ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 1/15 ojú ìwé 8-9
  • ‘Jáà Ni Ìgbàlà Mi’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Jáà Ni Ìgbàlà Mi’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Ṣì Ń Gbani Là Títí Dòní
  • Ta Ni Jehofa?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • ‘Ẹ Dúró Gbọn-in Kí ẹ Sì Rí Ìgbàlà Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tó Tẹ̀ Lé E
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 1/15 ojú ìwé 8-9

“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”

‘Jáà Ni Ìgbàlà Mi’

ÀWỌN èèyàn Jèhófà ní ìpinnu kan láti ṣe. Ṣé kí wọ́n ṣègbọràn sí òǹrorò tó jẹ́ alákòóso ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì ni? Àbí kí wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n fi oko ẹrú tí wọ́n wà sílẹ̀, kí wọ́n lọ máa gbé ní Ilẹ̀ Ìlérí?

Fáráò olóríkunkun tí í ṣe ọba Íjíbítì kọ̀ jálẹ̀ kò jẹ́ káwọn èèyàn Jèhófà lọ, ìdí nìyí tí Ọlọ́run fi fi Ìyọnu Mẹ́wàá kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì. Èyí fi hàn dájú pé agbára Ọlọ́run kì í ṣe kékeré! Àwọn òrìṣà táwọn ará Íjíbítì ń bọ kò lè dènà àwọn ìyọnu náà.

Nígbà tí Mósè sọ fún Fáráò pé kó jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run lọ, Fáráò kò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí, ó ní: “Ta ni Jèhófà, tí èmi yóò fi ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀ láti rán Ísírẹ́lì lọ? Èmi kò mọ Jèhófà rárá àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, èmi kì yóò rán Ísírẹ́lì lọ.” (Ẹ́kísódù 5:2) Ohun tó ṣe yìí ló kó bá àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n fi rí àwọn ìyọnu wọ̀nyí: (1) omi di ẹ̀jẹ̀, (2) àkèré, (3) kantíkantí, (4) eṣinṣin, (5) àjàkálẹ̀ àrùn kọ lu àwọn ohun ọ̀sìn, (6) oówo mú èèyàn àti ẹranko, (7) òjò yìnyín, (8) eéṣú, (9) òkùnkùn, àti (10) àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì kú, títí kan àrẹ̀mọ Fáráò. Níkẹyìn, Fáráò dá àwọn Hébérù sílẹ̀. Àní, ńṣe ló tún ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa lọ!—Ẹ́kísódù 12:31, 32.

Láìfi àkókò ṣòfò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àtọkùnrin àtobìnrin àtọmọdé àtàgbà tí iye wọn tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta títí kan onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata fi Íjíbítì sílẹ̀. (Ẹ́kísódù 12:37, 38) Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ni Fáráò kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ apániláyà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Òkun Pupa, iwájú ò ṣeé lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣeé padà sí nítorí àwọn ọmọ ogun Fáráò ń bọ̀ lẹ́yìn, inú aṣálẹ̀ eléwu ni wọ́n sì wà. Síbẹ̀, Mósè sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Ẹ má fòyà. Ẹ dúró gbọn-in-gbọn-in, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà.”—Ẹ́kísódù 14:8-14.

Lọ́nà ìyanu, Jèhófà pín Òkun Pupa sí méjì káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè rọ́nà sá àsálà. Àmọ́ nígbà táwọn ọmọ Íjíbítì tẹ̀ lé wọn, Ọlọ́run mú kí omi òkun náà padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. “Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ni [Jèhófà] sọ sínú òkun.” (Ẹ́kísódù 14:26-28; 15:4) Kíkọ̀ tí Fáráò agbéraga kọ̀ láti bọ̀wọ̀ fún Jèhófà mú kó ṣègbé.

