ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/15 ojú ìwé 4-7
  • Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi Wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi Wà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ló Fa Ìwà Ibi?
  • Sátánì Dá Ọ̀ràn Pàtàkì Kan Sílẹ̀
  • Ó Máa Gba Àkókò Kí Ọ̀ràn Náà Tó Lè Yanjú
  • Kí Lohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láti Àkókò Tó Ti Kọjá Fi Hàn?
  • Kí Ni Wàá Ṣe?
  • Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìjìyà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn—Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègbà Á?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Tá A sì Ń Jìyà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?
    Jí!—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/15 ojú ìwé 4-7

Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi Wà

BÍBÉLÌ sọ pé: “Olódodo ni Jèhófà [Ọlọ́run] ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Sáàmù 145:17; Ìṣípayá 15:3) Bákan náà, wòlíì Mósè sọ nípa Jèhófà pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Jákọ́bù 5:11 náà tún sọ pé: “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” Dájúdájú, Ọlọ́run kọ́ ló fa ìwà ibi. Kò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Jèhófà Ọlọ́run kì í fi ohun búburú dán ẹnikẹ́ni wò, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í tanni hùwà ibi. Ta ló wá fa ìwà ibi àti gbogbo ìpọ́njú tó yọrí sí?

Ta Ló Fa Ìwà Ibi?

Jákọ́bù tó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé inú Bíbélì sọ pé ẹ̀dá èèyàn wà lára ohun tó ń fa ìwà ibi tó wà láyé. Ó ní: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Èyí fi hàn pé ohun kan tó ń fa ìwà ibi ni pé àwọn èèyàn máa ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó wà lọ́kàn wọn. Ohun míì ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀dá èèyàn jogún. Ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn jogún yìí lágbára gan-an ni. Ó lè mú kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn èèyàn lágbára gan-an débi téèyàn á fi hùwàkiwà, èyí tó máa ń fa aburú. (Róòmù 7:21-23) Láìsí àní-àní, ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn jogún ti “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” lórí aráyé, ó ń mú káwọn èèyàn máa hùwà ibi, èyí tó ń fa ìpọ́njú bá aráyé. (Róòmù 5:21) Yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn jogún, àwọn oníwà ibi tún máa ń mú káwọn ẹlòmíì dà bí wọ́n ṣe dà.—Òwe 1:10-16.

Àmọ́, Sátánì Èṣù gan-an lẹni tó dá ìwà ibi sílẹ̀. Òun ló mú kí ìwà ibi wà láyé. Jésù Kristi pè é ní “ẹni burúkú náà” àti “olùṣàkóso ayé,” ìyẹn gbogbo èèyàn búburú lápapọ̀. Sátánì ni ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ aráyé ń ṣègbọràn sí. Wọ́n ń jẹ́ kó máa tì wọ́n ṣe ohun tí kò bá ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run mu. (Mátíù 6:13; Jòhánù 14:30; 1 Jòhánù 2:15-17) Jòhánù kìíní orí karùn-ún ẹsẹ kọkàndínlógún sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Dájúdájú, Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” èyí sì ń fa “ègbé,” ìyẹn ìpọ́njú tó ń bá aráyé. (Ìṣípayá 12:9, 12) Nítorí náà, Sátánì Èṣù ni olórí ẹni tó ń fa ìwà ibi tó wà láyé.

Oníwàásù 9:11 sọ ohun mìíràn tó ń fa ìpọ́njú bá àwa èèyàn, ó ní: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo [wa].” Bí àpẹẹrẹ, Jésù Kristi sọ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀, ó ní ilé gogoro kan wó pa èèyàn méjìdínlógún. (Lúùkù 13:4) Wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀ ló mú kí wọ́n kàgbákò. Wọ́n wulẹ̀ ṣe kòńgẹ́ rẹ̀ ni. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sì máa ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Bí àpẹẹrẹ, búlọ́ọ̀kù lè ré bọ́ látorí ilé kó sì pa ẹni tó ń kọjá lọ. Ṣé àmúwá Ọlọ́run ni? Rárá o. Ọlọ́run ò gbèrò àtiṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Bó ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí àìsàn bá kọ lu ìdílé kan tàbí nígbà tí ikú òjijì bá pa ẹnì kan tó sì sọ aya rẹ̀ di opó, táwọn ọmọ rẹ̀ náà si dọmọ aláìníbaba.

