Ẹ̀KỌ́ 21
Ìyọnu Kẹwàá
Mósè ṣèlérí fún Fáráò pé òun ò ní wá sọ́dọ̀ ẹ̀ mọ́. Àmọ́ kí Mósè tó lọ, ó sọ fún Fáráò pé: ‘Tó bá di òru, gbogbo àkọ́bí ẹ̀yin ará Íjíbítì máa kú, látorí ọmọkùnrin Fáráò dórí ọmọ àwọn ẹrú.’
Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì se oúnjẹ pàtàkì kan. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ pa àgbò kan tàbí òbúkọ kan tó ti pé ọdún kan, kẹ́ ẹ sì fi ẹ̀jẹ̀ ẹ̀ sàmì síbi ilẹ̀kùn ilé yín. Kẹ́ ẹ wá sun ẹran náà, kẹ́ ẹ sì fi búrẹ́dì aláìwú jẹ ẹ́. Kẹ́ ẹ wọ aṣọ àti bàtà yín, kẹ́ ẹ sì múra tán láti kúrò ní Íjíbítì. Òru yìí ni màá gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.’ Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ṣé inú wọn máa dùn àbí kò ní dùn?
Nígbà tó di òru, áńgẹ́lì Jèhófà lọ sí gbogbo ilé tó wà ní Íjíbítì. Tó bá ti dé ilé tí wọn ò fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí ilẹ̀kùn ẹ̀, ó máa pa àkọ́bí wọn. Àmọ́ ó máa ré kọjá àwọn ilé tí wọ́n bá fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí. Gbogbo àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì ló kú àtọmọ olówó àtọmọ tálákà. Àmọ́ kò sọ́mọ Ísírẹ́lì kankan tó kú.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọmọ Fáráò náà kú? Ìyẹn ló fà á tí ara Fáráò kò fi lè gbà á mọ́. Ló bá ránṣẹ́ pe Mósè àti Áárónì ní kíá, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ó yá, ó yá. Ẹ jáde kúrò nílùú wa. Ẹ lọ máa jọ́sìn Ọlọ́run yín. Ẹ kó gbogbo ẹran yín, kẹ́ ẹ máa lọ!’
Àárín òru tí òṣùpá mọ́lẹ̀ rokoṣo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọ́n ṣètò ara wọn ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, àti ní ẹbí kọ̀ọ̀kan. Iye àwọn ọkùnrin tó wà láàárín wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600,000). Àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó pọ̀ gan-an sì tún wà pẹ̀lú wọn. Àwọn míì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì náà bá wọn lọ kí wọ́n lè jọ máa sin Jèhófà. Níkẹyìn, Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú!
Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa rántí bóun ṣe dá wọn nídè, torí náà ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ pàtàkì yẹn lọ́dọọdún. Èyí ni wọ́n ń pè ní Ìrékọjá.
“Ìdí tí mo fi jẹ́ kí o máa wà nìṣó ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn nípasẹ̀ rẹ àti pé kí a lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.”—Róòmù 9:17