Jẹ́ Kí “Òfin Inú Rere” Máa Darí Rẹ
NÍGBÀ tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lisaa sọ ohun tó mú kóun bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó ní: “Inúure táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fi hàn sí mi ló jẹ́ kí n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ohun kan náà ló mú kí Anne wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sọ pé: “Kì í ṣe ohun tí wọ́n ń kọ́ mi ló jẹ́ kí n gba òtítọ́, àmọ́ inúure tí wọ́n fi hàn sí mi ló jẹ́ kí n ṣe bẹ́ẹ̀.” Ní báyìí, inú àwọn arábìnrin méjèèjì yìí ń dùn bí wọ́n ṣe ń ka Bíbélì tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, àmọ́ inúure tí wọ́n fi hàn sí wọn ló jẹ́ kí wọ́n wá sin Jèhófà.
Báwo la ṣe lè máa finúure hàn sáwọn èèyàn? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà méjì tá a lè gbà ṣe é. Ọ̀nà méjì náà ni ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn tá a máa fi inúure hàn sí.
JẸ́ KÍ “ÒFIN INÚ RERE” WÀ NÍ AHỌ́N RẸ
Ìwé Òwe orí 31 sọ pé “òfin inú rere” wà ní ahọ́n aya tó dáńgájíá. (Òwe 31:26) Ó ń jẹ́ kí “òfin” yìí máa darí ohun tó fẹ́ sọ àti bó ṣe máa sọ ọ́. Bákan náà, ó yẹ kí àwọn bàbá jẹ́ kí “òfin” yìí máa darí ohun tí wọ́n bá ń sọ. Ọ̀pọ̀ òbí mọ̀ pé táwọn bá sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sáwọn ọmọ wọn, inú àwọn ọmọ wọn ò ní dùn. Táwọn òbí bá sì ń sọ̀rọ̀ gbá àwọn ọmọ wọn lórí, àwọn ọmọ náà lè ya olórí kunkun. Torí náà, ó yẹ káwọn òbí máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tura, káwọn ọmọ wọn lè máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.
Bóyá òbí ni ẹ́ tàbí o ò kì í ṣe òbí, báwo lo ṣe lè máa sọ̀rọ̀ tó tura? A rí ìdáhùn ẹ̀ nínú apá àkọ́kọ́ ní Òwe 31:26 tó sọ pé: “Tó bá la ẹnu rẹ̀, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ló ń jáde.” Ìyẹn ni pé ká mọ ohun tá a fẹ́ sọ àti bá a ṣe máa sọ ọ́ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ohun tí mo fẹ́ sọ máa bí àwọn èèyàn nínú àbí ó máa yanjú ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀?’ (Òwe 15:1) Torí náà, ó yẹ ká máa ronú ká tó sọ̀rọ̀.
Ìwé Òwe tún sọ pé: “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni.” (Òwe 12:18) Tá a bá ronú nípa bí ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ sọ àti bá a ṣe máa sọ ọ́ ṣe máa rí lára àwọn èèyàn, ìyẹn á jẹ́ ká máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ wa. Tá a bá ń jẹ́ kí “òfin inú rere” máa darí wa, a ò ní máa sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí ká máa fohùn tó le sọ̀rọ̀. (Éfé. 4:31, 32) Á jẹ́ ká lè máa sọ̀rọ̀ tó tura, tó sì ń gbéni ró dípò tá à fi máa sọ̀rọ̀ tí ò ṣeni láǹfààní. Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ torí ó fi Èlíjà ìránṣẹ́ rẹ̀ tẹ́rù ń bà lọ́kàn balẹ̀ nígbà tó ń bá a sọ̀rọ̀. Áńgẹ́lì tó ń ṣojú fún Jèhófà fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” bá Èlíjà sọ̀rọ̀. (1 Ọba 19:12) Àmọ́, kéèyàn jẹ́ onínúure ju pé kéèyàn máa sọ̀rọ̀ tó tura. Ó tún gba pé kéèyàn máa ṣoore. Báwo la ṣe lè ṣe é?
TÁ A BÁ Ń ṢOORE, Ó LÈ MÚ KÁWỌN ÈÈYÀN YÍ PA DÀ
Tá a bá ń fara wé Jèhófà, a ò ní máa sọ̀rọ̀ tó tura nìkan, àá tún máa ṣoore fún àwọn èèyàn. (Éfé. 4:32; 5:1, 2) Arábìnrin Lisa tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ní ká kúrò nílé tá à ń gbé lójijì, àwọn ìdílé méjì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbàyè níbi iṣẹ́ láti wá bá wa kó ẹrù. Nígbà yẹn, mi ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!” Inúure tí wọ́n fi hàn sí Lisa ló jẹ́ kó wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Arábìnrin Anne tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ náà mọyì inúure táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn sí i. Ó sọ pé: “Torí pé ayé ti gbẹgẹ́ gan-an, ṣe ni mo máa ń ṣọ́ra ṣe. Ó ṣòro fún mi gan-an láti fọkàn tán àwọn èèyàn. Nígbà tí mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mi ò fọkàn tán wọn. Mò ń rò ó pé, ‘Kí ló dé tí wọ́n fi ń wá sọ́dọ̀ mi?’ Àmọ́ inúure tí ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi hàn sí mi ló jẹ́ kí n fọkàn tán an.” Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ó sọ pé: “Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn sí ohun tí mò ń kọ́.”
