“Ẹ Maṣe Maa Mu Awọn Ọmọ Yin Binu”
“ẸYIN BABA, ẹ maṣe maa mu awọn ọmọ yin binu.” Bẹẹni apọsiteli Pọọlu wi. (Efesu 6:4, NW) Ni awọn ilẹ Iwọ-oorun, nibi ti a ti fi awọn obi sabẹ masunmawo ati ìgalára awujọ oniṣẹ afẹrọṣe, ko maa nfigba gbogbo rọrun fun wọn lati fi inurere ba awọn ọmọ wọn lo. Ọmọ titọ si jẹ ipenija bakan naa ni awọn ilẹ ti ngoke agba. Loootọ, itẹsiwaju igbesi-aye le rẹlẹ sii ju ti Iwọ-oorun. Ṣugbọn awọn aṣa ibilẹ ati aṣa atọwọdọwọ onigba pipẹ le lo agbara idari lori awọn obi lati ba awọn ọmọ wọn lo ni awọn ọna ti o fẹrẹẹ daju pe yoo ni wọn lara ti yoo si mu wọn binu.
Awọn ọmọ ninu diẹ lara awọn ilẹ ti ngoke agba ni a fi si ipo rirẹlẹ julọ niti ìkàsí ati ọ̀wọ̀. Ninu awọn ẹgbẹ awujọ kan awọn ọmọ ni a nran kiri pẹlu ìró ohùn ti nhalẹmọni ti o jẹ apaṣẹwaa, awọn ni a njagbe mọ ti a si nfi ìwọ̀sí lọ̀. O le ṣọwọn lati gbọ ki agbalagba kan sọ ọrọ oninuure si ọmọ kan, ki a maa tii mẹnukan awọn ọna iwahihu rere iru bii “jọwọ” ati “o ṣeun.” Awọn baba nimọlara pe wọn gbọdọ fẹsẹ aṣẹ wọn mulẹ pẹlu ọwọ́ lilekoko; itẹnumọ ni a ngbekari awọn ọrọ lile pẹlu ìgbátí olóòyì.
Ninu awọn ẹgbẹ awujọ Africa kan, a tilẹ foju wo o gẹgẹ bi ọyaju fun ọmọ kan lati ki awujọ awọn ti o ti dagba kan lati inu idanuṣe tirẹ funraarẹ. Ko ṣajeji lati ri awọn ọdọ, ti awọn ẹru wiwuwo ori wọn ti wọ̀ lọrun, ti wọn nfi suuru duro de iyọnda lati ki awujọ awọn agbalagba kan. Awọn ti o jẹ agbalagba naa yoo maa ba ìtàkúrọ̀sọ wọn lọ, ni ṣiṣai ka awọn ọdọ ti nduro naa sí titi di igba ti wọn ba yan lati jẹ́ kí wọ́n kí wọn. Kiki lẹhin ti a ba ti sọ awọn ikini wọnni ni a o to yọnda awọn ọmọ naa lati kọja.
Òṣì jẹ okunfa miiran ti o le ṣiṣẹ lodisi ire awọn ọmọ. Ni ohun ti o ná wọn ní ilera ati iwe kika wọn, awọn ọdọlangba ni a nko nifa gẹgẹ bi ọmọ ọdọ. Ẹru iṣẹ pupọ rẹpẹtẹ lọna ti ko ba ọgbọn mu ni a le gbékarí awọn ọmọ ani ni ile paapaa. Nigba tí awọn idile ni agbegbe igberiko ba si ran awọn ọmọ wọn lọ si awọn ilu nla ki awọn ibatan baa le tọju wọn nigba ti wọn nran wọn lọ si ile iwe, niye igba ni a nhuwa si wọn ni ọna ti o fẹrẹẹ dabi ti ẹru. Dajudaju, gbogbo awọn ihuwasi ti ko dara yii nmu awọn ọmọ binu!
Ohun Ti ‘Mimu Wọn Binu’ Tumọsi
Awọn obi kan faye gba ìgbì awọn aṣa ọmọ titọ ti o gbodekan laironu nipa awọn abajade wọn. Bi o ti wu ki o ri, pẹlu idi rere ni Ọrọ Ọlọrun fi rọ awọn obi lati maṣe mu awọn ọmọ wọn binu. Ọrọ ipilẹṣẹ Giriiki naa ti a tumọ si “ẹ maṣe maa mu . . . binu” lọna olowuuru tumọsi “maṣe jẹ ki ẹyin ru ibinu soke.” (Kingdom Interlinear) Ni Roomu 10:19 (NW), ọrọ iṣe kan naa ni a tumọ si “ru . . . soke si owu.”
Bibeli naa Today’s English Version tipa bayii wi pe: “Ẹ maṣe bá awọn ọmọ yin lò ni iru ọna kan ti o le mu wọn binu.” The Jerusalem Bible lọna ti o farajọra wi pe: “Ẹ maṣe sun awọn ọmọ yin si irunu.” Nitori naa Bibeli ko sọrọ nipa awọn imunibinu ti ko to nǹkan ti obi kan le fà fun ọmọ rẹ laimọọmọ nitori aipe, bẹẹni ko dẹbi fun ibawi ti a fifunni lọna ododo. Gẹgẹ bi Lange’s Commentary on the Holy Scriptures ti wi, ẹsẹ Bibeli yii sọrọ nipa “biba awọn ọmọ lò ni ọna oniwaduwadu, lainigbatẹniro, lainidii rere, debi pe . . . a lé wọn pada a si ré wọn lọ si iṣatako, ipenija ati ẹdun.”
