ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/1 ojú ìwé 5-7
  • Ọjọ Ẹ̀san Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọjọ Ẹ̀san Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Eeṣe Ti Ọjọ Ẹ̀san Fi Wà?
  • Ki Ni Ọjọ Ẹ̀san Ọlọrun Yoo Ṣaṣepari Rẹ̀?
  • Ki Ni Iwọ Yoo Ṣe?
  • Ẹ̀san Ha Ṣàìtọ́ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • ‘Baba Yín Jẹ́ Aláàánú’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Táwọn Èèyàn Bá Ṣe Ohun Tó Dùn Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/1 ojú ìwé 5-7

Ọjọ Ẹ̀san Ọlọrun

GẸGẸ BI a ti ri i ninu ọrọ-ẹkọ ti ó ṣaaju, awọn ìdí melookan wà ti kò fi tọna lati wá ọna ẹ̀san. Kò tọna nitori pe ni ìgbẹ̀hìn-gbẹ́hín, kò yanju ohunkohun. Kò tọna nitori pe o nsọ ẹmi ọta di eyi ti o wà pẹtiti dipo siso ìdè ẹmi ọrẹ papọ. Kò sì tọna nitori pe ó buru fun ẹni naa ti ó di ironu ẹmi ẹ̀san sinu.

Bi o ti wu ki o ri, ìdí pataki julọ ti ẹ̀san eniyan ko fi tọna ni a rí ninu awọn ọrọ Mose sí Isirẹli pe: “Ọlọrun alaaanu ni Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ.” (Deutaronomi 4:31) Niwọn bi Ọlọrun ti jẹ alaaanu, awa gbọdọ jẹ alaaanu bii tirẹ̀. Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Njẹ ki ẹyin ki o ni aanu, gẹgẹ bi Baba yin sì ti ni aanu.”—Luuku 6:36.

Sibẹ, Bibeli tun ṣapejuwe Jehofa gẹgẹ bi “Ọlọrun ẹ̀san.” (Saamu 94:1) Wolii Aisaya sọrọ nipa “ọdun ìtẹ́wọ́gbà Oluwa [“Jehofa,” NW]” ati “ọjọ ẹ̀san Ọlọrun wa” pẹlu. (Aisaya 61:2) Bawo ni Ọlọrun ṣe lè jẹ́ alaaanu ati Ọlọrun ẹ̀san papọ? Ati bi awa yoo ba farawe aanu Ọlọrun, eeṣe ti awa kò fi lè farawe e ninu gbigbẹsan?

Lati dahun ibeere akọkọ, Ọlọrun jẹ́ alaaanu nitori pe oun nifẹẹ araye, oun sì ndarijini bi oun ti lè ṣe e tó fun iwọn ibi ti oun lè ṣe e dé ki ó baa le fun awọn eniyan ni anfaani lati tun ọna wọn ṣe. Ọpọlọpọ, bi apọsiteli Pọọlu, ti lo anfaani aanu yii lọna rere. Ṣugbọn Ọlọrun tun jẹ́ ẹlẹsan—ni itumọ ti fifi dandan beere idajọ ododo—nitori pe iru aanu bẹẹ le maa baa lọ kiki fun iwọn igba kan. Nigba ti awọn kan ba ti fihan pe awọn ki yoo yi ọna wọn pada, Ọlọrun yoo mu idajọ ṣẹ nigba ohun ti a npe ni ọjọ ẹ̀san rẹ̀.

Ni idahun si ibeere keji, bẹẹkọ, a kò dá wa lare ninu jijẹ ẹlẹmii ẹ̀san nitori pe Ọlọrun ni nfi dandan beere ẹ̀san. Jehofa jẹ́ ẹni pipe ni idajọ ododo. Awọn eniyan kò rí bẹẹ. Ọlọrun ri gbogbo ìhà ọran kan o sì nṣe ipinnu ododo nigba gbogbo. A kò le gbarale araawa lati ṣe ohun kan naa. Idi niyẹn ti Pọọlu fi gbaninimọran pe: “Olufẹ, ẹ maṣe gbẹsan araayin, ṣugbọn ẹ fi aye silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wi pe, Temi ni ẹ̀san, emi yoo gbẹsan.” (Roomu 12:19) Fun ire tiwa funraawa, a gbọdọ fi ẹ̀san silẹ si ọwọ Jehofa.

