‘Gbigbe Pẹlu Isunmọle Ọjọ Jehofa ni Ọkan’
GẸGẸ BI A TI SỌ Ọ LATI ẸNU LYLE REUSCH
LATI inu iranti mi akọkọ julọ, igbesi-aye idile wa rọ̀gba yika igbagbọ lilagbara ninu aye titun ododo ti nbọ. Iya ati baba mi yoo ka lati inu Bibeli fun awa ọmọ nipa ‘aye titun ati ọrun titun naa’ ati nipa ‘maluu ati beari ti njumọ jẹ pọ, kininun ti njẹ koriko bi maluu, ati ọdọmọkunrin kekere ti ndari wọn.’ Wọn mu ki o jẹ gidi gan an, mo finu woye araami lati jẹ ọdọmọkunrin kekere yẹn.—2 Peteru 3:11-13; Aisaya 11:6-9.
Ni awọn ọdun 1890 baba mi agba, August Reusch, kẹkọọ awọn otitọ Bibeli ipilẹ nipasẹ iwe kikọ si Charles T. Russell. O waasu jinna ni ile ati ayika rẹ ni Ipinlẹ Ariwa Iwọ-oorun Canada, tii ṣe Yorkton, Saskatchewan, nisinsinyi. Leralera o fun awọn ọmọkunrin rẹ ni imọran pe: “Ẹyin ọdọmọkunrin, ẹ maa ṣọ́ 1914!” Idaniloju naa pe ọjọ Jehofa sunmọle pẹkipẹki ru baba mi soke pẹlu imọlara kanjukanju ti nbaa lọ jalẹ akoko igbesi-aye rẹ iyẹn si ti di ọna igbesi-aye fun mi.
Iya ati Baba jẹ apẹẹrẹ pipe niti ẹmi alejo ṣiṣe. Awujọ ikẹkọọ Bibeli ti Kilaasi awọn Akẹkọọ Bibeli Saskatoon, Saskatchewan, npadepọ deedee ninu ile wa. Awọn ojiṣẹ arinrin ajo (ti a npe ni awọn arinrin ajo) maa nde sile wa lemọlemọ. Arakunrin mi, Verne, ati arabinrin mi, Vera, ati emi janfaani nipa tẹmi. Imọlara pe hin-iṣẹ Ijọba naa jẹ otitọ ati aini kanjukanju lati sọ fun awọn miiran nipa rẹ wà nigba gbogbo. (Matiu 24:14) Emi ko mọ pe ni awọn ọdun ehin ọla emi yoo lo apa ti o pọ julọ ninu igbesi-aye mi ni biba iṣẹ awọn arinrin ajo mimọ wọnyi lọ nipa ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Ni 1927, Baba mi ko idile wa lọ si Berkeley, California. Lẹhin naa, lakooko ti iwolulẹ ọrọ aje gogò ni 1933, mo kẹkọọ yege kuro ninu ile-ẹkọ giga. Arakunrin mi, Verne, ati emi ka ara wa si arinnakore lati ri iṣẹ ni ile iṣẹ ẹrọ ti Kọmpini Ọkọ Ayọkẹlẹ Ford ni Richmond, California. Bi o ti wu ki o ri, ni ọjọ kan ni akoko iruwe ti 1935, mo ronu siwa sẹhin pe: ‘Bi emi ba gbọdo ṣiṣẹ kára, emi le ṣiṣẹ kára bakan naa fun ohun ti o tọ́.’ Ni ọjọ yẹn mo kọwe fiṣẹ silẹ, ati ni ọjọ keji mo kọwe fun iwe iwọṣẹ lati sin ni Bethel, orile-iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ni Brooklyn, New York. Lẹhin lilọ si apejọpọ amunilọkanyọ naa ni Washington, D.C., ni June 1935, a gba mi fun iṣẹ-isin Bethel.
Iṣẹ-isin Bethel
Nathan Knorr, alaboojuto ile iṣẹ ẹrọ, fun mi niṣẹ bibojuto ile. Emi nikan ni mo nṣiṣẹ. Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ọlọjọ ori 20, mo nimọlara jijẹ ẹni pataki gan an. Mo le rin falala ninu ile iṣẹ ẹrọ naa, ko sì sí ẹni ti o bi mi leere ohun ti mo nṣe. Arakunrin Knorr mọriri ọna ti mo ngba ṣiṣẹ mi, ṣugbọn o róye iṣoro kan nipa iṣesi. O ntẹramọ ṣiṣiṣẹ le mi lori ki nba le mu ẹmi irẹlẹ dagba.
