‘Fifunrugbin Pẹlu Omije ati Kikarugbin Pẹlu Igbe Ayọ’
Gẹgẹ bi Miyo Idei ti sọ ọ́
“Mo kú o! Mo kú o! Ẹ gbà mí o!” Baba mi nsapa lati kébòòsí. Ariwo rẹ gbalẹ kankan gẹgẹ bi mo ti sá jade kuro ninu ile. O jẹ́ ọganjọ oru, baba mi sì ni ikọlu aisan ọkan-aya. Mo sare lọ sọdọ aburo baba mi, ti o ngbe nitosi, ṣugbọn nigba ti a pada de, a ko lè gbọ ìlùkìkì ọkan-aya Baba mi mọ.
IYẸN ṣẹlẹ ni December 14, 1918. Ni ẹni ọdun 13, a fi mi silẹ lailobii. Iya mi ti ku nigba ti mo jẹ́ ẹni ọdun meje. Ni pipadanu awọn obi mejeeji ni kutukutu igbesi-aye mi, mo bẹrẹ sii ṣe kayeefi, ‘Eeṣe ti awọn eniyan fi ńkú? Ki ni nṣẹlẹ lẹhin iku?’
Lẹhin ti mo kẹkọọ jade kuro ni ile-ẹkọ awọn olukọ, mo di olukọ kan ni Tokyo mo si ṣe olukọ ni Ile-ẹkọ Alakọọkọbẹrẹ ti Shinagawa. Lẹhin naa, ojulumọ mi kan fi mi han ọdọmọkunrin kan, Motohiro ẹni ti mo fẹ ni ẹni ọdun 22. Fun ọdun 64 ti o ti kọja, a ti ṣajọpin awọn iriri igbesi-aye didun ati kíkan. Laipẹ, a ṣí lọ si Taiwan, eyi ti o wà labẹ akoso Japan nigba naa. Ni akoko naa emi ko ronu pe emi yoo ri idi fun igbe ayọ ni ilẹ yẹn.
Kikẹkọọ Otitọ
Ni igba iruwe 1932, nigba ti a ngbe ni eréko Chiai ni aarin gbùngbùn Taiwan, ọkunrin kan ti a npe orukọ rẹ ni Saburo Ochiai bẹ̀ wá wò. O ṣalaye pe awọn asọtẹlẹ Bibeli ní ileri ajinde awọn oku ninu. (Johanu 5:28, 29) Iru ifojusọna agbayanu wo ni eyi jẹ́! Mo nfẹ gidigidi lati ri mama ati baba mi lẹẹkansii. Pẹlu awọn ero rẹ̀ ti o bá ọgbọn mu, awọn alaye ti o ba ọgbọn mu, ati ẹri lilagbara lati inu Bibeli, ọrọ rẹ jọ bii pe ó jẹ ootọ. Akoko yara kọja gẹgẹ bi a ti lo gbogbo ọjọ naa fun jijiroro Bibeli. O di iwe fifanimọra kan fun mi lojiji.
Laipẹ Ọgbẹni Ochiai ṣí lọ si ibomiran, ti o sì fi awọn iwe bii Creation, Duru Ọlọrun, Government, Prophecy, Light, ati Ilàjà silẹ fun wa, gbogbo rẹ ni a tẹ jade lati ọwọ Watch Tower Bible and Tract Society. Kíkà wọn gbà mi lọkan, gẹgẹ bi mo si ti nṣe bẹẹ, mo nimọlara isunniṣe lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa ohun ti mo nka. Bi Jesu ba bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ ni ilu ibilẹ rẹ̀ Nasarẹti, eeṣe ti emi ko le bẹrẹ nibi ti mo ngbe? Mo lọ si ẹnu ọna aladuugbo mi keji. Ko si ẹni ti o kọ́ mi ni bi a tii waasu, nitori naa mo lọ lati ile de ile pẹlu Bibeli mi ati awọn iwe ti mo ti kà, ni wiwaasu gẹgẹ bi mo ti le ṣe daradara tó. Awọn eniyan fi ojurere dahun pada wọn si gba awọn iwe irohin. Mo beere lọwọ Todaisha, gẹgẹ bi a ti npe Watch Tower Society nigba naa, lati fi 150 ẹ̀dà iwe pẹlẹbẹ ti o ni akori naa The Kingdom, the Hope of the World, ranṣẹ si mi mo si pín wọn kiri.
