ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/1 ojú ìwé 19-24
  • “Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Ṣe Ni A Ṣe”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Ṣe Ni A Ṣe”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Rírí Òtítọ́ Bíbélì
  • Ìtẹ̀síwájú Nínú Òtítọ́
  • Yíyí Iṣẹ́ Àyànfúnni Padà
  • Ìgbésí Ayé Bẹ́tẹ́lì Nítumọ̀
  • Àǹfààní Ìmúgbòòrò Tí Mo Nípìn-ín Nínú Rẹ̀
  • Ẹ̀kọ́ Tí Mo Ti Kọ́
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ibi Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Gbé Mi Dé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Fífi Ìmọrírì Wo “Ilé Ọlọrun”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/1 ojú ìwé 19-24

“Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Ṣe Ni A Ṣe”

GẸ́GẸ́ BÍ GEORGE COUCH ṢE SỌ Ọ́

Lẹ́yìn tí a ti fi òwúrọ̀ ọjọ́ náà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé, alábàáṣiṣẹ́ mí mú búrẹ́dì méjì eléròjà nínú jáde. Nígbà tí a jẹ ẹ́ tán, mo fa sìgá kan yọ, mo fẹ́ mu ún. Ó béèrè pé: “Ó ti tó ọdún mélòó tí o ti wà nínú òtítọ́?” Mo fèsì pé: “Ìpàdé alẹ́ àná ní àkọ́kọ́ ti màá wá sí.”

A BÍ mi ní March 3, 1917, ní abúléko kan tí ó tó nǹkan bí 50 kìlómítà síhà ìlà oòrùn Pittsburgh, Pennsylvania, U.S.A., lẹ́bàá ìletò Avonmore. Ibẹ̀ ni àwọn òbí mi ti tọ́ èmi pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi mẹ́rin, àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin dàgbà.

A kò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà kan àwọn òbí mi máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n àwa ọmọ ṣì kéré nígbà tí wọn ti pa lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tì. Ṣùgbọ́n, a nígbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá, ìgbésí ayé ìdílé wa sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà pàtàkì tí ń bẹ nínú Bíbélì.

Ẹ̀kọ́ dídára jù lọ tí mo kọ́ lọ́dọ̀ àwọn òbí mi jẹ́ nípa ẹrù iṣẹ́—bí a ṣe lè tẹ́wọ́ gbà á àti bí a ṣe lè mójú tó o. Gbogbo ohun tí ìgbésí ayé abúléko jẹ́ nìyẹn. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé iṣẹ́ ni a ń fi gbogbo ọjọ́ ayé ṣe. A máa ń ṣeré ìnàjú tí ó gbámúṣé, irú bí jíju bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ àti baseball, a máa ń gẹṣin, a sì máa ń lúwẹ̀ẹ́. Owó wọ́n nígbà yẹn lọ́hùn-ún, síbẹ̀ oko dùn ún gbé. Ilé ẹ̀kọ́ oníyàrá kan ṣoṣo ni a lọ nígbà tí a wà nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, nígbà tí a sì wọ ilé ìwé girama, a kọjá sí ilé ẹ̀kọ́ tí ó wà nílùú.

Lálẹ́ ọjọ́ kan, èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan jọ ń rìn lọ. Ọ̀dọ́mọbìnrin òrékelẹ́wà kan jáde wá kí ọ̀rẹ́ mi. Ọ̀rẹ́ mi fi mí han Fern Prugh. Ìgbà tí gbogbo rẹ̀ yóò ṣẹnuure, àdúgbò ibi tí ilé ìwé wa wà ni ọmọbìnrin ọ̀ún ń gbé. Lọ́pọ̀ ìgbà tí mo bá ń kọjá lọ lójúde rẹ̀, Fern máa ń ṣe iṣẹ́ ilé níta. Ẹ̀rí hàn gbangba pé, òṣìṣẹ́ aláápọn ni, èyí sì wú mi lórí. A dọ̀rẹ́ ara wa, ìfẹ́ wọ̀ wá lọ́kàn, a sì ṣègbéyàwó ní April ọdún 1936.

