Mú Inu Jehofa Dùn Nipa Fifi Inurere Hàn
“Ki ni Jehofa nbeere pada lọwọ rẹ bikoṣe lati mu idajọ ododo lò ati lati nifẹẹ inurere ati lati jẹ́ amẹtọmọwa ninu biba Ọlọrun rẹ rin?”—MIKA 6:8, NW.
1. Eeṣe ti ko fi nilati yà wá lẹnu pe Jehofa nreti ki awọn eniyan rẹ fi inurere han?
JEHOFA reti ki awọn eniyan rẹ fi inurere hàn. Eyi ko nilati yà wá lẹnu. Ọlọrun funraarẹ jẹ oninuure si gbogbo eniyan, ani si awọn eniyan buburu alailọpẹ paapaa. Nipa eyi Jesu Kristi sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ pe: “Ki ẹyin ki o fẹ́ awọn ọta yin, ki ẹyin ki o si ṣoore, ki ẹyin ki o si wínni, ki ẹyin ki o maṣe reti ati ri nǹkan gbà pada; ere yin yoo si pọ, awọn ọmọ Ọga-ogo ni ẹ o si jẹ: nitori ti o ṣeun fun alaimoore ati ẹni buburu. Njẹ ki ẹyin ki o ni aanu, gẹgẹ bi Baba yin sì ti ni aanu.”—Luuku 6:35, 36.
2. Awọn ibeere wo nipa inurere ni o lẹtọọ si igbeyẹwo wa?
2 Gẹgẹ bi Mika 6:8 (NW) ṣe polongo, awọn wọnni ti wọn nrin pẹlu Ọlọrun gbọdọ “nifẹẹ inurere” niti gidi. Lọna ti o hàn kedere, Jehofa ni a mu inu rẹ dun nigba ti awọn iranṣẹ rẹ ba nifẹẹ inurere ti wọn si fi han ni ọna atọkanwa. Ṣugbọn ki ni inurere? Awọn anfaani wo ni njẹyọ lati inu fifi i han? Bawo si ni a ṣe le fi animọ yii han?
Ohun Ti Inurere Jẹ́
3. Bawo ni iwọ yoo ṣe tumọ inurere?
3 Inurere ni animọ nini ifẹ-ọkan mimuna ninu awọn ẹlomiran. A fi i han nipa awọn iṣe ti o kun fun iranlọwọ ati awọn ọrọ igbatẹniro. Lati jẹ oninuure tumọ si ṣiṣe rere dipo ohunkohun ti o le panilara. Oninuure eniyan kan jẹ ẹni bi ọrẹ, ẹni pẹ̀lẹ́, abanikẹdun, ati oloore ọfẹ. Oun ni ẹmi ironu ọlọlawọ, agbatẹniro si awọn ẹlomiran. Inurere si jẹ apakan igbekalẹ olukuluku Kristẹni tootọ, nitori Pọọlu rọni pe: “Ẹ fi awọn ifẹni onikẹẹ ti iyọnu, inurere, irẹlẹ ero inu, iwa pẹ̀lẹ́, ati ipamọra wọ ara yin ni aṣọ.”—Kolose 3:12, NW.
4. Bawo ni Jehofa ṣe mu ipo iwaju ninu fifi inurere han si araye?
4 Jehofa mu ipo iwaju ninu fifi inurere han. Gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti wi, o jẹ “nigba ti inurere ati ifẹ fun eniyan lọdọ Olugbala wa, Ọlọrun, farahan” ni “o gbà wá là gẹgẹ bi aanu rẹ nipasẹ iwẹ ti o mu wa wá si iye ati nipasẹ sisọ wá di titun lati ọwọ ẹmi mimọ.” (Titu 3:4, 5, NW) Ọlọrun mú awọn Kristẹni ẹni ami ororo mọ́, tabi ‘wẹ,’ wọn ninu ẹjẹ Jesu, ni fifi itoye ẹbọ irapada Kristi silo nitori wọn. A tun sọ wọn di titun nipasẹ ẹmi mimọ, ni didi “ẹda titun” gẹgẹ bi awọn ọmọkunrin Ọlọrun ti a fẹmi bi. (2 Kọrinti 5:17) Dajudaju, inurere ati ifẹ Ọlọrun fun eniyan tun nasẹ̀ dé ọdọ “ogunlọgọ nla” jakejado aye, ti wọn “ti fọ aṣọ igunwa wọn wọn si sọ wọn di funfun ninu ẹjẹ Ọdọ agutan naa.” (Iṣipaya 7:9, 14, NW; 1 Johanu 2:1, 2) Ju bẹẹ lọ, awọn ẹni ami ororo ati ogunlọgọ nla, ti wọn ni ireti ti ilẹ-aye, wa labẹ ajaga “oninuure” Jesu.—Matiu 11:30, NW.
