ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/1 ojú ìwé 8-13
  • Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìpìlẹ̀ Yíyẹ Lélẹ̀
  • Fífi Àwọn Ohun Èlò Yíyẹ Kọ́lé
  • Ṣe Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?
  • Ẹ̀bi Ta Ni?
  • Gbigbe Awọn Animọ Iwa Kristian Ró Ninu Awọn Ọmọ Wa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ríran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Sún Mọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ìgbàlà Yín Yọrí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/1 ojú ìwé 8-13

Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?

“Kí olúkúlùkù máa ṣọ́ bí ó ti ń kọ́lé sórí [ìpìlẹ̀ náà].”—1 KỌ́RÍŃTÌ 3:10.

1. Ìrètí wo ni àwọn Kristẹni olóòótọ́ ní nípa àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọn di ọmọ ẹ̀yìn?

TỌKỌTAYA Kristẹni kan tẹjú mọ́ ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Akéde Ìjọba kan rí ẹ̀mí ìháragàgà lójú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Kristẹni alàgbà kan tí ń kọ́ni láti orí pèpéle ṣàkíyèsí olùfìfẹ́hàn kan nínú àwùjọ, tí ń fìháragàgà wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ rí nínú Bíbélì. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ní ọkàn-àyà onírètí. Wọ́n ṣáà ń rò ó lọ́kàn pé, ‘Ṣe ẹni yìí yóò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí yóò sì sìn ín—ṣé yóò jẹ́ olóòótọ́ lọ títí?’ Dájúdájú, irú àbájáde bẹ́ẹ̀ kì í ṣàdédé wá. Ó gba ìsapá.

2. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe rán àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù létí ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ kíkọ́ni, àyẹ̀wò ara ẹni wo sì ni èyí lè sún wa láti ṣe?

2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí òun alára jẹ́ ògbóǹtarìgì olùkọ́, tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ kíkọ́ni àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ó yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ ní ojú ìwòye ibi tí àkókò dé yìí.” (Hébérù 5:12) Bí a bá ro ti ìgbà tí àwọn Kristẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ ti di onígbàgbọ́, ìtẹ̀síwájú wọn kò tí ì tó nǹkan. Yàtọ̀ sí pé wọ́n ṣì ń fẹ́ kí a máa kọ́ wọn, àní wọ́n ṣì tún ń fẹ́ kí a máa rán wọn létí àwọn ìpìlẹ̀ òtítọ́. Lónìí, ì bá dára bí gbogbo wa bá lè máa ṣàyẹ̀wò bí a ti ń ṣe sí gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, kí a sì mọ bí a ṣe lè ṣe dáadáa sí i. Ọ̀ràn náà kan ìwàláàyè. Kí ni a lè ṣe?

3. (a) Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ọ̀nà tí a gbà ń sọni di Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn wé? (b) Gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni tí ń kọ́lé, àǹfààní ńláǹlà wo ni a ní?

3 Nínú àkàwé gbìgbòòrò kan, Pọ́ọ̀lù fi sísọni di ọmọ ẹ̀yìn wé ilé kíkọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ ní sísọ pé: “Àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí a ń ro lọ́wọ́, ilé Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 3:9) Nítorí náà, a ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé kan tí ó jẹ́ ti ènìyàn; a ń ṣèrànwọ́ láti sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. A ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ẹni náà tí ó “kọ́ ohun gbogbo.” (Hébérù 3:4) Àǹfààní ńlá mà ni èyí jẹ́ o! Ẹ jẹ́ kí a wo bí ìmọ̀ràn onímìísí tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá nínú iṣẹ́ wa. Ní pàtàkì, a óò darí àfiyèsí wa sí “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”—2 Tímótì 4:2.

Fífi Ìpìlẹ̀ Yíyẹ Lélẹ̀

4. (a) Ipa wo ni Pọ́ọ̀lù kó nínú iṣẹ́ ilé kíkọ́ ti àwọn Kristẹni? (b) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jésù àti àwọn olùgbọ́ rẹ̀ mọ ìjẹ́pàtàkì fífi ìpìlẹ̀ tí ó dára lélẹ̀?

