ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/15 ojú ìwé 3-5
  • Ta Ni Jehofa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Jehofa?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Galọla Ju Ọlọrun Awọn Ará Egipti Lọ
  • Olùpa Awọn Eniyan Rẹ̀ Mọ́
  • Awọn Ẹ̀kọ́ ti Iriri Fi Kọ́ni
  • ‘Jáà Ni Ìgbàlà Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Ìyọnu Mẹ́ta Àkọ́kọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Mósè Àti Áárónì Lọ Rí Fáráò
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Mose àti Aaroni—Àwọn Onígboyà Olùpòkìkí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/15 ojú ìwé 3-5

Ta Ni Jehofa?

“TA NI [Jehofa, NW]?” Ibeere yẹn ni Farao, ọba Egipti beere ni 3,500 ọdun sẹhin. Ìṣàyàgbàǹgbà sún un lọna ti o hàn gbangba lati fikun un pe: “Emi kò mọ [Jehofa, NW].” Awọn ọkunrin meji ti wọn duro niwaju Farao nigba naa mọ ẹni ti Jehofa jẹ́. Awọn ni tẹ̀gbọ́n-tàbúrò naa Mose ati Aaroni, lati inu ẹya Lefi ti Israeli. Jehofa ti rán wọn lati beere lọwọ oluṣakoso Egipti pe ki ó rán awọn ọmọ Israeli lọ sinu aginju lati ṣe ajọdun isin kan.—Eksodu 5:1, 2.

Farao kò fẹ́ idahun kankan si ibeere rẹ̀. Labẹ àṣẹ rẹ̀, awọn alufaa gbé ijọsin ọgọrọọrun awọn èké ọlọrun-ajọsinfun larugẹ. Họwu, Farao funraarẹ ni a kàsí ọlọrun kan! Gẹgẹ bi arosọ-atọwọdọwọ awọn ará Egipti ti wí, oun ni ọmọkunrin Ra ọlọ́run-oòrùn ati àtúnwáyé ọlọrun-ajọsinfun Horus ti o ní orí àṣá. Farao ni a ń fi awọn orúkọ-oyè bíi “ọlọrun alagbara” ati “ayeraye” pè. Nitori naa kò yanilẹnu pe oun yoo fi tẹgantẹgan beere pe: “Ta ni [Jehofa, NW], ti emi o fi gba ohùn rẹ̀ gbọ́.”

Mose ati Aaroni kò nilati dahun ibeere yẹn. Farao mọ̀ pe Jehofa ni Ọlọrun tí awọn ọmọ Israeli, tí wọn ń jiya ninu oko-ẹrú Egipti nigba naa ń jọsin. Ṣugbọn Farao ati gbogbo Egipti yoo mọ̀ laipẹ pe Jehofa ni Ọlọrun otitọ naa. Bakan naa lonii, Jehofa yoo sọ orukọ rẹ̀ ati ipo jíjẹ́ Ọlọrun rẹ̀ di mímọ̀ fun gbogbo eniyan lori ilẹ̀-ayé. (Esekieli 36:23) Nitori naa a lè janfaani nipasẹ ṣiṣagbeyẹwo bi Jehofa Ọlọrun ṣe gbé orukọ rẹ̀ ga ni Egipti igbaani.

Ó Galọla Ju Ọlọrun Awọn Ará Egipti Lọ

Nigba ti Farao fi ìṣàyàgbàǹgbà beere ẹni ti Jehofa jẹ́, oun kò reti abajade ti ó wá niriiri rẹ̀. Jehofa funraarẹ dahunpada, ní mímú awọn ìyọnu mẹwaa wá sori Egipti. Awọn ìyọnu wọnni kìí wulẹ ṣe àjálù lodisi orilẹ-ede naa. Wọn jẹ́ àjálù lodisi awọn ọlọrun Egipti.