Ni ọjọ kan ẹnikan ti o ti gba iwe ikẹkọọ sọ fun mi pe awọn ọlọpaa wá kete lẹhin ti mo kuro lati fi aṣẹ kó awọn iwe naa lọ. Laipẹ lẹhin iyẹn, awọn ọlọpaa-inu mẹrin wa si ile mi wọn sì fi aṣẹ kó gbogbo awọn iwe ati iwe irohin mi. Wọn fi Bibeli nikan silẹ. Fun ọdun marun un, emi ko pade ẹnikankan lara awọn eniyan Jehofa, ṣugbọn ina otitọ nbaa lọ lati jó ninu ọkan mi.
Lẹhin naa December 1937 de! Awọn apinwe isin kiri meji lati Japan bẹ̀ wá wò. O yà mi lẹnu, mo beere pe: “Bawo ni ẹ ṣe mọ nipa wa?” Wọn wi pe: “A ni orukọ yin nihin in.” Jehofa ti ranti wa! Awọn Ẹlẹrii mejeeji, Yoriichi Oe ati Yoshiuchi Kosaka, ti gun kẹkẹ fun nǹkan bi 150 ibusọ lati Taipei si Chiai lori awọn ogbologboo kẹkẹ pẹlu awọn ohun ìní wọn ti a dì gègèrè si ẹhin. Gẹgẹ bi wọn ti nba wa sọrọ, mo ni imọlara bii iwẹfa ara Etopia naa ẹni ti o wi pe: “Ki ni o dá mi duro lati baptisi?” (Iṣe 8:36) Ni alẹ ọjọ ti wọn dé, emi ati ọkọ mi ṣe baptisi.
Bibikita fun Awọn Arakunrin Ti A Fi Sẹwọn
Ni 1939 fifaṣẹ ọba mu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹrẹ lojiji jakejado Japan. Ìgbì inunibini naa dé Taiwan laipẹ. Ni April awọn Arakunrin mejeeji Oe ati Kosaka ni a faṣẹ ọba mu. Oṣu meji lẹhin naa awa pẹlu ni a tun faṣẹ ọba mu. Nitori pe mo jẹ olukọ, a tú mi silẹ ni ọjọ keji, ṣugbọn a dá ọkọ mi duro sinu itimọle fun oṣu mẹrin. Lẹhin ti a tú ọkọ mi silẹ, a ṣi lọ si Taipei. Gẹgẹ bi a ti wà nitosi ọgba ẹwọn nibi ti a fi awọn arakunrin mejeeji sí nisinsinyi, eyi jasi iṣeto rere kan.
Ọgba ẹwọn Taipei jẹ ọgba ẹwọn kan ti o ní aabo gírígírí. Ni mimu aṣọ ati ounjẹ, mo lọ lati ri awọn arakunrin naa. Lakọọkọ, Arakunrin Kosaka farahan pẹlu oluṣọ ati ọlọpaa-inu kan lẹhin ferese oni inṣi 12 ti o ni okun irin wọ́ngan wọ̀ngan. Ara rẹ ti ri ràndánràndán ete rẹ sì pupa bii awọn eso strawberry tutu. Ikọ ẹgbẹ ti mu un.
Lẹhin naa Arakunrin Oe jade wa pẹlu ẹrin musẹ ni oju rẹ̀, ni titun un sọ pẹlu ayọ pe: “O dara ti iwọ le wa.” Gẹgẹ bi oju rẹ̀ ti pọ́n tí ó sì wú, mo beere nipa ilera rẹ̀. O dahun pe, “Mo wà daadaa!” Ibi yii jẹ ibi ti ó dara gan an. Ko si idun tabi ina. Mo tilẹ le jẹ awọn mundunmundun ọka. Nṣe ni o wulẹ dabii ile àdágbé,” ni ó wí. Ọlọpaa ati oluṣọ naa ko le pa ẹrin mọra wọn si wi pe: “Óò, a ko le ṣẹgun ẹni ti ńjẹ́ Oe yii.”
