Ẹ Fi Iwapẹlẹ Wọ Araayin ni Aṣọ!
“Gẹgẹ bi ayanfẹ Ọlọrun, mímọ́ ati ololufẹ, ẹ fi awọn ifẹni onikẹẹ ti ìyọ́nú, inurere, irẹlẹ ero inu, iwapẹlẹ, ati ipamọra wọ araayin ni aṣọ.” —KOLOSE 3:12, NW.
1-3. Ni Kolose 3:12-14, ki ni apọsiteli Pọọlu sọ nipa iwapẹlẹ ati awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun miiran?
JEHOFA fun awọn eniyan rẹ̀ ni aṣọ iṣapẹẹrẹ didara julọ gan an. Nitootọ, gbogbo awọn ti o fẹ́ ojurere rẹ̀ ni a gbọdọ wọ̀ ni ẹwu kan ti o ni fọ́nrán alagbara ti iwapẹlẹ. Animọ yii ntuni ninu nitori pe o nmu aifararọ dinku ninu awọn ipo ti o kun fun ikimọlẹ. Ó jẹ́ ààbò pẹlu nitori ti o nṣe idena fun rogbodiyan.
2 Apọsiteli Pọọlu rọ awọn Kristẹni ẹni ami ororo ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Gẹgẹ bi ayanfẹ Ọlọrun, mímọ́ ati ololufẹ, ẹ fi awọn ifẹni onikẹẹ ti ìyọ́nú, inurere, irẹlẹ ero inu, iwapẹlẹ, ati ipamọra wọ araayin ni aṣọ.” (Kolose 3:12, NW) Itọka koko ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “wọ araayin laṣọ” duro fun igbesẹ ti a nilati gbé pẹlu ironu kanjukanju. Awọn ẹni ami ororo, ti wọn jẹ àyànfẹ́, mimọ, ati ẹni ti Ọlọrun nifẹẹ, ni wọn ko nilati fi ọrọ falẹ ninu wiwọ araawọn ni aṣọ pẹlu iru awọn animọ gẹgẹ bii iwapẹlẹ.
3 Pọọlu fikun un pe: “Ẹ maa baa lọ ni fifarada a fun araayin ati didariji araayin lọfẹẹ bi ẹnikẹni ba ni idi fun ìráhùn si ẹnikeji. Ani gẹgẹ bi Jehofa ti dariji yin lọfẹẹ, bẹẹ ni ki ẹyin pẹlu maa ṣe. Ṣugbọn yatọ si gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi ifẹ wọ araayin ni aṣọ, nitori o jẹ okun ìdè irẹpọ pipe.” (Kolose 3:13, 14, NW) Ifẹ, iwapẹlẹ, ati awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun miiran mu ki o ṣeeṣe fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati “gbe ni irẹpọ.”—Saamu 133:1-3.
Awọn Oluṣọ-agutan Ọlọkantutu Ni A Nilo
4. Awọn Kristẹni tootọ wọ ẹwu iṣapẹẹrẹ ti a fi awọn animọ wo hun?
4 Awọn Kristẹni tootọ sakun lati ‘sọ awọn mẹmba araawọn di oku niti agbere, àìmọ́, ìdálọ́rùn fun ibalopọ takọtabo, ifẹ ọkan aṣenilọṣẹ, ati ojukokoro.’ Wọn sì ṣiṣẹ lori bibọ ẹwu ogbologboo eyikeyii ti ó ní ẹ̀yà aṣọ ti ìkannú, ibinu, iwa buburu, ọrọ eebu, ati ọrọ rírùn kuro. (Kolose 3:5-11) Wọn bọ́ “iwa animọ ogbologboo naa danu (ni olowuuru, “ogbologboo ọkunrin naa”) wọn sì gbé “iwa animọ titun” wọ̀ (tabi, “ọkunrin titun naa”), aṣọ kan ti ó bojumu. (Efesu 4:22-24, Kingdom Interlinear) Ẹwu wọn titun, ti a fi ìyọ́nú, inurere, irẹlẹ ero inu, iwapẹlẹ, ati ipamọra hun, nran wọn lọwọ lati yanju awọn iṣoro ati lati gbe igbesi-aye oniwa-bi-Ọlọrun.—Matiu 5:9; 18:33; Luuku 6:36; Filipi 4:2, 3.