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìwà ibi, òun sì kọ́ ló fa ìpọ́njú tó ń bá ọmọ aráyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló pinnu láti mú ìwà ibi àtàwọn tó ń hù ú kúrò. (Òwe 2:22) Ó tiẹ̀ tún máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run ti pinnu láti tipasẹ̀ Kristi “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Ọlọ́run máa pa ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí run, ìyẹn ayé tó kún fún ìwọra, ìkórìíra àti ìwà ibi yìí. Kódà, Ọlọ́run á “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [gbogbo èèyàn],” bí gbogbo ìpọ́njú tó ń bá aráyé yóò ṣe dópin nìyẹn. (Ìṣípayá 21:4) Àmọ́ ó ṣeé ṣe kó o máa béèrè pé: ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run ò tíì ṣe bẹ́ẹ̀? Kí nìdí tó fi jẹ́ kí ìwà ibi àti ìpọ́njú wà títí di àkókò wa yìí?’ Ọ̀nà kan tá a lè gbà rí ìdáhùn ni pé ká gbé ìtàn Ádámù àti Éfà yẹ̀ wò nínú Bíbélì.

Sátánì Dá Ọ̀ràn Pàtàkì Kan Sílẹ̀

Ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi títí dòní olónìí ní í ṣe pẹ̀lú ohun kan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwọn èèyàn àkọ́kọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ náà mú kí ọ̀ràn pàtàkì kan jẹ yọ nípa Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Ọ̀ràn ọ̀hún ò rọrùn láti yanjú, kò sì gba ìkánjú. Ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀.

Jèhófà Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ́ ní pípé, ó sì fi wọ́n sínú Párádísè. Ó fún wọn ní nǹkan kan tó mú kí wọ́n yàtọ̀ sí ẹranko. Ohun náà sì ni òmìnira láti yan ohun to wù wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15, 19) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀dá onílàákàyè ni wọ́n tí wọ́n sì lè yan ohun tó wù wọ́n, wọ́n lè yàn láti nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn, láti sìn ín àti láti gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Wọ́n sì tún lè yàn láti kúrò lábẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí i.

Ọlọ́run tòótọ́ wá ṣe ohun tó máa mú kí Ádámù àti Éfà lè fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó ka nǹkan kan léèwọ̀ fún wọn. Ó pàṣẹ fún Ádámù pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Tí wọn ò bá fẹ́ pàdánù ojú rere Ọlọ́run, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi kan ṣoṣo yẹn. Ìyẹn ì bá sì ṣe àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn láǹfààní. Ǹjẹ́ wọ́n ṣègbọràn?

Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa. Ó ní Sátánì Èṣù gbẹnu ejò kan bá Éfà sọ̀rọ̀ pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Ni Éfà bá sọ àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún un. Sátánì wá sọ fún un pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ yìí mú kí igi náà dà bí èyí tó fani mọ́ra gan-an lójú Éfà débi pé ó “mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.” Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Bí Ádámù àti Éfà ṣe ṣi òmìnira tí wọ́n ní láti yan ohun tó wù wọ́n lò nìyẹn, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ o mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe burú tó? Ṣe ni Èṣù ta ko Ọlọ́run pé irọ́ lohun tó sọ fún Ádámù. Ó dọ́gbọ́n sọ pé kò pọn dandan kí Jèhófà máa tọ́ Ádámù àti Éfà sọ́nà kí wọ́n tó lè mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Nítorí náà, ńṣe ni Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ẹ̀dá èèyàn, àti pé kò bófin mu pé kó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ ni bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ tàbí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, èyí ló sì jẹ́ ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kí ni Ọlọ́run tòótọ́ ṣe láti yanjú ọ̀ràn pàtàkì yìí?

