣe ajeji Jehofa fi jẹ eyi ti awọn Juu ni ọjọ Aisaya lọkan ifẹ si, eesitiṣe ti o fi nilati jẹ eyi ti Kristẹndọm ode oni nilati lọkan ifẹ si?

3 Eyi jẹ iṣẹ àràmàǹdà kan, iṣẹ ajeji kan, ti Jehofa ṣaṣepari rẹ lodi si awọn Filisitini nitori ọba rẹ ẹni ami-ororo. Iṣe pipẹtẹri yii jẹ eyi ti a lọkan ifẹ si ni pataki nitori pe wolii naa Aisaya kilọ pe Jehofa yoo ṣe ohun kan ti o lagbara ti o si ṣajeji bẹẹ pẹlu si awọn ọ̀mutipara nipa tẹmi ti Juda. Nitori eyi, awọn aṣaaju isin alaiṣootọ ti ọjọ Aisaya gbọdọ fiyesi. Kristẹndọm ode oni pẹlu gbọdọ fiyesi nitori pe ohun ti o ṣẹlẹ si Juda jẹ awokọṣe kan fun kàdárà Kristẹndọm ni aṣẹhinwa-aṣẹhinbọ.

“Akete Kuru Ju”

4, 5. (a) Bawo ni Aisaya ṣe ṣapejuwe lọna ṣiṣe kedere ipo alaituni lara awọn aṣaaju isin ti ọjọ rẹ? (b) Ki ni okunfa ipo aisi itura ti Kristẹndọm ode oni?

4 Lakọọkọ, Aisaya tudii aṣiiri otitọ naa pe awọn imulẹ adehun ninu eyi ti awọn ọmutipara nipa tẹmi ti igbaani gbọkanle jẹ itanjẹ kan, irọ́ kan. Lẹhin naa oun fihan lọna apejuwe kedere ipo ti ko tu ni lara ti awọn wọnni ti wọn nigbẹkẹle ninu irọ́ yẹn. Oun wi pe: “Nitori akete kuru ju eyi ti eniyan le na ara rẹ si, ati ìbora ko ni ìbò to eyi ti oun le fi bo ara rẹ.” (Aisaya 28:20) Ẹnikẹni ti o ba na ara rẹ tan gbalaja sori ibusun kan ti o ti kuru ju yoo ri pe awọn ẹsẹ oun yọ sita sinu otutu. Lọwọ keji ẹwẹ, ti o ba ṣẹ awọn orukun rẹ po lati mu ara rẹ ba kikuru ti ibusun naa kuru mu, aṣọ ibusun naa yoo ti ṣe tóóró ju ti apa ibi pupọ ni ara rẹ yoo si yọ sita sibẹsibẹ. Laika ohun ti o wu ki o ṣe si, diẹ ninu ara rẹ yoo ṣi yọ sita sinu otutu.

5 Iyẹn ni ipo naa, ki a sọ ọ lọna iṣapẹẹrẹ, ti awọn wọnni ti wọn wà ni ọjọ Aisaya ti wọn fi igbẹkẹle wọn sinu ibi isadi irọ́. Ohun ni o si tun jẹ ipo alaituni lara ti awọn wọnni lonii ti wọn fi igbẹkẹle wọn sinu ibi isadi irọ́ ti Kristẹndọm. Wọn wa ni ita ninu otutu, ki a sọ ọ́ lọna bẹẹ. Akoko kọ ni yii fun wiwa itura ninu awọn iṣeto aye fun alaafia ati ailewu. Labẹ òjìji awọn iṣe idajọ ti nbọ lati ọdọ Ọlọrun, ajọṣepọ pẹlu awọn alakooso oṣelu ki yoo pese itura gbigbadun mọni kankan fun Kristẹndọm.