5. Ki ni o wà nibẹ nipa imuṣiṣẹ ijọ Kristẹni ti o mu ki jijẹ apakan rẹ̀ jẹ iru idunnu kan bẹẹ?
5 Awọn eniyan ti a kà si alaṣeyọri si rere ninu aye yii maa nlekoko niye igba, ti wọn sì maa njẹ oníwà-ìkà paapaa. (Owe 29:22) Bawo ni ó ti yatọ lọna ti o tunilara tó laaarin awọn eniyan Jehofa! Ijọ Kristẹni ni a kò mu ṣiṣẹ bí awọn eniyan kan ti ndari iṣẹ aje kan—pẹlu ijafafa ṣugbọn lọna ti o lekoko ti o le mu ki awọn eniyan ṣai layọ. Kaka bẹẹ, o jẹ idunnu lati jẹ apakan ijọ naa. Idi kan ni pe ọkan tutupẹlẹ jẹ apakan ọgbọn tí awọn Kristẹni nfihan ni gbogbogboo paapaa julọ nipasẹ awọn ọkunrin ti wọn tootun lati kọ awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn. Bẹẹni, idunnu njẹyọ lati inu itọni ati imọran ti awọn alagba ti a yan sipo nfifunni awọn ti nkọni “nipa iwatutu ati ọgbọn.”—Jakobu 3:13.
6. Eeṣe ti awọn alagba Kristẹni fi nilati jẹ ọlọkantutu?
6 Ẹmi, tabi iṣarasihuwa ti ó bori, ti awọn eniyan Ọlọrun beere pe ki awọn eniyan ti a fi iṣẹ abojuto le lọwọ ninu ijọ jẹ ọlọkantutu, ọlọgbọn-ninu, ati oloye. (1 Timoti 3:1-3) Awọn iranṣẹ Jehofa dabi agutan oniwa jẹ́jẹ́, kii ṣe ewurẹ alaigbọran, abo kẹtẹkẹtẹ alagidi, tabi ọ̀yánnú ikooko. (Saamu 32:9; Luuku 10:3) Bi wọn ti jẹ́ ẹni bi agutan, a nilati ba wọn lo pẹlu iwapẹlẹ ati jẹlẹnkẹ. (Iṣe 20:28, 29) Bẹẹni, Ọlọrun reti pe ki awọn alagba jẹ́ oninututu, oninuure, onifẹẹ, ati onisuuru si awọn agutan rẹ̀.—Esikiẹli 34:17-24.
7. Bawo ni awọn alagba ṣe nilati fun awọn ẹlomiran ni itọni tabi ran awọn alaisan nipa tẹmi lọwọ?
7 Gẹgẹ bi “ẹru Oluwa,” alagba kan “yẹ ki o maa ṣe pẹlẹ si ẹni gbogbo, ki o tootun lati kọni, ki o maa kó araarẹ nijanu kuro labẹ ibi, ki o sì maa fi iwapẹlẹ kọ awọn wọnni ti ko ni itẹsi bi ọrẹ lẹkọọ; bi boya Ọlọrun yoo fun wọn ni ironupiwada ti nsinni lọ si imọ pipeye ti otitọ.” (2 Timoti 2:24, 25, NW) Awọn Kristẹni oluṣọ agutan nilati fi igbatẹniro onijẹlẹnkẹ han nigba ti wọn ba ngbiyanju lati ran ẹni ti nṣaisan nipa tẹmi lọwọ, nitori awọn agutan jẹ ti Ọlọrun. Awọn alagba ko gbọdọ bá wọn lò gẹgẹ bi alagbaṣe kan yoo ti ṣe ṣugbọn wọn nilati jẹ ọlọkantutu, bi Oluṣọ-agutan Rere naa, Jesu Kristi.—Johanu 10:11-13.
