Jehofa—“Akin Ọkunrin Ogun”
AWỌN ẹgbẹ ologun ògbóǹtarìgì ti ọmọ ogun Ijibiti ni a ti parun patapata. Loju Okun Pupa, oku awọn onikẹkẹ-ẹṣin ati awọn ọmọ ogun ẹlẹṣin ni ìgbì okun ngba lọ, awọn ohun ija ologun sì fọnka soju omi. Awọn ọkunrin Isirẹli, ti Mose ṣiwaju wọn yọ ayọ nla ninu orin iṣẹgun pe: “Jẹ ki nkọrin si Jehofa, nitori o ti di ẹni ti a gbega fiofio. Ẹṣin ati olugun rẹ ni o ti yida sinu okun. Jehofa jẹ akin ọkunrin ogun. Jehofa ni orukọ rẹ̀.”—Ẹkisodu 15:1, 3, NW.
Iṣẹgun Jehofa ni Okun Pupa jẹ́ aṣefihan ipo gigalọlaju rẹ̀ ninu ija ogun. Isirẹli ti fi Ijibiti silẹ ninu ikorajọ ogun ṣugbọn pẹlu agbara ija ti ó mọniwọn. Nipasẹ ọwọ̀n kùrukùru ti o di ọwọ̀n iná kan ni alẹ, Jehofa ti ṣamọna wọn lati Ramesesi si “ẹba iju” ni Etamu. (Ẹkisodu 12:37; 13:18, 20-22, NW) Nigba naa ni Jehofa sọ fun Mose pe: “Sọ fun awọn ọmọkunrin Isirẹli, pe ki wọn ṣẹri pada ki wọn si pagọ niwaju Pihahiroti lagbedemeji Migidoli ati okun ni ọkankan Baali-sefoni. . . . Lẹhin naa Farao yoo sọ dajudaju nipa awọn ọmọkunrin Isirẹli pe, ‘Wọn ntarara ninu idarudapọ ni ilẹ naa.’ . . . Oun yoo si sare le wọn dajudaju.” (Ẹkisodu 14:1-4, NW) Pẹlu igbọran, Isirẹli yijupada wọn si rin lọ si Pihahiroti. Awọn amí Farao rohin ohun ti o jọ idarudapọ naa, ati gẹgẹ bi a ti sọ tẹlẹ, Farao ko awọn ologun rẹ jọ pọ fun ilepa.—Ẹkisodu 14:5-9.
Ikẹkun—Fun Isirẹli Tabi fun Farao?
Awọn ọmọ Isirẹli ti a dáyàfò naa ni o jọ bi ẹni pe a mu ninu ikẹkun nipa awọn oke ti o há wọn mọ ni ẹgbẹ mejeeji, okun niwaju, ati awọn ọmọ Ijibiti lẹhin, nitori naa wọn kepe Ọlọrun fun iranlọwọ. Ni pipa awọn eniyan naa jọ pọ, Mose wi pe: “Ẹ maṣe bẹru. Ẹ duro gbọnyin ki ẹ si ri igbala Jehofa, eyi ti yoo ṣe fun yin lonii. Nitori awọn ọmọ Ijibiti ti ẹ ri lonii ni ẹyin ki yoo rí mọ, bẹẹkọ, laelea. Jehofa funraarẹ yoo jà fun yin, ẹyin funraayin yoo si dakẹ.” (Ẹkisodu 14:10-14, NW) Lootọ si ileri yẹn, “ọwọ̀n kurukuru lọ kuro ni iwaju wọn o si duro ni ẹhin wọn. Nitori naa o wa saaarin agọ awọn ọmọ Ijibiti ati agọ Isirẹli. . . . Awujọ tìhín ko si sunmọ awujọ tọ̀hún ni gbogbo oru.”—Ẹkisodu 14:15-20, NW.
