ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 7/1 ojú ìwé 4-7
  • Ọlọ́run Bìkítà fún Ọ Lóòótọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Bìkítà fún Ọ Lóòótọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Nípasẹ̀ Rẹ̀ Ni Àwa Ní Ìwàláàyè”
  • Ṣé Ẹ̀bi Ọlọ́run Ni?
  • Ohun Tó Fa Ìṣòro Náà Gan-an
  • Ẹ̀rí Tó Lágbára Jù Lọ́ Pé Ọlọ́run Bìkítà fún Wa
  • “Sún Mọ́ Ọlọ́run”
  • Jésù Ń gbani Là—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Jìyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 7/1 ojú ìwé 4-7

Ọlọ́run Bìkítà fún Ọ Lóòótọ́

Ó JẸ́ ìwà ẹ̀dá láti ké pe Ọlọ́run nígbà tá a bá bára wa nínú ìṣòro tó le. Ó ṣe tán, Ọlọ́run “tóbi, ó sì pọ̀ yanturu ní agbára; òye rẹ̀ ré kọjá ríròyìn lẹ́sẹẹsẹ.” (Sáàmù 147:5) Òun nìkan ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro wa. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ fún wa pé ká ‘tú ọkàn-àyà wa jáde’ níwájú rẹ̀. (Sáàmù 62:8) Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi lérò pé Ọlọ́run ò dáhùn àdúrà wọn? Ṣé ó túmọ̀ sí pé kò bìkítà fún wa ni?

Dípò tí wàá fi yára dá Ọlọ́run lẹ́bi pé kì í dá sí ọ̀rọ̀ wa, rántí ìgbà tó o wà lọ́mọdé. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ ò bá gbà láti ṣe gbogbo nǹkan tó o ní kí wọ́n ṣe fún ọ, ǹjẹ́ o máa ń fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọn ò fẹ́ràn rẹ? Ọ̀pọ̀ ọmọ ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣá o. Àmọ́, nígbà tó o dàgbà, o wá rí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà lèèyàn lè gbà fi ìfẹ́ hàn àti pé táwọn òbí bá ń ṣe gbogbo nǹkan táwọn ọmọ fẹ́, ìfẹ́ kọ́ nìyẹn.

Bákan náà, tí Jèhófà ò bá dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́ ní gbogbo ìgbà, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò fẹ́ dá sí ọ̀ràn wa. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, oríṣiríṣi ọ̀nà ni Ọlọ́run máa ń gbà fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo wa.

“Nípasẹ̀ Rẹ̀ Ni Àwa Ní Ìwàláàyè”

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Ọlọ́run ló fún wa “ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Ẹ ò ri pé fífún tí Ọlọ́run fún wa ní ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́!

Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún fún wa ní àwọn nǹkan tá a nílò ká lè máa wà láàyè nìṣó. A kà á pé: “Ó ń mú kí koríko tútù rú jáde fún àwọn ẹranko, àti ewéko fún ìlò aráyé, láti mú kí oúnjẹ jáde wá láti inú ilẹ̀.” (Sáàmù 104:14) Ní tòótọ́, Ẹlẹ́dàá ò kàn wúlẹ̀ pèsè àwọn ohun kòṣeémáàní nìkan. Ó fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ pèsè “òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà [wa] dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 14:17.

Síbẹ̀, àwọn kan lè máa sọ pé, ‘Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ní Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀, kí nìdí tó fi jẹ́ ká máa jìyà?’ Ǹjẹ́ o mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí?

Ṣé Ẹ̀bi Ọlọ́run Ni?

Ọ̀pọ̀ lára ìyà tó ń jẹ aráyé ló jẹ́ àfọwọ́fà. Bí àpẹẹrẹ, kò sẹ́ni tí ò mọ ewu tó wà nídìí àwọn ìwà kan tó lè tètè fa jàǹbá fúnni. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò jáwọ́ nínú ìṣekúṣe, ọtí àmujù àti lílo oògùn nílòkulò, tábà mímu, eré ìdárayá tó léwu, fífi mọ́tò sá eré àsápajúdé àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Tí irú àwọn ìwà eléwu yìí bá yọrí sí àgbákò, ẹ̀bi ta ni? Ṣé ẹ̀bi Ọlọ́run ni àbí ẹ̀bi ẹni tó hu irú ìwà játijàti bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”—Gálátíà 6:7.

