Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Pọ́ọ̀lù Borí Ìpọ́njú
PỌ́Ọ̀LÙ ti sọ̀rètínù pátápátá. Òun pẹ̀lú àwọn igba èèyàn ó lé márùndínlọ́gọ́rin [275] mìíràn ló wà nínú ọkọ̀ òkun tí ẹ̀fúùfù Yúrákúílò rọ́ lù—ìyẹn ni ìjì líle jù lọ tó ń jà ní agbami òkun Mẹditaréníà. Ẹ̀fúùfù náà le tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé kò sẹ́ni tó lè rí oòrùn lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ sì lẹnì kan kò lè rí ìràwọ̀ lóru. A lè wá lóye ìdí tí àyà àwọn èrò ọkọ̀ náà fi ń já nítorí ẹ̀mí wọn. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù tù wọ́n nínú nípa sísọ ohun tí Ọlọ́run fi hàn án lójú àlá pé: “Kò sí ọkàn kan láàárín yín tí a ó pàdánù, kìkì ọkọ̀ ojú omi ni a ó pàdánù.”—Ìṣe 27:14, 20-22.
Nígbà tó di ọjọ́ kẹrìnlá tí ìjì náà ti ń jà, ni àwọn atukọ̀ bá ṣàwárí kan tó múni ta gìrì—omi náà kò jìn ju ogún ìgbọ̀nká lọ.a Lẹ́yìn tí wọ́n tún tẹ̀ síwájú díẹ̀, wọ́n tún wọn bí omi náà ti jìn tó. Lọ́tẹ̀ yìí o, ìgbọ̀nká mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ni omi náà fi jìn. Ilẹ̀ ò jìnnà mọ́! Ṣùgbọ́n ìhìn rere yìí ní ìtumọ̀ tó múni sorí kọ́. Bí ìjì ti ń gbé ọkọ̀ òkun náà sókè sódò lóru nínú omi tí kò jìn yìí, ó lè lọ sẹ̀ ẹ́ mọ́ àpáta, kó sì fọ́ ọ yángá. Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, àwọn atukọ̀ náà ju ìdákọ̀ró sílẹ̀. Àwọn kan lára wọn fẹ́ rọ ọkọ̀ ìgbájá sílẹ̀ sínú òkun, kí wọ́n lè ráyè bójú òkun sá lọ ní tiwọn.b Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù dá wọn dúró. Ó sọ fún àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn ọmọ ogun pé: “Láìjẹ́ pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró sínú ọkọ̀ ojú omi, a kò lè gbà yín là.” Àwọn ọ̀gá náà fetí sí Pọ́ọ̀lù, wàyí o, gbogbo èrò náà tí wọ́n jẹ́ igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [276] dúró, wọ́n ń retí ìgbà tí ilẹ̀ yóò mọ́.—Ìṣe 27:27-32.
Wọ́n Rì Sómi
Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn èrò ọkọ̀ òkun náà rí ibi ìyawọ̀ omi kan tí ó ní etíkun. Àwọn atukọ̀ náà mọ́kàn, wọ́n gé ìdákọ̀ró kúrò, wọ́n sì ta ìgbòkun iwájú ọkọ̀ sínú ẹ̀fúùfù. Ọkọ̀ òkun náà bẹ̀rẹ̀ sí forí lé èbúté—kò sí àní-àní pé ariwo ayọ̀ náà pọ̀ lápọ̀jù.—Ìṣe 27:39, 40.
Ṣùgbọ́n, lójijì ọkọ̀ òkun náà tàn sórí àpápá. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù lọ ni pé, ìjì líle wá ń rọ́ lu ẹ̀yìn ọkọ̀ náà, ló bá fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́. Gbogbo èrò pátá ló gbọ́dọ̀ kúrò nínú ọkọ̀ yìí o! (Ìṣe 27:41) Ṣùgbọ́n ìṣòro ńlá lèyí. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú ọkọ̀—títí kan Pọ́ọ̀lù—ni wọ́n jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n. Lábẹ́ òfin ilẹ̀ Róòmù, ẹ̀ṣọ́ kan tó bá jẹ́ kí ẹlẹ́wọ̀n lọ móun lọ́wọ́ ló máa forí fá gbogbo ìyà tó yẹ kí ẹlẹ́wọ̀n náà jẹ. Fún àpẹẹrẹ, bí apààyàn kan bá sá lọ, ẹ̀ṣọ́ tí kò mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ náà ló máa fẹ̀mí ara ẹ̀ dí i.
Nítorí tí àwọn ọmọ ogun ń bẹ̀rù irú àbájáde bẹ́ẹ̀, wọ́n pinnu láti pa gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà. Ṣùgbọ́n, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó ti ń bá Pọ́ọ̀lù ṣọ̀rẹ́, dá sí ọ̀ràn náà. Ó pàṣẹ fún gbogbo àwọn tó bá mọ̀wẹ̀, kí wọ́n kán lumi, kí wọ́n sì wẹdò já. Kí àwọn tí kò bá mọ̀wẹ̀ di pákó tàbí nǹkan mìíràn tó fọ́ lára ọkọ̀ òkun náà mú. Lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn èrò inú ọkọ̀ òkun tó fẹ́ wó náà wọ́ dé etíkun. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, wọn kò pàdánù ẹ̀mí kan ṣoṣo!—Ìṣe 27:42-44.