Eeṣe Ti Ọjọ Ẹ̀san Fi Wà?

Sibẹ, ọpọlọpọ ibi ni Bibeli fi aini naa han fun bibeere ìjíhìn lọwọ awọn oluṣe buburu alaironupiwada. Fun apẹẹrẹ, apọsiteli Pọọlu sọtẹlẹ pe Ọlọrun, nipasẹ Jesu yoo mu “ẹ̀san wá sori awọn wọnni ti wọn kò mọ Ọlọrun ati awọn wọnni ti wọn ko ṣegbọran si ihinrere nipa Oluwa wa Jesu.” (2 Tẹsalonika 1:8, NW) A ni ìdí rere lati fọwọ pataki mu awọn ọrọ wọnni. Eeṣe?

Idi kan niyii, nitori pe ọpọ julọ lonii tẹpẹlẹ mọ ṣiṣayagbangba pe ipo ọba alaṣẹ Ẹlẹdaa naa nija, wọn ṣaibọwọ fun awọn ofin ododo rẹ̀. Yala wọn jẹwọ pe awọn nigbagbọ ninu Ọlọrun tabi bẹẹ kọ, iwa wọn ni kedere fihan pe wọn kò nimọlara pe awọn yoo jihin niwaju Ọlọrun. Awọn ọrọ onisaamu naa ṣee fi silo fun gbogbo iru awọn eniyan bẹẹ: “Eeṣe ti ẹni buburu ko fi bọwọ fun Ọlọrun? Oun ti sọ ninu ọkan-aya rẹ̀ pe: ‘Iwọ ki yoo beere fun ijihin.’” (Saamu 10:13, NW) Dajudaju, Jehofa ki yoo jẹ ki a maa gan oun ni ọna yii titilae. Bi o tilẹ jẹ pe oun jẹ Ọlọrun ifẹ, oun tun jẹ Ọlọrun idajọ ododo. Oun yoo kọbiara si igbe awọn wọnni ti wọn nifẹẹ ninu idajọ ododo nitootọ: “Dide, Óò Jehofa. Iwọ Ọlọrun, gbe ọwọ rẹ soke. Maṣe gbagbe awọn ẹni ti a npọn loju.”—Saamu 10:12, NW.

Siwaju sii, awọn eniyan oluṣayagbangba pofinnija npa ilẹ-aye ti a ngbe lori rẹ̀ gan-an run. Wọn sọ afẹfẹ, ilẹ, ati omi di ẹlẹgbin; wọn fi aisi idajọ ododo ati iwa ìkà kún ilẹ-aye. Wọn sì to bọmbu onimajele oloro, àgbá atọmiiki, ati awọn ohun ija aṣekupani miiran ti o pọ̀ jọ pelemọ lati halẹ mọ iwalaaye iran eniyan. Ìdásí atọrunwa ni a nilo ni kanjukanju ki a baa le mu ọjọ ọla alaabo kan daju fun araye onigbọran. (Iṣipaya 11:18) Ìdásí yii ni Aisaya tọka si gẹgẹ bi ọjọ ẹ̀san.

Ki Ni Ọjọ Ẹ̀san Ọlọrun Yoo Ṣaṣepari Rẹ̀?

Gẹgẹ bi Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words ti wi, ninu Iwe mimọ lede Giriiki, ọrọ fun ẹ̀san, nigba ti a ba lo o ni isopọ pẹlu Ọlọrun, lọna olowuuru tumọ si “‘iyẹn ti ó jẹ jade lati inu idajọ ododo,’ kii ṣe, gẹgẹ bi o ti saba maa ńrí pẹlu ẹ̀san eniyan, eyi ti ńjẹ jade lati inu imọlara ipalara tabi lati inu imọlara ìkannú lasan.” Nipa bayii, akoko ẹ̀san Ọlọrun lodi si awọn ọta rẹ̀ ki yoo jẹ akoko itajẹsilẹ ti a kò kóníjàánu, bii ija laaarin ara-ẹni. Bibeli sọ fun wa pe, “Jehofa mọ bi a ṣee dá awọn eniyan olufọkansin oniwa-bi-Ọlọrun nide kuro ninu idanwo, ṣugbọn lati fi awọn eniyan alaiṣododo pamọ de ọjọ idajọ lati ké wọn kuro.”—2 Peteru 2:9, NW.