8. Ki ni o ṣẹlẹ si Mose ọlọkantutu, eesitiṣe?
8 Alagba kan nigba miiran le rii pe o ṣoro lati pa ẹmi pẹlẹ mọ. “Mose ni o jẹ oninututu julọ ninu gbogbo eniyan ti o wa lori ilẹ.” (Numeri 12:3, NW) Sibẹ, nigba ti awọn ọmọ Isirẹli dojukọ aito omi ni Kadeṣi, wọn ni gbolohun asọ pẹlu Mose wọn si da a lẹbi fun ṣiṣamọna wọn kuro ni Ijibiti wa sinu aginju aṣalẹ kan. Laika gbogbo eyi ti Mose ti fi inututu farada sí, oun fi ibinu sọrọ, lọna lile. Oun ati Aroni duro niwaju awọn eniyan wọn si dari afiyesi si araawọn, Mose nwi pe: “Ẹyin gbọ nisinsinyi, ẹyin ọlọtẹ; ki awa ki ó ha mu omi lati inu apata yii fun yin wá bi?” Lẹhin naa Mose lu apata naa pẹlu ọpa rẹ̀ lẹẹmeji, Ọlọrun si mu ki ‘ọpọlọpọ omi’ tu jade fun awọn eniyan naa ati ẹran ọ̀sìn wọn. Inu Jehofa ko dun nitori pe Mose ati Aroni kò yà Á si mímọ́, nitori naa Mose ko lanfaani lati ṣamọna awọn ọmọ Isirẹli wọnu Ilẹ Ileri naa.—Numeri 20:1-13; Deutaronomi 32:50-52; Saamu 106:32, 33.
9. Bawo ni a ṣe le dán iwapẹlẹ alagba kan wò?
9 Iwapẹlẹ Kristẹni alagba kan ni a tun le danwo ni oniruuru ọna. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu kilọ fun Timoti pe ẹnikan ti “o nfi igberaga wú fùkẹ̀” ati ti “ọpọlọ rẹ̀ dàrú lori awọn ibeere onijiyan ati ija ọrọ lè dide”. Pọọlu fikun un pe: “Lati inu nǹkan wọnyi ni ilara ti nsun jade, rogbodiyan, awọn ọrọ eebu sisọ, ifura buruku, ija oniwa ipa lori awọn ohun ti ko nilaari lọdọ awọn eniyan ti ero inu wọn ti dibajẹ ti otitọ ko sì sí mọ́ ninu wọn.” Timoti alaboojuto ni ko gbọdọ huwa lọna lile ṣugbọn yoo nilati “sá fun nǹkan wọnyi,” oun ni o sì nilati lepa ododo, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ, ifẹ, ifarada, ọkàn tutupẹlẹ.”—1 Timoti 6:4, 5, 11, NW.
10. Ki ni Titu nilati rán awọn ijọ létí rẹ̀?
10 Bi o tilẹ jẹ pe awọn alagba nilati jẹ oniwapẹlẹ, wọn gbọdọ jẹ aduro gbọnyingbọnyin fun ohun ti o tọ́. Titu dabi iyẹn, ni rírán awọn wọnni ti wọn nkẹgbẹpọ pẹlu ijọ Kirete létí lati “maṣe sọrọ ẹgan nipa ẹnikankan, ki wọn maṣe jẹ onija, ki wọn jẹ ọlọgbọn inu, ki wọn maa fi gbogbo iwapẹlẹ han si gbogbo eniyan.” (Titu 3:1, 2, NW) Ni fifi idi ti awọn Kristẹni fi nilati jẹ ọlọkantutu si gbogbo eniyan han, Titu nilati dari afiyesi sí bi Jehofa ti jẹ oninuure ati onifẹẹ tó. Ọlọrun ko tii gba awọn onigbagbọ là nitori awọn iṣe ododo eyikeyii ti wọn ti ṣe ṣugbọn ni ibamu pẹlu aanu rẹ̀ nipasẹ Jesu Kristi. Iwapẹlẹ ati suuru Jehofa tumọsi igbala fun wa pẹlu. Nitori naa, bi Titu, awọn alagba ode oni nilati rán awọn ijọ létí lati wà ni itẹriba sí Ọlọrun ni ṣiṣafarawe Rẹ̀ nipa biba awọn ẹlomiran lò ni ọna iwapẹlẹ.—Titu 3:3-7; 2 Peteru 3:9, 15.
