ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 12/15 ojú ìwé 16-20
  • ‘Ẹ Dúró Gbọn-in Kí ẹ Sì Rí Ìgbàlà Jèhófà’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Dúró Gbọn-in Kí ẹ Sì Rí Ìgbàlà Jèhófà’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Sílẹ̀
  • “Rí Ìgbàlà Jèhófà”
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Bí Ọlọ́run Ṣe Gba Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Là
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
  • ‘Jáà Ni Ìgbàlà Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ta Ni Jehofa?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Rí “Ẹni Tí A Kò Lè Rí”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 12/15 ojú ìwé 16-20

‘Ẹ Dúró Gbọn-in Kí ẹ Sì Rí Ìgbàlà Jèhófà’

“Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?” —SÁÀMÙ 118:6.

1. Ìṣẹ̀lẹ̀ gba-n-kọ-gbì wo ni aráyé dojú kọ?

LÓDE òní, aráyé dojú kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gba-n-kọ-gbì tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ tí wọn ò rírú ẹ̀ rí. Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́, a óò ké ọjọ́ wọnnì kúrú.”—Mátíù 24:21, 22.

2. Kí ló ń dá ìpọ́njú ńlá náà dúró?

2 Àwọn ọmọ ogun ọ̀run táráyé ò lè fojú rí ṣì dáwọ́ ìpọ́njú ńlá náà dúró. Nínú ìran tí Jésù fi han àpọ́sítélì Jòhánù ó rí ìdí táwọn áńgẹ́lì yìí ṣì fi ń dáwọ́ ìpọ́njú ńlá náà dúró. Báyìí ni àpọ́sítélì tó ti darúgbó yìí ṣe ṣàlàyé ìran náà, ó ní: “Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, wọ́n di ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé mú pinpin . . . Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń gòkè láti ibi yíyọ oòrùn, ó ní èdìdì Ọlọ́run alààyè; ó sì ké pẹ̀lú ohùn rara sí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin pé . . . ‘Ẹ má ṣe pa ilẹ̀ ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì di àwọn ẹrú Ọlọ́run wa ní iwájú orí wọn.’”—Ìṣípayá 7:1-3.

3. Kí lohun tó máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá?

3 Fífi èdìdì di àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ “àwọn ẹrú Ọlọ́run” ti ń lọ sópin báyìí. Àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà ti wà ní sẹpẹ́ láti tú ẹ̀fúùfù apanirun náà sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá tú ẹ̀fúùfù náà sílẹ̀, kí ló máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀? Áńgẹ́lì kan dáhùn ìbéèrè náà ó ní: “Lọ́nà kan náà, pẹ̀lú ìgbésọnù yíyára ni a ó fi Bábílónì ìlú ńlá títóbi náà sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yóò sì tún rí i mọ́ láé.” (Ìṣípayá 18:21) Ẹ wo bí ayọ̀ yóò ti pọ̀ tó lọ́run, nígbà tí Ọlọ́run bá pa gbogbo ìsìn èké ayé run!—Ìṣípayá 19:1, 2.

4. Kí làwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

4 Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ayé yóò para pọ̀ láti gbéjà ko àwọn èèyàn Jèhófà. Ǹjẹ́ àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyẹn á kẹ́sẹ́ járí nínú pípa àwọn Kristẹni tòótọ́ yìí run? Ó lè jọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ wò ó! Àwọn ọmọ ogun ọ̀run tó ń tẹ̀ lé Kristi Jésù yóò rí sí i pé àwọn ẹni ibi náà pa run. (Ìṣípayá 19:19-21) Níkẹyìn, Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ni a ó sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níbi tí wọn ò tí ní lè ta pútú. Wọn yóò wà ní dídè fún ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọn ò sì ní lè ṣi àwọn ẹ̀dá èèyàn lọ́nà mọ́. Ìtura ńlá gbáà nìyẹn á mà jẹ́ fún ogunlọ́gọ̀ àwọn tó bá la ìpọ́njú ńlá náà já o!—Ìṣípayá 7:9, 10, 14; 20:1-3.