Rírí Òtítọ́ Bíbélì

Kí ó tó di pé a bí mi, obìnrin àgbàlagbà kan wà tí àwọn aráàlú tí hùwà ìkà sí nítorí ìsìn rẹ̀. Màmá mi máa ń bẹ̀ ẹ́ wò lọ́jọọjọ́ Saturday nígbà tí ó bá ń lọ sí ṣọ́ọ̀bù. Màmá á gbá ilé rẹ̀ mọ́, á ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, ó ṣe bẹ́ẹ̀ títí obìnrin náà fi kú. Mo gbà pé Jèhófà bù kún Màmá nítorí inú rere púpọ̀ tí ó fi hàn sí obìnrin yìí, tí ó jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn.

Lẹ́yìn èyí, ọmọ àǹtí mi kú lójijì. Ṣọ́ọ̀ṣì kò tu àǹtí mi nínú, ṣùgbọ́n aládùúgbò rẹ̀ kan tí ó jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe bẹ́ẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ṣàlàyé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá kú fún un. (Jóòbù 14:13-15; Oníwàásù 9:5, 10) Èyí jẹ́ orísun ìtùnú ńláǹlà. Àǹtí mi, ẹ̀wẹ̀, bá Màmá sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde. Èyí ru ìfẹ́ Màmá sókè, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ó ṣì wà lọ́mọdé nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ ti kú, tí òun náà sì ń hára gàgà láti mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá kú. Ìrírí yẹn tẹ ìjẹ́pàtàkì lílo gbogbo àǹfààní tí a bá ní láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà mọ́ mi lọ́kàn.

Ní àwọn ọdún 1930, Màmá bẹ̀rẹ̀ sí fetí sílẹ̀ lówùúrọ̀ ọjọ́ Sunday sí ọ̀rọ̀ tí Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà, máa ń sọ lórí rédíò. Ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn, Àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ilé dé ilé níbi tí a ń gbé. Wọn yóò gbé ohun èlò agbóhùnjáde kékeré sílẹ̀ lábẹ́ igi tí ó ní ibòji, wọn yóò sì gbé ìwàásù Arákùnrin Rutherford sí i. Àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti gbà sílẹ̀ wọ̀nyẹn pẹ̀lú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Golden Age (tí a ń pè ní Jí! nísinsìnyí) mú kí iná ìfẹ́ Màmá máa jó lala.

Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ní ọdún 1938, a fi káàdì pélébé kan ránṣẹ́ sí àwọn tí ó san àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́, a pè wọ́n sí ìpàdé àkànṣe kan nínú ilé àdáni kan tí ó tó nǹkan bí kìlómítà 25 sí wa. Màmá fẹ́ lọ, nítorí náà, èmi àti Fern àti méjì lára àwọn arákùnrin mi bá a lọ. John Booth àti Charles Hessler, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ àsọyé fún àwa bí méjìlá. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àwùjọ tí yóò nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Kò sí ẹnì kan tí ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti bá wọn lọ, nítorí náà Arákùnrin Hessler yàn mí, ó sì béèrè pé, “Èé ṣe tí o kò fi bá wa lọ?” N kò mọ ohun tí wọ́n fẹ́ lọ ṣe gan-an, ṣùgbọ́n n kò lè ronú ìdí kankan tí n kò fi lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

A ṣiṣẹ́ ilé dé ilé títí di ọ̀sán, lẹ́yìn náà, Arákùnrin Hessler mú búrẹ́dì méjì eléròjà nínú jáde. A jókòó sórí pèpéle iwájú ṣọ́ọ̀ṣì, a bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ìgbà tí mo tó fa sìgá yẹn yọ ni Arákùnrin Hessler ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́ pé ìpàdé kan ṣoṣo ni mo tí ì wá rí. Ó ní òun yóò wá jẹ oúnjẹ alẹ́ ní ilé wa ní ọjọ́ náà, ó sì ní kí a ké sí àwọn aládùúgbò wa wá fún ìjíròrò Bíbélì. Lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́ ó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa, ó sọ àsọyé fún àwùjọ ẹlẹ́ni mẹ́wàá tí ó wá. Ó sọ fún wa pé ó yẹ kí a ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aládùúgbò wa kò fara mọ́ èyí, èmi àti Fern ṣètò láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ìtẹ̀síwájú Nínú Òtítọ́

