ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/1 ojú ìwé 28-29
  • Ọlọ́run Ha Ń Ṣe Nǹkan Lọ́nà “Wíwọ́” Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Ha Ń Ṣe Nǹkan Lọ́nà “Wíwọ́” Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àkókò Àtimú Nǹkan Tọ́
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Bí Ìṣòro Jíjẹ́ Aláàbọ̀ Ara Kò Ṣe Ní Sí Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
    “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
  • Ọlọ́run Bìkítà fún Ọ Lóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/1 ojú ìwé 28-29

Ọlọ́run Ha Ń Ṣe Nǹkan Lọ́nà “Wíwọ́” Bí?

“DEUS ESCREVE CERTO POR LINHAS TORTAS” (“Ọ̀NÀ WÍWỌ́ NI Ọlọ́run fi n kọ̀wé títọ́) jẹ́ àṣàyàn ọ̀rọ̀ nílẹ̀ Brazil. Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé Ọlọ́run sábà máa ń ṣe ohun tó tọ́ ṣùgbọ́n nígbà mìíràn ó máa ń jẹ́ ohun tó wọ́ lójú èèyàn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí géńdé kan bá ṣàdédé kú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè sọ pé, ‘Ọlọ́run ló pè é lọ sọ́run.’ Bí ẹnì kan bá sì jẹ́ aláàbọ̀ ara tàbí tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ ṣẹlẹ̀ sí i, àwọn kan á ní, ‘Àmúwá Ọlọ́run ni.’ Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run làwọn èèyàn ń dá lẹ́bi fún ikú, àwọn ìṣòro nípa ti ara, àti àwọn nǹkan mìíràn tí ń fa ìbànújẹ́, ohun tí irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ ń sọ ni pé Ọlọ́run ‘ń kọ̀wé lọ́nà wíwọ́,’ pé ó ń ṣe nǹkan lọ́nà tí ènìyàn kò lè lóye.

Èé ṣe tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ló gbà gbọ́ pé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ikú àti ìnira ti ń wá? Àwọn ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ni wọ́n gbé ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan pàtó tí wọ́n ṣì lóye. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ nínú wọn yẹ̀ wò.

● ”Ta ní yan ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ tàbí adití tàbí ẹni tí ó ríran kedere tàbí afọ́jú? Èmi Jèhófà ha kọ́ ni?”—Ẹ́kísódù 4:11.

Èyí ha túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ló lẹ̀bi gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara bí? Rárá o. Èyí kò ní bá àkópọ̀ ìwà Ọlọ́run mu. Bíbélì sọ fún wa pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run ni ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” (1 Tímótì 4:4) Òun kọ́ ló yẹ ká dá lẹ́bi bí a bá bí ẹnì kan láfọ́jú, odi, tàbí adití. Ohun tó dára ló ń fẹ́ fún ìṣẹ̀dá rẹ̀, nítorí òun ni Orísun “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.”—Jákọ́bù 1:17.

Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, tí wọ́n fúnra wọn yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì pàdánù ìjẹ́pípé àti agbára tí wọ́n ní láti mú ọmọ pípé jáde ló jẹ̀bi. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 16, 19; Jóòbù 14:4) Bí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ti ń ṣègbéyàwó, tí wọ́n ń bímọ, bẹ́ẹ̀ ni àìpé ń gorí àìpé, tí àlèébù ara sì ń pọ̀ sí i láàárín àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run ló fà á, ṣùgbọ́n ó yọ̀ǹda pé kó ṣẹlẹ̀. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tó fi lè sọ nípa ara rẹ̀ pé ‘òun ló yan’ ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, adití, àti afọ́jú.

● ”Èyí tí a ṣe ní wíwọ́ ni a kò lè mú tọ́.”—Oníwàásù 1:15.

Ṣé Ọlọ́run ló ṣe nǹkan ní wíwọ́ ni? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Oníwàásù 7:29 sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ ṣe aráyé ní adúróṣánṣán, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwéwèé.” Ìtumọ̀ ti Contemporary English Version tún ẹsẹ yìí sọ lédè mìíràn, ó ní: “A jẹ́ aláìlábòsí pátápátá nígbà tí Ọlọ́run dá wa, ṣùgbọ́n ní báyìí èrò inú wa ti dìdàkudà.” Kàkà tí a óò fi tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo ti Ọlọ́run, àwọn tó pọ̀ jù lọ, lọ́kùnrin lóbìnrin ti yàn láti tẹ̀ lé ìwéwèé ara wọn, ète, ọgbọ́n, tàbí àwọn ọ̀nà ara wọn—wọ́n sì ń pa ara wọn lára.—1 Tímótì 2:14.

Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ ọ́, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé, “a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo.” (Róòmù 8:20) Ìsapá ènìyàn kò sì lè sọ ipò yìí di ‘títọ́.’ Àfi tí Ọlọ́run bá dá sí i ni gbogbo ìwà wíwọ́ àti ìmúlẹ̀mófo tó wà nínú àlámọ̀rí ènìyàn tó lè kúrò.

● ”Wo iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, nítorí pé ta ní lè mú ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́ tọ́?”—Oníwàásù 7:13.

Lédè mìíràn, Ọba Sólómọ́nì ń béèrè pé: ‘Ta ni nínú aráyé tó lè mú àlèébù àti àìpé tí Ọlọ́run yọ̀ǹda tọ́?’ Kò sí ẹní tó lè ṣe é, nítorí ìdí kan wà tí Jèhófà Ọlọ́run fi fàyè gba kí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣẹlẹ̀.

Nítorí náà, Sólómọ́nì gbani níyànjú pé: “Ní ọjọ́ rere, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn, àti ní ọjọ́ oníyọnu àjálù, rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe èyí pàápàá gẹ́lẹ́ bí èyíinì, fún ète pé kí aráyé má bàa ṣàwárí ohunkóhun rárá lẹ́yìn wọn.” (Oníwàásù 7:14) Ó yẹ kí èèyàn máa mọrírì ọjọ́ tí nǹkan bá ṣẹnuure, kí ó sì fi ìmọrírì hàn nípa ríronú lórí ohun rere. Ó yẹ kí ó gbà pé Ọlọ́run ni ó fi ọjọ́ rere ta wá lọ́rẹ. Ṣùgbọ́n bí ọjọ́ náà bá lọ mú ìyọnu wá ńkọ́? Ó dáa kí èèyàn “rí i” pé, tàbí lédè mìíràn kó gbà pé, Ọlọ́run yọ̀ǹda kí ìyọnu náà ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Èé ṣe tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Sólómọ́nì sọ pé: “Fún ète pé kí aráyé má bàa ṣàwárí ohunkóhun rárá lẹ́yìn wọn.” Kí lèyí túmọ̀ sí?

Òtítọ́ náà pé Ọlọ́run ń yọ̀ǹda kí a dojú kọ ayọ̀ àti wàhálà ń rán wa létí pé a kò lè sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la. Bó ṣe jẹ́ pé ìyọnu lè dé bá olódodo, bẹ́ẹ̀ náà ló lè dé bá èèyàn burúkú. Kò sẹ́ni tí kò lè dé bá. Ó yẹ kéyìí mú wa mọ ìjẹ́pàtàkì pé kí a má máa gbára lé ara wa, àmọ́ kí a gbára lé Ọlọ́run, kí a rántí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun kan pàtó ń bẹ tí a kò lè lóye nísinsìnyí, a lè ní ìdánilójú pé lẹ́yìn tí gbogbo ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀, ohun tí Ọlọ́run yọ̀ǹda yóò jẹ́ fún ète tó ṣàǹfààní fún gbogbo àwọn tí ọ̀ràn náà kàn.

Ohunkóhun tó bá yọ̀ǹda kò ní fa ìbànújẹ́ ayérayé fún àwọn ọlọ́kàn títọ́. Àpọ́sítélì Pétérù mú kí èyí ṣe kedere nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìjìyà tó dé bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tí ó pè yín sí ògo àìnípẹ̀kun rẹ̀ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, yóò fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ yín di alágbára.”—1 Pétérù 5:10.

Àkókò Àtimú Nǹkan Tọ́

Jèhófà ń fún wa lókun láti fara da àdánwò wa ìsinsìnyí. Ó tún ṣèlérí láti sọ “ohun gbogbo di tuntun.” (Ìṣípayá 21:5) Bẹ́ẹ̀ ni, ète rẹ̀ ni pé kí Ìjọba rẹ̀ ọ̀run mú ìlera pípé padà wá láìpẹ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara, kí ó sì ṣàbójútó jíjí àwọn òkú dìde. Ìjọba yẹn pẹ̀lú yóò mú ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́ kúrò—Sátánì Èṣù. (Jòhánù 5:28, 29; Róòmù 16:20; 1 Kọ́ríńtì 15:26; 2 Pétérù 3:13) Ẹ wo irú ìbùkún tí yóò jẹ́ fún àwọn tí wọ́n wà káàkiri àgbáyé, tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run láti mú àwọn nǹkan tọ́!

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

Jóòbù Ń Gbọ́ Ìròyìn Àjálù Tó Dé Bá A/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́