A Fi Wa Sẹwọn Lẹẹkansii
Ni nǹkan bi ọganjọ oru ni November 30, 1941, ọjọ diẹ lẹhin igba ti mo pada si ile lẹhin bibẹ awọn ara wò, mo gbọ ìró ilẹkun lílù, mo ri ojiji awọn fila ti wọn rí ribiti ribiti bi oke ninu ilẹkun gilaasi aláfàpadé. Mẹjọ ni mo fi wọn kà. Wọn jẹ ọlọpaa. Wọn fipa wọ inu ile wa wọn si tú ohun gbogbo ká jánnajànna ninu ile—ṣugbọn gbogbo rẹ jasi asan. Lẹhin wakati kan ti wíwá inu ile naa kínníkínní, wọn fi aṣẹ kó awọn alubọọmu fọto diẹ wọn si sọ fun wa lati tẹle wọn. Mo ranti pe Jesu ni a faṣẹ ọba mu ni aarin òru. (Matiu 26:31, 55-57; Johanu 18:3-12) Ironu awọn ọkunrin mẹjọ naa ti wọn nṣeyọnu pupọ tobẹẹ lori awa mejeeji pa mi lẹrin-in.
A mu wa lọ si ile kan ti a kò mọ̀ ti o tobi ti o sì ṣokunkun. A wá mọ̀ lẹhin naa pe ile naa ni Ẹwọn Taipei Hichisei. A fi wa jokoo niwaju tabili titobi kan, ifọrọwanilẹnuwo sì bẹrẹ. Leralera wọn beere pe: “Ta ni ẹ mọ?” Ọkọọkan wa si fesi pada pe: “Emi ko mọ ẹni kankan.” Bawo ni a ṣe le mọ awọn ẹni ti wọn wa ni aarin ilu Japan? Awa mọ kiki Arakunrin Oe ati Kosaka, a si pa ẹnu wa mọ niti awọn orukọ eyikeyii miiran ti a ti le gbọ lọna aiṣe taarata.
Laipẹ agogo marun un owurọ lù, awọn ọlọpaa-inu meji mu mi lọ si yara ọgba ẹwọn mi. O pẹ diẹ ki ayika titun naa to lè mọ́ mi lara. Fun igba akọkọ ni igbesi-aye mi, mo ba ìdun pade. Awọn kokoro kekeke wọnyi, ti wọn nharagaga lati jàsè lara awọn ẹni titun, yọ mi lẹnu laisimi, ni fifi awọn obinrin meji yooku ninu sẹ́ẹ̀lì naa silẹ—laika a sí pe mo tẹ awọn eyi ti mo rí pa. Nikẹhin mo jọ̀gọ̀nù mo si jẹ ki wọn jẹ mi tẹ́rùn.
Ounjẹ wa jẹ ilaji agolo irẹsi ti a kò se jinna, ṣugbọn o dabii irẹsi tutu lẹnu mi. Awọn ewe daikon (radish awọn ara Japan) ti a fi iyọ sí ti o ní eerun okuta lara ni a fi njẹ irẹsi olomi ṣòròṣoro naa. Lakọọkọ, nitori pe ounjẹ naa run oorun ti ko dara ti o sì dọti, inu mi ko le gba a, awọn ẹlẹwọn miiran si wa wọn si jẹ ẹ́. Bi o ti wu ki o ri, ni kẹrẹkẹrẹ mo mu araami ba ipo mu ki nba le walaaye.
Igbesi-aye ninu ọgba ẹwọn buru pupọ. Ni akoko kan mo gbọ ti ọkunrin kan ti a fura sí pe o jẹ amí nkerora fun ọpọlọpọ ọjọ lati inu idaloro. Mo tun rí ẹnikan ninu iyara ẹwọn keji ti o kú ninu irora. Pẹlu gbogbo eyi ti o ṣẹlẹ ni oju mi, mo nimọlara mimuna pe eto-igbekalẹ ogbologboo yii gbọdọ dopin, ireti mi ninu awọn ileri Ọlọrun si lagbara ju ti igbakigba ri lọ.
Fifi Ibeere Wanilẹnuwo
A há mi mọ inu ẹwọn fun nǹkan bi ọdun kan a si fi ibeere wa mi lẹnuwo fun igba marun un. Ni ọjọ kan abaniṣẹjọ kan wa fun igba akọkọ a si mu mi lọ si iyara ifibeere wanilẹnuwo kotopo kan. Ohun akọkọ ti o sọ ni pe: “Ta ni o tobi ju, Amaterasu Omikami [abo-ọlọrun oorun] tabi Jehofa? Dá mi lohun kíá!” Mo ronu fun igba diẹ nipa bi emi yoo ṣe dahun.