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, èmi àti Fern jáde fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ẹ̀yìn ọkọ̀ ni a jókòó sí, a sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣáná sí sìgá ni nígbà tí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin yíjú sí wa, tí ó sì wí pé: “Mo mà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ ni pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mu sìgá.” Lójú ẹsẹ̀, Fern sọ sìgá rẹ̀ nù láti ojú fèrèsé ọkọ̀—mo fa tèmi tán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbádùn sìgá mímu, a kò tún fọwọ́ kan sìgá mọ́ láti ọjọ́ náà.

Lẹ́yìn ìrìbọmi wa ní ọdún 1940, èmi àti Fern wà ní ìpàdé kan níbi tí a ti kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ kan tí ó fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe iṣẹ́ ìwàásù ní àkókò kíkún, níṣìírí. Nígbà tí a ń darí sílé, arákùnrin kan béèrè pé: “Èé ṣe tí ìwọ àti Fern kò fi bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà? Kò sóhun tí ó dí yín lọ́wọ́.” A kò lè takò ó, nítorí náà a yọ̀ǹda ara wa. Mo fi ìwé ìfitónilétí ọlọ́gbọ̀n ọjọ́ sílẹ̀ níbi iṣẹ́ mi, a ṣi ṣètò láti ṣe aṣáájú ọ̀nà.

A béèrè ibi tí a óò ti sìn lọ́wọ́ Watch Tower Society, a sì ṣí lọ sí Baltimore, Maryland. Ilé kan wà fún àwọn aṣáájú ọ̀nà níbẹ̀, dọ́là mẹ́wàá sì ni owó ilé náà lóṣù kan. A ní owó díẹ̀ nípamọ́ tí a rò pé yóò tó wa lò dìgbà tí Amágẹ́dónì yóò jà. (Ìṣípayá 16:14, 16) Ó ṣe tán, èrò wa nígbà gbogbo ni pé Amágẹ́dónì ti dé tán. Nítorí náà, nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà, a ta ilé wa, a sì pa gbogbo nǹkan mìíràn tì.

A ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Baltimore láti ọdún 1942 di ọdún 1947. Àtakò sí iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ga ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn. Dípò tí a óò fi gbé ọkọ̀ wa lọ sílé àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, nígbà mìíràn a máa ń wọ ọkọ̀ ẹlòmíràn lọ síbẹ̀. Ìyẹn kò jẹ́ kí wọ́n bẹ́ táyà ọkọ̀ wa. Kò sí ẹni tó fẹ́ irú àtakò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n mo lè sọ pé ìgbà gbogbo ni a máa ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Àní, a máa ń fojú sọ́nà fún ìmóríyá díẹ̀ nínú ṣíṣe iṣẹ́ Olúwa.

Kò pẹ́ tí a fi ná gbogbo owó ọwọ́ wa tán. Táyà ọkọ̀ wa gbó, bẹ́ẹ̀ sì ni aṣọ àti bàtà wa. A ṣàìsàn fún ìgbà méjì tàbí mẹ́ta fún àkókò pípẹ́. Kò rọrùn láti máa bá a lọ, ṣùgbọ́n a kò ronú láti pa ohun tí a ń ṣe tì rárá. A kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rárá. A túbọ̀ mú ìgbésí ayé wa rọrùn sí i, kí a baà lè pẹ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.