Iwapẹlẹ Ńtọ́ Olugbaninimọran Ti Ó Jẹ Ọlọgbọn Sọ́nà
11. Gẹgẹ bi Galatia 6:1, 2 ti wi, bawo ni a ṣe nilati funni ni imọran?
11 Ki ni bi agutan afiṣapẹẹrẹ kan ba ṣìnà? Pọọlu wi pe: “Ẹyin ara, ani bi eniyan kan ba tilẹ ṣì ẹsẹ gbé ki o to mọ nipa rẹ̀, ẹyin ti ẹ ni ẹri titootun ti ẹmi nilati gbiyanju lati tun iru eniyan bẹẹ ṣe bọsipo ninu ẹmi iwapẹlẹ, bi olukuluku yin ti nkiyesi araarẹ, ni ibẹru pe a le dẹ ẹyin naa wò pẹlu. Ẹ maa baa lọ ni riru ẹrù inira araayin, ki ẹ sì tipa bayii mu ofin Kristi ṣẹ.” (Galatia 6:1, 2, NW) Imọran tubọ gbeṣẹ sii bi a ba fifunni pẹlu ẹmi iwapẹlẹ. Ani bi awọn alagba paapaa ba gbiyanju lati gba ẹnikan ti nbinu nimọran, wọn nilati fi ikora ẹni nijaanu han, ni mímọ̀ pe “ahọn ti ó tutupẹlẹ funraarẹ lè fọ́ egungun.” (Owe 25:15, NW) Ẹnikan ti ó le bi egungun ni a lè dẹ̀rọ̀ nipa gbolohun pẹlẹ kan, ilekoko rẹ̀ sì le rọ̀.
12. Bawo ni ẹmi iwapẹlẹ ṣe le ran agbaninimọran kan lọwọ?
12 Jehofa jẹ Olutọni ọlọkantutu, ọna igbakọni oniwapẹlẹ rẹ̀ sì gbeṣẹ ninu ijọ. Eyi ni pataki ri bẹẹ nigba ti awọn alagba ba ri i pe o pọndandan lati gba awọn wọnni ti wọn nbeere iranlọwọ tẹmi nimọran. Ọmọ-ẹhin naa Jakọbu wi pe: “Ta ni gbọn ti o sì loye ninu yin? Jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ han lati inu iwarere rẹ̀ pẹlu iwapẹlẹ tii ṣe ti ọgbọn.” Iwapẹlẹ njẹyọ lati inu ọ̀wọ̀ ati imoore fun “ọgbọn ti ó ti oke wa,” papọ pẹlu mimọ iwọntunwọnsi awọn ibi ti agbara ẹni mọ. Ẹmi iwapẹlẹ ati irẹlẹ ndaabobo agbaninimọran naa kuro ninu sísọ awọn ọ̀rọ̀ ati ṣiṣe awọn aṣiṣe ti kò ni iyọrisi rere ti yoo si mu ki imọran rẹ rọrun lati gbà.—Jakọbu 3:13, 17.
13. Bawo ni “iwapẹlẹ tii ṣe ti ọgbọn” ṣe ńnípa lori ọna ti a gba funni ni imọran?
13 “Iwapẹlẹ tii ṣe ti ọgbọn” nṣediwọ fun agbaninimọran kan lati maṣe jẹ́ alainiwa rere tabi lekoko lọna aironujinlẹ. Sibẹ, aniyan lori ipo ọrẹ tabi nini itẹwọgba ẹnikan ko gbọdọ sún alagba kan lati sọ awọn ohun ti a pete lati tẹnilọrun dipo ki o fi pẹ̀lẹ́tù gbe imọran taarata ti a gbekari Ọrọ Ọlọrun kalẹ. (Owe 24:24-26; 28:23) Imọran ti Aminọni gbà lati ọdọ ọmọ ibatan rẹ̀ tẹ́ ifẹ ọkan rẹ̀ lọ́rùn, ṣugbọn ó na an ní iwalaaye rẹ̀. (2 Samuẹli 13:1-19, 28, 29) Nitori naa, awọn alagba ode oni ko gbọdọ sọ awọn ilana Bibeli di alailagbara lati tu ẹ̀rí ọkan ẹnikan lara, nitori ṣiṣe bẹẹ le fi iwalaaye rẹ̀ sinu ewu. Bii Pọọlu, awọn alagba ko gbọdọ fà sẹhin kuro ninu sisọ “gbogbo ipinnu Ọlọrun” fun awọn ẹlomiran. (Iṣe 20:26, 27; 2 Timoti 4:1-4) Kristẹni olugbaninimọran kan ti o dàgbàdénú fi ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun han o sì nfunni ni imọran ododo pẹlu iwapẹlẹ tii ṣe ti ọgbọn.