Gẹgẹ bi olukọnilẹkọọ J. S. Farrant ti ṣakiyesi: “Otitọ naa ni pe awọn ọmọ jẹ eniyan. Wọn ko wulẹ ndahunpada ni ọna aimira gẹgẹ bi awọn ohun ọgbin ti nṣe si ayika wọn. Wọn nhuwa pada.” Ati niye igba ihuwa pada si ilosi ti ko ba idajọ ododo mu nyọrisi òfò ti ẹmi ati ti imọlara. Oniwaasu 7:7 wi pe: “Nitootọ inilara mu ọlọgbọn eniyan sinwin.”
Titọ Awọn Ọmọ Dagba Ninu Ibawi Ẹkọ Ti Ọlọrun
Awọn obi ti wọn fẹ ki awọn ọmọ wọn maa baa lọ ni ririn ninu otitọ ko gbọdọ yọnda ki awọn ọpa idiwọn aṣa ibilẹ ati ẹkọ atọwọdọwọ jẹ koko ti npinnu bi wọn yoo ṣe tọ awọn ọmọ wọn dagba. (Fiwe 3 Johanu 4.) Lẹhin kikilọ fun awọn obi nipa mimu awọn ọmọ wọn binu, Pọọlu fikun un pe: “Ẹ maa baa lọ ni titọ wọn dagba ninu ibawi ẹkọ ati ilana ero ori ti Jehofa.” (Efesu 6:4, NW) Awọn ọpa idiwọn Jehofa tipa bayii ga ju awọn aṣa ati oju iwoye adugbo lọ.
Nigba ti o le wọpọ ni awọn ilẹ kan pe ki a bá awọn ọmọ lò gẹgẹ bi awọn ti o rẹlẹ ju ati gẹgẹ bi ẹru ọmọ ọdọ, Bibeli polongo ni Saamu 127:3 pe: “Kiyesi i, awọn ọmọ ni ìní Oluwa: ọmọ inu si ni ere rẹ̀.” Obi kan ha le pa ibatan rere mọ́ pẹlu Ọlọrun bi oun ba lo ohun ìní rẹ̀ ni ilokulo? Bẹẹkọ. Bẹẹni ko si aye fun oju iwoye yẹn pe awọn ọmọ wà kiki lati pese fun aini awọn obi wọn. Ni 2 Kọrinti 12:14, Bibeli ran wa leti pe: “Nitori ti kò tọ́ fun awọn ọmọ lati maa to iṣura jọ fun awọn obi wọn, bikoṣe awọn obi fun awọn ọmọ wọn.”
Kii ṣe pe awọn ọmọ ni a nilati yọnda kuro ninu ṣiṣe ipin tiwọn ninu òpò ati iṣẹ inu ile. Ṣugbọn ko ha yẹ ki a gba ti ire didara julọ ti ọmọ kan funraarẹ ro? Fun apẹẹrẹ, nigba ti a beere lọwọ Yaa Kristẹni ọdọmọbinrin kan ni Africa, ohun ti oun yoo fẹran julọ ki awọn obi rẹ ṣe fun un, o dahun pe: “Emi iba fẹ ki a mu awọn iṣẹ ile mi dinku ni awọn ọjọ ti mo ba ní awọn iṣeto iṣẹ-isin papa.” Nitori naa bi o ba ṣoro fun ọmọ kan lati lọ si ile-ẹkọ ni akoko tabi lọ si awọn ipade nitori ẹru rẹpẹtẹ ti awọn iṣẹ ile, ko ha ni dara julọ lati ṣe awọn itunṣebọsipo diẹ bi?
O jẹ otitọ pe awọn ọmọde le ṣoro lati ba lo. Bawo ni awọn obi ṣe le ba wọn lo ni ọna ti kii ṣe ilokulo tabi eyi ti nmuni binu? Owe 19:11 wi pe: “Imoye eniyan mu un lọra ati binu.” Bẹẹni, lakọọkọ, iwọ le gbiyanju lati loye ọmọ rẹ gẹgẹ bi eniyan kan. Ọmọ kọọkan yatọ, pẹlu awọn ifẹ, agbara ati aini tirẹ funraarẹ. Ki ni awọn wọnyi? Iwo ha ti lo akoko lati mọ ọmọ rẹ ki o si mọ idahun si ibeere rẹ̀ bi? Ṣiṣiṣẹ ati jijọsin papọ, lilọwọ ninu ere idaraya idile—awọn nǹkan wọnyi pese anfaani fun awọn obi lati sunmọ awọn ọmọ wọn pẹkipẹki.