Gẹgẹ bi Jehofa ti paṣẹ, Mose gbe ọpa rẹ soke sori okun naa o si “pín in niya sọtọọtọ” ki awọn ọmọ Isirẹli baa le sá asala. Iṣẹ iyanu aṣeninikayefi kan ṣẹlẹ! (Ẹkisodu 14:16, 21) Atẹgun alagbara kan lati ila oorun bẹrẹ si pín omi Okun Pupa niya, ni ṣiṣe ọna ẹlẹsẹ ti o fẹ̀ tó fun gbogbo orilẹ-ede naa—nǹkan bi million mẹta lapapọ—lati la a kọja pẹlu itolọwọọwọ ologun. Ni apa osi ati ọtun awujọ awọn ọmọ Isirẹli, omi ti o ti dì naa duro bi ogiri nla meji.—Ẹkisodu 15:8.
Awọn ọmọ Isirẹli ti imọlẹ ọwọ́ ina naa ran lọwọ, gba ori isalẹ okun ti atẹgun ti mu gbẹ naa yebọ. Ni owurọ, eyi ti o kẹhin ninu awọn ọmọ Isirẹli ti goke sodikeji omi. “Awọn ọmọ Ijibiti si tẹpa mọ lilepa naa, gbogbo awọn ẹṣin Farao, awọn kẹkẹ ẹsin ogun rẹ ati awọn ọkunrin ogun ẹlẹṣin rẹ bẹrẹ si wọle tẹle wọn lẹhin, si aarin okun naa.” Awọn olulepa naa ti rọ́wọnú ikẹkun!—Ẹkisodu 14:23, NW.
“[Jehofa] bẹrẹ si da ibudo awọn ọmọ Ijibiti rú. Ó si nbaa lọ lati yọ àgbá danu lara kẹkẹ ẹṣin wọn debi pe wọn nwa wọn pẹlu iṣoro.” Mose nisinsinyi na ọwọ rẹ jade sori okun, ‘okun naa si bẹrẹ sii pada si ipo rẹ ti o wa tẹlẹ.’ Awọn ogiri omi wolulẹ o si bẹrẹ si bo awọn ara Ijibiti mọlẹ. Wọn gbiyanju lati sá, “ṣugbọn Jehofa gbọn [wọn] danu sinu aarin okun naa.” Ẹni kankan ko laaja! Ninu iho ayọ awọn ọmọ Isirẹli kọ orin iṣẹgun si Jehofa. —Ẹkisodu 14:24-15:3; Saamu 106:11.
Jehofa Jà Fun Joṣua
Jehofa fi ẹri jijẹ “akin ọkunrin ogun” han ninu awọn ija ogun miiran. Ọkan ni ti ija ogun ni Ai. Igbejakoni akọkọ si ilu naa kuna nitori iwa aitọ buburu ti Akaani. Nigba ti a mu ọran yii tọ́, Jehofa paṣẹ ogun fun Joṣua.—Joṣua 7:1, 4, 5, 11-26; 8:1, 2.
Ni ṣiṣegbọran si awọn itọni Jehofa, ni alẹ Joṣua ba si ibuba ni ẹhin ilu naa, ni ẹgbẹ iwọ-oorun rẹ̀. Ọpọjulọ awujọ ologun rẹ ṣí lọ si ariwa si afonifoji ti o wa lẹhin ode Ai gan an wọn si wà ni sẹpẹ fun igbejakoni lati iwaju. Awọn ọkunrin Ai ni a tàn sinu ikẹkun. Awọn ti wọn ṣì nyọ lori aṣeyọrisi rere ikọlu wọn iṣaaju, wọn dà gìrìgìrì jade kuro ninu ilu naa lodisi awọn ọmọ Isirẹli. Ni didibọn bi ẹni pe wọn nsapada, awọn ọmọ Isirẹli yipada bìrí wọn forile “ọna aginju,” ni fifa awọn ọta lọ jinna sii kuro ni Ai.—Joṣua 8:3-17.
Ni akoko yiyẹ gan an, Jehofa sọ fun Joṣua pe: “Na ọ̀kọ̀ ti nbẹ ni ọwọ rẹ nì si Ai; nitori ti emi o fi i lé ọ lọwọ.” Nipa ami yii, awọn ọkunrin ti wọn wa ninu ibuba gbejako ilu naa, ni fifi ida run un ati jijo o nina. Ni riri eefin ina, ogun ọta lẹhin ode di alailagbara patapata. Joṣua, ni yiyiju pada lati ẹnu sisapada si igbejakoni mú awọn ọta naa bọ sinu ikẹkun laaarin agbo ọmọ ogun rẹ mejeeji. Iṣẹgun eniyan ha ni bi? Bẹẹkọ. Awọn ọmọ Isirẹli ṣẹgun nitori pe, gẹgẹ bi Joṣua ti sọ fun wọn lẹhin naa: “Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun yin, ohun ni ẹni ti o ti jà fun yin.”—Joṣua 8:18-27; 23:3.