Iṣe Ajeji Ti Jehofa

6. Bawo ni Jehofa yoo ti gbégbeesẹ lodi si Juda, bawo si ni oun yoo ṣe gbegbeesẹ lodi si Kristẹndọm?

6 Lẹhin ti o ti ṣapejuwe ni kedere ipo alaituni lara ti Jerusalẹmu alaiṣootọ ni ọjọ rẹ—ati ti Kristẹndọm alaiṣootọ ti ode oni—Aisaya nbaa lọ lati sọ pe: “Nitori Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo dide bii ti oke Perasimu, yoo si binu gẹgẹ bi ti afonifoji Gibioni, ki o ba le ṣe iṣẹ rẹ, Iṣẹ àrà rẹ; yoo si mu iṣe rẹ ṣe, ajeji iṣe rẹ.” (Aisaya 28:21) Bẹẹ ni, Aisaya kilọ pe, laipẹ Jehofa yoo dide gẹgẹ bi o ti ṣe ni Baali-Perasimu. Ṣugbọn lọtẹ yii oun yoo gbé igbesẹ lodi si awọn eniyan rẹ alainigbagbọ, oun yoo si ṣe gẹgẹ bi ìkún omi alaiṣee da duro kan ti o nyajade gbati ẹnu alafo kan ninu ìsédò kan ti nwolulẹ. Majẹmu Jerusalẹmu pẹlu iku ni a o fihan pe o jẹ aláìgbéṣẹ́. Ni ọna ti o jọra, Jehofa yoo gbegbeesẹ ni ọjọ iwaju ti ko jinna lodi si Kristẹndọm, oun yoo si ri pe gbogbo awọn adehun rẹ apani-bi-ọti pẹlu aye yii ko ni itumọ. Gbogbo eto-ajọ rẹ̀ gbigbooro ni a o fọ́ si wẹ́wẹ́ ti a o si fọn awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ka. Awọn ọlọrun eke rẹ̀ ni a o fina jó patapata.

7. Eeṣe ti awọn ète Jehofa nipa Juda fi jẹ eyi ti a pe ni “ajeji” ati “àràmàǹdà”?

7 Eeṣe ti Aisaya fi pe igbesẹ Jehofa lodi si Jerusalẹmu ni ajeji ati iṣẹ àràmàǹdà? O dara, Jerusalẹmu ni ibujoko ijọsin Jehofa ati ilu ọba ti a fororo yàn ti Jehofa. (Saamu 132:11-18) Nitori bẹ́ẹ̀, a ko tii pa á run nigba kankan ri. Tẹmpili rẹ ni a koi tii figba kan ri jó. Ile ọlọba ti Dafidi, ni gbara ti a gbe e kalẹ ni Jerusalẹmu, ni a ko tii gba ijọba lọwọ rẹ ri. Iru awọn nǹkan wọnni ko ṣee finurò. O jẹ àràmàǹdà lọna giga pe Jehofa yoo ronu lati gba awọn nǹkan bawọnyi laaye lati ṣẹlẹ.

8. Ikilọ wo ni Jehofa funni nipa igbesẹ àràmàǹdà rẹ ti o nbọ?

8 Ṣugbọn Jehofa funni ni ikilọ ti o ṣe kedere tó nipasẹ awọn wolii rẹ pe awọn iṣẹlẹ amunita giri yoo ṣẹlẹ. (Mika 3:9-12) Fun apẹẹrẹ, wolii Habakuku, ẹni ti o gbe ni ọrundun keje Ṣaaju Sanmani Tiwa sọ pe: “Ẹ wo inu awọn keferi, ki ẹ si wò ó, ki háà ki o ṣe yin gidigidi: nitori ti emi yoo ṣe iṣẹ kan ni ọjọ yin, ti ẹ ki yoo si gbagbọ, bi a tilẹ sọ fun yin. Nitori pe, wò ó, emi ngbe awọn ara Kaldia dide, orilẹ-ede ti o koro, ti o si wára, yoo rin ìbú ilẹ naa ja, lati ni ibugbe wọnni ti kii ṣe tiwọn. Wọn ni ẹru, wọn si foni laya.”—Habakuku 1:5-7.

