Ẹ̀KỌ́ 19
Ìyọnu Mẹ́ta Àkọ́kọ́
Àwọn ọmọ Íjíbítì fi dandan sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, wọ́n sì fún wọn ní iṣẹ́ tó le gan-an. Jèhófà wá rán Mósè àti Áárónì lọ sọ́dọ̀ Fáráò, ó sì ní kí wọ́n sọ fún un pé: ‘Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, kí wọ́n lè jọ́sìn mi nínú aginjù.’ Àmọ́ Fáráò dá wọn lóhùn pé: ‘Kò sí èyí tó kàn mí pẹ̀lú ohun tí Jèhófà sọ, mi ò sì ní jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.’ Torí ìyẹn, Fáráò fi kún iṣẹ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe. Jèhófà wá kọ́ Fáráò lọ́gbọ́n. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà ṣe? Jèhófà mú kí Ìyọnu Mẹ́wàá ṣẹlẹ̀ sáwọn ará Íjíbítì. Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Fáráò ò ṣe ohun tí mo sọ. Tí ilẹ̀ bá mọ́, lọ bá a ní Odò Náílì, kó o sì sọ fún un pé, torí pé kò jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, gbogbo omi Odò Náílì máa di ẹ̀jẹ̀.’ Mósè ṣègbọràn sí Jèhófà, ó sì lọ bá Fáráò. Áárónì wá fi ọ̀pá ẹ̀ lu Odò Náílì níṣojú Fáráò, gbogbo omi náà sì di ẹ̀jẹ̀. Odò náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í rùn, àwọn ẹja inú ẹ̀ sì kú. Ó wá di pé omi odò náà kò ṣeé mu mọ́. Síbẹ̀, Fáráò ò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
Lẹ́yìn ọjọ́ méje, Jèhófà rán Mósè pa dà lọ sọ́dọ̀ Fáráò, ó ní kó sọ fún un pé: ‘Tó ò bá jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, àkèré máa kún gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.’ Áárónì wá na ọ̀pá ẹ̀, àkèré sì kún ilẹ̀ náà. Ṣe làwọn àkèré yẹn kún gbogbo inú ilé, wọ́n wà lórí bẹ́ẹ̀dì, kódà wọ́n tún kó sínú abọ́ oúnjẹ wọn. Gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì wá kún fún àkèré! Fáráò wá pe Mósè, ó sì ní kó bẹ Jèhófà pé kó dáwọ́ ìyọnu yẹn dúró. Fáráò tiẹ̀ sọ pé òun máa jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Torí náà, Jèhófà dáwọ́ ìyọnu yẹn dúró. Báwọn ará Íjíbítì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kó òkú àkèré jọ rẹpẹtẹ síbi gbogbo nìyẹn. Gbogbo ìlú náà sì wá ń rùn gan-an. Síbẹ̀, Fáráò ò gbọ́, kò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
Jèhófà ní kí Mósè sọ fún Áárónì pé kó fi ọ̀pá ẹ̀ lu ilẹ̀, iyẹ̀pẹ̀ sì máa di kòkòrò abìyẹ́, ìyẹn àwọn kòkòrò kéékèèké tó ń mùjẹ̀. Nígbà tí Áárónì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn kòkòrò náà kún gbogbo ìlú. Àwọn ọmọ Íjíbítì kan tiẹ̀ sọ fún Fáráò pé: ‘Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìyọnu yìí ti wá.’ Síbẹ̀, Fáráò ta kú, kò sì jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
“Màá jẹ́ kí wọ́n mọ agbára àti okun mi, wọ́n á sì gbà pé Jèhófà ni orúkọ mi.”—Jeremáyà 16:21