Yíyí Iṣẹ́ Àyànfúnni Padà

Ní ọdún 1947, a lọ sí àpéjọpọ̀ kan ní Los Angeles, California. Nígbà tí a wà níbẹ̀, a fún èmi àti William ẹ̀gbọ́n mi ní lẹ́tà tí a fi yàn wá sí iṣẹ́ arìnrìn-àjò láti bẹ àwọn ìjọ wò kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà yẹn a kò gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe fún iṣẹ́ yẹn. A kàn lọ bẹ́ẹ̀ ni. Ní ọdún méje tí ó tẹ̀ lé e, èmi àti Fern sìn ní Ohio, Michigan, Indiana, Illinois, àti New York. Ní ọdún 1954, a ké sí wa láti wá sí kíláàsì kẹrìnlélógún ti Gilead, ilé ẹ̀kọ́ tí a ti ń dá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́. Ibẹ̀ ni a wà tí àrùn rọpárọsẹ̀ fi kọlu Fern. Inú mi dùn pé ara rẹ̀ tètè dá, a sì yàn wá sí iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní New York àti Connecticut.

Nígbà tí a ń sìn ní Stamford, Connecticut, Nathan H. Knorr, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, ní kí a wá lo òpin ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú òun àti aya rẹ̀, Audrey. Wọ́n se ọbẹ̀ ẹran námọ̀ pẹ̀lú èròjà àjẹpọ́nnulá mìíràn fún wa lálẹ́ ọjọ́ náà. Ó ti ṣe díẹ̀ tí a ti mọ̀ wọ́n, mo sì mọ Arákùnrin Knorr dáadáa pé ó ní nǹkan mìíràn lọ́kàn ju kí a kàn jọ fara rora, kí a sì jọ jẹ oúnjẹ alẹ́ yẹn lọ. Lálẹ́ ọjọ́ tí mo ń wí yìí, ó bi mí pé, “Ṣé wàá fẹ́ wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì?”

Mo fèsì pé: “N kò tí ì lè sọ; nítorí n kò mọ púpọ̀ nípa ìgbésí ayé Bẹ́tẹ́lì.”

Lẹ́yìn ríronú lórí èyí fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan, a sọ fún Arákùnrin Knorr pé a óò wá bí ó bá fẹ́ kí a wá. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a rí lẹ́tà kan gbà tí ó sọ pé kí a dé Bẹ́tẹ́lì ní April 27, 1957, ọjọ́ tí ó pé ọdún 21 géérégé tí a ṣègbéyàwó.

Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ ní Bẹ́tẹ́lì, Arákùnrin Knorr ṣàlàyé tí ó ṣe kedere fún mi nípa ohun tí a ń retí kí n ṣe. Ó wí fún mi pé: “O kì í ṣe ìránṣẹ́ àyíká mọ́ o; iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì ni o wá ṣe. Iṣẹ́ yìí ni ó ṣe pàtàkì jù lọ fún ọ láti ṣe, a sì fẹ́ kí o lo àkókò àti okun rẹ̀ láti lo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí o bá gba níhìn-ín ní Bẹ́tẹ́lì. A fẹ́ kí o wà níhìn-ín.”

Ìgbésí Ayé Bẹ́tẹ́lì Nítumọ̀

Ẹ̀ka Ìwé Ìròyìn àti Ìfìwéránṣẹ́ ni mo ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ta, Arákùnrin Knorr pè mí lọ sí ọ́fíìsì rẹ̀. Ó ní ìdí pàtàkì tí a fi pè mí wá sí Bẹ́tẹ́lì gan-an ni láti wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ilé gbígbé. Ìtọ́ni rẹ̀ ṣe tààràtà, “Ìwọ ni yóò máa bójú tó Ilé Gbígbé ní Bẹ́tẹ́lì.”

Bíbójútó Ilé Gbígbé ní Bẹ́tẹ́lì rán mi létí ẹ̀kọ́ tí àwọn òbí mi ti kọ́ mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé ní abúléko. Bí agboolé kan ní Bẹ́tẹ́lì ṣe rí. Aṣọ ń bẹ láti fọ̀, oúnjẹ wà láti gbọ́, àwo ń bẹ láti fọ̀, bẹ́ẹ̀dì wà láti tẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò ilé gbígbé ń gbìyànjú láti mú kí Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi tí ó tura, ibi tí ẹnì kan lè pé ní ilé rẹ̀.