“Sọ ẹni ti o tobi ju fun mi, bikoṣe bẹẹ emi yoo lù ọ!” Ó gbójú koko mọ mi.
Mo fi pẹlẹ dahun pe: “Ni ibẹrẹ Bibeli gan an, a kọ ọ pe, ‘Ni atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun oun aye.’” Nko ri idi lati fi ohunkohun kun un. O wulẹ tẹju mọ mi laisọ ọrọ kankan ati lẹhin naa ó yi ọrọ naa pada.
Ó ṣetan, fun idi wo ni a ṣe fi mi sinu àhámọ́? Akọsilẹ ayẹwo wi pe: “O ṣeeṣe pe ki o ṣi awọn eniyan lọna nipa ọrọ ati iṣe rẹ.” Eyi ni idi ti a fi há mi mọ laisi igbẹjọ.
Jehofa maa nduro tì mí nigba gbogbo nigba ti mo nla gbogbo eyi kọja. Nipa inurere Jehofa, a pese Iwe mimọ Kristẹni lede Giriiki kan ti o ṣee ki bọ apo fun mi. Ọlọpaa inu kan ju u sinu yara ẹwọn mi ni ọjọ kan, ni wiwi pe: “Emi yoo fun ọ ni eyi.” Mo nka a ni gbogbo ọjọ dé ori híhá ohun ti mo nka sori. Awọn apẹẹrẹ onigboya ti awọn Kristẹni ọgọrun un ọdun kìn-ín-ní ninu iwe Iṣe di orisun iṣiri titobi kan fun mi. Awọn lẹta Pọọlu 14 tun fun mi lokun. Pọọlu niriiri apọju inunibini, ṣugbọn ẹmi mimọ tii lẹhin nigba gbogbo. Iru akọsilẹ bẹẹ fun mi lagbara.
Mo rù gan an mo si di alailagbara, ṣugbọn Jehofa gbé mi ró, niye igba ni awọn ọna airotẹlẹ. Ni ọjọ Sunday kan ọlọpaa-inu kan ti emi ko mọ rí wa pẹlu ẹru kan ti a dì sinu ìwérí. O ṣi ilẹkun yara ẹwọn naa o sì mu mi jade sinu agbala. Nigba ti a de idi igi kanfọ titobi kan, o tu ẹru naa. Wo o sì kiyesi! Awọn ọgẹdẹ ati bọnsi wa ninu rẹ̀. O sọ fun mi pe ki njẹ wọn nibẹ. Ọlọpaa-inu naa sọ pe: “Gbogbo yin ni ẹ jẹ eniyan rere gan an. Sibẹ a nhuwa si yin ni ọna yii. Emi yoo fẹ lati kuro ni ẹnu iṣẹ yii laipẹ.” Nipa bayii awọn oluṣọ ati ọlọpaa-inu bẹrẹ sii fi inurere lo sí mi. Wọn nigbọkanle ninu mi wọn si njẹ ki nmaa tọju iyara wọn wọ́n si nfun mi ni oniruuru anfaani iṣẹ miiran.
Niha opin 1942, ọkan lara awọn ọlọpaa-inu ti wọn faṣẹ ọba mu mi ké si mi. “Bi o tilẹ jẹ pe o lẹtọọ si idajọ iku, a o tu ọ silẹ lonii,” ni o polongo. Ọkọ mi ti pada si ile ni nǹkan bi oṣu kan ṣaaju ki a to tu mi silẹ.
Sisọ Ibakẹgbẹpọ Pẹlu Awọn Ẹlẹrii Dọtun
Nigba ti a wà ninu ọgba ẹwọn, Japan kowọnu Ogun Agbaye Keji. Lẹhin naa, ni 1945, a gbọ pe Japan ti padanu ogun naa, a si kà ninu iwe irohin pe awọn ẹlẹwọn oṣelu ni a o tú silẹ. A mọ pe Arakunrin Kosaka ti ku nitori aisan ninu ẹwọn, ṣugbọn mo yara kọ lẹta ranṣẹ si awọn ọgba ẹwọn ni Taipei, Hsinchu, ati awọn ilu miiran lati beere nipa ibi ti Arakunrin Oe wa. Bi o ti wu ki o ri, emi ko ri èsì kankan gba. Lẹhin naa mo mọ pe Arakunrin Oe ni a ti fiya iku jẹ nipa fifẹhin rẹ ti àgbá.