5. Eeṣe ti a fi nilati reti awọn wọnni ti ẹmi Ọlọrun ndari lati fi inurere han si awọn ẹlomiran?
5 Inurere tun jẹ apakan awọn eso ẹmi mimọ, tabi ipá agbékánkán ṣiṣẹ Ọlọrun. Pọọlu sọ pe: “Awọn eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere-iṣeun, igbagbọ, iwa pẹ̀lẹ́, ikora ẹni nijanu. Ko si ofin kankan lodi si iru nǹkan wọnyi.” (Galatia 5:22, 23, NW) Nitori naa, ki ni a nilati reti lọdọ awọn wọnni ti a nṣamọna nipasẹ ẹmi Ọlọrun? Dajudaju, wọn yoo fi inurere han si awọn ẹlọmiran.
6. Inurere nilati mu awọn alagba ati awọn Kristẹni miiran huwa ni ọna wo?
6 Inurere ni a le fihan sode ni ọpọlọpọ ọna. A fi inurere han nigba ti a ba jẹ alaanu. Fun apẹẹrẹ, awọn alagba Kristẹni jẹ oninuure nigba ti wọn ba nawọ aanu si oluṣe buburu aronupiwada kan ti wọn si wá ọna lati ran an lọwọ nipa tẹmi. Animọ inurere ti Ọlọrun fifunni mu ki awọn alaboojuto jẹ onisuuru, agbatẹniro, oniyọnu, ati ẹni pẹ̀lẹ́. O sun wọn lati “ba agbo naa lo pẹlu jẹlẹnkẹ.” (Iṣe 20:28, 29, NW) Nitootọ, eso inurere ti ẹmi naa nilati mu ki gbogbo Kristẹni jẹ alaanu, onisuuru, agbatẹniro, oniyọnu, ẹni bi ọrẹ, ati ẹlẹmii alejo ṣiṣe.
Yẹra Fun Inurere Aṣiṣe
7. Eeṣe ti iwọ yoo fi sọ pe inurere aṣiṣe jẹ ailera?
7 Awọn kan foju wo inurere gẹgẹ bi ailera. Wọn nimọlara pe ẹnikan gbọdọ lekoko, ani ki o tilẹ jẹ alaimọwa hù nigba miiran paapaa, ki a ba le mu ori awọn ẹlomiran wú nipa okun rẹ. Ṣugbọn a ti sọ ọ daradara pe “aimọwa hù jẹ afarawe okun eniyan alailagbara.” Niti tootọ, o gba okun gidi lati jẹ oninuure nitootọ ati lati yẹra fun inurere aṣiṣe. Inurere ti o jẹ eso ẹmi Ọlọrun kii ṣe ẹmi ironu alailera, ajuwọsilẹ fun iwa aitọ. Kaka bẹẹ, inurere aṣiṣe jẹ ailera ti o mu ki ẹnikan fayegba iwa aitọ.
8. (a) Niti awọn ọmọkunrin rẹ̀, bawo ni Eli ṣe fami ijafara han? (b) Eeṣe ti awọn alagba fi gbọdọ ṣọra fun jijọgọnu fun ṣiṣubu sabẹ inurere aṣiṣe?
8 Eli alufaa agba Isirẹli jafara ninu biba awọn ọmọkunrin rẹ, Hofini ati Finihasi wí, awọn ti nṣaboojuto gẹgẹ bi alufaa ninu agọ ajọ. Lainitẹlọrun pẹlu ìpín irubọ ti a pín fun wọn nipasẹ Ofin Ọlọrun, wọn mu ki onitọju kan fi dandangbọn beere ẹran tutu lọwọ oluṣerubọ kan ṣaaju ki wọn to sun ọra ẹbọ naa lori pẹpẹ. Awọn ọmọkunrin Eli tun ni ibalopọ takọtabo oniwa palapala pẹlu awọn obinrin ti wọn nṣiṣẹsin ni ẹnu ọna agọ ajọ naa. Bi o ti wu ki o ri, dipo lile Hofini ati Finihasi kuro ni ipo iṣẹ, Eli wulẹ bá wọn wí lọna jẹ́jẹ́, ni bibọla fun awọn ọmọkunrin rẹ ju Ọlọrun lọ. (1 Samuẹli 2:12-29) Abajọ ti ‘Ọrọ Oluwa [“Jehofa,” NW] fi ṣọwọn lọjọ wọnni.’ (1 Samuẹli 3:1) Nitori naa awọn alagba Kristẹni ko gbọdọ jọ̀wọ́ araawọn fun ironu eke tabi fi inurere aṣiṣe han eyi ti o le wu ipo tẹmi ijọ lewu. Inurere tootọ ko fọju si awọn ọrọ ati iṣe ibi ti o tapa si awọn ọpa idiwọn Ọlọrun.