5. Ayọ̀ wo làwọn tó bá ń jólóòótọ́ sí Jèhófà nìṣó máa ní?

5 Kò ní pẹ́ mọ́ tí a óò fi rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu tó kún fún ẹ̀rù yìí. Ìdí ni pé wọ́n wà lára ọ̀nà tí Jèhófà á fi mú kí gbogbo ẹ̀dá gbà pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Sì wo àǹfààní ńláǹlà tó máa jẹ́ tiwa, tá a bá ń jólóòótọ́ sí Jèhófà nìṣó, tá a sì gbà pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso, àwa náà á wà lára àwọn tó ń ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́ tí wọ́n sì ń ṣèfẹ́ rẹ̀. Ayọ̀ tí kò láfiwé mà lèyí o!

6. Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti sún mọ́lé, kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

6 Ǹjẹ́ a ti ń múra sílẹ̀ de ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí? Ṣé a ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti gbani là? Ṣé ó dá wa lójú pé Jèhófà yòó ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tó yẹ àti lọ́nà tó dára jù lọ? Bó o ti ń dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, fi ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù sọ́kàn, ó ní: “Nítorí gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Lára àwọn ohun tí a kọ fún ìtọ́ni wa, tó ń fún wa ní ìtùnú àti ìrètí, ni àkọsílẹ̀ bí Jèhófà ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íjíbítì tó ń ni wọ́n lára. Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá nípa bí Jèhófà ṣe darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti rí ìdáǹdè yóò máa fún wa ní ìṣírí gan-an bá a ti ń retí ìpọ́njú ńlá tó ń yára sún mọ́lé yìí.

Jèhófà Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Sílẹ̀

7. Lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé nílẹ̀ Íjíbítì?

7 Ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìṣẹ̀lẹ̀ tá a fẹ́ sọ yìí wáyé. Jèhófà ti fi ìyọnu mẹ́sàn-án kọ lu àwọn ara Íjíbítì. Lẹ́yìn ìyọnu kẹsàn-an, Fáráò fi ìkanra lé Mósè dà nù, ó ní: “Jáde kúrò lọ́dọ̀ mi! Ṣọ́ ara rẹ! Má gbìyànjú láti rí ojú mi mọ́, nítorí ní ọjọ́ tí o bá rí ojú mi ìwọ yóò kú.” Mósè fèsì pé: “Bí o ṣe sọ nìyẹn. Èmi kì yóò gbìyànjú láti rí ojú rẹ mọ́ rárá.”—Ẹ́kísódù 10:28, 29.

8. Ìtọ́ni wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó bàa lè dá wọn nídè, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?

8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé ìyọnu kan sí i ṣì máa wá sórí Fáráò àti gbogbo àwọn ará Íjíbítì, ìyẹn èyí tó máa kẹ́yìn. Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ábíbù (ìyẹn oṣù Nísàn), gbogbo àkọ́bí èèyàn àti ti ẹranko nílẹ̀ Íjíbítì yóò kú. Àmọ́ àjálù kankan kì yóò ṣẹlẹ̀ nílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kìkì tí wọ́n bá fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún Mósè. Wọ́n ní láti fi ẹ̀jẹ̀ akọ àgùntàn wọ́n ara òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ilé wọn. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní òru ọjọ́ tá à ń wí yìí? Jẹ́ kí Mósè fúnra rẹ̀ sọ fún wa: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ní ọ̀gànjọ́ òru Jèhófà kọlu gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Fáráò ṣe nǹkan kan sí ọ̀rọ̀ náà. Ní kíá, ó pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ dìde, ẹ jáde kúrò ní àárín àwọn ènìyàn mi, . . . ẹ lọ, kí ẹ sì sin Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti sọ.” Kíá làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbéra, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ta, pa pọ̀ pẹ̀lú “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” tí wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì.—Ẹ́kísódù 12:1-7, 29, 31, 37, 38.

9. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, kí sì nìdí?

9 Ọ̀nà tó sún mọ́ tòsí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbà ni ọ̀nà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Mẹditaréníà, èyí á sì mú kí wọ́n gba ilẹ̀ àwọn ará Filísínì kọjá. Ṣùgbọ́n agbègbè àwọn ọ̀tá nìyẹn. Ó lè jẹ́ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàa jagun ni Jèhófà fi mú kí wọ́n gba ọ̀nà aginjù Òkun Pupa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń rìn lọ, wọ́n wà létòlétò. Bíbélì sọ pé: “Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìtẹ́gun ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè lọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”—Ẹ́kísódù 13:17, 18.

“Rí Ìgbàlà Jèhófà”

10. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n dó sí Píháhírótì?

10 Lójijì, ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé kí wọ́n yí padà, kí wọ́n sì dó sí àtidé Píháhírótì láàárín Mígídólì àti òkun ní ìdojúkọ Baali-séfónì.” Nígbà táwọn èèyàn náà tẹ̀ lé ìtọ́ni náà, ńṣe ni wọ́n há, nítorí pé àwọn òkè ńlá yí wọn ká, Òkun Pupa sì wà níwájú wọn. Ó wá dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ. Àmọ́, Jèhófà mọ nǹkan tó ń ṣe o. Ó sọ fún Mósè pé: “Nítorí náà, èmi, ní tòótọ́, yóò jẹ́ kí ọkàn-àyà Fáráò di èyí tí ó ṣoríkunkun, òun yóò sì lépa wọn dájúdájú, èmi yóò sì gba ògo fún ara mi nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀; àwọn ará Íjíbítì yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.”—Ẹ́kísódù 14:1-4.

11. (a) Kí ni Fáráò ṣe, kí sì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe? (b) Kí ni Mósè ṣe nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ráhùn?

11 Fáráò rò pé òun ti ṣàṣìṣe pé òun jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kúrò ní Íjíbítì, ló bá kó ẹgbẹ̀ta [600] àṣàyàn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lépa wọn. Bí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì ṣe yọ lọ́ọ̀ọ́kán, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì ké jáde sí Mósè pé: “Ṣé tìtorí pé kò sí àwọn ibi ìsìnkú rárá ní Íjíbítì ni o ṣe mú wa wá síhìn-ín láti kú nínú aginjù?” Ó dá Mósè lójú pé Jèhófà lágbára láti gbà wọ́n là, nítorí náà, ó dá àwọn èèyàn náà lóhùn pé: “Ẹ má fòyà. Ẹ dúró gbọn-in-gbọn-in, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà, èyí tí yóò ṣe fún yín lónìí. . . . Jèhófà yóò fúnra rẹ̀ jà fún yín, ẹ̀yin fúnra yín yóò sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.”—Ẹ́kísódù 14:5-14.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀?

12 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ pé Jèhófà yóò jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ gan-an ló rí, nítorí ẹni tó lágbára ju ẹ̀dá èèyàn wá dá sí ọ̀rọ̀ náà. Lọ́nà ìyanu, áńgẹ́lì Jèhófà darí ọwọ̀n àwọsánmà tó ń ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní iwájú wọn, ó sì wá dúró sí ẹ̀yìn wọn. Bí ọwọ̀n àwọsánmà náà ṣe jẹ́ òkùnkùn fún àwọn ọmọ Íjíbítì, ìmọ́lẹ̀ ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 13:21, 22; 14:19, 20) Mósè ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ fún un, ó na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun. Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú òkun náà padà sẹ́yìn nípa ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle láti òru mọ́jú . . . Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la àárín òkun kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, bí omi náà ti jẹ́ ògiri fún wọn ní ọwọ́ ọ̀tún wọn àti ní òsì wọn.” Àwọn ará Íjíbítì ń lépa wọn nìṣó, ṣùgbọ́n Jèhófà wà lẹ́yìn àwọn èèyàn rẹ̀. Ó sì mú kí ibùdó àwọn ará Íjíbítì dà rú, lẹ́yìn náà ó sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí omi náà lè padà wá sórí àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn àti àwọn agẹṣinjagun wọn.” Kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan ṣoṣo nínú wọn tó ṣẹ́ kù, gbogbo àwọn ọmọ ogun Fáráò ló ṣègbé!—Ẹ́kísódù 14:21-28; Sáàmù 136:15.

Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Bí Ọlọ́run Ṣe Gba Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Là

13. Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tí Ọlọ́run dá wọn nídè?

13 Ipa wo ni ìdáǹdè lọ́nà ìyanu yìí ní lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn tó wà pẹ̀lú wọn? Ńṣe ni Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì bú sórin, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà! Wọ́n kọrin pé: “Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti di gbígbéga fíofío. . . . Jèhófà yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Ẹ́kísódù 15:1, 18) Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tó kọ́kọ́ wá sí wọn lọ́kàn ni pé kí wọ́n gbé Ọlọ́run ga. Látinú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó hàn kedere pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ.

14. (a) Kí la lè rí kọ́ nípa Jèhófà látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2008?

14 Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń múni láyọ̀ yìí ṣe fún wa ní ìtọ́ni, ìtùnú àti ìrètí? Ó dájú pé Jèhófà lè ṣẹ́pá àdánwò yòówù tí ì báà dojú kọ àwọn èèyàn rẹ̀. Bákan náà, ó lágbára láti yanjú ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n bá dojú kọ. Òkun Pupa kò lè dí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ nígbà tí Jèhófà mú kí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn líle náà fẹ́. Inú Òkun Pupa yìí kan náà ní àwọn ọmọ ogun Fáráò kú sí. Bá a bá ń ronú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àá lè sọ ọ̀rọ̀ tí ẹni tó kọ sáàmù yìí sọ, ó ní: “Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?” (Sáàmù 118:6) A tún lè rí ìtùnú nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà ní Róòmù 8:31. Ó sọ níbẹ̀ pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?” Ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí yìí mà fún ìgbàgbọ́ wa lókun o! Wọ́n paná gbogbo ìbẹ̀rù àti iyè méjì tá a lè ní, wọ́n sì fún wa nírètí. Nígbà náà, ẹ wo bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2008 ti dára tó, ó ní: “Ẹ dúró gbọn-in-gbọn-in, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà”!—Ẹ́kísódù 14:13.

15. Báwo ni ìgbọ́ràn ti ṣe pàtàkì tó nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì, báwo ló sì ti ṣe pàtàkì tó lónìí?

15 Kí la tún lè rí kọ́ nínú ìjáde àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì? Ẹ̀kọ́ náà ni pé, a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Jèhófà nínú gbogbo ohun tó bá sọ fún wa pé ká ṣe. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run ni kí wọ́n ṣe láti múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá. Wọ́n ṣègbọràn sí ohun tí Ọlọ́run sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ilé lóru ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn. Bákan náà, nígbà tí wọ́n kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, “pẹ̀lú ìtẹ́gun” ni wọ́n jáde lọ. (Ẹ́kísódù 13:18) Lónìí bákan náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ń fún wa! (Mátíù 24:45) A gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ká sì fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń dún lẹ́yìn wa pé: “‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:21) Bá a ti ń sún mọ́ àkókò tí ìpọ́njú ńlá náà máa bẹ́ sílẹ̀, ó ṣe kedere pé a ó máa gba àwọn ìtọ́ni. Nítorí náà, láti lè la àkókò wàhálà yẹn já, a gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin.

