Gbigbe Awọn Animọ Iwa Kristian Ró Ninu Awọn Ọmọ Wa
IYA Wanda, ẹni ti ọkọ rẹ ti fi silẹ, ṣiṣẹ kara lati gbe awọn animọ iwa Kristian ró ninu ọmọbinrin rẹ. Nigba ti Wanda jẹ ẹni ọdun 12, idanilẹkọọ yii ni a fi sinu idanwo. Ni akoko yẹn, Wanda, papọ pẹlu awọn aburo rẹ ọkunrin ati obinrin, ni a fi ipa mu lati fi iya rẹ silẹ ki o si lọ gbe lọdọ baba rẹ fun igba diẹ. Baba rẹ kii ṣe onigbagbọ, nitori naa bawo ni Wanda yoo ṣe huwa nigba ti iya rẹ ko si nitosi lati ṣọ́ ọ?
Atubọtan ti nde si gbogbo awọn obi Kristian ni akoko naa nigba ti awọn ọmọ wọn nilati ṣe awọn ipinnu funraawọn, ti ndan igbagbọ tiwọn funraawọn wo. Awọn ọmọ ni a le yà sọtọ kuro lara awọn obi wọn Kristian, gẹgẹ bi ti Wanda. Wọn le dojukọ ikimọlẹ ojugba ni ilé-ẹ̀kọ́ lati ṣe ohun ti ko tọ́. Tabi wọn le dojukọ awọn idanwo alagbara. Awọn obi Kristian nireti wọn si gbadura pe nigba ti akoko yẹn ba de, awọn ọmọ wọn yoo ni animọ Kristian ti o lagbara to lati farada adanwo naa.
Bawo ni awọn obi ṣe le gbé awọn animọ iwa Kristian lilagbara ró ninu awọn ọmọ wọn? Ṣaaju ki a to ṣawari ohun ti o ṣẹlẹ si Wanda, ẹ jẹ ki a wo bi Bibeli ṣe ran wa lọwọ lati dahun ibeere yẹn. Ipilẹ fun idahun ni a ri ninu awọn ọrọ apọsteli Pọọlu wọnyi si awọn Kristian ni Kọrinti: “Nitori ipilẹ miiran ni ẹnikẹni ko le fi lelẹ ju eyi ti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi. Njẹ bi ẹnikẹni ba mọ wura, fadaka, okuta iyebiye, igi, koriko, ageku koriko le ori ipilẹ yii; iṣẹ olukuluku eniyan yoo han. Nitori ọjọ naa yoo fi i han, nitori pe ninu ina ni a o fi i han; ina naa yoo si dan iṣẹ olukuluku wo iru eyi ti iṣe.”—1 Kọrinti 3:11-13.
Ipilẹ Naa
Eeṣe ti Pọọlu fi kọ awọn ọrọ wọnyi? Oun ti bẹrẹ itolẹsẹẹsẹ ti gbigbe awọn animọ iwa Kristian ró Kọrinti, ṣugbọn itolẹsẹẹsẹ naa ti bọ sinu awọn iṣoro. Niti tootọ, itolẹsẹẹsẹ ikọle Pọọlu ko wemọ awọn ọmọ tirẹ nipa ti ara. O wemọ awọn wọnni ti wọn di Kristian nipasẹ iwaasu rẹ. Ṣugbọn o ka awọn wọnyi si ọmọ tẹmi, ohun ti o si sọ ṣeyebiye fun awọn obi pẹlu.—1 Kọrinti 4:15.
Pọọlu ti wa si Kọrinti lakooko kan ṣaaju o si ti fidi ijọ Kristian mulẹ nibẹ. Awọn wọnni ti wọn dahun pada si iwaasu rẹ ti ṣe iyipada nlanla ninu awọn akopọ animọ wọn. Diẹ ninu wọn ti jẹ awọn eniyan oniwa palapala, ole, abọriṣa, ati ọmuti tẹlẹri. (1 Kọrinti 6:9-11) Ṣugbọn o ṣeeṣe fun wọn lati yipada si ironu Kristian nitori pe Pọọlu ti fi ipilẹ rere lelẹ, gẹgẹ bi o ti ri. Ki ni ipilẹ yẹn? “Ipilẹ miiran ni ẹnikẹni ko le fi lelẹ ju eyi ti a ti filelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi.”—1 Kọrinti 3:11.