9. (a) Ẹmi-ironu wo ni o le ran wa lọwọ lati yẹra fun jijọgọnu fun inurere aṣiṣe? (b) Bawo ni Jesu ṣe fi okun han ninu bibojuto awọn onisin ipẹhinda?
9 Bi awa ba nilati yẹra fun fifi inurere aṣiṣe han, awa gbọdọ gbadura fun iranlọwọ Ọlọrun lati ni iru okun ti o han gbangba ninu awọn ọrọ onisaamu naa pe: “Kuro lọdọ mi, ẹyin oluṣe buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ.” (Saamu 119:115) A tun nilati tẹle apẹẹrẹ Jesu Kristi, ẹni ti ko jẹbi fifi inurere aṣiṣe han rí. Nitootọ, Jesu ni apẹẹrẹ pipe inurere tootọ. Fun apẹẹrẹ, ‘oun nimọlara ifẹni onikẹẹ fun awọn eniyan nitori pe wọn jẹ wọn kan eegun wọn si tú wọn kaakiri gẹgẹ bi agutan laisi oluṣọ.’ Nitori naa, awọn eniyan alailabosi ọkan nimọlara ominira lati tọ Jesu lọ, wọn tilẹ mu awọn ọmọ wọn kekeke lọ sọdọ rẹ paapaa. Si ro inurere ati iyọnu ti oun fihan bi ‘o ti gbe awọn ọmọ naa si apa rẹ ti o si bẹrẹ sii sure fun wọn’! (Matiu 9:36; Maaku 10:13-16) Bi o tilẹ jẹ pe Jesu jẹ́ oninuure, oun laika eyiini si duro gbọnyingbọnyin fun ohun ti o tọ́ ni oju Baba rẹ ọrun. Jesu ko yọnda fun ibi lae; oun ní okun ti Ọlọrun fi funni lati bu ẹnu àtẹ́ lu awọn aṣaaju isin alagabagebe. Ni Matiu 23:13-26, ni awọn igba melookan oun sọ asọtunsọ ikede naa: “Egbe ni fun yin, ẹyin akọwe ati Farisi, agabagebe.” Nigba kọọkan, Jesu funni ni idi fun idajọ atọrunwa.
Inurere Sopọ Mọ Ifẹ
10. Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu ṣe fi inurere ati ifẹ han si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn?
10 Niti awọn ọmọlẹhin rẹ, Jesu wipe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ pe, ọmọ ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba ti ẹyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji yin.” (Johanu 13:35) Ki si ni ọkan lara iha ifẹ naa ti o fi awọn ọmọ-ẹhin tootọ Jesu han yatọ? Pọọlu wipe: “Ifẹ a maa ni ipamọra a si ni inurere.” (1 Kọrinti 13:4, NW) Jijẹ onipamọra ati oninuure tumọ si pe ki a farada aipe ati ikuna awọn ẹlomiran, ani gẹgẹ bi Jehofa ti nṣe lọna oninuure. (Saamu 103:10-14; Roomu 2:4; 2 Peteru 3:9, 15) Ifẹ ati inurere Kristẹni tun fara hàn nigba ti ipo iṣoro bá npọn awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni loju nibikan lori ilẹ-aye. Ni didahun pada pẹlu ohun ti o ju “inurere eniyan,” awọn Kristẹni nibomiran fi ifẹ ara han nipa ṣiṣetọrẹ ohun ìní ti ara lati ran iru awọn olujọsin Jehofa bẹẹ lọwọ.—Iṣe 28:2.
