ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/15 ojú ìwé 27-28
  • Balogun Ọ̀rún Ara Roomu Oninuure naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Balogun Ọ̀rún Ara Roomu Oninuure naa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọ́kàn Le​—Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • “Kò sí Ìkankan Lára Yín Tó Máa Ṣègbé”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Inú Rere​—Ànímọ́ Kan Tó Yẹ Kó Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ àti Ìṣe Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Pọ́ọ̀lù Borí Ìpọ́njú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/15 ojú ìwé 27-28

Balogun Ọ̀rún Ara Roomu Oninuure naa

AWỌN balogun ọ̀rún ti Roomu kò ni iyì   fun inurere. Gẹgẹ bi ẹnikan ti a yàn    lati ṣe aṣaaju fun ọgọrun-un ẹgbẹ awọn ọmọ ogun ti ogun ti kiláyà, balogun ọ̀rún kan nilati jẹ́ sajẹnti adìdájọ́ mú tí kò gba gbẹ̀rẹ́, olubaniwi kan, ati nigbamiran, afiya iku jẹni kan paapaa. Bi eyi tilẹ ri bẹẹ, Bibeli sọ fun wa nipa balogun ọ̀rún ara Roomu kan ti ẹgbẹ ọmọ ogun Ọgọsitọsi ẹni ti ó fi iwa ọlawọ gidi ati ìyọ́nú han si apọsiteli naa Pọọlu. Orukọ rẹ tii jẹ? Juliọsi.

Bibeli mu wa mọ ọkunrin yii ninu Iṣe ori 27. Apọsiteli naa Pọọlu ti beere pe ki Kesari gbọ ẹjọ oun ni Roomu. Nipa bayii, Pọọlu, pẹlu awọn oniruuru ẹlẹwọn miiran, ni a fà lé “ọgagun kan ti orukọ rẹ̀ njẹ Juliọsi ti ẹgbẹ ọmọ ogun Ọgọsitọsi,” lọwọ. Wọn wọkọ lati Kesaria, ilu nla ibudokọ okun kan ti ó wà laaarin ariwa ati ila oorun Jerusalẹmu ti ó sì jẹ olu ilu fun ọ̀wọ̀ ogun Roomu. Akọwe itan naa Luuku sọ pe: “Ni ijọ́ keji awa dé Sidoni. Juliọsi sì ṣe inurere si Pọọlu, o sì bun un laaye ki o maa tọ̀ awọn ọrẹ rẹ̀ lọ lati ri itọju.”—Iṣe 27:1-3.

Idi ti a fi sun Juliọsi lati fi iru inurere bẹẹ han ni a ko ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli. Oun lè ti wà labẹ aṣẹ lati ọdọ Gomina Fẹsitọsi lati fun Pọọlu ni iru ilosi pataki bayii. Tabi boya oun ti lè di ojulumọ pẹlu awọn ipo ti ó fa fifi aṣẹ ọba mu Pọọlu naa, igboya ati iwatitọ Pọọlu si lè wulẹ jẹ́ ohun ti ó jọ Juliọsi loju. Oun yoowu ki o ṣẹlẹ, ó dabi ẹni pe Juliọsi loye rẹ wi pe Pọọlu kii ṣe ẹlẹwọn kan lasan.

Sibẹ, Juliọsi yan lati maṣe tẹ́tí si ikilọ Pọọlu lodisi titukọ lati Ebute Yiyanju. Laipẹ afẹfẹ oníjì lile kan fẹ́ lu u eyi ti o halẹ̀ gbígbá a si ori ilẹ ni etikun oniyanrin kuro ni bebe okun ìhà ariwa Africa mọ́ ọn. (Iṣe 27:8-17) Ni aarin ìjì lile yii, Pọọlu dide duro ó sì mu un dá awọn eniyan inu ọkọ ti jìnnìjìnnì ti bá wọnyi loju wi pe ‘ki yoo sí òfò ẹmi ninu wọn, bikoṣe ti ọkọ.’ Sibẹ, awọn kan ninu awọn atukọ naa bẹrẹsii wa ọna lati yèbọ́. Nigba naa ni Pọọlu wi fun Juliọsi pe: “Bikoṣepe awọn wọnyi ba duro ninu ọkọ ẹyin ki yoo le là.”—Iṣe 27:21, 22, 30, 31.

Ni ọ̀tẹ̀ yii, Juliọsi yan lati tẹti si Pọọlu, àti-yèbọ́ awọn atukọ naa kò sì ṣeeṣe. Gan-an bi Pọọlu ti sọ ọ tẹlẹ, ọkọ naa ni a gbá si ori ilẹ ni ori ibi kan ti kò jin pupọ ti ó sì rì. Ni ero pe awọn ẹlẹwọn naa yoo yèbọ́, awọn ọmọ ogun ti ó wà ninu ọkọ naa pinnu lati pa gbogbo wọn. Bi o ti wu ki o ri, lẹẹkan sii, Juliọsi dá si ọran naa ó sì dá awọn ọkunrin rẹ̀ lẹkun, nipa bayii a gba ẹmi Pọọlu là.—Iṣe 27:32, 41-44.

Bibeli kò sọ fun wa ohun ti ó gbẹhin balogun ọ̀rún yii tabi boya oun tẹwọgba igbagbọ Kristẹni lae. Inurere yoowu ki oun ti fihan wulẹ jẹ aṣefihan kan ti awọn iṣiṣẹ ẹri-ọkan ti Ọlọrun fifunni ni. (Roomu 2:14, 15) Bi o ti wu ki o ri, awọn Kristẹni, nlọ rekọja inurere ti eniyan lasan wọn sì nfi inurere oniwa-bi-Ọlọrun han eyi ti ó jẹ nitori nini ẹmi Ọlọrun. (Galatia 5:22) Dajudaju, bi keferi ọmọ ogun kan ẹni ti kò mọ Ọlọrun ba lè fi inurere han, meloomeloo ni a gbọdọ sun awọn eniyan Ọlọrun lati ṣe bẹẹ!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́