Bawo ni Pọọlu ṣe fidi ipilẹ yii lelẹ gẹgẹ bi oun ti nkọ awọn onigbagbọ titun wọnyi ni Kọrinti? Ó sọ fun wa pe: “Emi, nigba ti mo wa sọdọ yin, ẹyin ara, [emi] ko wa pẹlu irekọja aala ọrọ tabi ti ọgbọn ni kikede aṣiiri mimọ ọlọwọ Ọlọrun fun yin. Nitori mo pinnu lati maṣe mọ ohunkohun laaarin yin bikoṣe Jesu Kristi, ati oun ti a kan mọgi.” (1 Kọrinti 2:1, 2, NW; Iṣe 18:5) Oun ko dari afiyesi si ara rẹ tabi dán otitọ mọ́ránmọ́rán lati fun un ni ifamọra ọlọgbọnloye ni orefee. Kaka bẹẹ, oun dari afiyesi si Jesu Kristi ati ọna ti Ọlọrun ti gba lo ẹni yii.
Nitootọ, Jesu ni ipilẹ alagbara ologo fun ikọle Kristian. O pese ẹbọ irapada naa. Oun jẹ Ọba ti ọrun nisinsinyi ati gẹgẹ bi bẹẹ yoo pa awọn ọta Ọlọrun run ni Amagẹdọn laipẹ. Lẹhin naa oun yoo mu ododo Ọlọrun ṣẹ lakooko ijọba ẹgbẹrun ọdun kan, ati gẹgẹ bi Alufaa Agba Ọlọrun, oun yoo gbe iran eniyan ga si ijẹpipe ni kẹrẹkẹrẹ. Ipilẹ miiran wo ni ẹnikan le fẹ?
Fun idi yii, ni gbigbe animọ Kristian ró ninu awọn ọmọ wa, awa ṣe daradara lati ṣafarawe Pọọlu ki a si ni idaniloju pe wọn mọriri awọn otitọ pataki wọnyi. Lati igba ọmọde jojolo wọn, a nilati kọ awọn ọmọ wa lati nifẹẹ Jesu fun ohun ti o ti ṣe ati eyi ti ó nṣe fun wa.—1 Peteru 1:8.
Ikọle Naa
Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Pọọlu ti fi ipilẹ rere yi lelẹ, iṣẹ ikọle naa ni idaduro diẹ lẹhin ti oun kuro. (1 Kọrinti 3:10) Iṣoro naa kò ṣai jọ ohun ti ọpọlọpọ awọn obi nniriiri rẹ lonii. Wọn tọ́ awọn ọmọ wọn dagba ninu igbagbọ Kristian wọn si nimọlara idaniloju pe awọn ọmọ loye ohun ti otitọ jẹ. Ṣugbọn nigba ti wọn ba dagba, awọn ọmọ naa sú lọ kuro tabi pa igbagbọ naa tì. Eeṣe ti iyẹn fi ri bẹẹ? Niye igba o jẹ nitori awọn ohun eelo ikọle ti a lo.
Pọọlu sọ pe awọn animọ iwa ni a le gbéró pẹlu awọn ohun eelo ikọle oniyebiye: wura, fadaka, ati awọn okuta oniyebiye. Tabi a le gbé wọn ró pẹlu awọn ohun elo olowo pọ́ọ́kú: Igi, koriko, ageku koriko. (1 Kọrinti 3:12) Nisinsinyi, bi olukọle kan ba lo wura, fadaka, ati awọn okuta oniyebiye, o nilati jẹ pe iru ile didara ju kan, ọkan ti iniyelori rẹ tayọ ni o ńkọ́. Ṣugbọn olukọle ti o lo igi, koriko, ageku koriko wulẹ nkọ ohun kan ti o jẹ ayederu, onigba kukuru, ati olowo pọ́ọ́kú.
O jọ bi pe awọn ohun eelo tẹmi ti ko lagbara tó ni a nlo ni Kọrinti. Awọn kan ti wọn nkọle lé ipilẹ ti apọsteli Pọọlu fi lelẹ nkọle olowo pọ́ọ́kú, wọn ko gbé ile ti o lagbara, ti o lè tọ́jọ́ ró. Awọn ara Kọrinti ti bẹrẹ si wo eniyan, aisopọṣọkan, owu, ati ija si wa laaarin wọn. (1 Kọrinti 1:10-12; 3:1-4) Bawo ni a ba ti ṣe dena eyi? Nipa lilo awọn ohun eelo ojulowo ti o dara, ti o le tọjọ.