4 Bí ilé kan yóò bá dúró gbọn-in, tí yóò sì wà fún ìgbà pípẹ́, ìpìlẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ dára. Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n olùdarí àwọn iṣẹ́, èmi fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 3:10) Nígbà tí Jésù Kristi ń lo irú àkàwé kan náà, ó sọ nípa ilé kan tí kò wó lulẹ̀ nígbà tí ìjì jà, nítorí pé ẹni tí ó kọ́ ọ yàn láti lo ìpìlẹ̀ lílágbára. (Lúùkù 6:47-49) Kò sí ohun tí Jésù kò mọ̀ nípa bí ìpìlẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó. Ìṣojú rẹ̀ ni Jèhófà ṣe fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀.a (Òwe 8:29-31) Àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú mọyì ìpìlẹ̀ tí ó dára. Àwọn ilé tí ó ní ìpìlẹ̀ dídúró gbọn-in nìkan ni ó lè la omíyalé àti ìsẹ̀lẹ̀ tí ó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní Palẹ́sìnì já. Ṣùgbọ́n, irú ìpìlẹ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?

5. Ta ni ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni, báwo sì ni a ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀?

5 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè fi ìpìlẹ̀ èyíkéyìí mìíràn lélẹ̀ ju ohun tí a ti fi lélẹ̀ lọ, èyí tí í ṣe Jésù Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 3:11) Èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí a óò fi Jésù wé ìpìlẹ̀. Ní tòótọ́, Aísáyà 28:16 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi òkúta kan lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ní Síónì, òkúta tí a ti dán wò, igun ilé ṣíṣeyebíye ti ìpìlẹ̀ dídájú.’” Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni Jèhófà ti pète pé Ọmọ òun ni yóò di ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni.—Sáàmù 118:22; Éfésù 2:19-22; 1 Pétérù 2:4-6.

6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìpìlẹ̀ tí ó dára lélẹ̀ nínú àwọn Kristẹni tí ó wà ní Kọ́ríńtì?

6 Kí ni ìpìlẹ̀ fún olúkúlùkù Kristẹni? Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti wí, kò sí ìpìlẹ̀ kankan fún Kristẹni tòótọ́ lẹ́yìn èyí tí a fi lélẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—Jésù Kristi. Dájúdájú, irú ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀. Ní Kọ́ríńtì, níbi tí a ti ń gbé ọgbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn gẹ̀gẹ̀, kò wọ́nà láti fi ọgbọ́n ayé fa àwọn ènìyàn mọ́ra. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù wàásù nípa “Kristi tí a kàn mọ́gi,” tí àwọn orílẹ̀-èdè kà sí “ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 1:23) Pọ́ọ̀lù kọ́ni pé Jésù jẹ́ òpómúléró nínú ète Jèhófà.—2 Kọ́ríńtì 1:20; Kólósè 2:2, 3.

7. Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nínú títọ́ka tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọlọ́gbọ́n olùdarí àwọn iṣẹ́”?

7 Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ń kọ́ni bẹ́ẹ̀, “gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n olùdarí àwọn iṣẹ́.” Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ti ẹni tí ó jọ ara rẹ̀ lójú. Ó wulẹ̀ jẹ́ mímọrírì ẹ̀bùn àgbàyanu tí Jèhófà fún un ni—ìyẹn ni ti mímọ bí a ti ń ṣètò àti bí a ti ń darí iṣẹ́. (1 Kọ́ríńtì 12:28) Lóòótọ́ ni pé, àwa lónìí kò ní àwọn ẹ̀bùn ìyanu tí a fi jíǹkí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. A sì lè má rò pé a ní ẹ̀bùn ìkọ́ni. Ṣùgbọ́n lọ́nà pàtàkì kan, bẹ́ẹ̀ gan-an la jẹ́. Rò ó wò ná: Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. (Fi wé Lúùkù 12:11, 12.) A tún ní ìfẹ́ Jèhófà àti ìmọ̀ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ẹ̀bùn àgbàyanu tí a lè lò nígbà tí a bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jẹ́ kí a pinnu láti lò wọ́n kí a bàa lè fi ìpìlẹ̀ tí ó yẹ lélẹ̀.