Bi o ti wu ki o ri, o pẹ diẹ ki nto mọ pe Arakunrin Knorr ngbiyanju nitootọ lati ran mi lọwọ. Nitori naa mo tọrọ aforiji fun iṣesi mi mo si sọ ipinnu mi lati tubọ ṣe daradara jade. Iyẹn ni ibẹrẹ ipo ibatan alakooko gigun, ati ọlọyaya pẹlu Arakunrin Knorr, ẹni ti o di aarẹ Watch Tower Society kẹta ni 1942.
Yatọ si ṣiṣe iṣẹ atunṣe, mo kọ́ lati mọ bi a ṣe nlo ọpọjulọ awọn ẹrọ ninu ile idipọ iwe tabi lati ṣiṣẹ lori wọn. Laipẹ laijina mo nṣiṣẹ ọfiisi, iwe kikọ ati fifi awọn iṣẹ ti a kọwe beere fun ranṣẹ nipasẹ ile-ẹrọ naa. Igba iruwe ati igba ẹẹrun 1943 jẹ awọn akoko ti ọwọ dí ti o si dunmọni ni pataki. Ayé wa laaarin Ogun Agbaye Keji, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa si nfarada ìfòòró, ifaṣẹ ọba muni, ati idajọ ẹwọn lori oniruuru awọn ẹsun ti ko ba idajọ ododo mu. Ni 1940, Ile-ẹjọ Giga U.S. ti paṣẹ pe awọn ile-ẹkọ le sọ ọ di dandan fun awọn ọmọ ile-ẹkọ lati kí asia. Eyi ru igbi iwa-ipa dide ni ipinlẹ 44 ninu 48. Awọn ọmọ Ẹlẹrii ni a le jade kuro ninu ile-ẹkọ, awọn obi ni a faṣẹ ọba mu, awọn awujọ eniyankeniyan si lé awọn Ẹlẹrii jade kuro ni ilu. Awọn ẹnikọọkan ni a yinbọn pa, awọn miiran ni a da ọda si lara ti a si to iyẹ mọ ọn.
Gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nja pada ni awọn ile-ẹjọ, ọpọ iṣẹ iwe iru bii iwe aṣẹ ile ẹjọ, awọn iwe ipẹjọ agbẹjọro, ati awọn iwe akọsilẹ awọn oṣiṣẹ Society ti nbojuto ofin pese wa sori tabili mi fun titẹ. Gbogbo wa nṣiṣẹ fun ọpọlọpọ wakati aṣekun lati lé akoko ti a dá bá. Iyọrisi awọn ipinnu Ile-ẹjọ Giga ni May ati June 1943—nigba ti a pinnu ọran 12 ninu 13 ni itilẹhin awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa—ti di apakan akọsilẹ itan ofin. Mo kun fun imoore lati ṣakiyesi funraami bi Jehofa ti ṣi ọna silẹ ninu gbigbeja ati fifidi ihinrere mulẹ lọna ofin.—Filipi 1:7.
Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun
Ni awọn ọna kan a ko mura wa silẹ daradara tó ni awọn ọjọ wọnni lati mu iṣẹ takuntakun ti a sọ tẹlẹ ni Matiu 24:14 ṣẹ, tii ṣe, ‘lati waasu ihinrere Ijọba Ọlọrun ni gbogbo ilẹ-aye ṣaaju ki opin ki o to de.’ Arakunrin Knorr, gẹgẹ bi aarẹ Society, ri aini naa fun itolẹsẹẹsẹ imọ ẹkọ kan. Papọ pẹlu awọn mẹmba idile Bethel miiran ti wọn jẹ ọkunrin, mo gba ikesini lati forukọ silẹ ninu “Idalẹkọọ Giga ninu Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun.” Eyi ni aṣẹhinwa-aṣẹhinbọ dagba soke di ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun, eyi ti o ti wa lẹnu iṣẹ ninu ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati 1943.
A pade ninu yara ipade idile Bethel ni irọlẹ ọjọ Monday, February 16, 1942, Arakunrin Knorr si funni ni ọrọ itọni akọkọ. Koko ọrọ rẹ ni “Awọn Iwe Afọwọkọ Bibeli.” Arakunrin T. J. Sullivan ni alaboojuto ile-ẹkọ o si fun wa ni imọran lati ran wa lọwọ lati sunwọn si. Laipẹ laijina a fun mi ni iṣẹ yii ti alaboojuto ile-ẹkọ Bethel, eyi ti mo ka si anfaani ńláǹlà kan. Ṣugbọn o tun jẹ akoko kan fun ibaniwi.