Ẹ kíyè sí i pé inúure táwọn ará ìjọ fi hàn sí Lisa àti Anne wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an, ìyẹn sì mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Inúure táwọn ará ìjọ fi hàn sí wọn mú kí wọ́n fọkàn tán Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀.
MÁA FI INÚURE HÀN SÁWỌN ÈÈYÀN BÍI TI ỌLỌ́RUN
Ó lè rọrùn fáwọn kan láti máa sọ̀rọ̀ tó tura, kí wọ́n sì máa rẹ́rìn-ín músẹ́ torí ibi tí wọ́n dàgbà sí. Irú ìwà yẹn dáa gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú àṣà ìbílẹ̀ wọn ni wọ́n ti kọ́ ọ tàbí kó jẹ́ pé wọ́n bí i mọ́ wọn ni. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan yẹn nìkan ló ń jẹ́ ká hùwà tó dáa, a ò ní lè máa finúure hàn bíi ti Ọlọ́run.—Fi wé Ìṣe 28:2.
Inúure tí Ọlọ́run kọ́ wa jẹ́ apá kan èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Gál. 5:22, 23) Torí náà, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú ká máa fi inúure hàn sáwọn èèyàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fara wé Jèhófà àti Jésù nìyẹn. Àmọ́ bíi ti Jésù, àwa Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Torí náà, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ló ń mú ká fi inúure hàn. Inúure tá à ń fi hàn yìí wá látinú ọkàn wa, inú Ọlọ́run sì dùn sí i.
ÀWỌN WO LÓ YẸ KÁ MÁA FI INÚURE HÀN SÍ?
A sábà máa ń fi inúure hàn sáwọn tó ń fi inúure hàn sí wa tàbí àwọn tá a bá mọ̀. (2 Sám. 2:6) Ọ̀kan lára ohun tá a máa ń ṣe ni pé a máa ń dúpẹ́ oore tí wọ́n ṣe fún wa. (Kól. 3:15) Àmọ́ tó bá ń ṣe wá bíi pé kò yẹ ká fi inúure hàn sẹ́nì kan ńkọ́?
Ẹ wo àpẹẹrẹ yìí: Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fi inúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn. Bíbélì sì kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì pé ká máa fi inúure hàn. Gbólóhùn náà, “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń fi inúure hàn sí wa?
Ronú nípa àìmọye èèyàn tí Jèhófà ń fi inúure hàn sí bó ṣe ń pèsè àwọn ohun tó máa gbé ẹ̀mí wọn ró. (Mát. 5:45) Kódà, káwa èèyàn tó mọ Jèhófà ló ti ń fi inúure hàn sí wa. (Éfé. 2:4, 5, 8) Bí àpẹẹrẹ, ó fún aráyé ní Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo tó fẹ́ràn gan-an. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà pèsè ìràpadà “nítorí ọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.” (Éfé. 1:7) Yàtọ̀ síyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń ṣẹ Jèhófà, ó ṣì ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń kọ́ wa. Kódà, àwọn ọ̀rọ̀ àti ìtọ́ni rẹ̀ máa ń dà bí “òjò winniwinni” tó ń tù wá lára. (Diu. 32:2) Kò sóhun tá a lè ṣe láti san gbogbo oore rẹ̀ lórí wa. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tá a bá yọwọ́ inúure Jèhófà kúrò lọ́rọ̀ wa, kò sírètí kankan fún wa lọ́jọ́ iwájú nìyẹn.—Fi wé 1 Pétérù 1:13.
Ó dájú pé inúure Jèhófà ń fani mọ́ra gan-an, ó sì ń ṣeni láǹfààní. Torí náà, kò yẹ kó jẹ́ pé àwọn èèyàn tá a fẹ́ nìkan la máa fi inúure hàn sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fara wé Jèhófà ká máa fi inúure hàn sí gbogbo èèyàn. (1 Tẹs. 5:15) Tá a bá ń fi inúure hàn nígbà gbogbo, ńṣe la máa dà bí iná táwọn èèyàn ń yá nígbà òtútù. Àá máa fi inú rere hàn sáwọn tó wà nínú ìdílé wa, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé wa àtàwọn tó wà ládùúgbò wa.
Máa ronú nípa àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ tó o lè ràn lọ́wọ́. Tó o bá ń sọ̀rọ̀ tó tura, tó o sì ń ṣoore fún wọn, ó máa ṣe wọ́n láǹfààní. Ẹnì kan lè wà nínú ìjọ ẹ tó fẹ́ kó o bá òun tún ilé àti ọgbà òun ṣe, ó sì lè fẹ́ kó o bá òun ra nǹkan lọ́jà. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá rí ẹnì kan lóde ẹ̀rí tó fẹ́ kó o ran òun lọ́wọ́, ṣé o lè ṣe ohun kan tó máa ràn án lọ́wọ́?
Torí náà, tá a bá ń fara wé Jèhófà, àá jẹ́ kí “òfin inú rere” máa darí ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.