8. Báwo ni a ṣe ń fi Kristi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ nínú àwọn tí wọn yóò di ọmọ ẹ̀yìn?

8 Nígbà tí a bá fi Kristi ṣe ìpìlẹ̀, a kì í sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ọmọ ọwọ́ jòjòló kan tí ó wà ní ibùjẹ ẹran, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì í sọ ọ́ bí apá kan Mẹ́talọ́kan tí ó bá Jèhófà dọ́gba. Rárá o, àwọn ayédèrú Kristẹni ni irú èrò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń kọ́ni pé òun ni ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí, pé ó fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé lélẹ̀ fún wa, àti pé lónìí, òun jẹ́ Ọba tí Jèhófà yàn, tí ó ń ṣàkóso ní ọ̀run. (Róòmù 5:8; Ìṣípayá 11:15) A tún ń fẹ́ sún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa láti tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù, kí wọ́n sì fara wé àwọn ànímọ́ rẹ̀. (1 Pétérù 2:21) A fẹ́ kí ìtara Jésù fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ìyọ́nú tí ó ní sí àwọn òtòṣì àti àwọn ti a ni lára, àánú tí ó fi hàn sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ẹ̀rí-ọkàn tiwọn fúnra wọn ti dá lẹ́bi, àìmikàn rẹ̀ láìfi ọ̀pọ̀ àdánwò pè, nípa lórí wọn lọ́nà jíjinlẹ̀. Lóòótọ́, Jésù jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dára gan-an. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ńkọ́?

Fífi Àwọn Ohun Èlò Yíyẹ Kọ́lé

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù gan-an ni ó fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, àníyàn wo ni ó ní fún àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí ó kọ́ wọn?

9 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Wàyí o, bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ wúrà, fàdákà, àwọn òkúta ṣíṣeyebíye, àwọn ohun èlò igi, koríko gbígbẹ, àgékù pòròpórò sórí ìpìlẹ̀ náà, iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò fara hàn kedere, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí a óò ṣí i payá nípasẹ̀ iná; iná náà fúnra rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀rí irú ohun tí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ hàn.” (1 Kọ́ríńtì 3:12, 13) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Gbé ipò tí ó yí ọ̀rọ̀ náà ká yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tí ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀. Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀, ó rìnrìn àjò láti ìlú dé ìlú, ó sì wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn tí kò gbọ́ nípa Kristi rí. (Róòmù 15:20) Bí àwọn ènìyàn ti ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí ó fi kọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń dá ìjọ sílẹ̀. Pọ́ọ̀lù bìkítà púpọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí. (2 Kọ́ríńtì 11:28, 29) Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ rẹ̀ kò jẹ́ kí ó lè dúró sójú kan. Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó ti lo oṣù 18 ní fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ ní Kọ́ríńtì, ó kọjá sí àwọn ìlú mìíràn láti lọ wàásù níbẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣì fẹ́ mọ bí àwọn yòókù ṣe ń bójú tó iṣẹ́ tí òun ti ṣe sílẹ̀ níbẹ̀.—Ìṣe 18:8-11; 1 Kọ́ríńtì 3:6.

10, 11. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìyàtọ̀ tí ó wà nínú onírúurú ohun èlò ìkọ́lé hàn? (b) Irú àwọn ilé gidi wo ni ó ṣeé ṣe kí ó ti wà ní Kọ́ríńtì ìgbàanì? (d) Irú àwọn ilé wo ni ó ṣeé ṣe jù lọ kí ó má gbiná, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí kọ́ àwọn Kristẹni tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn?