Ni 1948 a gba lẹta airotẹlẹ kan lati Shangai. O wá lati ọdọ Arakunrin Stanley Jones, ti a ti rán si China lati Gilead, ile-ẹkọ ojihin iṣẹ Ọlọrun titun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a ṣẹṣẹ dá silẹ. Jehofa ti ranti wa lẹẹkansii! Ayọ mi kún àkúnwọ́sílẹ̀ lati ni ibapade yii pẹlu eto-ajọ Jehofa. Ọdun meje ti kọja lati igba ti a ti rí Arakunrin Oe. Bi o tilẹ jẹ pe a wà ni àdádó patapata ni gbogbo igba yẹn, mo ti nsọ fun awọn ẹlomiran nipa ihinrere.
Nigba ti arakunrin Jones bẹ wá wò fun igba akọkọ, o jẹ akoko idunnu. O jẹ ẹni bi ọrẹ gan an. Bi o tilẹ jẹ pe a ko tii pade rẹ ṣaaju, a nimọlara gẹgẹ bi ẹni pe a nki ibatan ti o sunmọ wa pẹkipẹki kaabọ sinu ile wa. Ni kete lẹhin naa, Arakunrin Jones kuro lọ si T’ai-tung, la awọn oke kọja pẹlu ọkọ mi gẹgẹ bi ògbufọ̀ rẹ̀. Wọn pada ni nǹkan bi ọsẹ kan lẹhin naa laaarin akoko eyi ti wọn ti ṣe apejọ ọlọjọ kan ti wọn si baptisi nǹkan bi 300 lara awọn ẹya Amis ni etikun ila-oorun.
Ibẹwo Arakunrin Jones ni itumọ ni ọna miiran fun mi. Mo ti ndanikan waasu titi di igba yẹn. Ati nisinsinyi tọkọtaya kan, ti ọkọ jẹ onile wa ni a baptisi ni akoko ibẹwo Arakunrin Jones. Lati igba naa, mo ti fi ọpọlọpọ igba ni iriri ayọ sisọni di ọmọ-ẹhin ni afikun si ayọ pipolongo Ijọba naa. Lẹhin naa a ṣí lọ si Hsinchu, nibi ti Arakunrin Jones ti bẹ̀ wá wò lẹẹmẹta, ni igba kọọkan fun ọsẹ meji. Mo gbadun ibakẹgbẹpọ ti o ni ere naa gidigidi. Ni igba tí o wá kẹhin, o wi pe: “Ni igba miiran, emi yoo mu ẹnikeji mi wa, Harold King.” Ṣugbọn “igba miiran” yẹn ko dé mọ, nitori laipẹ lẹhin naa awọn mejeeji ni a fisẹwọn ni China.
Ni 1949, Joseph McGrath ati Cyril Charles, ojihin iṣẹ Ọlọrun lati kilaasi kọkanla ti Gilead, dé si Taiwan. Wọn mu iṣẹ naa gbooro ni Taiwan ni lilo ile wa gẹgẹ bi ibudo imuṣẹṣe. Apẹẹrẹ wọn fun mi niṣiiri niti gidi. Bi o ti wu ki o ri, ipo oṣelu fipa mu wọn lati fi ibẹ silẹ lọ si Hong Kong. Emi ko le pa omije mi mọra gẹgẹ bi wọn ti nlọ pẹlu ọlọpaa kan. Joe sọ pe, “Maṣe sunkun, Miyo.” O fikun un pe: “O ṣeun,” O si fun mi ni kalamu ikọwe rẹ ti o ti fẹrẹẹ tan gẹgẹ bi ohun iranti.
Yiyanju Iṣoro Ọmọ Títọ́
Emi ati ọkọ mi ko tii ni ọmọ kankan, nitori naa a gba ọmọ ibatan ọkọ mi tọ́ nigba ti o jẹ ọmọ oṣu mẹrin. Iwalaaye iya rẹ ni asthma ti fi sinu ewu.
