Iwọ Ha Ń Dáríjini Bí?
BILL ati ọmọbìnrin rẹ, Lisa, ẹni ọdún 16, ní ìṣòro gbígbé papọ̀ ní ìrọwọ́rọsẹ̀. Awọn èdè-àìyedè tí kò tó nǹkan sábà máa ń di ìjà aláriwo láàárín wọn. Lákòótán, gbọ́nmi-síi-omi-ò-tó naa ga débi pé a sọ fún Lisa lati kó jáde kúrò nílé.a
Nígbà tí ó ṣe, Lisa wá mọ̀ pé ọwọ́ oun ni ẹ̀bi wà ó sì tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ṣugbọn dípò kí ó gbójúfo àṣìṣe Lisa àtẹ̀yìnwá, baba rẹ̀ tí ó ti mú inú bí kọ ìsapá rẹ lati parí ìjà naa. Ẹ ò rí nǹkan bí! Kò múratán lati nawọ́ àánú sí ọmọbìnrin tirẹ̀ alára!
Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ọkùnrin aláìlẹ́bi kan ni a dálẹ́bi ikú nitori ìwà-ìrúfin kan tí oun kò jẹ̀bi rẹ̀. Awọn ẹlẹ́rìí jẹ́rìí èké síi, awọn òṣìṣẹ́-olóyè olóṣèlú sì mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ lati lo ìdájọ́-òdodo. Jesu Kristi ni ọkùnrin aláìmọwọ́mẹsẹ̀ yẹn. Gẹ́rẹ́ ṣáájú ikú rẹ̀, ó fi tàdúrà-tàdúrà béèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé: “Baba, dáríjì wọn; nitori ti wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.”—Luku 23:34.
Jesu dáríjini ní fàlàlà, lati inú ọkàn-àyà rẹ̀, a sì rọ awọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lati ṣàfarawé rẹ̀ ninu èyí. (Efesu 4:32) Ṣugbọn, gẹ́gẹ́ bíi ti Bill, ọ̀pọ̀lọpọ̀ kìí múratán lati fi tàánú-tàánú dáríjini. Bawo ni iwọ ti ń ṣesí ninu èyí? Iwọ ha ń múratán lati dáríji awọn ẹlòmíràn nígbà tí wọn bá ṣẹ̀ ọ́ bí? Kí sì ni nipa ti awọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo? A ha níláti dárí iwọnyi pẹlu jini bí?
Ìdáríjini Ìpèníjà Kan
Dídáríjini kìí fìgbà gbogbo rọrùn. Ati pé ní awọn àkókò lílekoko wọnyi, ipò-ìbátan láàárín ènìyàn ti di èyí tí ó túbọ̀ ń ṣòro síi. Ìgbésí-ayé ìdílé ní pàtàkì sábà máa ń kún fún másùnmáwo ati ìkìmọ́lẹ̀. Kristian aposteli Paulu ti kọ̀wé nígbà pípẹ́ sẹ́yìn pé irú awọn ipò bẹ́ẹ̀ yoo gbilẹ̀ ní “ìkẹyìn ọjọ́.” Ó sọ pé: “Awọn ènìyàn yoo jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afúnnu, agbéraga, . . . aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga.”—2 Timoteu 3:1-4.
Nígbà naa, lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀sílẹ̀, gbogbo wa dojúkọ awọn ìkìmọ́lẹ̀ ẹ̀yìn òde tí ń dán agbára wa wò lati dáríji awọn ẹlòmíràn. Ní àfikún síi, a tún ń bá awọn ìkìmọ́lẹ̀ ti inú wa lọ́hùn-ún jìjàkadì. Paulu kédàárò pé: “Nitori ire tí emi fẹ́ emi kò ṣe: ṣugbọn búburú tí emi kò fẹ́, èyíinì ni emi ń ṣe. Ṣugbọn bí ó bá ṣepé ohun ti emi kò fẹ́, èyíinì ni emi ń ṣe, emi kí ń ṣe é mọ́, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mí.” (Romu 7:19, 20) Nitori ìdí èyí, ọ̀pọ̀ ninu wa kìí dáríjini tó bí a ti ń fẹ́ lati ṣe. Ó ṣetán, àìpé ati ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogún ń lo agbára ìdarí lílágbára lórí gbogbo wa, ó sì máa ń já wá lólè ìyọ́nú fún ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa.
Obìnrin kan fèsì nígbà tí a gbà á níyànjú lati dáríji ẹlòmíràn nitori ẹ̀ṣẹ̀ kékeré kan pé: “Kò sí ẹni tí ó kájú òṣùwọ̀n ìsapá tí ń bèèrè lati dáríjini.” Lóréfèé, irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ lè dàbí èyí tí ó jẹ́ aláìníyọ̀ọ́nú, aláìláàánú, àní ti òṣónú pàápàá. Ṣugbọn, ní wíwò ó jinlẹ̀, a rí i pé ó fi ìjákulẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ń nímọ̀lára rẹ̀ hàn nígbà tí wọn bá dojúkọ ayé kan tí wọn kà sí onímọtara-ẹni-nìkan, aláìbìkítà, ati akóguntini. Ọkùnrin kan wí pé: “Awọn ènìyàn máa ń fi ọ̀bọ lọni bí a bá dáríjì wọn. Ṣe ni ó dàbí títẹni mọ́lẹ̀.”
Abájọ nígbà naa, tí mímú ìwà ìdáríjini dàgbà fi ṣòro ní awọn ọjọ́ ìkẹyìn wọnyi. Síbẹ̀, Bibeli gbà wá níyànjú lati fi inúrere dáríjini. (Fiwé 2 Korinti 2:7.) Èéṣe tí a fi níláti máa dáríjini?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí awọn orúkọ naa padà.