9. Ni ọna wo ni Jehofa fi mu ikilọ rẹ̀ ṣẹ lodi si Jerusalẹmu?

9 Ni 607 B.C.E., Jehofa mu ikilọ rẹ ṣẹ. Lẹhin ti o ti gba ẹgbẹ ọmọ-ogun Babiloni laaye lati wa dojukọ Jerusalẹmu, oun yọnda fun wọn ki wọn pa ilu naa ati tẹmpili rẹ̀ run. (Idaro 2:7-9) Ju bẹẹ lọ, o gba Jerusalẹmu laaye lati di eyi ti a parun lẹẹkeji. Eeṣe? O dara, lẹhin 70 ọdun ni igbekun, awọn Juu ti wọn ronupiwada pada lọ si ilẹ ibilẹ wọn, ati ni aṣẹhinwa-aṣehinbọ tẹmpili miiran ni a kọ si Jerusalẹmu. Bi o ti wu ki o ri, lẹẹkan sii, awọn Juu sú lọ kuro lọdọ Jehofa. Ni ọrundun kin-inni Sanmani Tiwa, Pọọlu fa awọn ọrọ Habakuku yọ fun awọn Juu ni ọjọ rẹ̀, ti o ntipa bayii nṣekilọ pe asọtẹlẹ yii yoo ni ifisilo ọjọ iwaju kan. (Iṣe 13:40, 41) Jesu funraarẹ lọna pato ti kilọ pe Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ yoo di eyi ti a parun nitori aini igbagbọ ni iha ọdọ awọn Juu naa. (Matiu 23:37-24:2) Awọn Juu ọrundun kin-inni wọnni ha kọbiara sii bi? Bẹẹkọ. Gẹgẹ bi awọn babanla wọn, ikilọ Jehofa ni wọn ṣátì patapata. Nitori eyi, Jehofa tun ṣe ajeji iṣẹ rẹ. Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ ni a parun ni 70 C.E. nipasẹ ẹgbẹ ọmọ-ogun Roomu.

10. Bawo ni Jehofa yoo ṣe gbe igbesẹ lodi si Kristẹndọm ni ọjọ iwaju ti ko jinna?

10 Eeṣe, nigba naa, ti ẹnikẹni fi gbọdọ ronu pe Jehofa ki yoo ṣe ohun kan ti o farajọra ni akoko tiwa? Otitọ naa ni pe, oun yoo ṣi mu ete rẹ ṣẹ bi o tilẹ jẹ pe o dabi ẹni pe o ṣajeji ti o si jẹ àràmàǹdà si awọn oniye meji. Lọ́tẹ̀ yii, ohun ti yoo gbe igbesẹ le lori yoo jẹ Kristẹndọm, eyi ti, gẹgẹ bi Juda igbaani, o sọ pe oun njọsin Ọlọrun ṣugbọn ti o ti di oniwa ibajẹ rekọja iwosan. Nipasẹ Dafidi Titobiju rẹ, Kristi Jesu, Jehofa yoo de sori awọn “Filisitini” Kristẹndọm ni wakati kan ti wọn ko foju sọna fun. Oun yoo mu iṣẹ àràmàǹdà rẹ̀ ṣe de ori pipa ràlẹ̀rálẹ̀ aṣẹku eto-igbekalẹ Kristẹndọm rẹ ráúráú.—Matiu 13:36-43; 2 Tẹsalonika 1:6-10.

Ikilọ Nipa Iṣe Jehofa

11, 12. Bawo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe kilọ nipa awọn idajọ Jehofa ti nbọ wa?

11 Fun ọpọlọpọ ọdun, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti kilọ nipa iṣe idajọ ti nbọ yii lati ọdọ Jehofa. Wọn ti tọka jade pe iparun Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ̀ ni 607 B.C.E. ati lẹẹkan sii ni 70 C.E. jẹ awọn ikilọ alasọtẹlẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ si Kristẹndọm. Siwaju sii, wọn ti ṣaṣefihan pe Kristẹndọm, nitori ipẹhinda rẹ̀, ti di apakan ilẹ-ọba isin eke agbaye, Babiloni Nla. Nitori eyi, awọn idajọ Ọlọrun lori Babiloni Nla ni a o fi bẹ Kristẹndọm wo ni pataki, niwọn bi oun ti jẹ apa ti o jẹbi julọ ninu àjọ ẹgbẹ Satani yẹn.—Iṣipaya 19:1-3.

