ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/15 ojú ìwé 10-14
  • Bi Awọn Ọlọkantutu Ti Jẹ́ Alayọ Tó!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bi Awọn Ọlọkantutu Ti Jẹ́ Alayọ Tó!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wiwo Iwapẹlẹ Fínnífínní Sii
  • Bi A Ṣe Le Mu Iwapẹlẹ Dagba
  • Awọn Anfaani Iwapẹlẹ
  • Iwapẹlẹ Ngbe Ayọ Larugẹ
  • Ìwà Tútù—Báwo Ló Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ẹ Fi Iwapẹlẹ Wọ Araayin ni Aṣọ!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìwà Tútù—Ànímọ́ Kristẹni Tó Ṣe Pàtàkì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ẹ “Máa Fi Gbogbo Ìwà Tútù Hàn Sí Ènìyàn Gbogbo”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/15 ojú ìwé 10-14

Bi Awọn Ọlọkantutu Ti Jẹ́ Alayọ Tó!

“Alayọ ni awọn ọlọkantutu, niwọn bi wọn yoo ti jogun ilẹ-aye.”—MATIU 5:5, NW.

1. Ki ni ọkan tutupẹlẹ ti Jesu sọ nipa rẹ̀ ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke?

NINU iwaasu rẹ̀ lori Oke, Jesu Kristi wi pe: “Alayọ ni awọn ọlọkantutu, niwọn bi wọn yoo ti jogun ilẹ-aye.” (Matiu 5:5, NW) Ọkan tutupẹlẹ, tabi inututu yii, kii ṣe awúrúju ti ìwà-jẹ́jẹ́ alagabagebe, bẹẹ ni kii wulẹ ṣe akopọ animọ iwa adanida kan. Kaka bẹẹ, ó jẹ ojulowo iwapẹlẹ àtinúlọ́hùn ún wá ati wíwà lalaafia ti a lo ni pataki ni idahunpada sí ifẹ-inu ati itọsọna Jehofa Ọlọrun. Awọn eniyan ti wọn jẹ́ ọlọkantutu nitootọ ní òye mimuna ti igbarale Ọlọrun ti a fihan ninu iwapẹlẹ sí awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn.—Roomu 12:17-19; Titu 3:1, 2.

2. Eeṣe ti Jesu fi pe awọn ọlọkantutu ni alayọ?

2 Jesu pe awọn ọlọkantutu ni alayọ nitori pe wọn yoo jogun ilẹ-aye. Gẹgẹ bi Ọmọkunrin Ọlọrun ọlọkantutu lọna pipe, Jesu ni Olori Ajogun ilẹ-aye. (Saamu 2:8; Matiu 11:29; Heberu 1:1, 2; 2:5-9) Ṣugbọn gẹgẹ bi “ọmọ eniyan” ti Mesaya naa, oun nilati ni awọn oluṣakoso alabaakẹgbẹ ninu Ijọba rẹ̀ ti ọrun. (Daniẹli 7:13, 14, 22, 27) Gẹgẹ bi “awọn ajumọjogun” Kristi, awọn ẹni ami ororo ọlọkantutu wọnyi yoo ṣajọpin ninu ogún rẹ̀ ti ilẹ-aye. (Roomu 8:17) Awọn ọlọkantutu miiran, awọn eniyan bi agutan yoo gbadun ìyè ayeraye ninu Paradise ninu ayika ilẹ-aye ti Ijọba naa. (Matiu 25:33, 34, 46; Luuku 23:43) Ifojusọna yẹn mu wọn layọ nitootọ.

3. Ọlọrun ati Kristi gbé apẹẹrẹ wo kalẹ niti iwapẹlẹ?