16. Kí la lè rí kọ́ nínú bí Ọlọ́run ṣe darí àwọn nǹkan nígbà tó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè?

16 Má gbàgbé pé Jèhófà darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ọ̀nà kan tó jọ pé wọ́n ti há sáàárín àwọn òkè ńlá àti Òkun Pupa. Ó jọ pé kì í ṣe ibi tó yẹ kí wọ́n gbà nìyẹn. Àmọ́, nítorí pé kò sóhun tó kọjá agbára Jèhófà, ohun gbogbo yọrí sí ìyìn rẹ̀, ó sì dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Lóde òní, bí wọ́n ṣe bójú tó àwọn ọ̀ràn kan nínú ètò Ọlọ́run lè má ṣe kedere sí wa, síbẹ̀ a ní láti gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà nípasẹ̀ ọ̀nà tó ṣeé gbára lé tó ń gbà bá wa sọ̀rọ̀. Nígbà míì, ó lè jọ pé àwọn ọ̀tá ti borí. Àmọ́ o, a ò lè rí gbogbo nǹkan kedere nítorí ibi tí agbára wa mọ. Síbẹ̀ Jèhófà lágbára láti yí àwọn nǹkan padà lásìkò tó tọ́, bó ti ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Òwe 3:5.

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

17. Kí nìdí tá a fi lè gbọ́kàn lé Ọlọ́run pátápátá pé yóò dáàbò bò wá?

17 Ǹjẹ́ o ò rí i bí ìgbẹ́kẹ̀lé táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nínú Ọlọ́run á ti lágbára tó bí wọ́n tí ń ronú nípa ọwọ̀n àwọsánmà tó ṣamọ̀nà wọn lọ́sàn-án tó sì fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lóru? Ó dájú pé “áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́” lo ṣamọ̀nà wọn nínú ìrìn àjò náà. (Ẹ́kísódù 13:21, 22; 14:19) Lóde òní, a lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ láti darí wọn, láti dáàbò bò wọ́n, kó sì gbà wọ́n. A lè fi ìlérí yìí sọ́kàn pé: “[Jèhófà] kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú.” (Sáàmù 37:28) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé àwọn áńgẹ́lì alágbára tó ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ lóde òní. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn wọn, àwa náà lè ‘dúró gbọn-in, kí á sì rí ìgbàlà Jèhófà’—Ẹ́kísódù 14:13.

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀”?

18 Kí ni yòó ràn wá lọ́wọ́ láti ‘dúró gbọn-in’ ní ọ̀nà òtítọ́? Ohun tí yóò ràn wá lọ́wọ́ ni gbígbé ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Éfésù. Kíyè sí i pé àpọ́sítélì náà gbà wá níyànjú láti “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.” Ṣé a ń wọ gbogbo apá tí ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní? Lọ́dún 2008 yìí, á dáa kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ láti rí i pé òun ń lo gbogbo apá tí ìhámọ́ra yìí ní dáadáa. Sátánì Èṣù, ọ̀tá wa mọ ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí, ó sì ń lò ó láti dẹkùn mú wa láìròtẹ́lẹ̀. À ń bá àwọn ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ja “gídígbò kan.” Ṣùgbọ́n a ó borí lágbára Jèhófà!—Éfésù 6:11-18; Òwe 27:11.

19. Tá a bá fara dà á, kí la máa láǹfààní láti ṣe?

19 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.” (Lúùkù 21:19) Ẹ jẹ́ ká wà lára àwọn tó ń fi ìṣòtítọ́ fara da ìnira èyíkéyìí tí wọ́n dojú kọ, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run sì jẹ́ ká láǹfààní láti “dúró gbọn-in-gbọn-in, kí [a] sì rí ìgbàlà Jèhófà.”

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń múni láyọ̀ wo ló máa tó ṣẹlẹ̀?

• Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni pé òun lágbára láti gbani là?

• Kí lo pinnu láti ṣe lọ́jọ́ iwájú?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2008 ni : “Ẹ dúró gbọn-in-gbọn-in, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà.”—Ẹ́kísódù 14:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

“Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Orí kunkun tí Fáráò ṣe mú kí Íjíbítì kàgbákò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ísírẹ́lì yè bọ́ nítorí pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́