11. Ki a sọ lọna ti o ba Iwe mimọ mu, ki ni iṣeun-ifẹ?
11 Inurere ni a so pọ pẹlu ifẹ ninu ọrọ naa “iṣeun-ifẹ,” ti a saba maa nlo ninu Iwe mimọ. Inurere yii jẹ jade lati inu ifẹ aduroṣinṣin. Ọrọ orukọ Heberu naa ti a tumọ si “iṣeun-ifẹ” (cheʹsedh) ni pupọ sii ninu ju ikanisi onijẹlẹnkẹ lọ. O jẹ inurere ti o fi tifẹtifẹ so araarẹ pọ mọ ohun kan titi di igba ti ete rẹ ni isopọ ohun naa bá di eyi ti o ṣẹ. Iṣeun-ifẹ Jehofa, tabi ifẹ aduroṣinṣin, ni a nfihan ni oniruuru ọna. Fun apẹẹrẹ, a fihan ninu awọn iṣe igbala ati idaabobo rẹ̀.—Saamu 6:4; 40:11; 143:12.
12. Nigba ti awọn iranṣẹ Jehofa ba gbadura fun iranlọwọ tati ìdáǹdè, ki ni wọn leni idaniloju rẹ?
12 Abajọ ti iṣeun-ifẹ Jehofa fi fa awọn eniyan sọdọ rẹ! (Jeremaya 31:3) Nigba ti awọn iranṣẹ oluṣotitọ ti Ọlọrun nilo idande tabi iranlọwọ, wọn mọ pe iṣeun-ifẹ rẹ jẹ ifẹ aduroṣinṣin nitootọ, eyi ti ki yoo já wọn kulẹ. Fun idi yii, wọn le gbadura ninu igbagbọ, gẹgẹ bi onisaamu naa ti ó wi pe: “Niti emi, ninu iṣeun-ifẹ rẹ ni mo ti gbẹkẹle; jẹ ki ọkan-aya mi kun fun ayọ ninu igbala rẹ.” (Saamu 13:5, NW) Niwọn igba ti ifẹ Ọlọrun ti jẹ aduroṣinṣin, awọn iranṣẹ rẹ ko nigbẹkẹle ninu iṣeun-ifẹ rẹ̀ lofo. Nigba ti wọn ba gbadura fun iranlọwọ tabi ìdáǹdè, wọn ni idaniloju yii: “Oluwa [“Jehofa,” NW] ki yoo ṣá awọn eniyan rẹ tì, bẹẹ ni ki yoo kọ awọn eniyan ìní rẹ̀ silẹ.”—Saamu 94:14.
Awọn Èrè Inurere
13, 14. Eeṣe ti ẹni oninuure kan fi ni awọn ọrẹ aduroṣinṣin?
13 Ni afarawe Jehofa, awọn iranṣẹ rẹ “ńbá iṣeun-ifẹ ati aanu lọ laaarin araawọn ẹnikinni keji.” (Sekaraya 7:9, NW; Efesu 5:1) “Ẹwa eniyan ni iṣeun [“iṣeun-ifẹ,” NW] rẹ,” ẹni kan ti o si nfi animọ yii han tun nka awọn èrè jìngbìnnì. (Owe 19:22) Ki ni diẹ lara awọn wọnyi?
14 Inurere mu wa kun fun ọgbọn ẹwẹ o si tipa bayii ran wa lọwọ lati pa ipo ibatan rere mọ pẹlu awọn ẹlomiran. Ẹni ọlọgbọn ẹwẹ kan nsọ o si nṣe awọn nǹkan tabi yanju awọn ipo iṣoro ni ọna igbatẹniro ati alaibani ninu jẹ́. Nigba ti o jẹ pe “ika eniyan” jiya ìtanù lẹ́gbẹ́, “ẹni iṣeun-ifẹ nba ẹmi oun tikaararẹ lò lọna tí ńmú èrè wá.” (Owe 11:17, NW) Awọn eniyan maa nyẹra fun ika eniyan ṣugbọn a fà wọn sunmọ ẹni ti nfi iṣeun ifẹ han si wọn. Fun idi yii, ẹni oninuure kan ni awọn ọrẹ aduroṣinṣin.—Owe 18:24.