Iṣẹ́ Ìyanu ní Màlítà
Àwùjọ àwọn tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu náà rí ibì kan sinmi ní erékùṣù táà ń pè ní Màlítà. Àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ “àwọn elédè ilẹ̀ òkèèrè,” ní ṣáńgílítí “àjèjì aláìgbédè” là ń pè wọ́n (lédè Gíríìkì, barʹba·ros).c Ṣùgbọ́n àwọn ará Màlítà kì í ṣe òǹrorò èèyàn. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Lúùkù, tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù, ròyìn pé wọ́n “fi àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá ènìyàn hàn sí wa, nítorí wọ́n dá iná, wọ́n sì gba gbogbo wa pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ nítorí òjò tí ń rọ̀ àti nítorí òtútù.” Pọ́ọ̀lù alára dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Màlítà bí wọ́n ti ń wá igi ìdáná, tí wọ́n sì ń kó igi sínú iná.—Ìṣe 28:1-3, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References.
Lójijì, ni paramọ́lẹ̀ kan wé ara rẹ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́! Àwọn ará erékùṣù náà bẹ̀rẹ̀ sí rò pé apààyàn ni Pọ́ọ̀lù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ èrò wọn ni pé Ọlọ́run máa ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nípa títa jàǹbá fún ẹ̀yà ara wọn tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀ náà gan-an. Ṣùgbọ́n, ẹ wo nǹkan! Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ará àdúgbò náà pé, Pọ́ọ̀lù gbọn paramọ́lẹ̀ náà dànù sínú iná. Gẹ́gẹ́ bí Lúùkù ẹni tó fojú rí ohun tó ṣẹlẹ̀ ti sọ, “wọ́n ń fojú sọ́nà pé wíwú ni ara [Pọ́ọ̀lù] yóò wú bèǹbè tàbí kí ó sì ṣubú lulẹ̀ kú lójijì.” Làwọn ará erékùṣù náà bá yí èrò wọn padà, ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé Pọ́ọ̀lù ní láti jẹ́ ọlọ́run kan.—Ìṣe 28:3-6.
Pọ́ọ̀lù lo oṣù mẹ́ta tó tẹ̀ lé e ní Màlítà, àkókò yìí ló wá wo baba Púbílọ́sì sàn, ẹni tó jẹ́ baálẹ̀ erékùṣù náà, tí ó gba Pọ́ọ̀lù tọwọ́tẹsẹ̀, Pọ́ọ̀lù tún wo àwọn mìíràn tí oríṣiríṣi àmódi kọ lù sàn pẹ̀lú. Láfikún sí i, Pọ́ọ̀lù gbin irúgbìn òtítọ́, tó yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún fún àwọn olùgbé Màlítà, tí wọ́n ní aájò àlejò.—Ìṣe 28:7-11.
Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́
Lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù, ó dojú kọ ọ̀pọ̀ ìpèníjà. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Nínú àkọsílẹ̀ tó wà lókè yìí, ó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nítorí ìhìn rere. Lẹ́yìn náà, ó ní láti dojú kọ àwọn àdánwò tí kò retí: ìjì líle àti ọkọ̀ rírì tó tẹ̀ lé e. Nínú gbogbo èyí, ìpinnu Pọ́ọ̀lù kò mì láti jẹ́ ẹni tí ń fi ìtara wàásù ìhìn rere náà. Láti inú ìrírí, ó kọ̀wé pé: “Nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní. Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:12, 13.
A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìṣòro ayé mi ìpinnu tí a ti ṣe pé a fẹ́ jẹ́ òjíṣẹ́ onítara fún Ọlọ́run tòótọ́ náà láé! Báwọn àdánwò tí a kò retí bá dé, ẹ jẹ́ ká ju ẹrù wa sọ́dọ̀ Jèhófà. (Sáàmù 55:22) Nígbà náà, ká wá ní sùúrù láti rí bí yóò ṣe mú kó ṣeé ṣe fún wa láti fara da ìdánwò náà. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó ní fífi tòótọ́tòótọ́ sìn ín, ká sì nígbọkànlé pé ó bìkítà fún wa. (1 Kọ́ríńtì 10:13; 1 Pétérù 5:7) Báa bá jẹ́ adúróṣinṣin, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, a óò borí ìpọ́njú wa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A sábà máa ń fojú wo ìgbọ̀nká kan gẹ́gẹ́ bí ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, tàbí nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà.
b Ọkọ̀ ìgbájá jẹ́ ọkọ̀ ojú omi kékeré táa lè fi dé èbúté nígbà tí a bá dá ọkọ̀ òkun ró sí ibi tí kò jìnnà sí etíkun. Ó ṣe kedere pé, ṣe ni àwọn atukọ̀ náà fẹ́ gba ẹ̀mí ara wọn là, kí wọ́n sì fi ẹ̀mí àwọn tí wọn yóò fi sílẹ̀ wewu, àwọn tí kò mọ nǹkan kan nípa bí a ṣe lè tukọ̀.
c Ìwé tí Wilfred Funk ṣe, tó pè ní Word Origins sọ pé: “Yẹ̀yẹ́ làwọn Gíríìkì máa ń fi àwọn tí kì í bá sọ èdè tiwọn ṣe, wọ́n a máa sọ pé èdè wọn ń dún bí ‘bá-bá’ wọ́n a sì máa pe ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ èdè náà ní barbaros.”