Ni 1952, Arakunrin Lloyd Barry, ẹni ti o nṣiṣẹsin gẹgẹ bi ojihin iṣẹ Ọlọrun ni Japan, ṣebẹwo si Taiwan lati ṣiṣẹ lori kíka igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí labẹ ofin. O gbe pẹlu wa o si fun wa niṣiiri gidigidi. Ni akoko yẹn ọmọbinrin wa jẹ ọmọ oṣu 18. O gbe e nilẹ o si beere lọwọ rẹ pe: “Ki ni orukọ Ọlọrun?” Bi eyi ti yà mí lẹnu, mo beere lọwọ rẹ pe: “Ṣe a nilati maa kọ ọ bi o ti kere tó yii?” O fi idaniloju dahun pe, “Bẹẹni.” Lẹhin naa ni o ba mi sọrọ nipa ijẹpataki titọ ọmọ lati ọjọ ori ọmọde jojolo gan an. Awọn ọrọ rẹ̀ pe: “O jẹ ẹbun lati ọwọ Jehofa fun itunu rẹ,” wọnu ọkan mi.
Lọgan, mo dawọle kikọ ọmọbinrin mi, Akemi, lati mọ ki o si nifẹẹ Jehofa ati lati di iranṣẹ rẹ. Mo kọ ọ ni awọn ami ìró ọ̀rọ̀, bẹrẹ pẹlu awọn lẹta meta e, ho, ati ba ti o papọ di ọrọ naa “Ehoba,” tabi Jehofa, ni ede Japan. Nigba ti o di ọmọ ọdun meji, o ṣeeṣe fun un lati loye ohun ti mo nsọ fun. Nitori naa alaalẹ ṣaaju ki o to lọ sun, mo nsọ awọn itan Bibeli fun un. O fetisilẹ pẹlu ifẹ o si ranti wọn.
Nigba ti o di ẹni ọdun mẹta ati aabọ, Arakunrin Barry ṣebẹwo lẹẹkan si o si fun Akemi ni Bibeli ti a kọ ni ede Japan ti a saba maa nsọ lẹnu nikan. O rin yika yara pẹlu Bibeli naa ni wiwi pe: “Bibeli Akemi!” Ni iṣẹju melookan lẹhin naa, o sọ jade lojiji pe: “Bibeli Akemi ko ni Jehofa! Emi ko fẹ eyi!” O ju u silẹ. Pẹlu iyalẹnu, mo wo ohun ti o wa ninu rẹ. Lakọọkọ mo ṣi Aisaya ori 42, ẹsẹ 8. Nibẹ orukọ naa Jehofa ni a fi ọrọ naa “Oluwa” rọpo. Mo wo awọn ẹsẹ iwe mimọ miiran, ṣugbọn emi ko le ri orukọ atọrunwa naa, Jehofa. Akemi ni a pẹtu si ninu nigba ti mo fi orukọ Jehofa han an ninu Bibeli mi ti o ti gbó, ti o jẹ ni ede Japan ti a ko sọ mọ.
Pipada si Japan
A pada si Japan ni 1958 a si darapọ pẹlu Ijọ Sannomiya ni Kobe. Bi mo ti ni ọpọlọpọ idi lati kun fun ọpẹ si Jehofa, mo fẹ fi imoore mi yẹn han nipa didi aṣaaju-ọna—ojiṣẹ alakooko kikun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Mo lo araami dé góńgó ninu iṣẹ-ojiṣẹ aṣaaju-ọna. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, o ṣeeṣe fun mi lati dari awọn ikẹkọọ Bibeli ile ki nsi tọ́ ayọ riran awọn eniyan ti wọn tó 70 si 80 lọwọ lati wá sinu otitọ wò. Fun akoko kan mo tilẹ lanfaani lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna akanṣe ni ṣiṣiṣẹ ju 150 wakati loṣooṣu ninu pápá, nigba ti mo tun nbojuto ọkọ ati ọmọbinrin mi.
Gẹgẹ bi a ti gbe ni Taiwan fun ohun ti o ju 30 ọdun lọ, igbesi-aye ni Japan jẹ ipo ajeji patapata niti aṣa yiyatọ, mo si la awọn iriri adanniwo melookan kọja. Ni iru awọn akoko bẹẹ Akemi di itunu ati itilẹhin mi, gan an gẹgẹ bi Arakunrin Barry ti sọ fun mi ni ọpọlọpọ ọdun ṣaaju. Nigba ti mo ba rẹwẹsi, oun yoo sọ fun mi pe: “Mọmi, ẹ tujuka. Jehofa yoo ṣe ọna atiyọ.” “Bẹẹni, oun yoo ṣe bẹẹ, abi ko ni ṣe bẹẹ ni?” Emi yoo dahun emi yoo si gba a mọra pinpin. Ẹ wo iru orisun iṣiri ti o jẹ! Ki ni mo le ṣe bikoṣe ki ndupẹ lọwọ Jehofa!