Awọn iranṣẹ Ọlọrun nfojusọna fun ọjọ ẹ̀san Ọlọrun gẹgẹ bi akoko kan nigba ti a o dá iwa titọna lare ti a o sì dá awọn olododo nídè kuro ninu ìnilára awọn eniyan buburu. Eyi kò tumọ si pe wọn jẹ aláràn-ánkàn tabi ẹlẹmii ẹ̀san. Bibeli kilọ pe, “Ẹni ti o ba kun fun ayọ nitori ìjábá ẹlomiran ki yoo wà lominira kuro lọwọ ìjìyà.” (Owe 17:5, NW) Ni odikeji, wọn mu aanu ati ìyọ́nú dagba, ni fifi awọn ipinnu eyikeyii nipa ẹ̀san lé Ọlọrun lọwọ.

Loootọ, kò rọrun fun awọn ẹni ti nbinu lati huwa ni ọna yii. Ṣugbọn ó ṣeeṣe, ọpọlọpọ sì ti ṣe bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, Pedro ko layọ ni igba ọmọde rẹ̀ ẹgbọn rẹ̀ ọkunrin a sì maa lu u nigba gbogbo. Nitori naa o dagba di oniwa ipá ti ó maa nwọ gàù pẹlu awọn ọlọpaa lemọlemọ ti o sì nfi ikanra ibinu ti o ni si arakunrin rẹ̀ mọ́ aya ati awọn ọmọ rẹ̀. Nikẹhin, o fetisilẹ si ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa o sì bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli lẹhin naa. Ó rohin pe, “Pẹlu iranlọwọ Jehofa, mo yipada, ati nisinsinyi, dipo biba awọn eniyan jà, mo nran wọn lọwọ gẹgẹ bi Kristẹni alagba kan.” Pẹlu iranlọwọ Bibeli ati ẹmi mimọ, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn ẹlomiran ti yipada bakan naa kuro ninu jijẹ aláràn-ánkàn tabi ẹlẹmii ẹ̀san si fifi ifẹ ati suuru han si awọn ẹlomiran.

Ki Ni Iwọ Yoo Ṣe?

Fifi dídé ọjọ ẹ̀san Ọlọrun sọkan yoo ran wa lọwọ lati lo anfaani suuru Jehofa. Ṣugbọn aye lati ṣe bẹẹ kii ṣe alailopin. Laipẹ ọjọ yẹn yoo dé. Apọsiteli Peteru fi idi ti ko fi tii de titi di akoko yii hàn pe, “Oluwa [“Jehofa,” NW] kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran tii ka ìjáfara; ṣugbọn o nmu suuru fun yin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbe, bikoṣe ki gbogbo eniyan ki o wá si ironupiwada.”—2 Peteru 3:9.

Ó jẹ kanjukanju, nigba naa, lati murasilẹ nisinsinyi fun ọjọ ìjíhìn fun Ọlọrun nipa kikẹkọọ Iwe mimọ ati fifi imọran wọn silo. Eyi yoo ran wa lọwọ lati tẹle awọn ọrọ onisaamu naa pe: “Dakẹ inu-bibi, ki o sì kọ ikannu silẹ: maṣe ikanra, ki o ma baa ṣe buburu pẹlu. Nitori ti a o ké awọn oluṣe buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa [“Jehofa,” NW] ni yoo jogun aye.”—Saamu 37:8, 9.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Lẹhin ọjọ ẹ̀san Ọlọrun, ‘awọn wọnni ti o duro de Oluwa ni yoo jogun aye’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́