Iwọnyi duro fun awọn iwa animọ ṣiṣeyebiye wọnni ti o jẹ apa pataki ti animọ Kristian. Awọn iwa animọ wo? Apọsteli Peteru mẹnukan ọkan: “Idanwo igbagbọ yin, ti o niyelori ju wura.” (1 Peteru 1:6, 7) Ọba Solomọni mẹnukan meji sii: ọgbọn ati imoye, nini wọn ti o “ju owo fadaka lọ.” (Owe 3:13-15) Ọba Dafidi si ran wa leti pe ibẹru Jehofa ati imọriri awọn aṣẹ rẹ “ni a nilati fi ọkan fẹ ju wura lọ.”—Saamu 19:9, 10, NW.
Awọn wọnyi ati awọn ohun eelo oniyebiye miiran ni a le fi gbé animọ Kristian ró lati ran awọn ọmọ wa lọwọ lati la adanwo já. Bawo, nigba naa ni a ṣe le ni idaniloju pe a nkọle pẹlu iru awọn ohun eelo bẹẹ? Nipa kikiyesi ọkan, ati ti awọn ọmọ wa ati tiwa funraawa.
Iṣẹ Ikọle Alaṣeyọrisirere Kan
Ipa ti ọkan-aya obi kan nko ninu iṣẹ ikọle yii ni a ri ninu aṣẹ ti Jehofa fifun awọn obi ni orilẹ-ede Isirẹli igbaani: “Ọrọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ ni oni, ki o maa wa ni aya rẹ.” Lẹhin naa o nbaa lọ lati wipe: “Ki iwọ ki o si maa fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi.” (Deutaronomi 6:6, 7) Fun idi yii, ṣaaju ki a to le gbé awọn ẹlomiran ró, a gbọdọ gbe araawa ró ná. Awọn ọmọ wa nilati ri ninu awọn ohun ti a nsọ ti a si nṣe pe animọ iwa wa ni a fi awọn ohun eelo ti o yẹ kọ́.—Kolose 3:9, 10.
Lẹhin naa, awọn ikọnilẹkọọ wa nilati de inu ọkan wọn. Jesu, olukọ awọn animọ iwa Kristian alaṣeyọri si rere julọ, de inu awọn ọkan nipa lilo awọn akawe ati ibeere. (Matiu 17:24-27; Maaku 13:34) Awọn obi rii pe iru ọgbọn ikọnilẹkọọ kan naa wọnyi gbeṣẹ gan an. Wọn lo awọn akawe lati mu awọn otitọ Kristian fa ọkan awọn ọmọ wọn mọra, wọn si lo awọn ibeere ti a ronu jinlẹ sọ lati woye ohun ti awọn ọmọ wọn ti o ti dagba nro niti gidi, ohun ti wọn nronu le lori ninu ọkan wọn.—Owe 20:5.
Nigba ti Mose ngbiyanju lati gbé ifẹ lati wa ni olootọ ró ninu awọn ọmọ Isirẹli, oun wipe: “Maa pa ofin Oluwa [“Jehofa,” NW] mọ, ati ilana rẹ, . . . fun rere rẹ.” (Deutaronomi 10:13) Lọna ti o farajọra, awọn obi ṣe rere ki iṣe kiki lati ṣalaye ohun ti awọn ọpa idiwọn Ọlọrun jẹ fun awọn ọmọ wọn ni kedere nikan ṣugbọn wọn tun nilati fihan pẹlu idaniloju idi ti iru awọn nǹkan bẹẹ gẹgẹ bi ailabosi, imọtonitoni ọna iwahihu, ati ibakẹgbẹpọ rere fi wa fun ire wọn.
Nikẹhin, Jesu wipe: “Iye ainipẹkun naa si ni eyi, ki wọn ki o le mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi ẹni ti iwọ ran.” (Johanu 17:3) Nigba ti awọn ọmọ ba wá mọ Jehofa funraawọn ni kutukutu ọjọ aye, ti wọn kẹkọọ lati baa sọrọ nipa awọn iṣoro wọn, ti wọn si niriiri pe o ndahun awọn adura wọn, wọn nmu apa pataki julọ ninu animọ iwa Kristian dagba: ipo-ibatan pẹlu Ẹlẹdaa wọn gẹgẹ bi ẹnikan.
Ina Naa
Pọọlu ri pe nigba ti a ko ṣe iṣẹ ikọle ni Kọrinti lọna titọ, awọn iwa animọ aye iru bii ẹmi iyapa ati ija ipinya ta gbongbo. Eyi lewu nitori pe gẹgẹ bi oun ti ṣalaye, ‘ina yoo dan iṣẹ olukuluku wo iru eyi tii ṣe.’—1 Kọrinti 3:13.