12 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti tọka si awọn ikilọ alasọtẹlẹ ti Bibeli pe ni akoko yiyẹ ti Jehofa, awọn àlè oloṣelu ti Babiloni Nla yoo yiju pada sii. Ni fifi iwo mẹwaa ati ẹranko ẹhanna alawọ rirẹdodo kan ṣapẹẹrẹ awọn wọnyi, Iṣipaya kilọ pe: “Ati iwo mẹwaa ti iwọ ri, ati ẹranko naa, awọn wọnyi ni yoo korira agbere [Babiloni Nla] naa wọn yoo si sọ ọ́ di ahoro ati ẹni ìhòhò, wọn o si jẹ ẹran ara rẹ, wọn yoo si fi ina sun ún patapata.” (Iṣipaya 17:16) Kristẹndọm onisin ni a o sun ti a o si parun papọ pẹlu gbogbo awọn isin eke yooku. Eyi yoo jẹ ajeji iṣe Jehofa, iṣẹ àràmàǹdà rẹ fun ọjọ wa.

13. Bawo ni ihuwa pada si awọn ikilọ Jehofa lonii ṣe jọra si ohun ti Aisaya doju kọ?

13 Nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ba njiṣẹ ikilọ ajalu ti nbọ yii, wọn saba maa nṣalabaapade ẹ̀rin ẹlẹ́yà. Awọn eniyan maa nṣekayeefi nipa ẹni ti wọn ro pe wọn jẹ ti wọn fi nsọ iru awọn nǹkan bẹẹ. Kristẹndọm dabii eyi ti o fẹsẹ mulẹ gidi gan an, ti o ti fidi mulẹ daradara. Họwu, awọn diẹ nimọlara pe ipo rẹ tubọ nsunwọn siwaju sii ni. Awọn ijọba kan ti wọn ti ńtẹ̀ ẹ́ loriba tẹlẹri ti yọnda ominira igbeṣẹṣe ti o pọ sii fún un laipẹ yii. Niti tootọ, bi o ti wu ki o ri, Kristẹndọm gbọdọ kọbiara si imọran Aisaya: “Njẹ nitori naa, ẹ maṣe jẹ ẹlẹgan, ki a ma baa sọ ide yin di lile; nitori emi ti gbọ iparun lati ọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] , awọn ọmọ-ogun wa, ti o si ti pinnu lori gbogbo ilẹ.”—Aisaya 28:22; 2 Peteru 3:3, 4.

14. Bawo ni ide Kristẹndom ṣe di eyi ti o tubọ le ti o si fún pinpin sii?

14 Ninu apa ti o pọ̀ julọ, Kristẹndọm yoo maa ba a niṣo lati doju ija kọ Ọba naa ati Ijọba naa. (2 Tẹsalonika 2:3, 4, 8) Lẹsẹ kannaa, bi o ti wu ki o ri, awọn ide wọn yoo tubọ maa le ti yoo si maa fún pọ̀ pinpin sii. Lede miiran, iparun rẹ yoo tubọ maa daju siwaju ati siwaju sii. Jehofa ki yoo yipada kuro ninu ipinnu rẹ̀ lati mu ki a pa Kristẹndọm run bi oun ko ti yi pada ninu ipinnu rẹ̀ lati yọnda fun iparun Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ̀ ni 607 B.C.E.

“Ẹ Ti Inu Rẹ Jade”

15. Ki ni ọna asala ti o ṣi silẹ fun awọn eniyan ọlọkan aya titọ?

15 Bawo ni ẹnikan ṣe le yèbọ́ lọwọ kàdárà Kristẹndọm? Pada sẹhin lọhun ni awọn ọjọ Isirẹli, Jehofa ran awọn wolii oluṣotitọ lati pe awọn ọlọkan otitọ pada wa sinu ijọsin mimọgaara. Lonii, oun ti gbe awọn Ẹlerii rẹ dide ti iye wọn nlọ si ọpọ araadọta ọkẹ nisinsinyi, fun ete kan ti o fara jọra pẹlu eyi. Wọn fi aiṣojo tudii aṣiiri ipo oku nipa tẹmi ti Kristẹndọm. Ninu ṣiṣe bẹẹ, wọn fi iṣotitọ ṣe gbohùn gbohùn awọn ọrọ ikede ti o dabii iyọnu ti awọn iro ipe kàkàkí angẹli ninu Iṣipaya ori 8 ati 9. Siwaju sii, wọn ti fi taápọn taápọn polongo igbani niyanju ti a ṣakọsilẹ rẹ ninu Iṣipaya 18:4 pe: “Ẹ ti inu rẹ jade, ẹyin eniyan mi, . . . ki ẹ ma ba ṣalabaapin ninu ẹṣẹ rẹ̀, ki ẹ ma ba si ṣe gba ninu iyọnu rẹ.” “Rẹ” ti a tọka si nihin in ni Babiloni Nla, ilẹ ọba isin eke agbaye, eyi ti Kristẹndọm jẹ mẹmba aṣiwaju julọ rẹ.