3 Olori Ajogun ọlọkantutu naa gba ilẹ-aye lọwọ Baba rẹ̀, Jehofa, apẹẹrẹ akọkọ naa ti ẹmi iwapẹlẹ. Bawo ni Iwe mimọ ti sọ leralera to pe Ọlọrun “lọra lati binu ti o sì pọ ni iṣeun-ifẹ”! (Ẹkisodu 34:6, NW; Nehemaya 9:17; Saamu 86:15) Oun ní agbara nla ṣugbọn o nfi iru iwapẹlẹ bẹẹ han debi pe awọn olujọsin rẹ̀ le lọ sọdọ rẹ̀ laisi ifoya. (Heberu 4:16; 10:19-22) Ọmọkunrin Ọlọrun, ẹni ti ó jẹ “ọlọkantutu ati onirẹlẹ ni ọkan-aya,” kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ lati jẹ oniwapẹlẹ. (Matiu 11:29, NW; Luuku 6:27-29) Ni ọ̀dọ̀ tiwọn, awọn ẹru Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀ ọlọkantutu wọnyi ṣadakọ ti wọn sì kọwe nipa “iwapẹlẹ ati inurere Kristi.”—2 Kọrinti 10:1, NW; Roomu 1:1; Jakobu 1:1, 2; 2 Peteru 1:1.

4. (a) Gẹgẹ bi Kolose 3:12 ti wi, ki ni awọn wọnni ti wọn jẹ ọlọkantutu nitootọ ti ṣe? (b) Awọn ibeere wo ni wọn yẹ fun igbeyẹwo wa?

4 Lonii, awọn Kristẹni ẹni ami ororo ati awọn alabaakẹgbẹ wọn ni ilẹ-aye nilati jẹ ọlọkantutu. Lẹhin ti wọn ti mu iwa buburu, ẹtan, agabagebe, ilara, ati isọrọ ẹni lẹhin eyikeyii kuro, a ti ran wọn lọwọ nipasẹ ẹmi mimọ Ọlọrun lati di titun ninu ‘ipá ti nsun ero-inu wọn ṣiṣẹ.’ (Efesu 4:22-24 NW; 1 Peteru 2:1, 2) A rọ̀ wọn lati fi aṣọ “ifẹni onikẹẹ ti ìyọ́nú, inurere, irẹlẹ ero inu, iwapẹlẹ, ati ipamọra” wọ araawọn ni aṣọ. (Kolose 3:12, NW) Ṣugbọn ni pato ki ni iwapẹlẹ ní ninu? Eeṣe ti o fi ṣanfaani lati jẹ ọlọkantutu? Bawo sì ni animọ yii ṣe le fikun ayọ wa?

Wiwo Iwapẹlẹ Fínnífínní Sii

5. Bawo ni a ṣe le tumọ iwapẹlẹ?

5 Ẹni ọlọkantutu kan jẹ ẹni jẹ́jẹ́ ninu itẹsi ifẹ inu ati ihuwa. Ninu awọn ẹ̀dà itumọ Bibeli kan, ọrọ àpọ́nlé naa pra·ysʹ ni a tumọsi “oninututu,” “oniwapẹlẹ,” “ọlọkantutu,” ati “ẹni jẹ́jẹ́.” Ninu ede Giriiki igbaani, ọrọ apejuwe naa pra·ysʹ ni a lè lo fun afẹfẹ jẹ́jẹ́ tabi ohùn pẹlẹ. O tun le duro fun ẹnikan ti o jẹ alaaanu. Ọmọwe W. E. Vine wi pe: “Awọn ìlò [ọrọ orukọ naa pra·yʹtes] jẹ lakọọkọ ati ni pataki siha ọdọ Ọlọrun. Ó jẹ nitori ẹmi jẹ́jẹ́ yẹn ni a fi tẹwọgba awọn ibalo Rẹ̀ pẹlu wa gẹgẹ bi eyi ti ó dara, ati nitori naa laisi jijiyan tabi ṣiṣatako; ó sopọ pẹkipẹki pẹlu ọrọ naa tapeinophrosunē [ẹmi irẹlẹ].”