Awọn ìyọnu naa fi igalọla Jehofa lori awọn ọlọrun-ajọsinfun Egipti hàn. (Eksodu 12:12; Numeri 33:4) Ronuwoye igbe naa nigba ti Jehofa yí Odò Nile ati gbogbo omi Egipti pada di ẹ̀jẹ̀! Nititori iṣẹ-iyanu yii, Farao ati awọn eniyan rẹ̀ mọ̀ pe Jehofa galọla ju Hapi, ọlọrun Nile lọ. Ikú awọn ẹja ninu odò Nile tun jẹ́ àjálù lodisi isin awọn ará Egipti, nitori pe iru awọn ẹja kan bayii ni a ń kunlẹ bọ.—Eksodu 7:19-21.

Tẹlee, Jehofa mú ìyọnu awọn ọ̀pọ̀lọ́ wá sori Egipti. Eyi dójú ti Heqt, abo-ọlọrun ọ̀pọ̀lọ́ awọn ará Egipti. (Eksodu 8:5-14) Ìyọnu kẹta tojú sú awọn alufaa pidánpidán, ti wọn kò lè jádìí ọgbọ́n iṣẹ-iyanu Jehofa nipa sisọ ekuru di kokoro iná. “Ìka Ọlọrun ni eyi,” ni wọn pariwo. (Eksodu 8:16-19) Thoth ọlọrun awọn ará Egipti, ti a ka imujade awọn ọgbọ́n idán sí tirẹ̀, kò lè ran awọn onímàgòmágó wọnni lọwọ.

Farao ń kẹkọọ ẹni ti Jehofa jẹ́. Jehofa ni Ọlọrun naa ti o lè kede ète rẹ̀ nipasẹ Mose ki o sì wá mú un ṣẹ nipa mímú awọn agbayanu ìyọnu wá sori awọn ará Egipti. Jehofa tun lè bẹrẹ ki o sì fopin si awọn àjálù ni ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀. Ìmọ̀ yii, bi o ti wu ki o ri, kò sún Farao lati tẹriba fun Jehofa. Dipo bẹẹ, oluṣakoso Egipti onigbeeraga naa ń fi oríkunkun baa lọ lati dena Jehofa.

Nigba ìyọnu kẹrin, awọn eṣinṣin-ńlá ba ilẹ naa jẹ́, wọn yawọ awọn ile, ati boya gbá yìì ninu afẹfẹ, eyi ti oun funraarẹ jẹ́ ohun ijọsin tí ọlọrun naa Shu tabi abo-ọlọrun naa Isis, ọbabinrin ọ̀run duro fun. Ọ̀rọ̀ Heberu naa fun kokoro yii ni a ti tumọsi “gbọ̀nyìngbọ̀nyìn,” “eṣinṣin-ajá,” ati “ọ̀bọ̀n-ùn-bọn-ùn.” (New World Translation; Septuagint; Young) Bi ó bá ní kokoro yímíyímí ninu, awọn ará Egipti ni a fi kokoro ti wọn kà si mímọ́ yọlẹnu, awọn eniyan kò sì lè rìn lai tẹ̀ wọn pa labẹ ẹsẹ wọn. Lọna kan ṣá, ìyọnu yii kọ́ Farao ni ohun titun kan nipa Jehofa. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọlọrun-ajọsinfun Egipti kò lè daabobo awọn olujọsin wọn kuro lọwọ awọn eṣinṣin-ńlá naa, Jehofa lè daabobo awọn eniyan rẹ̀. Eyi ati gbogbo awọn ìyọnu ti o tẹlee pọ́n awọn ará Egipti nikan loju ṣugbọn kìí ṣe awọn ọmọ Israeli.—Eksodu 8:20-24.

Ìyọnu karun-un jẹ́ ajakalẹ-arun lara awọn ẹran-ọsin Egipti. Àjálù yii dójú ti Hathor, Apis, ati Nut abo-ọlọrun ofuurufu alára-màlúù. (Eksodu 9:1-7) Ìyọnu kẹfa mú eéwo wá sara eniyan ati ẹranko, ní rírẹ awọn ọlọrun-ajọsinfun Thoth, Isis, ati Ptah, ti wọn fi ikuna gbé ògo agbara iwosan fun silẹ.—Eksodu 9:8-11.