16. Ni ọna wo ni araadọta ọkẹ ti gba yèbọ́ kuro ninu isin eke?

16 Lati 1919, ati ni pataki julọ lati 1922, ogunlọgọ awọn eniyan oninu tutu ti wọn tubọ npọ sii ti dahun pada si igbani niyanju yẹn, ti wọn si kọ Babiloni Nla silẹ. Lakọọkọ awọn ẹgbẹẹgbẹrun, lẹhin naa ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun, ati bayii araadọta ọkẹ ti ya ara wọn sọtọ kuro ninu isin eke, paapaa julọ Kristẹndọm ti wọn si ti yèbọ́ wa sinu ijọsin mimọgaara. (Aisaya 2:2-4) Wọn mọ pe kiki nipa titipa bayii fi Babiloni Nla silẹ ni wọn fi le yẹra fun jijiya lọwọ awọn iyọnu ti nbọ lori rẹ̀, eyi ti yoo yọrisi iparun rẹ nigba ti akoko ba to fun iṣẹ àràmàǹdà Jehofa lati de aṣepari.

17, 18. Bawo ni Jehofa ṣe di ade ọsọ ati ẹwa ogo fun awọn eniyan rẹ̀?

17 Wolii Aisaya ṣapejuwe ipo alayọ awọn wọnni ti wọn mu iduro wọn fun ijọsin mimọgaara. Oun wi pe: “Ni ọjọ naa ni Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ-ogun yoo jẹ ade ogo, ati ade ẹwa fun iyoku awọn eniyan rẹ̀, ati ẹmi idajọ fun awọn ẹni ti o jokoo ni idajọ, ati agbara fun awọn ti o lé ogun pada si ibode.”—Aisaya 28:5, 6.

18 Nitori iduro ṣinṣin wọn ti otitọ, Jehofa ní ade ogo alaileeku fun awọn mẹmba ẹni ami-ororo ti ẹgbẹ ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu naa. Eyi ti jẹ otitọ ni pataki lati 1926 wa. Ni ọdun yẹn itẹjade January 1 ti Ile-Iṣọ Naa tẹnumọ aini ṣiṣekoko naa lati gbe orukọ Jehofa ga ninu ọrọ-ekọ kan ti nrunisoke ti o ni akọle naa “Ta Ni Yoo Bọla Fun Jehofa?” Lati igba naa wa, awọn Kristian ẹni ami-ororo ti kede orukọ yẹn kari aye ju ti igbakigbari lọ. Ni 1931 wọn tubọ wa di awọn ti a da mọ yatọ timọtimọ pẹlu Jehofa nipa titẹwọ gba orukọ naa Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ju bẹẹ lọ, ogunlọgọ nla ti agutan miiran ti jade pẹlu lati inu Kristẹndọm ati iyooku Babiloni Nla. Awọn wọnyi pẹlu ti fi ọ̀yàyà tẹwọ gba orukọ Ọlọrun. Ki ni iyọrisi rẹ? Jehofa funraarẹ—kaka ti iba fi jẹ ominira orilẹ-ede alaiwa pẹ́ titi—ti jẹ ade ogo ati ẹwa onitanna fun eyi ti o fẹrẹẹ to araadọta ọkẹ lọna mẹrin lọ awọn eniyan ni ohun ti o ju 212 ilẹ ati awọn erekuṣu okun. Ẹ wo ọla tí awọn wọnyi ní lati jẹ orukọ Ọlọrun alaaye tootọ kan ṣoṣo naa!—Iṣipaya 7:3, 4, 9, 10; 15:4.