Ija Ogun Ni Kiṣoni
Ipo ajulọ Jehofa ninu ija ogun ni a tun ṣaṣefihan rẹ ni Afonifoji Kiṣoni, lẹbaa Mẹgido. Jabini ọba Kenani ti ni Isirẹli lara fun 20 ọdun. Awọn ọmọ ogun rẹ, labẹ aṣẹ Sisera, ni 900 kẹkẹ-ẹṣin ogun ti o ní ganmugánmú lara àgbá wọn ninu—awujọ ologun ti o jọ bi eyi ti a ko le ṣẹgun ni awọn ọjọ wọnni.—Onidaajọ 4:1-3.
Bi o ti wu ki o ri, nipasẹ Debora wolii obinrin, Jehofa kesi Onidaajọ Baraki lati kó awọn jagunjagun ẹgbẹrun mẹwaa jọ sori Oke Tabori lati pe awọn ẹgbẹ ọmọ ogun ti Jabini nija. Sisera yara gbegbeesẹ pada si awọn ologun ti npọ sii yii, ni yiyara sare lati Haroṣeti lọ si afonifoji Kiṣoni, lagbedemeji Oke Tabori ati Mẹgido. Oun laiṣiyemeji ronu pe nihin in lori ilẹ pẹrẹsẹ, awọn ọmọ ogun ẹlẹsẹ ti ko ni ohun ija daradara ti Isirẹli ki yoo ri ohunkohun fi awọn kẹkẹ-ogun rẹ ṣe. Bi o ti wu ki o ri, oun ko fojusọna fun biba Ọta ti ọrun ja.—Onidaajọ 4:4-7, 12, 13.
Jehofa paṣẹ fun Baraki lati ṣí kuro ni awọn ibi giga alaabo ti Tabori sinu pẹtẹlẹ afonifoji, ni titan awọn ọ̀wọ́ ogun ti Sisera sinu ija ogun. Lẹhin naa Jehofa ṣe igbejakoni! Ikun omi ayalunilojiji yi pápá ogun naa pada si ibi ẹrọfọ kan, ti ko jẹ ki ọ̀wọ́ ogun Sisera tẹsiwaju. Ninu idarudapọ ti o ṣẹlẹ lẹhin naa, awọn ọmọ ogun ẹlẹsẹ ti Isirẹli ṣẹgun ọta wọn ni kedere. “Gbogbo ogun Sisera sì ti oju ida ṣubu; ọkunrin kanṣoṣo kò sì kù.” Akunya omi Kiṣoni ti nga sii ti rì kẹkẹ-ẹṣin awọn ara Kenani mọlẹ o si ti le gba awọn ara oku diẹ lọ.—Onidaajọ 4:14-16; 5:20, 21.
Iṣẹgun Gọọgu ati Ogunlọgọ Rẹ
Awọn iṣẹlẹ igbaani wọnyi pese anfaani riri aritẹlẹ ijagunmolu titobi julọ ti Jehofa ti nbọ wa ṣẹlẹ. Eyi ti nrọdẹdẹ lọ́kàn-ánkán ni ija ogun ti yoo ṣẹlẹ “ni apa ikẹhin awọn ọdun.” Gẹgẹ bi asọtẹlẹ Esekiẹli ti wi, Gọọgu, apẹẹrẹ “oluṣakoso aye yii,” Satani Eṣu, yoo gbá awujọ ologun agbejakoni kan kari aye jọ. Oun yoo dari ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ lati gbejako “awọn oke Isirẹli” iṣapẹẹrẹ, iyẹn ni, ogun ìní tẹmi ti a gbega ti Kristẹni “Isirẹli Ọlọrun.”—Esekiẹli 38:1-9, NW; Johanu 12:31; Galatia 6:16.