14. Eeṣe ti alagba kan fi gbọdọ ṣọra lati maṣe ṣe awọn ipinnu ti awọn ẹlomiran nilati ṣe funraawọn?
14 Iwapẹlẹ papọ pẹlu ọgbọn ti ọrun yoo dí alagba kan lọwọ kuro ninu bibeere awọn ibeere lilekoko. Oun nilati tun mọ pe kò bọgbọnmu ko si tọna fun un lati ṣe ipinnu kan ti ẹlomiran yẹ ki o ṣe funraarẹ. Alagba kan ni yoo dahun fun abajade bi oun bá ṣe ipinnu fun awọn ẹlomiran, oun yoo sì ṣajọpin ẹ̀bi fun abajade buburu eyikeyii. Alagba kan lè pe afiyesi sí ohun ti Bibeli sọ, ṣugbọn bi kò bá sí ofin kankan ti ó bá Iwe mimọ mu lori ọran kan, ero ati ẹ̀rí ọkàn ẹnikọọkan gbọdọ pinnu ohun ti yoo ṣe tabi ti ki yoo ṣe. Gẹgẹ bi Pọọlu ti wi: “Olukuluku ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Galatia 6:5; Roomu 14:12) Bi o ti wu ki o ri, a le ran oluwadii kan lọwọ siha ṣiṣe ipinnu ti o tọ́ nipa ki alagba kan beere awọn ibeere ti yoo ran ẹni naa lọwọ lati ronu lori awọn iwe mimọ ti o tan mọ́ awọn ipa ọna ti a le yàn ti o le ṣí silẹ fun un.
15. Ki ni alagba kan nilati ṣe bi kò bá mọ idahun si ibeere kan?
15 Bi alagba kan ko ba mọ idahun si ibeere kan, oun ko nilati dahun kìkì lati gbé itiju tà. Iwapẹlẹ tii ṣe ti ọgbọn yoo paa mọ kuro ninu mimefo ati boya fifunni ni idahun ti ko tọna kan ti o lè ṣokunfa inira nikẹhin. “Igba didakẹ, ati igba fifọhun” wà. (Oniwaasu 3:7; fiwe Owe 21:23.) Alagba kan gbọdọ “sọrọ” kiki nigba ti o ba mọ idahun si ibeere kan tabi ti ó ti ṣe iwadii ti o tó lati funni ni idahun pipeye kan. Ó bọgbọnmu lati fi awọn ibeere alábàá ìméfò silẹ laidahun.—Owe 12:8; 17:27; 1 Timoti 1:3-7; 2 Timoti 2:14.
Iniyelori Ọpọlọpọ Olugbaninimọran
16, 17. Eeṣe ti o fi bojumu fun awọn alagba lati fi ọran lọ araawọn?
16 Adura ati ikẹkọọ yoo ran awọn alagba lọwọ lati dahun awọn ibeere ki wọn sì bojuto awọn iṣoro, ṣugbọn wọn gbọdọ ranti pe “ninu ọpọlọpọ olugbaninimọran ni aṣeyọri wà.” (Owe 15:22, NW) Fifi ọran lọ awọn alagba miiran nyọrisi akojọpọ ọgbọn ti o ṣeyebiye. (Owe 13:20) Kii ṣe gbogbo awọn alagba ni wọn niriiri tabi imọ Bibeli ti o dọgba. Fun idi yii, iwapẹlẹ tii ṣe ti ọgbọn nilati sun alagba ti iriri rẹ mọniwọn lati fi ọran lọ awọn alagba ti wọn ni imọ ati iriri ti o pọ sii, ni pataki nigba ti ọran wiwuwo kan ba ńfẹ́ abojuto.