15. Iyọrisi wo ni inurere le ni ninu agbo ile ti o pinya niti isin?
15 Aya Kristẹni kan ti o ni ọkọ alaigbagbọ le fa a si otitọ Ọlọrun nipa iru animọ kan gẹgẹ bi inurere. Saaju ki oun to kẹkọọ otitọ ki o si to gbe “akopọ animọ iwa titun wọ̀ eyi ti a dá gẹgẹ bi ifẹ inu Ọlọrun ninu ododo tootọ ati iduroṣinṣin,” oun ti le jẹ alaininu-unre, ani alasọ paapaa. (Efesu 4:24, NW) Bi ọkọ rẹ̀ ba ti mọ awọn owe kan bayii ni, oun bakan naa iba ti fohunṣọkan pe “asọ aya kan dabi orule ti njo ti nle ẹnikan sẹhin” ati “o san lati jokoo ni aginju ju pẹlu onija obinrin ati oṣonu lọ.” (Owe 19:13, NW; 21:19) Ṣugbọn nisinsinyi iwa mimọ ati ọwọ jijinlẹ aya Kristẹni naa, papọ pẹlu iru awọn animọ gẹgẹ bi inurere, le ṣeranwọ lati jere olubaṣegbeyawo rẹ̀ sinu igbagbọ tootọ. (1 Peteru 3:1, 2) Bẹẹni, eyi le jẹ ere kan fun inurere rẹ̀.
16. Bawo ni a ṣe le janfaani lati inurere ti a fihan si wa?
16 Inurere ti a fihan si wa le ṣanfaani nipa mimu wa jẹ agbatẹniro ati adarijini sii. Fun apẹẹrẹ, bi a ba ṣalaini itilẹhin tẹmi ti a si ba wa lo lọna pẹlẹ ati oninuure, iyẹn ko ha ni mu wa ni itẹsi pupọ sii lati ba awọn ẹlomiran lo ni ọna ti o farajọra? O dara, ihuwasi ti o ṣe pẹlẹ ti o si jẹ oninuure ni a le reti lati ọdọ awọn ọkunrin ti wọn tootun nipa tẹmi, nitori Pọọlu kọwe pe: “Ara, bi a tilẹ mu eniyan ninu iṣubu kan, ki ẹyin ti iṣe ti ẹmi ki o mu iru ẹni bẹẹ bọ sipo ni ẹmi iwa tutu; ki iwọ tikaararẹ maa kiyessara, ki a ma baa dan iwọ naa wò pẹlu.” (Galatia 6:1) Awọn alagba ti a yàn sipo nsọrọ lọna pẹlẹ ati lọna oninuure nigba ti wọn nwa ọna lati ran awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti wọn huwa aitọ lọwọ. Bi o ti wu ki o ri, yala awa funraawa ti gba iru iranlọwọ oninuure bẹẹ tabi bẹẹkọ, ki ni Ọlọrun nreti lọdọ gbogbo awọn wọnni ti wọn nṣiṣẹ sin in? Gbogbo awọn Kristẹni nilati fi inurere han si awọn ẹlomiran wọn si nilati kọbiara si imọran Pọọlu pe: “Ẹ di oninurere si ara yin ẹnikinni keji, ẹ ni iyọnu onípẹ̀lẹ́tù, ẹ maa dariji ara yin ẹnikinni keji falala gẹgẹ bi Ọlọrun pẹlu nipasẹ Kristi ti ndariji yin falala.” (Efesu 4:32, NW) Dajudaju bi ẹnikan ba ti darijì wa tabi ti a ti ran wa lọwọ kuro ninu iṣoro tẹmi ni ọna oninurere kan, eyi nilati mu agbara fun idarijini, iyọnu, ati inurere tiwa funraawa pọsii.
Mọriri Inurere Ailẹtọọsi Ọlọrun
17. Niwọn bi a ti jẹ ẹlẹṣẹ lati igba ibi, inurere wo ni a nilati kun fun imoore fun ni pataki?
17 Niwọn bi a ti bi gbogbo wa gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ ti a dá lẹbi iku, inurere kan wà eyi ti a nilati kun fun imoore fun ni pataki. Ohun ni inurere ailẹtọọsi ti Jehofa Ọlọrun. Fun awọn ẹlẹṣẹ lati di ẹni ti a tú silẹ kuro ninu idalẹbi iku ati lati di ẹni ti a polongo ni olododo jẹ inurere ti o jẹ alailẹtọọsi patapata. Pọọlu, ẹni ti o mẹnukan inurere ailẹtọọsi Ọlọrun ni igba 90 ninu awọn lẹta onimiisi atọrunwa 14 rẹ, sọ fun awọn Kristẹni ni Roomu igbaani pe: “Gbogbo eniyan ti ṣẹ wọn si rẹ̀hìn si ogo Ọlọrun, gẹgẹ bi ẹbun ọfẹ ni a si fi nka wọn si olododo nipa inurere ailẹtọọsi rẹ nipasẹ itusilẹ nipa irapada tí Kristi Jesu san.” (Roomu 3:23, 24, NW) Ẹ wò bi o ti yẹ ki a mọriri inurere ailẹtọọsi tí Jehofa Ọlọrun fihan!