6. Eeṣe ti a fi le sọ pe iwapẹlẹ kii ṣe ailera?

6 Iwapẹlẹ kii ṣe ailera. “Ìwà-jẹ́jẹ́ wà ninu praus,” ni ọmọwe William Barclay kọwe, “ṣugbọn lẹhin ìwà-jẹ́jẹ́ ni agbara bii ti irin wà.” Ó gba agbara lati jẹ ọlọkantutu. Fun apẹẹrẹ, agbara ni a nilo lati jẹ oniwapẹlẹ labẹ imunibinu tabi nigba ti a ba nṣe inunibini si wa. Ọmọkunrin ọlọkantutu ti Ọlọrun, Jesu Kristi, gbe apẹẹrẹ rere kan kalẹ ni ọna yii. “Ẹni, nigba ti a kẹgan rẹ̀, ti ko si pada kẹgan; nigba ti o jiya, ti ko si kilọ; ṣugbọn o fi ọran rẹ̀ le [Jehofa Ọlọrun] ẹni ti nṣe idajọ ododo lọwọ.” (1 Peteru 2:23) Bii Jesu ọlọkantutu, awa le nigbọkanle pe Ọlọrun yoo fiya jẹ awọn olukẹgan ati oninunibini wa. (1 Kọrinti 4:12, 13) A lè jẹ ẹni ti o parọ́rọ́, gẹgẹ bi Sitefanu ti a ṣe inunibini sí ti jẹ, ni mímọ̀ pe bi a ba jẹ oloootọ, Jehofa yoo mu wa duro kò si ni jẹ ki ohunkohun ṣe wa ni ipalara pipẹtiti.—Saamu 145:14; Iṣe 6:15; Filipi 4:6, 7, 13.

7. Ki ni Owe 25:28 fihan nipa ẹnikan ti ó ṣalaini iwapẹlẹ?

7 Jesu jẹ ọlọkantutu, sibẹ o fi agbara han ninu diduro gbọnyingbọnyin fun ohun ti ó tọ́. (Matiu 21:5; 23:13-39) Ẹnikẹni ti o ni “inu Kristi” yoo dabi rẹ̀ ni ọna yii. (1 Kọrinti 2:16) Bi ẹnikan ko ba jẹ oniwapẹlẹ, oun ko dabi Kristi. Kaka bẹẹ, ó ba awọn ọrọ wọnyi mu: “Ẹni ti ko le ṣe akoso araarẹ, ó dabi ilu ti a wó lulẹ, ti ko sì ni odi.” (Owe 25:28) Iru eniyan bẹẹ ti ó ṣaini iwapẹlẹ ni a ṣí kalẹ si ìkọlù awọn ero tí kò tọ́ ti o lè mu ki ó huwa ni awọn ọna ti kò yẹ. Nigba ti Kristẹni ọlọkantutu kan kii ṣe alailera, sibẹ oun mọ pe “idahun pẹlẹ yí ibinu pada; ṣugbọn ọrọ lile nii ru ibinu soke.”—Owe 15:1.

8. Eeṣe ti ko fi rọrun lati jẹ ọlọkantutu?

8 Ko rọrun lati jẹ ọlọkantutu, nitori a ti jogun aipe ati ẹṣẹ. (Roomu 5:12) Bi awa ba jẹ iranṣẹ Jehofa, a tun ni ijakadi lodisi awọn ipá ẹmi buburu ti o le maa dan iwapẹlẹ wa wò nipa inunibini. (Efesu 6:12) Ọpọjulọ ninu wa si nṣiṣẹ laaarin awọn wọnni ti wọn ni ẹmi lile ti aye ti ó wà labẹ idari Eṣu. (1 Johanu 5:19) Nitori naa bawo ni a ṣe le mu iwapẹlẹ dagba?

Bi A Ṣe Le Mu Iwapẹlẹ Dagba

9. Oju iwoye wo ni yoo ran wa lọwọ lati mu iwapẹlẹ dagba?

9 Idaniloju ti a gbekari Bibeli pe a beere lọwọ wa lati fi iwapẹlẹ han yoo ran wa lọwọ lati mu animọ yii dagba. Lojoojumọ a gbọdọ ṣiṣẹ lati mu iwapẹlẹ dagba. Bi kò ṣe bẹẹ, awa yoo dabi awọn eniyan ti wọn foju wo iwapẹlẹ gẹgẹ bi ailera ti wọn si ronu pe aṣeyọri si rere njẹyọ lati inu jijẹ onirera, alagidi, ani oníwà-ìkà paapaa. Bi o ti wu ki o ri, Ọrọ Ọlọrun dẹbi fun igberaga, owe ọlọgbọn kan sì wi pe: “Alaaanu eniyan ṣe rere fun araarẹ: ṣugbọn ìkà eniyan nyọ ẹran-ara rẹ lẹnu.” (Owe 11:17; 16:18) Awọn eniyan maa ńfà sẹhin kuro lọdọ ẹni lile, eniyan alaininuure, ani bi wọn ba tilẹ ṣe bẹẹ kiki lati yẹra fun didi ẹni ti a palara nipasẹ iwa ìkà ati aini iwapẹlẹ rẹ̀.

