ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/1 ojú ìwé 3-5
  • Ẹ̀san Ha Ṣàìtọ́ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀san Ha Ṣàìtọ́ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iwa Ẹmi Igbẹsan Npanilara
  • Ìjìyà—Lati Ọwọ Ta Ni?
  • Ẹ̀san—Lati Ọwọ Ta Ni?
  • Ọjọ Ẹ̀san Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Táwọn Èèyàn Bá Ṣe Ohun Tó Dùn Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbẹ̀san?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/1 ojú ìwé 3-5

Ẹ̀san Ha Ṣàìtọ́ Bi?

Loju ọna márosẹ̀ kan ni United States, ọkọ̀ ayọkẹlẹ kan kò tete yà lọna lati jẹ ki omiran kọja. Awakọ ọkọ̀ ayọkẹlẹ keji gbẹsan nipa yiyinbọn lu ọkọ̀ ti ó ṣeláìfí naa, ti ó sì pa ero ọkọ̀ kan tí kò mọwọmẹsẹ.

Ọmọbinrin ọdọlangba kan ni ọmọbinrin miiran gbapo rẹ̀ ninu apa eré ile-ẹkọ kan. Ó gbẹsan nipa sisọ fun ọ̀rẹ́kùnrin ọmọbinrin naa pe ọmọbinrin naa ńbẹ ọmọkunrin miiran wò ni ile-ẹkọ miiran. O tipa bayii ba ipo ibatan ọmọbinrin naa jẹ́ pẹlu ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀.

ỌPỌLỌPỌ eniyan nimọlara ìdáláre ninu gbigbẹsan nigba ti wọn ba ronu pe a ti ṣaitọ si wọn. Ni ọna kan tabi omiran, wọn tẹle ọrọ amọ̀nà naa pe: “Bi adiyẹ bá dà ọ́ lóògùn nù, iwọ naa fọ́ ọ lẹyin.” Lonii, ifẹ aladuugbo ti lọ silẹ gan-an, ẹmi ẹ̀san sì ńmókè sii.—Matiu 24:12.

Bi o ti wu ki o ri, oju wo ni o fi nwo ẹ̀san? Bi iwọ ba gba Bibeli gbọ, boya iwọ nimọlara pe ni ipilẹ ẹ̀san kò tọna. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti ngbe ninu aye alaiwa-bi-Ọlọrun kan, iwọ le nimọlara pe idariji, ti o jẹ odikeji ẹmi igbẹsan, ni kii saba jẹ́ didojukọ otitọ. Bawo ni iwọ yoo ṣe huwa pada bi a bá rẹ́ ọ jẹ tabi fipa jà ọ́ lólè ni igboro? Iwọ ha di ẹlẹmii igbẹsan bi ẹnikan bá foju tẹmbẹlu rẹ tabi sọrọ lọna ibanilorukọjẹ nipa rẹ fun awọn ẹlomiran? Iwọ ha jẹ ẹlẹmii igbẹsan tabi adarijini bi?

Iwa Ẹmi Igbẹsan Npanilara

Nitootọ, ṣiṣẹni ní iwọn ọtọọtọ. Ṣugbọn ọpọ julọ awọn eniyan ti wọn fẹ lati gbẹsan lara ẹnikan ni a ko tii fipa jà lólè nigboro tabi kọlù lọna iwa ọdaran. “Awọn ìṣẹ̀síni” ti a fayọ ni ibẹrẹ ọrọ-ẹkọ yii ko wulẹ to nǹkan bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ́ bàbàrà ni ọkan awọn ẹni naa ti wọn pinnu lati gbẹsan.

Bibeli wi pe a ko gbọdọ mu ẹmi igbẹsan dagba. Owe 24:29 gbani nimọran pe: “Maṣe wi pe, bẹẹ ni emi yoo ṣe sí i, gẹgẹ bi o ti ṣe sí mi: emi yoo san an fun ọkunrin naa gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.” Eeṣe ti a ko fi nilati ṣe bẹẹ? Idi kan niyii, iru iṣarasihuwa kan bẹẹ npanilara lọna ti imọlara ati ti ara. Awọn ironu ẹlẹmii ẹ̀san ngba alaafia ọkan kuro ó sì nṣedena ironu ti ó yèkooro. Gbe akọsilẹ irohin yii yẹwo: “Agbẹ meji ni yiyinbọn lati inu ọkọ̀ akẹ́rù wọn pa araawọn ẹnikinni keji ni ibi ìgbọ́kọ̀sí kan, ni fifopin si ija ologoji ọdun ti o ti bẹrẹ lati igba ti wọn ti wà lọmọde.” Rò ó wò, jalẹ gbogbo igbesi-aye wọn ironu awọn ọkunrin meji wọnyi ni a ti pọ oró si nipa ẹmi igbẹsan ti ńgbèèràn!—Owe 14:29, 30.

