ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 7/1 ojú ìwé 3
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Ìṣòro Wa Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Ìṣòro Wa Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Dán Jèhófà Wò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ọlọ́run Bìkítà fún Ọ Lóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Iwọ Ha Ń Dáríjini Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 7/1 ojú ìwé 3

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Ìṣòro Wa Ni?

NÍGBÀ tí jàǹbá ṣe ọpọlọ ọmọ Marion kan tó ti di ọmọge, ohun tí ọ̀pọ̀ nínú wa yóò ṣe tó bá jẹ́ pé àwa ló ṣẹlẹ̀ sí ni Marion ṣe.a Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́. Marion sọ pé, “Nǹkan ò tíì pin mí lẹ́mìí tó bẹ́ẹ̀ ri, mi ò sì tíì wá ìrànlọ́wọ́ tì bí irú èyí rí láyé mi.” Nígbà tó yá, nǹkan tó ń ṣe ọmọge náà túbọ̀ burú sí i, Marion wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa Ọlọ́run. Ó ń béèrè pé, “Kí ló fà á tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ ná?” Obìnrin náà ò mọ ìdí tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tó ń bìkítà nípa èèyàn fi lè pa òun tì.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Marion kì í ṣe tuntun. Àìmọye èèyàn jákèjádò ayé ló máa ń rò pé Ọlọ́run ti kọ àwọn lákòókò ìṣòro. Lẹ́yìn tí wọ́n pa ọmọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọmọ Lisa, ó sọ pé: “Àwọn ìbéèrè kan wà tó ṣì máa ń rú mi lójú, irú bíi ‘kí nìdí tí ỌLỌ́RUN fi ń jẹ́ kéèyàn rí láburú.’ Lóòótọ́, mo ṣì gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ ìgbàgbọ́ mi ò lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.” Bákan náà, lẹ́yìn tí jàǹbá kan ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ọwọ́ obìnrin kan, obìnrin náà sọ pé: “Ọlọ́run ò tiẹ̀ tù mí nínú rárá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Mi ò rí àmì kankan pé ó bìkítà nípa mi tàbí pé ó láàánú mi.” Ó wá fi kún un pé: “Mi ò lè dárí ji Ọlọ́run láé.”

Nígbà táwọn mìíràn bá wo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wọn, ńṣe ni inú Ọlọ́run máa ń bí wọn burúkú-burúkú. Wọ́n ń rí àwọn tí ipò òṣì ń hàn léèmọ̀, àwọn tí ebi ń pa, àwọn tí ogun tí lé kúrò nílé tí wọn ò tiẹ̀ mọ ọ̀nà àbáyọ, àìmọye ọmọ tí àrùn éèdì tí gbẹ̀mí àwọn òbí wọn àti ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí àwọn àìsàn mìíràn ń ṣe. Nígbà táwọn nǹkan wọ̀nyí àti irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ bá wáyé, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń dẹ́bi fún Ọlọ́run pé kò tiẹ̀ dá sí ọ̀ràn náà.

Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé kì í ṣe ẹ̀bi Ọlọ́run rárá pé gbogbo àwọn ìṣòro wọ̀nyí ń pọ́n aráyé lójú. Ká sòótọ́, àwọn ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ ká gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kò ní pẹ́ sọ ẹkún ìran èèyàn dayọ̀. A rọ̀ ẹ́ láti wo àpilẹ̀kọ tó kàn, wàá rí i pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà fún wa.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ wọn padà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́