10 Ó dà bíi pé díẹ̀ lára àwọn tí ń kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ ní Kọ́ríńtì kò ṣiṣẹ́ náà dáradára. Kí wọ́n lè mọ ohun tí ó jẹ́ ìṣòro náà, Pọ́ọ̀lù fi oríṣi ohun èlò ìkọ́lé méjì wéra: ọ̀kan ni wúrà, fàdákà, àti àwọn òkúta ṣíṣeyebíye; èkejì ni igi, koríko gbígbẹ, àti àgékù pòròpórò. Ẹnì kan lè fi àwọn ohun èlò dáradára, tí ó lè wà fún ìgbà pípẹ́, tí kò sì ní gbiná kọ́lé; ẹnì kan sì lè kánjú fi àwọn ohun èlò tí kò ní pẹ́ bà jẹ́, tí ó wà fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì lè tètè gbiná kọ́lé. Ó dájú pé irú ọ̀nà ìkọ́lé méjèèjì ló wà ní ìlú Kọ́ríńtì. Àwọn tẹ́ńpìlì ràgàjì tí a fi búlọ́ọ̀kù olókùúta ńláńlá, tí ó tún jẹ́ olówó gọbọi kọ́, tí ó sì ṣeé ṣe kí a fi wúrà àti fàdákà bò tàbí kí a fi ṣe apá kan rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ wà níbẹ̀.b Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ àwọn ilé kéékèèké, ilé gẹ̀rẹ̀jẹ̀, àwọn káńtà ìtajà tí a fi igi ṣágiṣàgi kọ́, tí a sì fi koríko bò, ni àwọn ilé ńlá tí ó lè wà fún ìgbà pípẹ́ yìí wà.

11 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ilé wọ̀nyí bí iná bá ràn mọ́ wọn? Bí ìdáhùn náà ti ṣe kedere ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe kedere lónìí. Ní tòótọ́, láti ọdún 146 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Ọ̀gágun Mummius láti Róòmù, ti ṣẹ́gun ìlú Kọ́ríńtì, tí ó sì ti finá sun ún. Ọ̀pọ̀ ilé tí a fi igi, àgékù koríko, tàbí ti pòròpórò kọ́ ni a ti run pátápátá. Àmọ́ àwọn ilé dídúró gbọn-in tí a fi òkúta kọ́, tí a sì fi fàdákà àti wúrà ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ńkọ́? Kò sí iyèméjì pé, ìwọ̀nyí kò run. Ó ṣeé ṣe kí àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní Kọ́ríńtì ti máa kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́—àwọn ilé olókùúta tí kò run nígbà jàǹbá tí wọ́n sì ti sọ àwọn ilé yẹpẹrẹ tí ó wà nítòsí wọn di ilẹ̀. Ẹ wo bí Pọ́ọ̀lù ṣe mú kí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe kedere tó! Nígbà tí a bá ń kọ́ni, ó yẹ kí a ka ara wa sí kọ́lékọ́lé. Kí a lo àwọn ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí jù lọ. Nípa bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ wa fi lè wà fún ìgbà pípẹ́. Kí ni àwọn ohun tí ó lè wà pẹ́ títí, èé sì ti ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti lò wọ́n?

Ṣe Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?

12. Ọ̀nà wo ni àwọn kan nínú àwọn Kristẹni tí ó wà ní Kọ́ríńtì fi ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà?