Yàtọ̀ sí ìṣòro táwọn èèyàn ń fi ọwọ́ ara wọn fà, àwọn èèyàn tún máa ń ṣe ọmọnìkejì wọn léṣe. Nígbà tí orílẹ̀-èdè kan bá dá ogun sílẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run kọ́ ló máa ru ẹ̀bi ìṣòro tó bá ti ẹ̀yìn ogun náà jáde. Tí ọ̀daràn kan bá gbéjà ko ọmọnìkejì rẹ̀, tí onítọ̀hún sì ṣèṣe tàbí tó kú, ṣé ẹ̀bi Ọlọ́run ni? Ẹ̀bi rẹ̀ kọ́ o! Tí àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ bá ń ṣe àwọn tó wà lábẹ́ wọn bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú, tí wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n tiẹ̀ pa wọn, ǹjẹ́ ó yẹ ká dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí ìyẹn? Kò ní bọ́gbọ́n mu rárá láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Oníwàásù 8:9.

Àmọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó jẹ́ tálákà paraku tàbí tí ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wọn ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run ló ni ẹ̀bi ìyẹn náà ni? Rárá o. Oúnjẹ tó ń hù lórí ilẹ̀ ayé wa yìí tóó bọ́ gbogbo èèyàn ní àbọ́yó. (Sáàmù 10:2, 3; 145:16) Ṣíṣàì pín ọ̀pọ̀ yanturu àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti pèsè bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ ló fà á tí ebi àti ipò òṣì fi gbòde kan. Ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tí àwọn èèyàn ní ni kò sì jẹ́ kí ìṣòro náà yanjú.

Ohun Tó Fa Ìṣòro Náà Gan-an

Àmọ́, ta ni ká dá lẹ́bi nígbà tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn, tàbí tẹ́nì kan bá kú nítorí ọjọ́ ogbó? Ǹjẹ́ ó máa yà ọ́ lẹ́nu tá a bá sọ pé kì í ṣe ẹ̀bi Ọlọ́run? Ọlọ́run ò dá èèyàn láti darúgbó, kó sì kú o.

Nígbà tí Jèhófà fi èèyàn méjì àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, sínú ọgbà Édẹ́nì, ó fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n, ó ṣe kedere pé àwọn tó mọyì ohun tá a fún wọn ni Ọlọ́run fẹ́ kó kún orí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, Ọlọ́run sọ pé kìkì ìgbà tí Ádámù àti Éfà bá ń ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́ nìkan ni wọ́n tó lè máa gbé inú Párádísè náà nìṣó.—Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:2, 3, 17-23.

Ó mà ṣe o, Ádámù àti Éfà di ọlọ̀tẹ̀. Éfà gba ọ̀rọ̀ Sátánì Èṣù gbọ́. Sátánì parọ́ fún Éfà, ó ní Ọlọ́run ò fẹ́ nǹkan tó dáa fún un. Nítorí náà, Éfà bẹ̀rẹ̀ sí í dá nǹkan ṣe láyè ara rẹ̀, ó fẹ́ “dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Ádámù náà di ọlọ̀tẹ̀ bíi ti Éfà.—Jẹ́nẹ́sísì 3:5, 6.

Nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ lọ́nà yìí, ńṣe ni wọ́n fi hàn pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó máa wà láàyè títí láé. Wọ́n jìyà nǹkan búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yọrí sí. Okun àti agbára tí wọ́n ní wá bẹ̀rẹ̀ sí dín kù, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n kú. (Jẹ́nẹ́sísì 5:5) Àmọ́ o, nǹkan tí ọ̀tẹ̀ wọn dá sílẹ̀ jù gbogbo ìyẹn lọ. Ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà la ṣì ń jìyà rẹ̀ títí dòní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí ọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn bí àjàkálẹ̀ àrùn.

Ẹ̀rí Tó Lágbára Jù Lọ́ Pé Ọlọ́run Bìkítà fún Wa

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan fún ẹ̀dá ènìyàn tí Ọlọ́run dá ni? Rárá o, èyí ló mú wa dórí ẹ̀rí tó lágbára jù lọ tó fi hàn pé Ọlọ́run bìkítà fún wa. Kì í ṣe nǹkan kékeré ló ná Ọlọ́run láti ṣètò bí a ó ṣe ra aráyé padà látinú oko ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ohun tó ná an láti rà wá padà ni ìwàláàyè pípé tí Jésù fi lélẹ̀ tinútinú ní tìtorí wa. (Róòmù 3:24) Abájọ tí àpọ́sítélì Jòhánù fi kọ̀wé pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ọ̀nà tó tayọ tó gbà fi ìfẹ́ hàn yìí ló jẹ́ ká lè padà ní àǹfààní àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Róòmù pé: “Nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.”—Róòmù 5:18.