Jèhófà fi hàn ní Òkun Pupa pé “akin lójú ogun” lòun. (Ẹ́kísódù 15:3) Bíbélì sọ pé: “Ísírẹ́lì tún rí ọwọ́ ńlá tí Jèhófà lò ní ìlòdìsí àwọn ará Íjíbítì; àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 14:31; Sáàmù 136:10-15) Àwọn èèyàn náà fi hàn pé àwọn mọrírì ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, ìyẹn ló mú káwọn ọkùnrin wọn dára pọ̀ mọ́ Mósè nínú kíkọ orin ìṣẹ́gun, tí Míríámù ẹ̀gbọ́n Mósè sì ṣíwájú àwọn obìnrin nínú ijó.a

Jèhófà Ṣì Ń Gbani Là Títí Dòní

Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun kọ́ látinú bí Ọlọ́run ṣe lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó ta yọ láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là. Ẹ̀kọ́ kan ni pé agbára tí kò láàlà ni Jèhófà ní, àti pé kì í fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. Nínú orin ìṣẹ́gun tí Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ, wọ́n fi tìdùnnú-tìdùnnú sọ pé: “Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń fi ara rẹ̀ hàn ní alágbára nínú agbára ìlèṣe-nǹkan, Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè fọ́ ọ̀tá túútúú.”—Ẹ́kísódù 15:6.

Ẹ̀kọ́ míì tá a lè rí kọ́ ni pé ààbò àwọn èèyàn Ọlọ́run Olódùmarè jẹ ẹ́ lógún gan-an ni. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ ọ́ lórin pé: “Okun mi àti agbára ńlá mi ni Jáà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìgbàlà mi. Èyí ni Ọlọ́run mi, èmi yóò sì gbé e lárugẹ.” Ẹ̀kọ́ mìíràn sì tún ni pé kò sẹ́ni tó lè dènà ohun tí Jèhófà Ọlọ́run bá fẹ́ ṣe. Àwọn tí Ọlọ́run gbà là yìí fi tìdùnnú-tìdùnnú kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà, ta ní dà bí rẹ láàárín àwọn ọlọ́run? Ta ní dà bí rẹ, tí o ń fi ara rẹ hàn ní alágbára ńlá ní ìjẹ́mímọ́? Ẹni tí ó yẹ kí a fi àwọn orin ìyìn bẹ̀rù, Ẹni tí ń ṣe àwọn ohun ìyanu.”—Ẹ́kísódù 15:2, 11.

Bí Fáráò ọba Íjíbítì ìgbàanì ṣe fojú àwọn èèyàn Jèhófà gbolẹ̀, bẹ́ẹ̀ làwọn alákòóso ayé ń ṣe lóde òní. Àwọn agbéraga alákòóso lè máa “sọ ọ̀rọ̀ lòdì sí Ẹni Gíga Jù Lọ, [kí wọ́n] sì máa bá a lọ ní fífòòró àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ.” (Dáníẹ́lì 7:25; 11:36) Àmọ́ Jèhófà fi dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí [yín] kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí [yín] nínú ìdájọ́ ni [ẹ̀yin] yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.”—Aísáyà 54:17.

Ó ti dájú pé àwọn alátakò Ọlọ́run ò ní ṣàṣeyọrí, gẹ́gẹ́ bí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ò ṣe ṣàṣeyọrí. Ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń dáni nídè, irú bó ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè nígbèkùn àwọn ará Íjíbítì, fi ẹ̀rí hàn pé ohun tó tọ̀nà ni pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà táwọn àpọ́sítélì Jésù sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo oṣù January àti February nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2006.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

ǸJẸ́ O MỌ̀?

• Pé Jèhófà mú kí ẹ̀fúùfù líle fẹ́ láti òru mọ́jú kó bàa lè ṣeé ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gba àárín Òkun Pupa kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.—Ẹ́kísódù 14:21, 22.

• Pé ibi tó máa gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù kan láti kọjá láàárín Òkun Pupa ní àkókò kúkúrú yẹn ní láti fẹ̀ tó kìlómítà kan àtààbọ̀ tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn òrìṣà ilẹ̀ Íjíbítì ò lè dá Ìyọnu Mẹ́wàá tí Jèhófà fi kọ lu ilẹ̀ náà dúró

[Credit Line]

British Museum ló yọ̀ǹda ká ya fọ́tò àwọn ère mẹ́tẹ̀ẹ̀ta

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́