17 Nigba ti a ba yan awọn alagba lati bojuto ọran wiwuwo kan, sibẹ wọn le fi ìpàṣírímọ́ wá iranlọwọ nikọkọ. Lati ràn án lọwọ ninu ṣiṣedajọ awọn ọmọ Isirẹli, Mose yan “awọn ọkunrin ti o tó, ti wọn bẹru Ọlọrun, awọn ọkunrin oloootọ, ti wọn koriira ojukokoro.” Bi o tilẹ jẹ pe wọn je alagba, wọn ko ni imọ ati iriri ti ó pọ̀ tó gẹgẹ bi Mose ti ni. Fun idi yii, “ọran ti o ṣoro ni wọn a mu tọ Mose wá, ṣugbọn gbogbo ọran keekeeke ni awọn tikalara wọn yoo bojuto gẹgẹ bi onidaajọ.” (Ẹkisodu 18:13-27, NW) Bi o ba pọndandan, nigba naa, awọn alagba ti wọn nbojuto ẹjọ lile kan lonii le wá iranlọwọ awọn alaboojuto oniriiri lọna ti o bojumu, bi o tilẹ jẹ pe wọn yoo ṣe ipinnu ti o kẹhin funraawọn.
18. Ni bibojuto awọn ọran idajọ, ki ni awọn koko apinnu ti nmu awọn ipinnu titọna daniloju?
18 Mishnah Juu wi pe ni Isirẹli awọn wọnni ti wọn parapọ jẹ kóòtù abule ni iye wọn maa nyipada ni ibamu pẹlu bi ẹjọ naa ti wuwo tó. Iniyelori tootọ wa ninu ọpọlọpọ olugbaninimọran, bi o tilẹ jẹ pe iyẹn nikan kò funni ni idaniloju ijotiitọ, nitori ọpọ eniyan lè ṣaitọna. (Ẹkisodu 23:2) Awọn koko apinnu ti nmu ki o daniloju pe awọn ipinnu titọna ni a o ṣe ni Iwe mimọ ati ẹmi Ọlọrun. Ọgbọn ati iwapẹlẹ yoo sun awọn Kristẹni lati juwọsilẹ fun iwọnyi.
Wiwaasu Pẹlu Iwapẹlẹ
19. Bawo ni iwapẹlẹ ṣe ran awọn eniyan Jehofa lọwọ lati jẹrii fun awọn ẹlomiran?
19 Iwapẹlẹ tun nran awọn iranṣẹ Jehofa lọwọ lati waasu fun awọn eniyan ti wọn ní oniruuru itẹsi ọkan. (1 Kọrinti 9:22, 23) Nitori pe Jesu kọni pẹlu iwapẹlẹ, awọn onirẹlẹ ko bẹru rẹ̀, bi wọn ti ṣe si awọn aṣaaju isin lilekoko. (Matiu 9:36) Nitootọ, awọn ọna iwapẹlẹ rẹ̀ fa “awọn agutan” mọra, kii ṣe “awọn ewurẹ” buburu. (Matiu 25:31-46; Johanu 3:16-21) Bi o tilẹ jẹ pe Jesu lo awọn ede isọrọ alagbara ni biba awọn agabagebe ẹni bi ewurẹ lò, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbọdọ jẹ oniwapẹlẹ nigba ti wọn bá npolongo awọn ihin iṣẹ idajọ Ọlọrun lonii nitori wọn ko ni ijinlẹ oye ati ọla-aṣẹ tí Jesu ni. (Matiu 23:13-36) Bi wọn ti ngbọ ihin iṣẹ ijọba naa ti a waasu rẹ̀ pẹlu iwapẹlẹ, ‘awọn wọnni ti wọn ni itẹsi ọkan fun iye ainipẹkun di onigbagbọ,’ gẹgẹ bi awọn ẹni bi agutan ti wọn gbọ iwaasu Jesu ti ṣe.—Iṣe 13:48.