Ki ni ina naa? O le jẹ adanwo eyikeyii ti Satani mu wa sori Kristian kan. O le jẹ ikimọlẹ ojugba, adanwo ti ẹran-ara, ifẹ ọrọ alumọọni, inunibini, ani agbara idari ajẹnirun ti iyemeji paapaa. O daju pe iru awọn adanwo bẹẹ yoo wa. “Iṣẹ olukuluku eniyan yoo han. Nitori ọjọ naa yoo fi i han, nitori pe ninu ina ni a o fi i han.” Awọn ọlọgbọn obi gbé animọ iwa awọn ọmọ wọn ró ni ireti pe awọn ọmọ naa ni a o danwo. Ṣugbọn wọn ni igbọkanle pe pẹlu iranlọwọ Jehofa, awọn ọmọ wọn le la adanwo naa já. Bi awọn obi ba ni ẹmi ironu yii, a o bukun wọn lọpọlọpọ.
Èrè Naa
Pọọlu wipe: “Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rẹ ba duro, oun yoo gba èrè.” (1 Kọrinti 3:14) Apọsteli Pọọlu gba èrè kan. Si awọn Kristian ni ilu Tẹsalonika, nibi ti ó ti tun ṣe iṣẹ ikọle, ó kọwe pe: “Nitori ki ni ireti wa, tabi ayọ wa, tabi ade isogo wa? Ki ha ṣe ẹyin ni niwaju Jesu Oluwa wa ni abọ rẹ? Nitori ẹyin ni ogo ati ayọ wa.”—1 Tẹsalonika 2:19, 20.
Iya Wanda ni èrè yii. Nigba ti Wanda ẹni ọdun 12 ba ara rẹ ninu ipinya kuro lọdọ iya rẹ, o sunkún titi lakọọkọ. Lẹhin naa o ranti imọran iya rẹ lati jiroro awọn iṣoro rẹ pẹlu Jehofa ninu adura. O gbadura ati laipẹ ero na wa si i lọkan lati ṣayẹwo iwe tẹlifoonu lati rii bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa eyikeyi ba wa nitosi. O kan wọn lara o si mọ pe idile kan ngbe nisalẹ opopona ti o gba iwaju ile baba rẹ. Wanda wipe, “Inu mi dun!”
Pẹlu iṣiiri idile yii, Wanda ṣeto aburo rẹ ọkunrin ati obinrin lati pada sinu igbokegbodo Kristian. O ṣalaye pe, “Emi ni ẹru iṣẹ mimura wa silẹ fun awọn ipade já lé lori. Mo nilati fọ awọn aṣọ wa, ya irun wa, ki nsi rii daju pe a mọ́ a si ṣee wò.” O jẹ iṣẹ lile fun ọdọmọbinrin kan, ṣugbọn ó ṣe e. Ni akoko kan baba rẹ gbiyanju lati da lilọ si ipade wọn duro, ṣugbọn awọn ọmọ naa bẹbẹ, o si jẹ ki wọn lọ.
Lẹhin naa, awọn ọmọ naa ni a tun sopọṣọkan pẹlu iya wọn. Nigba ti Wanda di ẹni ọdun 15, o di Kristian ti a baptisi, o si sọ ilepa rẹ lati di ojihin iṣẹ Ọlọrun jade. Bẹẹni, iṣẹ iya Wanda la idanwo kọja. O gbadun èrè ti riri ọmọbinrin rẹ ti o funraarẹ duro gbọnyingbọnyin fun otitọ. Njẹ ki gbogbo awọn obi Kristian ni aṣeyọri si rere ti o farajọra gẹgẹ bi wọn ti nṣiṣẹ lati gbé awọn animọ iwa Kristian ró ninu awọn ọmọ wọn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Gẹgẹ bi ọrọ-ẹkọ yii ti fihan, nigba ti awọn obi ngbiyanju kárakára lati gbé awọn animọ iwa Kristian ró ninu awọn ọmọ wọn, awọn ọmọ funraawọn tun ni ẹru-iṣẹ kan. Awọn, bi gbogbo awọn Kristian gbọdọ ṣe iṣẹ igbeniro funraawọn. (Efesu 4:22-24) Bi o tilẹ je pe, awọn obi ni anfaani agbayanu lati ṣeranlọwọ ninu eyi, ni ipilẹṣẹ ẹnikọọkan nilati ṣe ipinnu tirẹ funraarẹ lọkunrin tabi lobinrin lati ṣiṣẹsin Jehofa.