‘Lori Rẹ Ni Ẹmi Jehofa Yoo Bà Lé’

19. Ta ni ẹni naa ti o jokoo ninu idajọ, bawo si ni Jehofa ṣe di ẹmi idajọ fún un?

19 Si Jesu, “ẹni ti o jokoo ni idajọ,” Jehofa ti di “ẹmi idajọ.” Nigba ti Jesu wà lori ilẹ-aye, o kọ̀ lati jẹ ki ẹmi ajọṣepọ aye apani bi ọti bori oun. Lonii, gẹgẹ bi Ọba tí Jehofa ti gbé gun ori itẹ, o kún fun ẹmi mimọ, eyi ti o ndari rẹ lati maa ṣe awọn ipinnu ariran ri iwaju kedere, ti o wà deedee. Ninu Jesu ni asọtẹlẹ naa ti ni imuṣẹ: “Lori rẹ ni ẹmi Jehofa yoo si bà lé, ẹmi ọgbọn ati oye, ẹmi igbani nimọran ati agbara, ẹmi imọ ati ibẹru Jehofa.” (Aisaya 11:2, NW) Nitootọ, nipasẹ Jesu, Jehofa “yoo fi idajọ ododo ṣe okun iwọn ati ododo ṣe ohun eelo imutẹju dọgba.” (Aisaya 28:17, NW) Nigba ti awọn ọta ti o ti mutipara nipa tẹmi yoo di títẹ̀rẹ́ mọ́lẹ̀ ninu iparun, idajọ-ododo ni a o ṣe fun orukọ mimọ Jehofa ati ipo ọba alaṣẹ agbaye rẹ.

20, 21. Ni ọna wo ni awọn ọrọ Aisaya 28:1-22 ṣe nipa lori rẹ?

20 Ẹ wo itumọ titobilọla, nigba naa ti asọtẹlẹ Aisaya ori 28 ni funwa lonii! Bi a ba yago patapata kuro fun awọn ọmuti para nipa tẹmi ti Kristendọm ti a si tòrò pinpin mọ ijọsin mimọgaara, a o daabo bo wa nigba ti Jehofa ba ṣe ajeji iṣe rẹ ati iṣẹ àràmàǹdà rẹ. Bawo ni inu wa ti dùn tó lati mọ eyi! Bawo ni a si ti layọ tó nigba ti a ba ronu siwa sẹhin pe nigba ti awọn nǹkan wọnyi ba ṣẹlẹ, olukuluku lẹnikọọkan ni a o fipa mu lati mọ pe Jehofa ẹgbẹ awọn ọmọ ogun ti gbegbeesẹ nitori awọn eniyan rẹ ati fun idalare tirẹ funraarẹ nipasẹ Jesu Kristi!—Saamu 83:17, 18.

21 Nitori naa njẹ ki gbogbo awọn Kristain ojulowo maa baa niṣo laiṣojo lati kilọ nipa awọn iṣe ajeji Jehofa. Jẹ ki wọn tẹpẹlẹ mọ ọn ni sisọ nipa iṣẹ àràmàǹdà rẹ̀. Bi wọn ti nṣe bẹẹ, jẹ ki wọn pokiki fun gbogbo eniyan pe ireti wa diduro gbọnyin wà ninu Ijọba Ọlọrun labẹ Ọba rẹ ti a ti gbé gun ori ìtẹ́. Njẹ ki itara, ipinnu, ati iduro ṣinṣin wọn ṣeranwọ si iyin ainipẹkun fun Ọlọrun wa olodumare, Jehofa.—Saamu 146:1, 2, 10.

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Eeṣe ti awọn Kristẹndọm fi wà ni ipo alaituni lara?

◻ Ki ni ohun ti Jehofa pete fun Jerusalẹmu, eeṣe ti eyi si fi jẹ “ajeji” ati “àràmàǹdà”?

◻ Ikilọ wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti kede ti o niiṣe pẹlu Kristẹndọm, ki si ni ihuwa pada ti wọn ti ṣalabaapade?

◻ Bawo ni awọn eniyan ṣe le yèbọ́ kuro ninu kadara Kristẹndọm?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Jehofa yoo tun gbe awọn igbesẹ ajeji rẹ̀, lọ́tẹ̀ yii lodi si Kristẹndọm

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́