Fifi Ọmọbinrin Mi Silẹ Fun Jehofa
Akemi di akede nigba ti o jẹ ẹni ọdun 7 o sì gba iribọmi nigba ti o jẹ ẹni ọdun 12, ni igba ẹrun 1963. Mo gbiyanju lati lo akoko pupọ bi o ti lè ṣeeṣe tó pẹlu rẹ̀. (Deutaronomi 6:6, 7) Awọn akoko iṣoro wà nigba ti o wà ni igba ọdọlangba, ṣugbọn pẹlu awọn apẹẹrẹ rere ati iṣiri lati ọdọ awọn aṣaaju-ọna akanṣe ti a ran wa si ijọ wa, Akemi fi ṣiṣe aṣaaju-ọna ninu awọn ipinlẹ titun ṣe gongo rẹ̀ lẹhin-ọ-rẹhin.
Ni apejọpọ agbegbe ni 1968, o kó ipa ọmọbinrin Jẹfuta ninu awokẹkọọ Bibeli. Gẹgẹ bi mo ti nwo awokẹkọọ naa, mo pinnu, gẹgẹ bi Jẹfuta ti ṣe, lati yọọda ọmọ mi kanṣoṣo, ẹni ti mo ti ṣikẹ titi di igba naa, fun Jehofa fun iṣẹ-isin alakooko kikun. Bawo ni igbesi-aye yoo ti rí laisi ọmọ mi timọtimọ lẹgbẹ ọdọ mi? O jẹ ipenija kan, gẹgẹ bi mo ti kọja ẹni ọdun 60 nigba naa.
Ni 1970 akoko tó fun ọmọbinrin wa lati fi wa silẹ. O gba ifọwọsi lọwọ ọkọ mi o si lọ si Kyoto lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan. Ni liloye imọlara wa, ọkàn rẹ̀ jọ bi eyi ti o bajẹ gẹgẹ bi o ti nfi wa silẹ. Mo ṣayọlo Saamu 126:5, 6 gẹgẹ bi iwe mimọ idagbere fun un: “Awọn ti nfi omije fun irugbin yoo fi ayọ ka a. Ẹni ti nfi ẹkún rin lọ, ti o si gbe irugbin lọwọ, lootọ, yoo fi ayọ pada wa, yoo si ru iti rẹ̀.” Awọn ọrọ wọnyi jasi amunilọkanle fun mi bakan naa.
Lẹhin naa Akemi ṣegbeyawo o si nba ṣiṣe aṣaaju-ọna akanṣe lọ pẹlu ọkọ rẹ̀. Lati 1977, nigba ti a yan ọkọ rẹ̀ gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo kan, wọn ti ṣiṣẹsin ninu iṣẹ arinrin-ajo. Mo saba maa ńtẹ́ aworan ilẹ kan siwaju ti emi yoo si maa “rinrin-ajo” lori aworan ilẹ pẹlu ọmọbinrin mi. O jẹ idunnu mi lati gbọ awọn iriri wọn ati lati di ojulumọ pẹlu ọpọlọpọ awọn arabinrin nipasẹ ọmọbinrin mi.
Mo ti jẹ ẹni ọdun 86 bayii. Awọn ọjọ ti wọn ti kọja dabi kiki ìṣọ́ kan ni òru. Emi ko le ṣiṣẹ gẹgẹ bi ti atẹhinwa, ṣugbọn iṣẹ-isin pápá ṣì nmu ayọ̀ wá fun mi. Nigba ti mo ba ronu lori 60 ọdun ti o ti kọja lati igba ti mo ti kẹkọọ otitọ, ileri afinilọkan balẹ ti Ọlọrun á ru dide ninu ọkan-aya mi. Bẹẹni, Jehofa ẹni ti yoo gbegbeesẹ ni iduroṣinṣin pẹlu awọn aduroṣinṣin njẹ ki a karugbin ayọ yanturu.—Saamu 18:25.