18, 19. Bawo ni a ṣe le yẹra fun sisọ ete inurere ailẹtọọsi Ọlọrun nù?
18 Nipa jijẹ alaini imọriri, awa le sọ ete inurere ailẹtọọsi Ọlọrun nù. Nipa eyi, Pọọlu wipe: “Nitori naa awa ni ikọ fun Kristi, bi ẹni pe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun yin: awa nbẹ yin ni ipo Kristi, ẹ bá Ọlọrun laja. Nitori o ti fi ṣe ẹṣẹ nitori wa, ẹni ti ko mọ ẹṣẹkẹṣẹ ri; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ. Njẹ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ, awa nbẹ yin ki ẹ maṣe gba ore-ọfẹ [“inurere ailẹtọọsi,” NW] Ọlọrun lasan. Nitori o wipe, [ni Aisaya 49:8, Septuagint] emi ti gbohun rẹ ni akoko itẹwọgba, ati ni ọjọ igbala ni mo ti ran ọ́ lọwọ. Kiyesi i, nisinsinyi ni akoko itẹwọgba; kiyesi i, nisinsinyi ni ọjọ igbala. A ko si ṣe ohun ikọsẹ ni ohunkohun, ki iṣẹ iranṣẹ maṣe di isọrọ buburu si. Ṣugbọn ni ohun gbogbo awa nfi araawa han bi awọn iranṣẹ Ọlọrun.” (2 Kọrinti 5:20–6:4) Ki ni Pọọlu ni lọkan?
19 Awọn Kristẹni ẹni ami ororo jẹ ikọ̀ ti ndipo fun Kristi, awọn ogunlọgọ nla si jẹ onṣẹ aṣoju rẹ̀. Lapapọ wọn nrọ awọn eniyan lati di onilaja pẹlu Ọlọrun ki wọn ba le jere igbala. Pọọlu ko fẹ ki ẹnikẹni gba inurere ailẹtọọsi Jehofa Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi ki o si sọ ete rẹ nu. Iyẹn le ṣẹlẹ si wa bi awa ba kuna lati ṣiṣẹ naa eyi ti inurere ailẹtọọsi mú wa yẹ fún. Nini ibatan rere pẹlu Ọlọrun gẹgẹ bi awọn wọnni ti wọn ti bá a laja, awa ki yoo gba inurere ailẹtọọsi rẹ lasan bi awa ba mu “iṣẹ iranṣẹ ilaja . . . eyiini ni pe, Ọlọrun wa ninu Kristi, o nba araye laja sọdọ ara rẹ.” (2 Kọrinti 5:18, 19) Awa yoo tun maa ṣe inurere titobi julọ fun awọn ẹlomiran nipa riran wọn lọwọ lati di onilaja pẹlu Ọlọrun.
20. Ki ni a o ṣayẹwo tẹle e?
20 Awọn iranṣẹ Jehofa lo akoko ati awọn ọrọ̀ wọn ninu iṣe oninuure nigba ti wọn ba wa ọna lati ran awọn eniyan lọwọ nipa tẹmi nipasẹ iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni. Ṣugbọn ki ni a le kẹkọọ lati inu awọn apẹẹrẹ Iwe mimọ nipa inurere ti a fisilo? Ẹ jẹ ki a ṣayẹwo diẹ lara iwọnyi ki a si gbe awọn ọna miiran yẹwo lati mu inu Jehofa dun nipa fifi inurere han.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni inurere?
◻ Bawo ni a ṣe le yẹra fun jijọgọnu fun inurere aṣiṣe?
◻ Eeṣe ti awọn eniyan Jehofa fi le nigbẹẹkẹle ninu iṣeun-ifẹ rẹ?
◻ Ki ni diẹ lara awọn èrè inurere?
◻ Nipa ṣiṣe ki ni awa ki yoo fi sọ ete inurere ailẹtọsi Ọlọrun nù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Inurere mu ki awọn alagba Kristẹni jẹ onisuuru, agbatẹniro, ati oniyọọnu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Inurere aya Kristẹni kan le ṣeranlọwọ lati jere olubaṣegbeyawo rẹ wa sinu igbagbọ tootọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
A le fi inurere titobi julọ han si awọn ẹlomiran nipa riran wọn lọwọ lati di onilaja pẹlu Ọlọrun