Ìyọnu keje jẹ́ yìnyín wiwuwo, pẹlu iná ti ń kọ yẹ̀rì laaarin awọn okuta yìnyín naa. Àjálù yii kótìjú bá ọlọrun naa Reshpu, ti a tànmọ́-ọ̀n pe o jẹ́ ọ̀gá mànàmáná, ati Thoth, ti a sọ pe o ń ṣalaga lori òjò ati àrá. (Eksodu 9:22-26) Àjálù kẹjọ, ìyọnu eéṣú, fi igalọla Jehofa lori Min ọlọrun ọlọmọyọyọ hàn, eyi ti wọn tànmọ́n ọ̀n pe ó jẹ́ oludaabobo awọn ohun ọ̀gbìn. (Eksodu 10:12-15) Àjálù kẹsan-an, okunkun ọlọjọ-mẹta lori Egipti, da ẹ̀gbin sara iru awọn ọlọrun-ajọsinfun Egipti bii Ra ati Horus ọlọrun-oorun.—Eksodu 10:21-23.

Laika awọn ìyọnu mẹsan-an ti ń ṣeparun wọnyi si, Farao ṣì kọ̀ sibẹ lati tú awọn ọmọ Israeli silẹ. Ọkàn líle rẹ̀ di ohun ti ó ná Egipti ni ohun pupọ gidigidi nigba ti Ọlọrun mú ìyọnu kẹwaa ati eyi ti o kẹhin wá—ikú awọn àkọ́bí eniyan ati ẹranko. Àní ọmọkunrin àkọ́bí Farao paapaa parun, bi o tilẹ jẹ pe oun ni a wò gẹgẹ bi ọlọrun kan. Nipa bayii Jehofa ‘mú idajọ ṣẹ lori gbogbo awọn ọlọrun Egipti.’—Eksodu 12:12, 29.

Farao wá késí Mose ati Aaroni nisinsinyi ó sì wi pe: “Ẹ dide, ki ẹ jade lọ kuro laaarin awọn eniyan mi, ati ẹyin ati awọn ọmọ Israeli; ki ẹ sì lọ sin [Jehofa, NW], bi ẹ ti wí. Ẹ sì mú agbo yin ati ọwọ-ẹran yin, bi ẹ ti wí, ki ẹ sì maa lọ; ki ẹ sì súre fun mi pẹlu.”—Eksodu 12:31, 32.

Olùpa Awọn Eniyan Rẹ̀ Mọ́

Awọn ọmọ Israeli jade lọ, ṣugbọn laipẹ ó jọbi pe wọn ń rìn régberègbe kiri ninu aginju loju Farao. Oun ati awọn iranṣẹ rẹ̀ wá beere nisinsinyi pe: “Eeṣe ti awa fi ṣe eyi, ti awa fi jẹ ki Israeli ki o lọ kuro ninu isin wa?” (Eksodu 14:3-5) Ipadanu orilẹ-ede ẹrú yii yoo jẹ́ àjálù wiwuwo fun Egipti niti iṣunna-owo.

Farao kó awọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọpọ̀ wọn sì lé Israeli dé iyàníyàn Pi-hahirotu. (Eksodu 14:6-9) Niti ológun dé, ipo naa jọbi eyi ti o dara fun awọn ará Egipti nitori pe awọn ọmọ Israeli ni a ti sémọ́ aarin okun ati oke. Ṣugbọn Jehofa gbé igbesẹ lati daabobo awọn ọmọ Israeli nipa fifi awọsanma saaarin wọn ati awọn ará Egipti. Niha awọn ará Egipti, “awọsanma ati okunkun” wà, ni titipa bayii dènà igbejakoni. Ni ẹgbẹ́ keji, awọsanma naa mọlẹ, “ìmọ́lẹ̀ ni òru” fun Israeli.—Eksodu 14:10-20.