Ki ni yoo dẹ Gọọgu wo lati gbé ija àjàkú akátá ko awọn eniyan Ọlọrun? Asọtẹlẹ naa tọka si ipo alalaafia, alaasiki tẹmi wọn. Gọọgu wipe: “‘Emi yoo goke lọ lodisi ilẹ igberiko gbalasa alailaju. Emi yoo wọle tọ awọn wọnni ti ko ni idilọwọ kankan lọ, ti wọn ngbe laisewu, gbogbo wọn ti wọn ngbe laisi odi, wọn ko tilẹ ni irin idabuu ati awọn ilẹkun.’ Yoo jẹ lati kó ikogun pupọ ati lati piyẹ lọpọlọpọ . . . awọn eniyan kan . . . ti wọn nko ọrọ̀ ati dukia jọ.”—Esekiẹli 38:10-12, NW.
Ni gbogbogboo, awọn eniyan Jehofa kò lọ́rọ̀ ni ọna ti ara. Bi o ti wu ki o ri, wọn ti mu ọpọ yanturu ọrọ̀ tẹmi jade gẹgẹ bi iyọrisi iṣẹ iwaasu wọn yika aye. “Ogunlọgọ nla . . . lati inu gbogbo orilẹ-ede” ni a ti kojọ, ti iye wọn nisinsinyi si lé ni aadọta ọkẹ mẹrin. (Iṣipaya 7:9, 10, NW) Ọrọ̀ nitootọ! Satani—ti o kún fun ibinu nitori aasiki tẹmi yii—gbidanwo lati pa awọn eniyan Ọlọrun rẹ́ patapata.
Ṣugbọn nipa wiwa sinu ilẹ iṣapẹẹrẹ ti Isirẹli, Gọọgu, ní ọrọ miiran, gbejako Jehofa Ọlọrun funraarẹ. “Irunu mi yoo wa sinu iho imu mi,” ni Jehofa wí, ẹni ti yoo gbẹsan nitori ti awọn eniyan rẹ. Awọn ọmọ ogun Gọọgu yoo fọ́nká ni rudurudu. “Lodisi arakunrin tirẹ funraarẹ ni ida ẹnikọọkan yoo wà.” Lẹhin naa Jehofa tu agbara aṣeparun rẹ silẹ—“ikun omi ojo ati okuta yinyin, ina ati imí ọjọ́.” Gẹgẹ bii ni Okun Pupa, Ai, ati Kiṣoni, Jehofa yoo tun jà fun awọn eniyan rẹ̀ lẹẹkan sii yoo si yin orukọ rẹ logo. ‘Dajudaju emi yoo gbé ara mi ga lọla emi yoo si sọ ara mi di mímọ́ ki nsi sọ ara mi di mímọ̀ niwaju oju ọpọlọpọ orilẹ-ede; wọn yoo si nilati mọ pe emi ni Jehofa.”—Esekiẹli 38:18-23, NW.
Akọsilẹ onitan ti ija ogun Jehofa ni akoko igbaani fun wa ni idi fun igbọnkanle patapata ninu ijagunmolu ọjọ ọla yii lakooko “ipọnju nla.” (Matiu 24:21, 22) Bi o ti jẹ pe oun nṣakoso nigba gbogbo, Jehofa le ronu tayọ ti awọn ọta rẹ ki o sì dari awọn ipo fun igabla awọn eniyan rẹ. Nitootọ, yoo já si gẹgẹ bi Aisaya ti sọtẹlẹ: “Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo jade bi ọkunrin alagbara, yoo rú owú soke bi ologun: yoo kigbe, nitootọ, yoo ké ramuramu; yoo bori awọn ọta rẹ.” (Aisaya 42:13) Ni oju awọn Ẹlẹrii rẹ, oun yoo maa figba gbogbo jẹ JEHOFA, “AKIN ỌKUNRIN OGUN”!—Ẹkisodu 15:3.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ipa-ọna Ijadelọ kuro ni Ijibiti
GOSHEN
Memphis
Rameses
Succoth
Migdol
Pihahiroth
Etham
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nihin in, ni agbegbe Ai, Jehofa ṣamọna Joṣua ati awọn eniyan rẹ si ijagunmolu yiyanilẹnu
Omi Kiṣoni kún soke kiakia, ni fifi kún ṣiṣẹgun awọn ọta Jehofa.
[Credit Line]
Photos: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.