10. Bi awa ba nilati jẹ ọlọkantutu, ki ni awa gbọdọ juwọsilẹ fun?

10 Lati jẹ ọlọkantutu, a gbọdọ juwọ silẹ fun agbara idari ẹmi mimọ, tabi ipá agbekankan ṣiṣẹ Ọlọrun. Gẹgẹ bi Jehofa ti mu ki ó ṣeeṣe fun ilẹ-aye lati mu eso jade, bẹẹ ni oun mu ki o ṣeeṣe fun awọn iranṣẹ rẹ̀ lati mu awọn eso ti ẹmi rẹ jade, ti o ní iwapẹlẹ ninu. Pọọlu kọwe pe: “Eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere iṣeun, igbagbọ, iwapẹlẹ, ikora-ẹni-nijaanu. Ko si ofin kankan lodisi iru nǹkan wọnyi.” (Galatia 5:22, 23, NW) Bẹẹni, iwapẹlẹ jẹ ọkan lara awọn eso ẹmi Ọlọrun ti awọn wọnni ti wọn nwu u fihan. (Saamu 51:9, 10) Bawo ni awọn iyipada ti iwapẹlẹ nmu jade ti pọ to! Lati ṣapejuwe: oníjàgídíjàgan kan wà ti a npe ni Tony ẹni ti ó ba awọn eniyan jà, ti ó ja awọn eniyan lólè, ti ó ṣe fàyàwọ́ oogun oloro, ti ó jẹ́ aṣaaju awọn ìpàǹpá ti nlo alùpùpù, ti o sì lo akoko ninu ọgba ẹwọn. Sibẹ, nipa gbigba imọ Bibeli ati pẹlu iranlọwọ ẹmi Ọlọrun, o yipada si iranṣẹ Jehofa ọlọkantutu kan. Itan Tony kii ṣe titun. Nigba naa, ki ni ẹnikan le ṣe bi aini iwapẹlẹ ba ti jẹ apa ti ó bori ninu animọ rẹ̀?

11. Ni mimu iwapẹlẹ dagba, ipa wo ni adura ńkó?

11 Adura atọkanwa fun ẹmi mimọ Ọlọrun ati fun eso iwapẹlẹ rẹ̀ yoo ran wa lọwọ lati mu animọ yii dagba. Awa le nilati “maa baa lọ ni bibeere,” gẹgẹ bi Jesu ti wi, Jehofa yoo si fọwọsi ibeere wa. Lẹhin fifihan pe awọn baba eniyan nfun awọn ọmọ wọn ni awọn ohun rere, Jesu wi pe: “Bi ẹyin, bi ẹ tilẹ jẹ eniyan buruku, ba mọ bi a tii fi awọn ẹbun rere fun awọn ọmọ yin, melomelo ni Baba yin ni ọrun yoo fi ẹmi mimọ fun awọn wọnni ti nbeere lọwọ rẹ̀!” (Luuku 11:9-13, NW) Adura le ṣeranwọ lati sọ iwapẹlẹ di apa ti ó bori ninu itẹsi ero inu wa—animọ kan ti nfikun ayọ wa ati ti awọn alabaakẹgbẹ wa.

12. Eeṣe ti pipa a mọ lọkan pe awọn eniyan jẹ alaipe fi le ran wa lọwọ lati jẹ ọlọkantutu?

12 Fifisọkan pe awọn eniyan jẹ alaipe le ran wa lọwọ lati jẹ ọlọkantutu. (Saamu 51:5) Awa ko le ronu tabi huwa lọna pipe, ju bi awọn eniyan miiran ti le ṣe lọ, nitori naa awa dajudaju nilati ní igbatẹniro ki a sì bá wọn lò gẹgẹ bi awa yoo ṣe fẹ ki a bá wa lò. (Matiu 7:12) Mimọ pe gbogbo wa nṣe aṣiṣe nilati mu wa jẹ adarijini ati ọlọkantutu ninu ibalo wa pẹlu awọn ẹlomiran. (Matiu 6:12-15; 18:21, 22) Ó ṣetan, awa ko ha kun fun ọpẹ pe Ọlọrun fi ifẹ ati iwapẹlẹ han si wa?—Saamu 103:10-14.

