Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jehofa
Mose àti Aaroni—Àwọn Onígboyà Olùpòkìkí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
RONÚ nípa ìran náà: Mose ẹni 80 ọdún àti arákùnrin rẹ̀, Aaroni, dúró níwájú ọkùnrin lílágbára jù lọ lórí ilẹ̀ ayé—Farao ti Egipti. Lójú àwọn ará Egipti, ọkùnrin yìí kì í wulẹ̀ ṣe aṣojú àwọn ọlọrun. Wọ́n gbà gbọ́ pé, òun alára jẹ́ ọlọrun. Wọ́n kà á sí Horus ní àwọ̀ ènìyàn, ọlọrun àjúbàfún aborí-bíi-ti-àṣá. Pa pọ̀ pẹ̀lú Isis àti Osiris, Horus jẹ́ apá pàtàkì mẹ́talọ́kan láàárín àwọn ọlọrun àti abo-ọlọ́run Egipti.
Kedere ni ẹni tí ó bá tọ Farao wá, yóò máa wo àwòrán akópayàbáni ti orí ọká tí ó yọ ṣọnṣọ láti àárín adé rẹ̀. Wọ́n gbà pé, ejò yìí lè tu iná jáde, kí ó sì pa èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀tá Farao run. Wàyí o, Mose àti Aaroni ti wá síwájú aṣọlọ́run-ṣọba yìí pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ kan tí irú rẹ̀ kò wáyé rí—pé kí ó ran àwọn ọmọ Israeli tí ó wà ní oko ẹrú jáde, kí wọn baà lè ṣe àjọyọ̀ sí Ọlọrun wọn, Jehofa.—Eksodu 5:1.
Jehofa ti sọ tẹ́lẹ̀ rí pé, ọkàn Farao yóò yigbì. Nítorí náà, kò ya Mose àti Aaroni lẹ́nu láti gbọ́ èsì aṣàyà-gbàǹgbà-peni-níjà rẹ̀ pé: “Ta ni OLUWA, tí èmi óò fi gba ohùn rẹ̀ gbọ́ láti jẹ́ kí Israeli kí ó lọ? Èmi kò mọ OLUWA náà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí Israeli kí ó lọ.” (Eksodu 4:21; 5:2) Nípa báyìí, ohun gbogbo ti wà ní sẹpẹ́ fún ìkòlójú amúnijígìrì. Nígbà ìtàpórógan tí ó tẹ̀ lé e, Mose àti Aaroni pèsè ẹ̀rí amúnigbọ̀nrìrì fún Farao, pé àwọn ń ṣojú fún Ọlọrun tòótọ́, alágbára gbogbo.
Iṣẹ́ Ìyanu Ṣẹlẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tí Jehofa fún un, Aaroni ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tí ó fi ẹ̀rí hàn pé, Jehofa tóbi lọ́lá ju àwọn ọlọrun Egipti lọ. Ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao, lójú ẹsẹ̀, ó di ejò ńlá! Nítorí tí iṣẹ́ ìyanu yìí pá a láyà, Farao ké sí àwọn abọrẹ̀ onídán rẹ̀.a Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ agbára ẹ̀mí èṣù, ó ṣeé ṣe fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí láti ṣe ohun kan tí o fara jọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀pá wọn.
Bí Farao àti àwọn abọrẹ̀ rẹ̀ bá rò pé àwọn ti ṣàṣeyọrí, kìkì fún ìgbà díẹ̀ ni. Ronú nípa bí ojú wọn yóò ṣe rí, nígbà tí ejò Aaroni gbé ejò wọn mì káló, lọ́kọ̀ọ̀kan! Gbogbo àwọn tí o pésẹ̀ lè rí i pé àwọn ọlọrun àjúbàfún àwọn ará Egipti kò jẹ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọrun tòótọ́ náà, Jehofa.—Eksodu 7:8-13.
Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn èyí, ọkàn Farao yigbì síbẹ̀. Kìkì lẹ́yìn ìgbà tí Ọlọrun mú àwọn àgbálù tàbí ìyọnu mẹ́wàá amúnibanújẹ́ wá sórí Egipti ni Farao tó, sọ fún Mose àti Aaroni nígbẹ̀yìngbẹ́yín pé: “Ẹ dìde, kí ẹ jáde lọ kúrò láàárín àwọn ènìyàn mi, àti ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Israeli; kí ẹ sì lọ sin OLUWA, bí ẹ ti wí.”—Eksodu 12:31.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Kí ni ó ran Mose àti Aaroni lọ́wọ́ láti lè tọ Farao alágbára, ti Egipti lọ? Lákọ̀ọ́kọ́, Mose fi àìní ìgbọ́kànlé hàn nínú agbára rẹ̀, ní sísọ pé ‘olóhùn wíwúwo ni òun, àti aláhọ́n wíwúwo.’ Àní lẹ́yìn tí a fi í lọ́kàn balẹ̀ pé Jehofa yóò tì í lẹ́yìn, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Èmí bẹ̀ ọ́, rán ẹni tí ìwọ óò rán.” Ní èdè míràn, Mose bẹ̀bẹ̀ pé, kí Ọlọrun rán ẹlòmíràn. (Eksodu 4:10, 13) Síbẹ̀, Jehofa lo Mose ọlọ́kàn tútù, ní fífún un ní ọgbọ́n àti okun tí ó nílò láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un.—Numeri 12:3.
Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi ń tẹ̀ lé àṣẹ náà láti “sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn.” (Matteu 28:19, 20) Láti ṣe ojúṣe wa nínú iṣẹ́ àṣẹ yìí, a ní láti lo ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ àti agbára èyíkéyìí tí a lè ní lọ́nà tí ó dára jù lọ. (1 Timoteu 4:13-16) Dípò dídarí àfiyèsí sí ìkù-díẹ̀-káàtó wa, ẹ jẹ́ kí a fi ọkàn ìgbàgbọ́ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ọlọrun bá yàn fún wa. Ó lè mú kí a tóótun, ó sì lè fún wa lókun láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—2 Korinti 3:5, 6; Filippi 4:13.
Níwọ̀n bí Mose ti dojú kọ ẹ̀dá ènìyàn àti ẹ̀mí èṣù alátakò, dájúdájú, ó nílò ìrànlọ́wọ́ tí ó ré kọjá ti ẹ̀dá ènìyàn. Nítorí èyí, Jehofa fi í lọ́kàn balẹ̀ pé: “Wò ó, èmi fi ọ́ ṣe ọlọrun fún Farao.” (Eksodu 7:1) Bẹ́ẹ̀ ni, Mose ní ìtìlẹyìn àti ọlá àṣẹ àtọ̀runwá. Pẹ̀lú ẹ̀mí Jehofa lórí rẹ̀, Mose kò ní ìdí kankan láti bẹ̀rù Farao tàbí ẹgbẹ́ ọmọ ogun agbéraga olùṣàkóso náà.
Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Jehofa, tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀, láti lè ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Johannu 14:26; 15:26, 27) Pẹ̀lú ìtìlẹyìn àtọ̀runwá, a lè tún àwọn ọ̀rọ̀ Dafidi sọ, ẹni tí ó kọrin pé: “Ọlọrun ni èmi gbẹ́kẹ̀ mi lé, èmi kì yóò bẹ̀rù kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi.”—Orin Dafidi 56:11.
Nínú ìyọ́nú rẹ̀, Jehofa kò fi Mose sílẹ̀ lóun nìkan nínú iṣẹ́ tí ó yàn fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọrun wí pé: “Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò sì máa ṣe wòlíì rẹ. Ìwọ óò sọ gbogbo èyí tí mo pa láṣẹ fún ọ: Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò sì máa sọ fún Farao.” (Eksodu 7:1, 2) Ẹ wo bí Jehofa ṣe fi ìfẹ́ hàn tó, láti fi iṣẹ́ Mose mọ sí ìwọ̀nba ibi tí agbára rẹ̀ ká!
Ọlọrun pèsè ìkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa fún wa, àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìpèníjà ti dídi Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, Ọ̀gá Ògo. (1 Peteru 5:9) Láìka àwọn ìdènà tí a lè dojú kọ sí, ẹ jẹ́ kí a dà bíi Mose àti Aaroni—àwọn onígboyà olùpòkìkí ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Heberu náà tí a túmọ̀ sí “àwọn abọrẹ̀ onídán” ń tọ́ka sí ẹgbẹ́ àwọn oṣó tí wọ́n jẹ́wọ́ pé, àwọ́n ní agbára tí ó ré kọjá ti àwọn ẹ̀mí èṣù. Wọ́n gbà gbọ́ pé, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lè pe àwọn ẹ̀mí èṣù láti ṣègbọràn sí wọn, àti pé àwọn ẹ̀mí èṣù kò ní agbára lórí àwọn oṣó wọ̀nyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Mose àti Aaroni fi tìgboyàtìgboyà ṣojú fún Jehofa níwájú Farao