Mo gbà gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ wà tí àwọn ìdílé lè kọ́ nínú bí a ṣe ṣètò Bẹ́tẹ́lì. A máa ń jí lówùúrọ̀ kùtùkùtù, a óò sì fi ohun tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ náà nípa ṣíṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì ti ọjọ́ náà. A retí pé kí a ṣiṣẹ́ kára, kí a sì gbé ìgbésí ayé tí ó wà déédéé, ṣùgbọ́n tí ó mọ́wọ́ ẹni dí. Bẹ́tẹ́lì kò dà bí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé, bí àwọn kan ti rò. Ọ̀nà tí a gbà ṣètò ìgbésí ayé wa mú kí a lè ṣàṣeparí ọ̀pọ̀ nǹkan. Ọ̀pọ̀ ti sọ pé ohun tí àwọn kọ́ níhìn-ín ran àwọn lọ́wọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ nínú ìdílé wọn àti nínú ìjọ Kristẹni.

A lè yan àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó bá wá sí Bẹ́tẹ́lì láti máa tọ́jú àyíká, láti ṣiṣẹ́ ní ilé ìfọṣọ, tàbí ilé ìtẹ̀wé. Ayé lè mú kí a gbà gbọ́ pé irú iṣẹ́ alágbára bẹ́ẹ̀ buni kù, kò sì buyì kúnni. Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ tí ó wà ní Bẹ́tẹ́lì mọ̀ pé irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì kí nǹkan lè máa lọ létòlétò nínú ìdílé wa, kí ìdílé náà sì lè jẹ́ aláyọ̀.

Ayé tún lè gbé èrò pé o nílò ipò àti àyè láti fẹlá láti lè jẹ́ aláyọ̀ ní tòótọ́ lárugẹ. Irọ́ nìyẹn. Bí a bá ṣe ohun tí a yàn fún wa láti ṣe, a ń ṣe “ohun tí ó yẹ kí a ṣe,” a óò sì rí ìbùkún Jèhófà. (Lúùkù 17:10) Kìkì bí a bá rántí ète iṣẹ́ wa—láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà kí a sì mú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú—ni a fi lè ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ tòótọ́. Bí a bá fi ìyẹn sọ́kàn, a óò gbádùn iṣẹ́ èyíkéyìí tí a bá yàn fún wa, yóò sì tẹ́ wa lọ́rùn.

Àǹfààní Ìmúgbòòrò Tí Mo Nípìn-ín Nínú Rẹ̀

Ní àpéjọpọ̀ Cleveland, Ohio, ní ọdún 1942, ìyẹn lé ní ọdún mẹ́wàá kí a tó wá sí Bẹ́tẹ́lì, Arákùnrin Knorr sọ àsọyé náà, “Àlàáfíà—Yóò Ha Wà Pẹ́ Bí?” Ó là á pé Ogun Àgbáyé Kejì, tí ó ń jà lọ́wọ́ nígbà náà, yóò parí, àti pé àkókò àlàáfíà yóò wà tí yóò ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún mímú ìgbétásì ìwàásù náà gbòòrò sí i. A dá Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead tí yóò máa dá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ àti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run tí yóò mú kí àwọn ará túbọ̀ dáńgájíá nínú ọ̀rọ̀ sísọ ní gbangba sílẹ̀ ní ọdún 1943. A tún ṣètò àwọn àpéjọpọ̀ ńláńlá. Èyí tí òkìkí rẹ̀ kàn jù lọ ní àwọn ọdún 1950 ni èyí tí a ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee, New York. Ní ti àwọn àpéjọ tí a ṣe níbẹ̀ ní ọdún 1950 àti 1953, mo láǹfààní láti ṣèrànwọ́ nínú ṣíṣètò Ìlú Ọkọ̀-Àfiṣelé rẹpẹtẹ tí a fi ẹgbẹẹgbàárùn-ún wọ̀ sí fún ọjọ́ mẹ́jọ tí àpéjọ náà gbà.