13. Bawo ni a ṣe le ran wa lọwọ lati mu iwapẹlẹ dagba bi a ba gbà pe Ọlọrun ti ṣe awọn eniyan ni olominira iwahihu?

13 Gbigba pe Ọlọrun ti ṣe eniyan ni olominira iwahihu tun le ran wa lọwọ lati mu iwapẹlẹ dagba. Eyi ko fayegba ẹnikẹni lati fi aṣegbe ṣá awọn ofin Jehofa tì, ṣugbọn ó fayegba oniruuru ninu awọn ohun ti eniyan nfẹ, awọn ohun ti a nifẹẹ sí, ati awọn ohun ti a ko nifẹẹ sí laaarin awọn eniyan rẹ̀. Nitori naa ẹ jẹ ki a gbà pe ko si ẹnikẹni ti a fi ọranyan mu lati ba animọ pato kan ti a le kà sí eyi ti o dara julọ mu. Ẹmi yii yoo ran wa lọwọ lati jẹ ọlọkantutu.

14. Niti iwapẹlẹ, ki ni ó gbọdọ jẹ ipinnu wa?

14 Ipinnu lati maṣe pa iwapẹlẹ tì yoo ran wa lọwọ lati maa baa lọ ni mimu animọ yii dagba. Jijuwọsilẹ fun agbara idari ẹmi Jehofa mu iyipada kan wá ninu ironu wa. (Roomu 12:2) Ẹmi iwapẹlẹ, bii ti Kristi nran wa lọwọ nisinsinyi lati ká wa lọwọ kò kuro ninu lilọwọ ninu “iwa wọbia, ifẹkufẹẹ, ọti amupara, irede oru, kiko ẹgbẹ ọmuti, ati ibọriṣa.” Awa ko gbọdọ pa iwapẹlẹ tì lae fun ete ọran inawo, ẹgbẹ-oun-ọgba, tabi awọn idi miiran tabi nitori pe awọn eniyan nsọ ọrọ eebu nipa ìwà-bí-Ọlọ́run wa. (1 Peteru 4:3-5) Awa ko gbọdọ jẹ ki ohunkohun mu wa lọwọ ninu “awọn iṣẹ ti ara,” debi pe a ó padanu iwapẹlẹ wa ki a sì kuna lati jogun Ijọba Ọlọrun tabi gbadun awọn ibukun rẹ̀. (Galatia 5:19-21) Ẹ jẹ ki a maa ṣikẹ anfaani jijẹ awọn ẹni ọlọkantutu ti Ọlọrun nigba gbogbo, yala ẹni ti a fi ami ororo yàn sí iye ti ọrun tabi nini ireti ti ilẹ-aye kan. Si opin yẹn, ẹ jẹ ki a gbe awọn anfaani iwapẹlẹ diẹ yẹwo.

Awọn Anfaani Iwapẹlẹ

15. Gẹgẹ bi Owe 14:30 ti wi, eeṣe ti o fi bọgbọnmu lati jẹ oniwapẹlẹ?

15 Ẹni oniwapẹlẹ kan ní iparọrọ ọkan-aya, ero inu, ati ara. Eyi jẹ bẹẹ nitori pe oun kii lọwọ ninu rògbòdìyàn, ọkàn rẹ̀ kii gbọgbẹ nitori iṣesi awọn ẹlomiran, tabi dara rẹ̀ lóró pẹlu aniyan alaidawọduro. Iwapẹlẹ ran an lọwọ lati pa ero imọlara rẹ̀ mọ́, eyi sì ṣanfaani niti ero ori ati ti ara iyara. Owe kan wi pe: “Aya ti ó yè korokoro ni ìyè ara.” (Owe 14:30) Aini iwapẹlẹ le ṣamọna si ibinu ti o le mu irusoke ẹjẹ ga tabi ṣokunfa awọn iṣoro dídà ounjẹ, ikọ fée, awọn iṣoro oju, ati awọn iṣoro miiran. Kristẹni ọlọkantutu kan gbadun oniruuru anfaani, ti o ní ninu “alaafia Ọlọrun” ti nṣọ agbara ọkan-aya ati ero ori rẹ̀. (Filipi 4:6, 7) Bawo ni ó ti lọgbọn ninu tó lati jẹ ọlọkantutu!