Mo ti le koko ju mo si ṣaini ọ̀wọ̀ ti o tọna ni fifun arakunrin agbalalagba kan nimọran, nitori naa Arakunrin Knorr sọ fun mi lai fọrọ sabẹ ahọn sọ: “Ko si ẹni ti o nifẹẹ si nigba ti o ba nfi gbogbo bi o ḍe jẹ han kaakiri.” Nigba ti o ṣalaye koko rẹ kedere tan ti eti mi si ti kun fun ọ̀rọ̀, oju rekete alawọ ilẹ ti Arakunrin Knorr walẹ. Ni ohùn tutupẹlẹ kan, o ka Saamu 141:5: “Jẹ ki olododo ki o lu mi; iṣeun ni yoo jasi: jẹ ki o si ba mi wi; ororo daradara ni yoo jasi, ti ki yoo fọ mi lori.” Mo ti lo ọrọ ẹsẹ Bibeli yẹn ni ọpọlọpọ igba nigba ti o ba di ẹru iṣẹ mi lati fun awọn ẹlomiran ni itọni atọnisọna.
Ṣaaju ibẹrẹ ilé-ẹ̀kọ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ Iṣakoso Ọlọrun, diẹ ninu wa ni a ní anfaani lati sọ ọpọ asọye itagbangba. Nigba ti Arakunrin Rutherford ku, Arakunrin Knorr ṣiṣẹ kára lati mu agbara isọrọ rẹ dagba. Yara mi ní Bethel wa taraata ni isalẹ ibi ti o ngbe, mo si le gbọ ti nṣe ifidanrawo ọrọ sisọ rẹ. Niti gidi ni aimọye igba, oun ka ọrọ asọye itagbangba naa “Alaafia—Yoo Ha Tọjọ Bi?” jade ketekete, eyi ti o sọ ni apejọpọ Cleveland ni 1942.
Loju Ọna
Lẹhin ti mo ti ṣiṣẹsin fun ọdun 13 ni Bethel, Arakunrin Knorr pinṣẹ yan fun mi lati ṣiṣẹsin ni papa gẹgẹ bi alaboojuto agbegbe. Ni fifun mi ni itọni lori isẹ ti a ṣẹṣẹ yan fun mi, o wipe: “Lyle, iwọ ni anfaani nisinsinyi lati ṣakiyesi funraarẹ ọna ti Jehofa gba nba awọn eniyan rẹ lo gan an.” Pẹlu eyi lọkan ati apoti ifalọwọ meji ni ọwọ, mo bẹrẹ iṣẹ igbesi-aye mi gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo ni May 15, 1948. Ṣaaju ki nto bẹrẹ iṣẹ agbegbe, mo ṣiṣesin gẹgẹ bi alaboojuto ayika fun oṣu melookan.
Kọ́ḿpìnì, tabi ijọ akọkọ, ti mo bẹwo jẹ ti abuleko kekere kan ni Waseca, Minnesota. Mo ti kọwe ṣaaju si Dick Cain, iranṣẹ ijọ (gẹgẹ bi a ti npe alaboojuto oluṣalaga nigba naa) lati pade mi nidiikọ oju-irin. Oun jẹ aṣaaju-ọna akanṣe kan, ati lati din inawo kù, o ṣẹṣẹ kó kuro ninu yara rẹ ti o háyà, nibi ti o ti lo igba otutu sinu ibugbe rẹ igba ẹrun, atibaba kan. Bi o ti wu ki o ri, Minnesota kii ṣe akoko oru gan an ni oṣu May! Ni alẹ yẹn, ti mo ngbọn ninu atibaba, mo ṣe kayefi bi ọna igbesi-aye yii ba bámi lara mu lọna ti ẹda. Otutu nla dà bomi ti o gba ọpọlọpọ ọsẹ, ṣugbọn mo yè é bọ́.
Ni awọn ọdun akọkọbẹrẹ wọnni nigba ti mo ba nbẹ awọn ijọ ati ayika oriṣiriṣi wò, mo nde sinu ile awọn ara, mo so ngbe laini dúkìá. Mo niriri oriṣiriṣi ile gbigbe, ti o ni ninu sisun lori ilẹ ile idana, lori awọn aga irọgbọku inu yara gbigbe, ninu iyara ori àjà ti ko ni ferese. Nigba miiran mo gbe ninu awọn ile nibi ti ọkan lara mẹmba idile naa ti lodisi igbagbọ wa. Ni Wisconsin alaigbagbọ ọkọ kan foju simi lara ni gbogbo ọsẹ gẹgẹ bi mo ti nlọ ti mo si nbọ. Nigba ti o mutiyo wa sile ni alẹ ọjọ kan, mo gbọ́ ọ fínrín ti o nhalẹ lati “yinbọn lu lagbaja yẹn,” mo pari ero pe akoko tó lati lọ. Ṣugbọn awọn iriri alaitẹnilọrun ṣọwọn ni ifiwera o si wulẹ fi kún adùn iṣẹ ti a yan fun mi ni. Wọn jẹ ohun kan lati fi rẹrin-in lẹhin naa.