20. Bawo ni akẹkọọ Bibeli kan ṣe janfaani nigba ti a ba kọ́ ọ pẹlu iwapẹlẹ?
20 Awọn iyọrisi rere ni a ri nipa jijẹrii ati fifun awọn ẹlomiran ni itọni pẹlu iwapẹlẹ ati nipa fifa wọn mọra lori ipilẹ ti o ba ọgbọn ironu mu, ilana Bibeli, ati otitọ. “Ẹ ya Kristi sí mímọ́ gẹgẹ bi Oluwa ninu ọkan-aya yin,” ni Peteru kọwe, “ki ẹ muratan nigba gbogbo lati gbeja niwaju olukuluku ti nfi dandangbọn beere lọwọ yin idi fun ireti ti nbẹ ninu yin, ṣugbọn ki ẹ ṣe bẹẹ pẹlu ọkantutu ati ọ̀wọ̀ jijinlẹ.” (1 Peteru 3:15, NW) Akẹkọọ kan ti a kọ́ ni ọna iwapẹlẹ lè pọkàn pọ̀ sori akojọpọ ẹkọ dipo jijẹ ẹni ti a pín níyà tabi ti o ṣeeṣe ki a mú kọsẹ̀ paapaa nipa sisọrọ lọna lile ati lọna ariyanjiyan. Bii Pọọlu, awọn ojiṣẹ ti nfuuni ni itọni pẹlu iwapẹlẹ le wi pe: “A ko sì ṣe ohun ikọsẹ ni ohunkohun, ki iṣẹ iranṣẹ ki o maṣe di isọrọ buburu si.” (2 Kọrinti 6:3) Ani awọn alatako paapaa nigba miiran maa ndahunpada lọna rere si awọn wọnni ti nfunni ni itọni pẹlu iwapẹlẹ.
Iwapẹlẹ Ni A Beere Lọwọ Gbogbo Eniyan
21, 22. Bawo ni iwapẹlẹ ṣe ṣanfaani fun gbogbo awọn eniyan Jehofa?
21 Iwapẹlẹ Kristẹni ni a ko gbọdọ gbéwọ̀ kiki lati wú awọn wọnni ti wọn wà lẹhin ode eto-ajọ Jehofa lori. Animọ yii tun ṣekoko ninu awọn ibatan wa laaarin awọn eniyan Ọlọrun. (Kolose 3:12-14; 1 Peteru 4:8) Awọn ijọ ni a gbéró nipa tẹmi nigba ti awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ọlọkantutu ba ṣiṣẹ papọ pẹlu iṣọkan. Fifi iwapẹlẹ ati awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun miiran han ṣe pataki fun ẹnikọọkan lara awọn eniyan Jehofa nitori pe “ofin kan” ni nbẹ fun gbogbo eniyan.—Ẹkisodu 12:49; Lefitiku 24:22.
22 Iwapẹlẹ nfikun alaafia ati ayọ awọn eniyan Ọlọrun. Nitori naa, o gbọdọ jẹ apakan ẹ̀yà aṣọ awọn animọ ti ó parapọ jẹ́ ẹwu ti gbogbo awọn Kristẹni nwọ ni ile, ninu ijọ, ati nibomiran. Bẹẹni, gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa ni a nilati wọ̀ ni aṣọ pẹlu iwapẹlẹ.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Eeṣe ti awọn Kristẹni alagba fi nilati jẹ ọlọkantutu?
◻ Bawo ni iwapẹlẹ ṣe nṣamọna olugbaninimọran ọlọgbọn?
◻ Ki ni iniyelori ọpọlọpọ olugbaninimọran?
◻ Eeṣe ti o fi ṣanfaani lati jẹrii pẹlu iwapẹlẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Awọn eniyan Jehofa jẹ ẹni bi agutan a sì nilati bá wọn lò pẹlu iwapẹlẹ
[Credit Line]
Garo Nalbandian
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Iwapẹlẹ mu ki o ṣeeṣe fun awọn eniyan Jehofa lati jẹrii fun awọn eniyan ti wọn ní oniruuru itẹsi ọkan