16-18. Iyọrisi wo ni iwapẹlẹ ńní lori ibatan wa pẹlu awọn ẹlomiran?

16 Animọ iwapẹlẹ mu ipo ibatan wa pẹlu awọn ẹlomiran sunwọn sii. Boya nigba kan rí a ni iwa titẹpẹlẹ mọ awọn ọran titi di igba ti ọwọ wa ba tẹ ohun ti a nfẹ. Awọn eniyan ti le binu si wa nitori pe a ṣaini ẹmi irẹlẹ ati iwapẹlẹ. Labẹ iru awọn ipo bẹẹ, ko nilati yà wá lẹnu bi a ba kówọnú ariyanjiyan kan lẹhin omiran pẹlu awọn eniyan. Bi o ti wu ki o ri, Owe kan wi pe: “Nigba ti igi tan, ina a kú; bẹẹni nigba ti olofoofo kò sí, ija a dá. Bi ẹyin [“èédú igi,” NW] ti ri si ẹyin-iná [“ẹ̀ṣẹ́ná,” NW], ati igi si ina; bẹẹ ni eniyan onija lati dá ija silẹ.” (Owe 26:20, 21) Bi awa ba jẹ ọlọkantutu, dipo ‘kiko igi si ina sii’ ati mimu awọn ẹlomiran binu, awa yoo ni ibatan rere pẹlu wọn.

17 Ẹni ọlọkantutu kan ni o ṣeeṣe ki o ní awọn ọrẹ rere. Awọn eniyan gbadun kikẹgbẹpọ pẹlu rẹ̀ nitori pe ó ní ẹmi ironu onifojusọna fun rere, awọn ọrọ rẹ sì jẹ atunilara ati aladun bí oyin. (Owe 16:24) Iyẹn jẹ otitọ nipa Jesu, ẹni ti ó le wi pe: “Ẹ gba ajaga mi si ọrun yin, ki ẹ si maa kọ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninututu ati onirẹlẹ ọkan ni emi; ẹyin ó sì rí isinmi fun ọkan yin. Nitori ajaga mi rọrun, ẹru mi sì fuyẹ.” (Matiu 11:29, 30) Jesu kò rorò ajaga rẹ̀ kii sii ṣe aninilara. Awọn wọnni ti wọn wa sọdọ rẹ̀ ni a bálò lọna ti ó dara ti a sì tù lára nipa tẹmi. Ipo naa jọra nigba ti a ba kẹgbẹpọ pẹlu Kristẹni ọrẹ ọlọkantutu kan.

18 Iwapẹlẹ sọ wa di ẹni ọ̀wọ́n fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa. Laiṣiyemeji, ọpọjulọ awọn Kristẹni ni Kọrinti ni a fà sunmọ Pọọlu nitori pe oun “fi iwapẹlẹ ati inurere Kristi” parọwa fun wọn. (2 Kọrinti 10:1, NW) Awọn ara Tẹsalonika dajudaju ti gbọdọ dahun pada si apọsiteli naa, niwọn bi oun ti jẹ oniwapẹlẹ ati olukọni oniwa jẹ́jẹ́. (1 Tẹsalonika 2:5-8) Kò si iyemeji kankan nibẹ pe awọn alagba Efesu ti kẹkọọ ohun pupọ lati ọdọ Pọọlu ti wọn sì nifẹẹ rẹ̀ gidigidi. (Iṣe 20:20, 21, 37, 38) Iwọ ha nfi iwapẹlẹ ti ńmú ọ di ẹni ọ̀wọ́n fun awọn ẹlomiran han bi?

