Ẹ̀KỌ́ 22
Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa
Nígbà tí Fáráò rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kúrò ní Íjíbítì, ó dùn ún pé òun jẹ́ kí wọ́n lọ. Ó wá pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé: ‘Ẹ kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun mi jáde, kẹ́ ẹ sì jẹ́ ká lé wọn! Kò yẹ ká jẹ́ kí wọ́n lọ.’ Bó ṣe di pé òun àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn.
Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn ẹ̀, ó lo ìkùukùu ní ọ̀sán, ó sì ń lo iná ní alẹ́. Ó darí wọn gba ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pàgọ́.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ tí wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n torí wọn ò mọ ibi táwọn máa sá gbà. Àwọn ọmọ ogun Íjíbítì rèé lẹ́yìn, Òkun Pupa sì wà níwájú. Wọ́n wá sọ fún Mósè pé: ‘Ikú ti dé! Ò bá ti fi wá sílẹ̀ ní Íjíbítì.’ Àmọ́ Mósè sọ pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kẹ́ ẹ sì rí bí Jèhófà ṣe máa gbà wá là.’ Ó ṣe kedere pé Mósè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kó àwọn àgọ́ wọn. Lóru ọjọ́ yẹn, Jèhófà mú kí ìkùukùu náà lọ sí ẹ̀yìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó wá wà láàárín àwọn àtàwọn ọmọ Íjíbítì. Ìkùukùu yẹn mú kí òkùnkùn wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Íjíbítì, ó sì mú kí ìmọ́lẹ̀ wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
Jèhófà sọ fún Mósè pé kó na ọwọ́ rẹ̀ sí òkun náà. Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí afẹ́fẹ́ tó lágbára fẹ́ ní gbogbo òru títí ilẹ̀ fi mọ́. Bó ṣe di pé òkun yẹn pín sí méjì nìyẹn, tó sì mú kí ọ̀nà wà tí wọ́n lè gbà kọjá. Ojú ọ̀nà yẹn làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà, omi náà wá dà bí ògiri lọ́tùn-ún àtòsì wọn.
Àwọn ọmọ ogun Fáráò tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú òkun náà. Jèhófà wá mú kí nǹkan dojú rú fáwọn ọmọ ogun Fáráò. Bó ṣe di pé ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fò yọ nìyẹn. Làwọn ọmọ ogun náà bá pariwo pé: ‘Ẹ jẹ́ ká pa dà lẹ́yìn wọn! Jèhófà ló ń jà fún wọn.’
Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Na ọwọ́ rẹ sí òkun náà.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, omi náà ya bo àwọn ọmọ ogun Íjíbítì. Fáráò àti gbogbo àwọn ọmọ ogun ẹ̀ sì kú. Kò sẹ́nì kankan nínú wọn tó yè é.
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé òdìkejì òkun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin yin Jèhófà pé: “Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà, torí ó ti di ẹni àgbéga. Ó taari ẹṣin àti ẹni tó gùn ún sínú òkun.” Báwọn èèyàn náà ṣe ń kọrin, àwọn obìnrin ń jó, wọ́n sì ń lu ìlù tanboríìnì. Inú wọn dùn pé ní báyìí àwọn ti kúrò lóko ẹrú.
“Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?’”—Hébérù 13:6