12 Ó ṣe kedere pé, Pọ́ọ̀lù nímọ̀lára pé àwọn Kristẹni kan ní Kọ́ríńtì ń fi ohun èlò tí kò dára kọ́lé. Kí ló fà á? Gẹ́gẹ́ bí àyíká ọ̀rọ̀ náà ti fi hàn, ìyapa wà nínú ìjọ, ìyẹn ni dídarí àfiyèsí sórí àwọn ènìyàn láìfi ewu tí ó lè ní lórí ìṣọ̀kan ìjọ pè. Àwọn kan ń wí pé, “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” nígbà tí àwọn mìíràn sì ń rin kinkin mọ́ ọn pé, “Èmi [jẹ́] ti Àpólò.” Ó dà bí pé ọgbọ́n àwọn kan jọ wọ́n lójú ju bí ó ti yẹ lọ. Kò yani lẹ́nu láti rí i pé ó yọrí sí ìrònú ti ẹran ara, àìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí, pẹ̀lú “owú àti gbọ́nmisi-omi-ò-to.” (1 Kọ́ríńtì 1:12; 3:1-4, 18) Ìwà wọ̀nyí hàn gbangba nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi kọ́ni nínú ìjọ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọ́n fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ó wá dà bí fífi àwọn ohun èlò gbàrọgùdù kọ́lé. Kò lè la “iná” já. Irú iná wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá?

13. Kí ni iná tí Pọ́ọ̀lù lò nínú àkàwé rẹ̀ túmọ̀ sí, kí sì ni ó yẹ kí gbogbo Kristẹni mọ̀?

13 Iná kan wà tí gbogbo wa dojú kọ nínú ìgbésí ayé—ìdánwò ìgbàgbọ́ wa. (Jòhánù 15:20; Jákọ́bù 1:2, 3) Bí ti àwa pẹ̀lú lónìí, ó yẹ kí àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni a óò dán wò. Bí a kò bá kọ́ wọn dáradára, àbájáde rẹ̀ lè bani nínú jẹ́. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó ti kọ́ sórí rẹ̀ bá wà síbẹ̀, òun yóò gba èrè; bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a ó gbà là; síbẹ̀, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹní la iná já.”c—1 Kọ́ríńtì 3:14, 15.

14. (a) Báwo ni àwọn Kristẹni tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe lè “pàdánù,” síbẹ̀, báwo ni a ṣe lè gbà wọ́n là bí ẹni la iná já? (b) Báwo ni a ṣe lè dín ewu pípàdánù kù?

14 Ọ̀rọ̀ tí ó gbàrònú jinlẹ̀ nìyí lóòótọ́! Ó máa ń dunni púpọ̀ láti sapá gidigidi láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, kìkì láti wá rí i pé ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìdánwò tàbí inúnibíni, tí ó sì wá fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀ níkẹyìn. Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú gbà bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó fi sọ pé a pàdánù nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ìrírí náà máa ń dunni gan-an débi tí a fi ṣàpèjúwe ìgbàlà wa gẹ́gẹ́ bí “ẹni la iná já”—bí ẹnì kan tí ó pàdánù gbogbo ohun tí ó ní nínú iná, tí ó jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ni òun alára fi rù ú là. Ní tiwa, báwo ni a ṣe lè dín ewu pípàdánù kù? Ẹ jẹ́ kí a fi ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí kọ́lé! Bí a bá kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ láti lè dé inú ọkàn-àyà wọn, tí a sún wọn láti mọyì àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣíṣeyebíye bí ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, ìbẹ̀rù Jèhófà, àti ojúlówó ìgbàgbọ́, a jẹ́ pé a ń fi ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí, tí kò lè gbiná kọ́lé. (Sáàmù 19:9, 10; Òwe 3:13-15; 1 Pétérù 1:6, 7) Àwọn tí wọ́n bá ní irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yóò máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó; wọ́n ní ìrètí tí ó dájú láti wà láàyè títí láé. (1 Jòhánù 2:17) Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè fi àkàwé Pọ́ọ̀lù sílò? Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

15. Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà rí i dájú pé a yẹra fún fífọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa?