Ó dá wa lójú pé nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, ìyà tàbí ikú yóò di ohun àtijọ́ lórí ilẹ̀ ayé yìí. Dípò ìyẹn, bí ìwé Ìṣípayá ṣe sọ pé ayé yìí yóò rí ló ṣe máa rí, ó ní: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) O lè máa sọ pé, ‘Màá ti kú kó tó dìgbà yẹn.’ Òótọ́ ibẹ̀ sì ni pé ìyẹn lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́, bó o tiẹ̀ kú, Ọlọ́run lè jí ọ dídé látinú ikú. (Jòhánù 5:28, 29) Ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun fẹ́ ṣe fún wa nìyẹn, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí. Ẹ ò ri pé irọ́ gbuu làwọn tó ń sọ pé Ọlọ́run ò bìkítà fún aráyé ń pa!

“Sún Mọ́ Ọlọ́run”

Ó ń tuni nínú láti mọ̀ pé Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ ètò kan láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé. Àmọ́, ìṣòro ti ìsinsìnyí ńkọ́? Kí lohun tá a lè ṣe nígbà téèyàn wa bá kú tàbí tí àìsàn dá ọmọ wa gúnlẹ̀? Lóòótọ́, kò tíì tó àkókò lójú Ọlọ́run láti mú àìsàn àti ikú kúrò. Bíbélì fi yé wa pé a ṣì ní láti dúró fúngbà díẹ̀ ná kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe pé Ọlọ́run gbàgbé wa o. Ọmọ ẹ̀yìn Jésù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ẹlẹ́dàá sọ pé ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun, àwọn tó bá sì sún mọ́ ọn kò ní yéé rí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ àní lákòókò tí nǹkan le koko fún wọn pàápàá.

Báwo la ṣe lè sún mọ́ Ẹlẹ́dàá? Dáfídì Ọba béèrè irú ìbéèrè yẹn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, ó ní: “Jèhófà, . . . ta ni yóò máa gbé ní òkè ńlá mímọ́ rẹ?” (Sáàmù 15:1) Dáfídì fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè náà nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́. Kò ṣe ohun búburú kankan sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 15:2, 3) Ohun tá à ń sọ ni pé, tọwọ́tẹsẹ̀ ni Jèhófà tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n bá kọ ọ̀nà tí Ádámù àti Éfà tọ̀ sílẹ̀. Ó ń sún mọ́ àwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Diutarónómì 6:24, 25; 1 Jòhánù 5:3.

Báwo lá ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? A ní láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó “dára lọ́pọ̀lọpọ̀, [tó] sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Olùgbàlà wa, Ọlọ́run,” lẹ́yìn náà ká wá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ohun tá a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣèwà hù. (1 Tímótì 2:3) Ìyẹn kan gbígba ìmọ̀ pípéye tí ń bẹ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú. (Jòhánù 17:3; 2 Tímótì 3:16, 17) Èyí ju pé ká kàn máa ka Bíbélì lóréfèé lọ. A ní láti máa fara wé àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní tó wà ní Bèróà, tí wọ́n gbọ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù. A kà nípa wọn pé: “Wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:11.

Bákan náà lónìí, fífara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (Hébérù 11:6) Ó tún ń mú ká lóye ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá aráyé lò, pé kì í kàn án ṣe kó lè ṣe wọ́n láǹfààní fúngbà díẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ní pàtàkì kó lè ṣe gbogbo àwọn tó bá ní ọkàn rere láǹfààní fún àkókò tí ó lọ kánrin.

Wo ohun tí díẹ̀ lára àwọn Kristẹni tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run sọ. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Danielle sọ pé: “Mó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an ni, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó fún mi láwọn òbí onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n fẹ́ràn mí tí wọ́n sì fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ mi.” Kristẹni kan ní Uruguay kọ̀wé pé: “Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ àti fún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Inú Ọlọ́run máa ń dùn sí àwọn ògo wẹẹrẹ pẹ̀lú. Ọmọ ọdún méje kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gabriela sọ pé: “Nínú gbogbo ohun tó wà láyé yìí, Ọlọ́run ni mo fẹ́ràn jù! Mo ní Bíbélì tèmi. Mo fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.”

Lónìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé ló fara mọ́ ọ̀rọ̀ onísáàmù náà tó sọ pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” (Sáàmù 73:28) A ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n bójú tó ìṣòro tí wọ́n ń dójú kọ nísinsìnyí, wọ́n sì nírètí tó dájú pé àwọn yóò gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé títí láé. (1 Tímótì 4:8) O ò ṣe pinnu láti “sún mọ́ Ọlọ́run”? Ní tòótọ́, ó mú un dá wa lójú pé: “[Òun] kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run bìkítà fún wa lóòótọ́!

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà gbà fi hàn pé ire wa jẹ òun lọ́kàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kódà àwọn ògo wẹẹrẹ pàápàá lè sún mọ́ Ọlọ́run

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Lónìí, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro. Nígbà tí àkókò bá sì tó ní ojú rẹ̀, yóò mú àìsàn àti ikú kúrò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́