Mo Ri Alabakẹgbẹ Kan
Mo ranti rẹ daradara. Ni apejọ ayika kan ni Tiffin, Ohio, mo pade ọdọ ọmọge rirẹwa, ẹlẹ́yinjúẹgẹ́ kan, Leona Ehrman, ti o wa lati Fort Wayne, Indiana. Oun pẹlu ni a tọ́ dagba ninu igbagbọ Kristian o si ti jẹ aṣaaju-ọna oluṣotitọ fun ọdun melookan. Ririnrin-ajo lemọlemọ ko yẹ fun fifẹra sọna, ṣugbọn a ńgbúròó ara nipa kikọwe ranṣẹ. Lẹhin naa, ni 1952, mo beere pe, “Ṣe iwọ yoo gba?” Oun naa si wipe, “Bẹẹni, emi yoo gba!” Bẹẹ ni a si ṣe. A ṣegbeyawo. Wọn ti saba maa nbeere lọwọ wa idi ti awa ko fi ti farabalẹ sibikan ki a ni ile ati idile, ṣugbọn a sọ pe awa ni idile kan—awọn arakunrin, arabinrin, baba, ati iya ni awọn ipinlẹ ti o tó 44 nibiti a ti ṣiṣẹsin.—Maaku 10:29, 30.
Awọn kan ti beere pe, ‘Ṣe ko rẹ̀ yin nigba kankan ri ki ẹ si nimọlara bii pe ki ẹ fiṣẹ silẹ ni?’ Bẹẹni, o ju igba kan lọ. Ṣugbọn laaarin awa mejeeji, nigba ti o ba rẹ ẹnikan, ẹnikeji yoo gbe e dide. Ni igba kan mo tilẹ kọwe si arakunrin mi, Verne, ni bibeere lọwọ rẹ nipa bi o ba ṣeeṣe lati ṣiṣẹ pẹlu rẹ ninu iṣẹ ilé kíkùn rẹ̀. O dahun pada pe oun ti maa nfoju sọna si iyẹn nitori pe a ṣe timọtimọ gan an nigba ti a ndagba. Bi o ti wu ki o ri, o fun mi nimọran lati gbe ipinnu mi lori iwọn daradara. Lẹhin naa mo pe awọn ọrọ ti Arakunrin Knorr maa nsọ leralera fun awọn mẹmba idile Bethel wa sọkan pe: “Ko gba isapa pupọ lati fiṣẹ silẹ; o gba igboya ati iwatitọ lati rọ̀ mọ iṣẹ rẹ.” Iyẹn ṣì jẹ amọran rere sibẹ.
Ko si alabojuto arinrin-ajo ti o le rọ̀ mọ iṣẹ ti a yan fun un timọtimọ laisi aya kan ti o jẹ aduroṣinṣin ati atinilẹhin, gẹgẹ bi Leona ti jasi fun mi. Animọ iwa iṣesi olọyaya amárayá gágá rẹ igba gbogbo ninu awọn ijọ ti sọ ọ di ẹni ọwọn fun ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan. Ko rẹ mi rí ninu sisọ fun un bi mo ṣe nifẹẹ rẹ̀ tó. Eyi ti o dá mi loju pe, o ran an lọwọ lati rọ̀ mọ iṣẹ naa timọtimọ pẹlu.
Ijẹrii si Ibukun Jehofa
Lajori iṣẹ alaboojuto agbegbe rọgba yika apejọ ayika, nibi ti oun ti nṣiṣẹsin lọsọọsẹ gẹgẹ bi alaga, olubanisọrọ nigbangba, ati alaboojuto ilé-ẹ̀kọ́. Ibukun Jehofa lori iṣeto yii ni o han gbangba lati inu otitọ naa pe ninu ọgọrọọrun awọn apejọ ayika ti mo ti ni iṣẹ abojuto, ko si ọkanṣoṣo ti a ko ṣe. Lootọ, awọn kan wa ti a ṣedilọwọ fun, ṣugbọn ko si ọkan ti a wọgi le.