Ni 2 Timoti 2:22, Pọọlu sọ akiyesi ti o dunmọni miiran nigba ti o sọ fun Timoti pe: “Maa sá fun ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ewe.” Bẹẹni, Pọọlu loye pe igba ewe le jẹ saa akoko oniyọnu kan. Awọn iyipada amunijigiri ti ara iyara ati ti imọlara nṣẹlẹ. Òòfà si ẹya odikeji ngberu. Lakooko yii, awọn ọdọ nilo idari adagbadenu ati onifẹẹ lati yẹra fun awọn ọ̀fìn buburu. Ṣugbọn a ko nilati bá wọn lò bi ẹni pe wọn jẹ oniwa palapala. Ọmọbinrin Kristẹni ọkunrin kan ti a mu binu kedaaro pe: “Bi emi ko ba tii ṣagbere, ṣugbọn ti baba mi nfẹsun kan mi nipa rẹ, mo le tẹsiwaju ki nsì ṣe e bakan naa.” Dipo kika ete isunniṣe buburu si i lọrun, fi igbọkanle han ninu ọmọ rẹ. (Fiwe 2 Tẹsalonika 3:4.) Dipo jijẹ ẹni ti o lekoko, jẹ agbatẹniro ati oloye ni ọna onifẹẹ, ti o ṣe deedee.
Bi o ti wu ki o ri, ọpọlọpọ iṣoro ni a le mu kuro, bi awọn obi ba jiroro awọn ewu iwa palapala ti ọmọ kan dojukọ ṣaaju. Ranti pe, Ọlọrun fun awọn obi lẹru iṣẹ lati tọ́ ki wọn si kọ́ awọn ọmọ wọn ni Ọrọ Ọlọrun. (Deutaronomi 6:6, 7) Iyẹn le beere fun akoko ati isapa gigun. Lọna ti o banininujẹ, awọn obi kan kuna lati ṣe iṣẹ ikọni wọn nitori pe wọn ṣalaini suuru. Aimọọkọ mọọka, ọran iṣoro ńláǹlà kan ni ọpọlọpọ awọn ilẹ ti o ṣẹṣẹ ngoke agba, ndi awọn obi miiran lọwọ.
Ninu awọn ọran kan Kristẹni ogboṣaṣa kan ni a le pe lati ṣeranlọwọ. O le wulẹ jẹ ọran pipese awọn idamọran fun awọn obi ti iriri wọn kere. (Owe 27:17) Tabi o le wemọ ṣiṣe iranlọwọ pẹlu didari ikẹkọọ idile funraarẹ. Ṣugbọn eyi ko fun obi ni itura kuro ninu ẹru iṣẹ rẹ lati kọ ọmọ rẹ ni Ọrọ Ọlọrun. (1 Timoti 5:8) Oun le ṣe isapa lati ṣiṣẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ ninu iṣẹ-isin papa ki o si jiroro awọn ọran tẹmi ni akoko ounjẹ tabi ni awọn akoko ti o ba a mu miiran.
Ọdọ kan ti o ti nsunmọ ipo agba le fẹ ominira pupọ sii lọna ti ẹda. Niye igba eyi ni a ńṣì tumọ si itapa si aṣẹ tabi afojudi. Bawo ni yoo ti jẹ eyi ti nbini ninu tó bi awọn obi ba huwapada nipa biba a lò gẹgẹ bi ọmọ kekere kan ki wọn si kọ̀ lati fun un ni ominira pupọ sii ninu awọn igbesẹ rẹ̀! Yoo dọgba pẹlu mimuni binu fun wọn lati pinnu gbogbo iha igbesi-aye rẹ̀—imọ-ẹkọ, iṣẹ igbesi-aye, igbeyawo—laiba a sọrọ pọ nipa rẹ ni ọna tutu ati onirẹlẹ. (Owe 15:22) Apọsiteli rọ awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati “dagba di gende ninu agbara oye.” (1 Kọrinti 14:20, NW) Ko ha yẹ ki awọn obi fẹ pe ki awọn ọmọ tiwọn funraawọn dagba di gende—niti imọlara ati nipa tẹmi bi? Sibẹ, “awọn agbara imoye” ọdọ kan ni a le tọ́ kiki “nipasẹ lilo.” (Heberu 5:14, NW) Lati lo wọn oun ni a gbọdọ yọnda iwọn ominira yiyan kan fun.
Titọ awọn ọmọ dagba lakooko awọn ọjọ lilekoko wọnyi ko rọrun. Ṣugbọn awọn obi ti wọn ntẹle Ọrọ Ọlọrun kii mu awọn ọmọ wọn binu tabi da wọn lágara “ki wọn maa baa rẹwẹsi.” (Kolose 3:21) Kaka bẹẹ, wọn nsakun lati fi ọyaya, oye, ati ọlá ba wọn lo. Awọn ọmọ wọn ni a nṣamọna, a ko fipa mu wọn; awọn ni a kọ́, a ko ṣaikiyesi wọn; a sun wọn si ifẹ, a ko mu wọn binu tabi ni ijakulẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Tita “oware,” ayo adugbo ti a nta ninu ile ni Ghana, fun awọn obi wọnyi ni anfaani lati kẹgbẹpọ pẹlu awọn ọmọ wọn