Ẹ̀KỌ́ 20
Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tó Tẹ̀ Lé E
Mósè àti Áárónì lọ jíṣẹ́ Jèhófà fún Fáráò, wọ́n sọ fún un pé: ‘Tó ò bá jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, màá rán àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ sí ilẹ̀ yìí.’ Àwọn eṣinṣin náà kún ilé gbogbo àwọn ọmọ Íjíbítì, àti ilé olówó àti ti tálákà. Gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì pátápátá ló kún fún àwọn eṣinṣin náà. Àmọ́ àwọn eṣinṣin yìí ò dé ilẹ̀ Góṣénì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé. Látorí ìyọnu kẹrin, àwọn ọmọ Íjíbítì nìkan ló ń jìyà àwọn ìyọnu náà. Fáráò wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ bá mi bẹ Jèhófà pé kó mú àwọn eṣinṣin náà kúrò. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ.’ Àmọ́, nígbà tí Jèhófà mú àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà kúrò tán, ńṣe ni Fáráò tún yíhùn pa dà pé òun ò ní jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Ṣé Fáráò tiẹ̀ kọ́gbọ́n kankan nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀?
Jèhófà sọ pé: ‘Tí Fáráò bá kọ̀, tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, gbogbo ẹranko àwọn ọmọ Íjíbítì máa ṣàìsàn, wọ́n á sì kú.’ Lọ́jọ́ kejì, àwọn ẹranko náà bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Ṣùgbọ́n kò sóhun tó ṣe àwọn ẹranko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, Fáráò ń ṣe agídí, kò sì gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
Jèhófà wá ní kí Mósè pa dà lọ sọ́dọ̀ Fáráò, kó sì da eérú sínú afẹ́fẹ́. Eérú náà wá di eruku, ó sì dà pọ̀ mọ́ afẹ́fẹ́. Eruku náà wá bo gbogbo àwọn ọmọ Íjíbítì. Ó sì fa eéwo tó ń dunni gan-an sára àwọn àtàwọn ẹranko wọn. Síbẹ̀, Fáráò yarí kanlẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lọ.
Jèhófà tún rán Mósè lọ sọ́dọ̀ Fáráò pé: ‘Kí ló dé tó ò jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ? Tó bá dọ̀la, òjò yìnyín máa rọ̀ sórí ilẹ̀ náà.’ Lọ́jọ́ kejì, Jèhófà mú kí òjò yìnyín rọ̀, ó mú kí àrá máa sán, ó sì mú kí iná sọ̀ kalẹ̀. Àwọn ọmọ Íjíbítì ò rí irú òjò tó le tó báyìí rí. Ọ̀pọ̀ igi ló wó, àwọn nǹkan ọ̀gbìn sì bà jẹ́. Ṣùgbọ́n kò sóhun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Góṣénì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé. Fáráò tún pe Mósè, ó sì sọ fún un pé: ‘Bá wa bẹ Jèhófà pé kó dáwọ́ òjò náà dúró.’ Ó tiẹ̀ tún sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ. Àmọ́ lẹ́yìn tí òjò yìnyín náà dáwọ́ dúró, Fáráò tún yarí, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ mọ́.
Lẹ́yìn náà, Mósè sọ pé: ‘Ní báyìí, àwọn kòkòrò eéṣú máa jẹ ohun tó bá ṣẹ́ kù nínú nǹkan ọ̀gbìn tí òjò yìnyín náà ò bà jẹ́.’ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò ya dé, wọ́n sì jẹ gbogbo nǹkan tó ṣẹ́ kù lórí àwọn igi àti ní ilẹ̀ náà run. Fáráò tún wá pe Mósè, ó sì ní kó bẹ Jèhófà pé kó lé àwọn kòkòrò náà dà nù. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Jèhófà mú káwọn kòkòrò náà lọ, Fáráò kò tún gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
Jèhófà tún wá sọ fún Mósè pé: ‘Na ọwọ́ rẹ sí ojú ọ̀run.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ojú ọ̀run dúdú. Fún odindi ọjọ́ mẹ́ta, àwọn ọmọ Íjíbítì ò rí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ wà níbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé.
Fáráò wá sọ fún Mósè pé: ‘Ìwọ àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ. Ṣùgbọ́n ẹ fi àwọn ẹranko yín sílẹ̀ níbí.’ Mósè fèsì pé: ‘A gbọ́dọ̀ kó àwọn ẹranko wa dání ká lè fi wọ́n rúbọ sí Ọlọ́run wa.’ Inú bí Fáráò gan-an, ó wá pariwo pé: ‘Kóra ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi! Tí mo bá tún rí ẹ, màá pa ẹ́ ni.’
“Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—Málákì 3:18