Lẹ́yìn àwọn àpéjọ wọ̀nyẹn, títí kan èyí tí ó tóbi jù lọ tí a ṣe ní ọdún 1958, àwọn akéde Ìjọba pọ̀ sí i. Èyí nípa lórí iṣẹ́ wa ní Bẹ́tẹ́lì ní tààràtà. Ní àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn àwọn ọdún 1960 àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, a ń wá àyè àti iyàrá fún àwọn òṣìṣẹ́ lójú méjèèjì. Láti lè rí àyè fún ìdílé wa tí ń tóbi sí i, a nílò iyàrá, ilé ìdáná, àti ilé ìjẹun púpọ̀ sí i.

Arákùnrin Knorr ní kí èmi àti Arákùnrin Max Larson, alábòójútó ilé ìtẹ̀wé, wá ilé tí ó lè tó waá lò fún ìmúgbòòrò. Ní ọdún 1957, nígbà tí mo dé Bẹ́tẹ́lì, ilé kan ṣoṣo ni ìdílé wa tí ó ní 500 mẹ́ńbà ń gbé. Ṣùgbọ́n jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, Society ti ra hòtẹ́ẹ̀lì ńláńlá mẹ́ta nítòsí, wọ́n sì ti tún un ṣe—ti Towers, Standish, àti Bossert—wọ́n tún ra àwọn ilé kéékèèké mìíràn. Ní ọdún 1986, Society ra ibi tí Hòtẹ́ẹ̀lì Margaret wà, ó sì sọ ilé tuntun pípinminrin tí ó wà níbẹ̀ di ilé gbígbé fún nǹkan bí 250 ènìyàn. Lẹ́yìn náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, a kọ́ ilé ọlọ́gbọ̀n-àjà, tí ó lè gba 1,000 òṣìṣẹ́. Ní báyìí, Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn gba mẹ́ńbà ìdílé wa tí ó lé ní 3,300 ó sì ń pèsè àtijẹ àtimu wọn.

A tún ra ilẹ̀ kan sí Wallkill, New York, tí ó tó nǹkan bí 160 kìlómítà sí Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn. Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn àwọn ọdún 1960, a ti kọ́ àwọn ilé gbígbé àti ilé ìtẹ̀wé ńlá síbẹ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ibẹ̀ ni nǹkan bí 1,200 mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa ń gbé, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ní ọdún 1980, a bẹ̀rẹ̀ sí wá nǹkan bí 250 hẹ́kítà ilẹ̀ tí ó súnmọ́ New York City dáadáa, tí ọ̀nà márosẹ̀ sì gba ibẹ̀ kọjá. Abániwá ilé àti ilẹ̀ rẹ́rìn-ín, ó sì wí pé: “Ibo lẹ óò ti rí irú ilẹ̀ yẹn? Kò lè ṣeé ṣe rárá.” Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó padà ké sí wa, ó sì wí pé: “Mo ti rí ilẹ̀ tí ẹ ń fẹ́.” Lónìí, a mọ̀ ọ́n sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní Patterson, New York. Ibẹ̀ ni a ti ń darí àwọn ilé ẹ̀kọ́, ìdílé tí mẹ́ńbà rẹ̀ sì lé ní 1,300 òjíṣẹ́ wà níbẹ̀.

Ẹ̀kọ́ Tí Mo Ti Kọ́

Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé alábòójútó dídáńgájíá ni ẹni tí ó lè rí ìsọfúnni gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èrò tí mo láǹfààní láti gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ilé Bẹ́tẹ́lì ti wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.