Awọn ará Egipti ni wọn pinnu lati piyẹ́ ki wọn sì ṣeparun ṣugbọn awọsanma naa dí wọn lọwọ. (Eksodu 15:9) Nigba ti o gbéra, ẹ wo iru iyanu ti o jẹ́! Awọn omi Òkun Pupa ni a ti pínníyà, ti awọn ọmọ Israeli sì ń kọja lọ si odikeji lori ilẹ gbígbẹ! Farao ati awọn ipá ológun rẹ̀ rá wọnu pẹ̀tẹ́lẹ̀ inu odò naa, ni mimuratan pẹlu lati kó awọn ẹrú wọn tẹlẹri ki wọn sì fi wọn ṣèjẹ. Bi o ti wu ki o ri, oluṣakoso Egipti onígbèéraga kò fi ti Ọlọrun awọn Heberu pè. Jehofa bẹrẹ sii sọ awọn ará Egipti sinu idarudapọ, ni yíyọ àgbá-kẹ̀kẹ́ kuro lara kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn.—Eksodu 14:21-25a.

“Ẹ jẹ ki a sá kuro niwaju Israeli,” ni awọn ọkunrin alagbara Egipti figbe ta, “nitori ti [Jehofa, NW] ń bá awọn ará Egipti jà fun wọn.” Ẹ̀pa kò bóró mọ́ fun Farao ati awọn ọkunrin rẹ̀ fun ohun ti wọn mọ̀ yii. Bi [awọn ọmọ Israeli] ti wà laisewu ni odikeji odò, Mose na ọwọ́ rẹ̀ jade siha òkun naa, omi naa sì pada, ni pípa Farao ati awọn ipá ológun rẹ̀.—Eksodu 14:25b-28.

Awọn Ẹ̀kọ́ ti Iriri Fi Kọ́ni

Wàyí o, nigba naa, ta ni Jehofa? Farao onígbèéraga rí idahun si ibeere yẹn. Awọn iṣẹlẹ ni Egipti fihàn pe Jehofa ni Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, ti kò dabi ‘awọn oriṣa asán’ ti awọn orilẹ-ede lọnakọna. (Orin Dafidi 96:4, 5) Nipa agbara mímọ́-ọlọ́wọ̀ rẹ̀, Jehofa “dá ọ̀run òun ayé.” Oun tun ni Oludande Ńlá, Ẹni naa ti o ‘mú awọn eniyan rẹ̀ Israeli jade wá lati ilẹ Egipti, pẹlu awọn àmì, iṣẹ-iyanu, ọwọ́ agbara, ati ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ńlá.’ (Jeremiah 32:17-21) Eyi ti fihàn daradara tó pe Jehofa lè daabobo awọn eniyan rẹ̀!

Farao kọ́ awọn ẹ̀kọ́ wọnni nipasẹ iriri kikoro. Niti tootọ, ẹ̀kọ́ ti o gbẹhin ná an ni iwalaaye rẹ̀. (Orin Dafidi 136:1, 15) Oun ì bá ti tubọ jẹ́ ọlọgbọ́n bi ó bá ti fi ẹmi irẹlẹ hàn nigba ti o beere pe, “Ta ni [Jehofa, NW]?” Nigba naa oluṣakoso yẹn ìbá ti huwa ni ibamu pẹlu idahun ti ó gbà. Lọna ti o muni layọ, ọpọlọpọ awọn onirẹlẹ eniyan lonii ń kẹkọọ ẹni ti Jehofa jẹ́. Iru akopọ animọ-iwa wo ni O sì ní? Ki ni ó beere lọwọ wa? Ǹjẹ́ ki ọrọ-ẹkọ ti o tẹlee mú imọriri rẹ pọ̀ sii fun Ẹni kanṣoṣo naa ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Jehofa.—Orin Dafidi 83:18.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́