Ni Wooster, Ohio, ni igba iruwe 1950, gẹgẹ bi mo ti pe orin ipari ti ijokoo alẹ Saturday, awujọ eniyankeniyan ti wọn ju ẹgbẹrun kan awọn alatako gbarajọ lode ile eré ìtàgé nibi ti a ti nṣe apejọ naa. Awujọ eniyankeniyan naa ti ko ọpọlọpọ kíréètì ẹyin ti o ti bajẹ lọwọ lati jù u lù wa bi a ti nlọ. Nitori naa a foju diwọn ipo naa a si fa itolẹsẹẹsẹ naa gun pẹlu awọn orin, iriri, ati ọrọ asọye Bibeli alairotẹlẹ. Awọn Ẹlẹrii 800 wa ni jẹẹjẹẹ wọn si ni suuru.
Ni agogo meji oru, oju ọjọ ti tutu bi yinyin. Bi ẹni pe a nmura silẹ fun jijade, awọn olutọju ero gbe ifami ti a fi ntú omi pa ina jade wọn si bẹrẹ si fọ awọn ẹyin ti wọn ti balẹ sori pepele irinsẹ ti o wa lode. Awujọ eniyankeniyan naa gbarajọ lẹẹkan sii, ni fifi ibi ibudo ọkọ ti o lọ́ wọ́ọ́wọ́ ti o wa nitosi silẹ. Ṣugbọn igbesẹ awọn olubojuto ero jẹ lati dari wọn sibomiran, a si yọnda awọn ero naa wọọrọwọ nipasẹ ọna abajade ti o wa lẹhin. Gbogbo eniyan debi ọkọ ayọkẹlẹ wọn laisewu. Iṣedilọwọ awujọ eniyankeniyan ṣẹlẹ ni awọn apejọ Ohio miiran, ni Canton, Defiance, ati Chillicothe. Ṣugbọn iwa ipa awujọ eniyankeniyan ti npoora, bi awọn ipinnu Ile-ẹjọ Gigajulọ U.S. ni itilẹhin wa ti bẹrẹ sii nipa lori awọn eniyan alailofin.
Bi akoko ti nlọ iṣoro ilera mu ki iyipada pọndandan. Nitori naa ni agbedemeji awọn ọdun 1970, Society fi inurere yan mi lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto ayika ni agbegbe iha guusu California nibi ti awọn ijọ ti sunmọra pẹkipẹki ti awọn ohun relo itọju ilera si wa larọọwọto. Nigba ti awọn iṣẹ alaboojuto agbegbe ni irin ajo pupọ ati itọju ati abojuto ọpọlọpọ ayika ninu, awọn iṣẹ alaboojuto ayika wemọ ṣiṣeto awọn apejọ ayika ati yiyan awọn apa itolẹsẹẹsẹ funni ati ṣiṣe aṣedanrawo wọn. Ni afikun, awọn ile-ẹkọ iṣẹ-isin aṣaaju-ọna ni a nilati ṣeto ki a si bojuto. Nitori naa iṣẹ awọn alaboojuto arinrin-ajo, yala agbegbe tabi ayika, jẹ ọna igbesi-aye alakooko kikun, ti o ni ere.
Mo Nfojusọna Si Ọjọ Jehofa Sibẹ
Lati igba inu iranti mi akọkọ julọ ni nǹkan ti o ju 70 ọdun sẹhin, mo ti maa nnimọlara kanjukanju oniharagaga nigba gbogbo. Ninu ironu mi, Amagẹdọn maa nfigba gbogbo jẹ ọtunla. (Iṣipaya 16:14, 16) Bii baba mi, ati baba ti o ṣaaju rẹ̀, mo ti gbe igbesi-aye mi gẹgẹ bi apọsteli naa ti rọ ni, ‘fi wiwa nihin-in ọjọ Jehofa sọkan pẹkipẹki.’ Mo ti saba maa nwo ileri aye titun naa gẹgẹ bi ‘otitọ gidi bi a ko tilẹ ri.’—2 Peteru 3:11, 12; Heberu 11:1, NW.
Ifojusọna yii ti a ti fi simi lọkan lati igba ọmọde jojolo yoo ni imuṣẹ laipẹ. “Maluu ati beari yoo si jẹ pọ,” “kininun yoo si jẹ koriko bi maluu,” “ọmọ kekere yoo [si] maa dà wọn.” (Aisaya 11:6-9) Iru awọn ileri amunilọkanyọ bẹẹ ni a jẹrii si nipa awọn ọrọ Jesu si Johanu ni Iṣipaya 21:5: “Ẹni ti o joko lori itẹ ni si wipe, kiyesi, mo sọ ohun gbogbo di ọtun. O si wi fun mi pe, kọwe rẹ: Nitori ọrọ wọnyi ododo ati otitọ ni wọn.”