Nígbà tí mo dé Bẹ́tẹ́lì, ọ̀pọ̀ ni ó ti dàgbà, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti wà lónìí. Ọ̀pọ̀ kò sí mọ́ báyìí. Ta ni rọ́pò àwọn tí ó darúgbó, tí ó sì ti kú? Kì í fìgbà gbogbo jẹ́ àwọn tí wọ́n jáfáfá jù lọ. Àwọn tí ó ṣì wà níhìn-ín ni, tí ń fi tòótọ́tòótọ́ ṣiṣẹ́, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn.

Kókó pàtàkì mìíràn tí mo rántí ni ìníyelórí aya rere. Ìtìlẹ́yìn aya mi ọ̀wọ́n Fern, ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún mi láti lè ṣe iṣẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run tí a yàn fún mi dé ojú ìlà. Ojúṣe àwọn ọkọ ni láti rí i dájú pé àwọn aya wọn gbádùn iṣẹ́ tí a yàn fún wọn. Mo ń gbìyànjú láti wá nǹkan tí inú èmi àti Fern yóò dùn láti ṣe. Kò dìgbà tó bá náni lówó, àní kó sáà ti jẹ́ ohun ìpawọ́dà. Iṣẹ́ ọkọ ni láti ṣe ohun tí yóò máa mú aya rẹ̀ láyọ̀. Àkókò tí ó bá lò pẹ̀lú rẹ̀ ṣeyebíye, nítorí tí a kì í rọ́jọ́ mú so lókùn, ó gbọ́dọ̀ lò ó lọ́nà rere.

Mo láyọ̀ láti máa gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àkókò àgbàyanu jù lọ nínú ìtàn ènìyàn ni a wà yìí. Ó ṣeé ṣe fún wa láti fi ojú ìgbàgbọ́ wa rí bí Olúwa ṣe gbé ètò àjọ rẹ̀ kalẹ̀ ní ìmúrasílẹ̀ fún ayé tuntun tí a ṣèlérí. Bí mo ti bojú wẹ̀yìn wo ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mo lè rí i pé Jèhófà ni ẹni náà tí ó ń darí ètò àjọ yìí—kì í ṣe ènìyàn. Ìránṣẹ́ rẹ̀ lásán ni a jẹ́. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa yíjú sí i nígbà gbogbo fún ìtọ́sọ́nà. Gbàrà tí ó bá la ohun tí a óò ṣe sílẹ̀, ṣe ni ó yẹ kí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kí a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣe é.

Fi ara rẹ̀ fún ètò àjọ náà, sì ní ìdánilójú pé ìwọ yóò ní ìgbésí ayé tí ó láyọ̀ délẹ̀délẹ̀. Ohunkóhun tí o bá ń ṣe—bóyá aṣáájú ọ̀nà ni, iṣẹ́ àyíká, sísìn nínú ìjọ gẹ́gẹ́ bí akéde, iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, tàbí míṣọ́nnárì—tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí a là sílẹ̀, kí o sì ka iṣẹ́ tí a yàn fún ọ sí ohun iyebíye. Sa gbogbo ipá rẹ láti gbádùn iṣẹ́ èyíkéyìí tí a bá yàn fún ọ àti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nígbà mìíràn àárẹ̀ lè mú ọ, o lè rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí gbogbo nǹkan sú ọ. Ìgbà yẹn ni o gbọ́dọ̀ rántí ète tí o fi ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó jẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ tara rẹ.

Kò sí ọjọ́ kan tí mo ṣiṣẹ́ rí tí n kò gbádùn ohun tí mo ṣe. Èé ṣe? Nítorí pé nígbà tí a bá fi ara wa fún iṣẹ́ àfitọkàntọkànṣe fún Jèhófà, mímọ̀ pé “ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe” máa ń fún wa ní ìtẹ́lọ́rùn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ẹ̀ka Ìwé Ìròyìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ìlú Ọkọ̀-Àfiṣelé, 1950

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ní Baltimore, 1946

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Èmi àti Fern ní Ìlú Ọkọ̀-Àfiṣelé ní 1950

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwa pẹ̀lú Audrey àti Nathan Knorr

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watch Tower ní Patterson, New York

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi àti Fern lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́