19. Bawo ni iwapẹlẹ ṣe ran awọn eniyan Jehofa lọwọ lati pa ipo wọn mọ ninu eto-ajọ rẹ̀?

19 Ọkan tutupẹlẹ ńran awọn eniyan Jehofa lọwọ ati jẹ onitẹriba ati lati pa ipo wọn mọ ninu eto-ajọ rẹ. (Filipi 2:5-8, 12-14; Heberu 13:17) Iwapẹlẹ ńká wa lọ́wọ́ kò kuro ninu wiwa ogo, eyi ti a gbekari igberaga o si jẹ irira si Ọlọrun. (Owe 16:5) Ẹni oninututu kan kii ka araarẹ si ẹni ti ó lọla ju awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ lọ, kii sii gbiyanju lati fi wọn gbayì. (Matiu 23:11, 12) Kaka bẹẹ, oun tẹwọgba ipo ẹṣẹ rẹ̀ ati aini rẹ̀ fun ipese irapada Ọlọrun.

Iwapẹlẹ Ngbe Ayọ Larugẹ

20. Ipa wo ni iwapẹlẹ ni lori igbesi-aye idile?

20 Gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun nilati ranti pe iwapẹlẹ jẹ eso ẹmi rẹ̀ ti ngbe ayọ larugẹ. Fun apẹẹrẹ, nitori pe awọn eniyan Jehofa fi iru awọn animọ bi ifẹ ati iwapẹlẹ han, idile alayọ wọpọ laaarin wọn. Nigba ti ọkọ ati aya ba bá araawọn lò lọna pẹlẹ, awọn ọmọ wọn ni a tọ ni ayika ti ó parọrọ kan, kii ṣe ninu idile ti o fi araarẹ fun awọn ọ̀rọ̀ ati iwa rírorò. Bi baba ti nfun awọn ọmọ rẹ̀ ni imọran pẹlu iwapẹlẹ, eyi ni iyọrisi rere lori ero inu jòjòló wọn, ẹmi suuru si ni o ṣeeṣe ki o jẹ apakan iwa animọ wọn. (Efesu 6:1-4) Ọkan tutupẹlẹ nran awọn ọkọ lọwọ lati maa baa lọ ní ninifẹẹ awọn aya wọn. O nran awọn aya lọwọ lati jẹ onitẹriba fun awọn ọkọ wọn ti o sì sun awọn ọmọ lati ṣegbọran si awọn obi wọn. Iwapẹlẹ tun mu ki awọn mẹmba idile ni ẹmi idarijini ti nfikun ayọ.—Kolose 3:13, 18-21.

21. Ni pataki julọ, imọran wo ni apọsiteli Pọọlu fifunni ní Efesu 4:1-3?

21 Awọn idile ati eniyan ọlọkantutu ngbe ayọ larugẹ ninu ijọ ti wọn ndarapọ mọ. Nitori naa, awọn eniyan Jehofa nilati ṣe isapa alaapọn lati jẹ ọlọkantutu. Iwọ ha nṣe bẹẹ bi? Apọsiteli Pọọlu parọwa fun awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati rin lọna yiyẹ si ipe ti ọrun wọn, ni ṣiṣe bẹẹ “pẹlu irẹlẹ ero inu pipe perepere ati iwapẹlẹ, pẹlu ipamọra, ni fifarada a fun ara [wọn] ninu ifẹ, ni fifi ìfọkànsí sapa lati pa iṣọkan ẹmi mọ ninu isopọṣọkan ide alaafia.” (Efesu 4:1-3, NW) Awọn Kristẹni ti wọn ni ireti ti ilẹ-aye tun gbọdọ fi iwapẹlẹ ati awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun miiran han. Eyi ni ipa ọna ti nmu ayọ tootọ wá. Alayọ nitootọ ni awọn ọlọkantutu!

Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Eeṣe ti awọn eniyan ọlọkantutu fi jẹ alayọ?

◻ Ki ni ó tumọ si lati jẹ ọlọkantutu?

◻ Bawo ni a ṣe le mu iwapẹlẹ dagba?

◻ Ki ni diẹ lara awọn anfaani iwapẹlẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́