15 Nígbà tí a bá ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a kò gbọ́dọ̀ gbé ènìyàn ga ju Jèhófà Ọlọ́run lọ. Góńgó wa kì í ṣe láti kọ́ wọn láti máa wò wá gẹ́gẹ́ bí orísun ìpìlẹ̀ ọgbọ́n. A fẹ́ kí wọ́n máa yíjú sí Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà. Láti ṣe èyí, a kò ní wulẹ̀ máa gbé èrò tiwa kalẹ̀ láti dáhùn ìbéèrè wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò kọ́ wọn láti wá ìdáhùn náà, nípa lílo Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè. (Mátíù 24:45-47) Fún ìdí kan náà, a óò ṣọ́ra, kí a má ra kaka lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lórí. Dípò tí a kò fi ní fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sí wọn, ó yẹ kí a fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa níṣìírí láti “gbòòrò síwájú” nínú ìfẹ́ni wọn, kí wọ́n túbọ̀ dojúlùmọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i nínú ìjọ, kí wọ́n sì mọyì wọn, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—2 Kọ́ríńtì 6:12, 13.

16. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè lo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná?

16 Àwọn Kristẹni alàgbà pẹ̀lú ń kó ipa pàtàkì nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ni nínú ìjọ, wọ́n ń wọ́nà àtilo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná. Agbára ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn, ìrírí wọn, àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́ lè yàtọ̀ síra púpọ̀púpọ̀, ṣùgbọ́n wọn kì í lo àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí láti fa ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn. (Fi wé Ìṣe 20:29, 30.) A kò mọ ìdí náà gan-an tí àwọn kan ní Kọ́ríńtì fi ń sọ pé: “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù” tàbí, “Èmi ni ti Àpólò.” Ṣùgbọ́n ó dá wa lójú pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn alàgbà olóòótọ́ wọ̀nyí tí ó gbé èrò ìyapa yìí lárugẹ. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò wú Pọ́ọ̀lù lórí; ó ta kò wọ́n pátápátá. (1 Kọ́ríńtì 3:5-7) Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà ń fi í sọ́kàn pé àwọn ń ṣolùṣọ́ àgùntàn “agbo Ọlọ́run.” (1 Pétérù 5:2) Agbo àgùntàn kì í ṣe ti ènìyàn kankan. Nítorí náà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ dúró gbọn-in láìfàyè gba ìtẹ̀sí náà pé kí ọkùnrin kan fẹ́ jẹ gàba lórí agbo tàbí lórí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà. Àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná ni àwọn alàgbà fi ń kọ́lé nígbà tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bá ń sún wọn láti sin ìjọ, láti dé inú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n sì ran àwọn àgùntàn lọ́wọ́ láti fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà.

17. Báwo ni àwọn Kristẹni òbí ṣe lè sapá láti lo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná?

17 Ọ̀ràn yìí náà kan àwọn Kristẹni òbí gbọ̀ngbọ̀n. Ẹ wo bí wọ́n ti ṣe ń yán hànhàn tó pé kí àwọn ọmọ wọn wà láàyè títí láé! Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sa gbogbo ipá wọn láti “gbin” ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “sínú” ọkàn-àyà àwọn ọmọ wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Wọ́n fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ òtítọ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àkójọ òfin tàbí kókó tí a tò jọ gìn-ìn-rìn, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀, tí ó mú èrè wá, tí ó sì láyọ̀. (1 Tímótì 1:11) Láti lè mú kí àwọn ọmọ wọn di olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi, àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ ń sakun láti lo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná. Wọ́n ń fi sùúrù bá àwọn ọmọ wọn ṣiṣẹ́, nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ tí Jèhófà kórìíra kúrò nínú wọn, kí wọ́n sì gbin àwọn ànímọ́ tí ó nífẹ̀ẹ́ síbẹ̀.—Gálátíà 5:22, 23.

Ẹ̀bi Ta Ni?

18. Nígbà tí ọmọ ẹ̀yìn kan bá kọ ẹ̀kọ́ tí ń fúnni ní ìlera sílẹ̀, èé ṣe tí ó lè máà jẹ́ ẹ̀bi ẹni tí ń sapá láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?