Idi miiran ti a ko fi gbọdọ mu ẹmi igbẹsan dagba ni pe awọn oluṣaitọ—ani awọn oluṣaitọ buburu jai paapaa—lè yipada. Fun apẹẹrẹ, apọsiteli Pọọlu ni akoko kan “fọwọ si pipa” Sitefanu ọmọ-ẹhin naa o sì mí eemi ìhàlẹ̀ ati ipaniyan lodi si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa.” Ṣugbọn ó yipada. Ni ọpọlọpọ ọdun lẹhin naa apọsiteli Peteru—ẹni ti iwalaaye rẹ̀ ti wa ninu ewu lati ọwọ Pọọlu lakooko iṣaaju yẹn—pè é ni “Pọọlu arakunrin wa olufẹ.” (Iṣe 8:1; 9:1; 2 Peteru 3:15, NW) Awọn Kristẹni ìbá ti gbiyanju lati gbẹsan lara Pọọlu paapaa nigba ti oun nduro, láìríran ni Damasiku. (Iṣe 9:3-15) Aṣiṣe abanininujẹ wo ni iyẹn ìbá ti jẹ́!

Nitori naa, o ṣeeṣe fun Pọọlu lati gbaninimọran ni Roomu 12:20 pe: “Bi ebi ba npa ọ̀tá rẹ, fun un ni ounjẹ; bi oungbẹ ba ńgbẹ ẹ́, fun un ni omi mu.” Eeṣe? Nitori pe bi a ba gbẹsan araawa lara ọta kan, a nmu iṣarasihuwa rẹ̀ yigbì a sì nsọ ẹmi ọta ti o wà laaarin wa di eyi ti ó wà pẹtiti. Ṣugbọn bi awa ba ṣe rere si ẹnikan ti ó ṣẹ̀ tabi fi ìwọ̀sí lọ̀ wá, awa le pẹ̀rọ̀ si iṣarasihuwa rẹ̀ ki a sì sọ ọta tẹlẹri kan di ọ̀rẹ́

Mimọ ailera tiwa funraawa tun le ran wa lọwọ lati ṣẹpa ẹ̀dùn ti ńṣamọ̀nà si ifẹ fun igbẹsan. Onisaamu naa beere pe: “Oluwa, ìbáṣepé iwọ ńsàmì ẹṣẹ, Oluwa, ta ni ìbá duro?” (Saamu 130:3) Gbogbo wa ni a ti fi ìwọ̀sí lọ awọn ẹlomiran tabi ṣẹ̀ wọn. Inu wa ko ha dun bi wọn ko ba gbiyanju lati gbẹsan? Nigba naa, ko ha yẹ ki a huwa pẹlu ìkálọ́wọ́kò kan naa? Jesu gbaninimọran pe: “Nitori naa gbogbo ohunkohun ti ẹyin ba nfẹ ki eniyan ki o ṣe sí yin, bẹẹ ni ki ẹyin ki ó sì ṣe sí wọn gẹgẹ.”—Matiu 7:12.

Loootọ, Bibeli wi pe: “Ẹ koriira ibi.” (Saamu 97:10; Amosi 5:15) Ṣugbọn ko sọ fun wa lati koriira ẹni naa ti nṣe ibi. Nitootọ, Jesu paṣẹ fun wa pe: “Ẹ fẹ awọn ọta yin, ẹ sure fun awọn ẹni ti o nfi yin ré.” (Matiu 5:44) Bi a ba fi oró yaró, a ṣe afarawe ẹmi oluṣe buburu naa. Owe igbaani naa wi pe: “Iwọ maṣe wi pe, emi yoo gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa [“Jehofa,” NW], oun yoo sì gbà ọ́.” (Owe 20:22) Iru iṣarasihuwa ọlọgbọn wo ni eyi! Ẹ wo bi ó ti dara ju tó lati fi araawa hàn ni olubori nipa didena idanwo lati ṣafarawe awọn oluṣe buburu.—Johanu 16:33; Roomu 12:17, 21.

Ìjìyà—Lati Ọwọ Ta Ni?

Nitootọ, awọn ìṣe kan tubọ buru ju awọn ìṣàfojúdi tabi ìwọ̀sí ti a ṣe si ni lọ. Ki ni bi awa ba jẹ ẹni ti iwa-ọdaran kan ṣẹlẹ sí? Gẹgẹ bi iwa ẹda, a maa nnimọlara pe fun ete idajọ ododo, ohun kan ni a gbọdọ ṣe. Ṣugbọn ki ni? Ninu awọn awujọ kan ko ṣajeji lati bojuto awọn ọran funra-ẹni ki a sì ránró. Ṣugbọn iru awọn awujọ bẹẹ niye igba ni wọn ti ndi eyi ti a fọ́ nipasẹ awọn ìjà onítàjẹ̀sílẹ̀ nikẹhin. Lonii, yala awọn ofin Ọlọrun tabi ninu ọran pupọ julọ awọn ofin eniyan ni o yọnda ẹnikọọkan lati dá gbẹ̀san awọn iwa ọdaran, fun idi rere si ni. Iru iwa ipá àdáṣe bẹẹ wulẹ ńbí iwa ipá pupọ sii ni.

Nigba naa, o ha yẹ ki ojiya ipalara iwa ọdaran kan jokoo tẹtẹrẹ ki o sì maa rún ilosi buburu naa mọra ni bi? Ko fi dandan rí bẹẹ. Nigba ti a ba pa eniyan tabi ohun ìní wa lara, awọn alaṣẹ ti a lè yiju si wà. Iwọ le fẹ lati pe awọn ọlọpaa. Ni ibi iṣẹ, lọ sọdọ alaboojuto iṣẹ. Ni ile-iwe, iwọ le fẹ lati rí ọga àgbà. Idi kan ti wọn fi wà nibẹ niyẹn—lati gbe idajọ ododo ró. Bibeli sọ fun wa pe awọn alaṣẹ ijọba jẹ́ “ojiṣẹ Ọlọrun, olugbẹsan lati fi ibinu hàn lori awọn wọnni ti wọn nṣe ohun ti o buru.” (Roomu 13:4, NW) Idajọ ododo beere fun pe ki ijọba lo aṣẹ rẹ̀ ki o dá iwa buburu duro, ki ó sì jẹ awọn oluṣe buburu niya.

Loootọ, idajọ ododo maa nfalẹ nigba miiran. Onkọwe kan ti igbesi-aye sú wi pe: “Idajọ ododo dabi ọkọ oju-irin kan ti o fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ pe igba gbogbo ni ó npẹ dé.” Nitootọ, nigba miiran, ọkọ oju-irin naa kò ni dé rara. Awọn oluhuwa aiṣedajọ ododo le jẹ alagbara gan-an debi pe awọn alaṣẹ kò le ṣakoso wọn. Sibẹ, ipa ọna ọgbọn ni ìkára-ẹni-lọ́wọ́kò. “Omugọ eniyan a jọwọ gbogbo ẹmi rẹ̀ lọwọ, ṣugbọn ọlọgbọn a pa a mọ ni idakẹjẹẹ titi dé opin,” ni Bibeli wi.—Owe 29:11, NW.

Ẹ̀san—Lati Ọwọ Ta Ni?

Kíká araawa lọ́wọ́kò kuro ninu ìránró yoo tipa bayii mu awọn anfaani wá fun wa, awa sì le fi idakẹjẹẹ duro, ni mímọ̀ pe bi a ba nilati mu idajọ ododo ṣẹ, Ọlọrun yoo ṣe e ni akoko ti ó yẹ. Jehofa mọ pe àìtọ́ ti a kò konijaanu nṣamọna si iwa ibi. (Oniwaasu 8:11) Oun ki yoo yọnda awọn olubi ti wọn ti jingiri lati pọn araye loju titilae. Idi niyii ti apọsiteli Pọọlu fi gbaninimọran pe: “Olufẹ, ẹ maṣe gbẹsan araayin, ṣugbọn ẹ fi aye silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wi pe, Temi ni ẹ̀san, emi yoo gbẹsan.” (Roomu 12:19) Nitootọ, Bibeli sọrọ nipa ọjọ ẹ̀san ni apa ọdọ Ẹlẹdaa naa. Ki ni ọjọ ẹ̀san yii yoo jẹ́? Awọn wo sì ni a o dari ẹ̀san Ọlọrun sí? Awa yoo jiroro eyi ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Lati ṣekawọ awọn imọlara ẹ̀san ranti pe

□ Ọlọrun daniyan fun idajọ ododo

□ dídi ẹmi igbẹsan sinu léwu

□ jíjẹ́ oninuure saba maa ńdín iṣoro pẹlu awọn ẹlomiran kù

□ ọpọlọpọ awọn aṣiṣe tiwa funraawa ni a ti gbójúfòdá

□ awọn oluṣaitọ le yipada

□ a ṣẹgun aye nipa lilodisi awọn ọna rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́