18 Ìjíròrò yìí mú ìbéèrè pàtàkì kan wá. Bí ẹnì kan tí a sapá láti ràn lọ́wọ́ bá kúrò nínú òtítọ́, ìyẹn ha túmọ̀ sí pé a kùnà gẹ́gẹ́ bí olùkọ́—pé ṣe ni a ti lo àwọn gbàrọgùdù ohun èlò bí? Ó lè má jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù rán wa létí lọ́nà tí kò ṣeé sẹ́ pé ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà ni nínípìn-ín nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́. A fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti kọ́lé náà dáradára. Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ pé kí a tẹ́rí gba gbogbo ẹrù iṣẹ́ náà, kí ẹ̀rí ọkàn wa sì wá dá wa lẹ́bi nígbà tí àwọn tí a ràn lọ́wọ́ bá kúrò nínú òtítọ́. Àwọn ohun mìíràn wà tí ó lè fà á tí ó tún yàtọ̀ sí ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí kọ́lékọ́lé. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa olùkọ́ kan tí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí ó ṣe kò dára tó: “Òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a ó gbà là.” (1 Kọ́ríńtì 3:15) Bí a óò bá gba ẹni yìí là níkẹyìn—nígbà tí a ti fi hàn pé àkópọ̀ ìwà Kristẹni tí ó sapá láti gbìn sínú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ti “jóná” nígbà tí a fi iná dán an wò—ibo ni kí a wá parí èrò sí? Dájúdájú, ìparí èrò náà ni pé, akẹ́kọ̀ọ́ náà fúnra rẹ̀ ni yóò jíhìn fún Jèhófà lórí àwọn ìpinnu tí ó ṣe ní ti bóyá òun yóò tọ ipa ọ̀nà òtítọ́ tàbí òun kò ní tọ̀ ọ́.

19. Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí yóò tẹ̀ lé èyí?

19 Ìjíhìn ara ẹni, tàbí ti ẹnì kọ̀ọ̀kan, jẹ́ ọ̀ràn pàtàkì. Ó kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ní pàtó, kí ni Bíbélì fi kọ́ni lórí ọ̀ràn náà? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò gbé ìyẹn yẹ̀ wò.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé” lè tọ́ka sí àwọn agbára tí ó ṣeé fojú rí tí ó gbé ayé ró—àti gbogbo ohun tí ń bẹ ní ọ̀run—tí ó mú kí ó dúró gbọn-in ní ipò rẹ̀. Ní àfikún sí i, a ṣàgbékalẹ̀ ilẹ̀ ayé lọ́nà tí ó jẹ́ pé kò fi ní lè “ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n,” tàbí parun láé.—Sáàmù 104:5.

b “Àwọn òkúta ṣíṣeyebíye” tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí lè máà jẹ́ ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye, bí dáyámọ́ńdì àti rúbì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ àwọn òkúta tí ó wọ́n, tí a fi ń kọ́lé, bíi mábìlì, òkúta alabásítà, tàbí akọ òkúta.

c Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń ṣiyèméjì nípa ìgbàlà kọ́lékọ́lé náà, ṣùgbọ́n ó ń ṣiyèméjì nípa ìgbàlà “iṣẹ́” rẹ̀. Bí The New English Bible ṣe túmọ̀ ẹsẹ náà nìyí: “Bí ilé tí ẹnì kan kọ́ bá dúró, a óò san èrè fún un; bí ó bá jóná, òun ni yóò pàdánù; síbẹ̀ yóò yè é bọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó la iná já.”

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Kí ni “ìpìlẹ̀” tí ó wà nínú Kristẹni tòótọ́, báwo sì ni a ṣe fi lélẹ̀?

◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ láti inú onírúurú ohun èlò ìkọ́lé?

◻ Kí ni “iná” náà túmọ̀ sí, báwo sì ni ó ṣe lè mú kí ẹnì kan “pàdánù”?

◻ Báwo ni àwọn tí ń fi Bíbélì kọ́ni, àwọn alàgbà, àti àwọn òbí ṣe lè lo ohun èlò tí kò lè gbiná?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá ìgbàanì, àwọn ilé tí kò lè gbiná tí a fi òkúta kọ́ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ilé ahẹrẹpẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́