Ó Máa Gba Àkókò Kí Ọ̀ràn Náà Tó Lè Yanjú

Jèhófà lágbára láti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, ìyẹn Sátánì, Ádámù àti Éfà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dájúdájú, Ọlọ́run lágbára jù wọ́n lọ fíìfíì. Àmọ́ kì í ṣe pé Sátánì jiyàn bóyá Ọlọ́run lágbára tàbí kò ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Gbogbo ẹ̀dá tí wọ́n lómìnira láti yan ohun tó wù wọ́n, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì àtẹ̀dá èèyàn, lọ̀rọ̀ náà sì kàn. Ó yẹ kí wọ́n rí i pé àwọn gbọ́dọ̀ máa lo òmìnira tí Ọlọ́run fún wọn lọ́nà tó tọ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa lò ó lọ́nà tó bá àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nípa ìwà, ìṣe àti àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run mu. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n á kàgbákò. Ńṣe ló dà bí ẹni tí kò ka agbára òòfà ilẹ̀ sí, tó wá forí kunkun bẹ́ sílẹ̀ látorí ilé gíga fíofío. Á fara pa yánnayànna. (Gálátíà 6:7, 8) Gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì àtèèyàn, ló lè jàǹfààní tí wọ́n bá fojú ara wọn rí aburú tí yíyàn láti kúrò lábẹ́ Ọlọ́run fà. Ó sì máa gba àkókò kí wọ́n tó lè fúnra wọn rí èyí.

Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe kan ná láti fi hàn pé ó máa ń gba àkókò láti yanjú àwọn ọ̀ràn kan. Ká sọ pé baálé ilé kan pe baálé ilé míì níjà pé kó jẹ́ káwọn jọ díje láti mọ ẹni tó lágbára jù nínú àwọn méjèèjì, wọ́n lè yanjú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kíákíá. Kò ju pé káwọn méjèèjì gbé òkúta lọ. Ẹni tó bá gbé òkúta tó wúwo jù ló lágbára jù. Àmọ́ ká sọ pé ohun tẹ́ni náà sọ ni pé, nínú òun àti baálé ilé kejì, ta ló nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lóòótọ́ táwọn ọmọ rẹ̀ náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tàbí pé ta ló ń bójú tó ilé rẹ̀ lọ́nà tó dára jù nínú àwọn méjèèjì? Tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bá fi bó ṣe lágbára tó hàn tàbí tó kó àlàyé palẹ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́, ìyẹn ò lè yanjú ọ̀ràn náà. Kí ọ̀ràn náà tó lè yanjú, ó máa gba àkókò káwọn èèyàn lè fara balẹ̀ kíyè sí bí àwọn méjèèjì ṣe ń ṣe sí, kí wọ́n wá fúnra wọn sọ bàbá tó ń ṣe dáadáa jù nínú àwọn méjèèjì.

Kí Lohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láti Àkókò Tó Ti Kọjá Fi Hàn?

Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún báyìí tí Sátánì ti fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso. Kí wá làwọn nǹkan tó ti ń ṣẹlẹ̀ látìgbà náà fi hàn? Ó dáa, ẹ jẹ́ ká gbé kókó méjì yẹ̀ wò nínú ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Ọlọ́run. Àkọ́kọ́, Sátánì fi dá Éfà lójú pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4) Bí Sátánì ṣe sọ pé Ádámù àti Éfà ò ní kú tí wọ́n bá jẹ èso tí Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, ohun tó ń sọ ni pé òpùrọ́ ni Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ẹ̀sùn ńlá nìyẹn! Àbí, tó bá jẹ́ pé irọ́ ni Ọlọ́run pa lóòótọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run máa tún ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé mọ́? Àmọ́, kí làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tó ti kọjá fi hàn?

Ádámù àti Éfà dẹni tó ń ṣàìsàn, wọ́n ń ní ìrora, wọ́n darúgbó, wọ́n sì kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ọjọ́ Ádámù tí ó fi wà láàyè jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n, ó sì kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19; 5:5) Ikú tó jẹ́ nǹkan ìbànújẹ́ yìí sì lohun tí gbogbo ẹ̀dá èèyàn jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ti wá fi hàn pé Sátánì jẹ́ ‘òpùrọ́ àti baba irọ́,’ ó sì fi hàn pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́.”—Jòhánù 8:44; Sáàmù 31:5.

Sátánì tún sọ fún Éfà pé: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú [èso igi tóun kà léèwọ̀] ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin [Ádámù àti Éfà] yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:5) Ńṣe ni Sátánì lo ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí láti fi mú káwọn èèyàn rò pé èèyàn lè kúrò lábẹ́ Ọlọ́run kó wá máa ṣàkóso ara rẹ̀. Ó tún fi ọ̀rọ̀ yìí kan náà mú kí wọ́n máa rò pé nǹkan á túbọ̀ dáa fún aráyé tí wọ́n ò bá sí lábẹ́ àkóso Ọlọ́run. Ṣó ti wá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?

Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn tí Sátánì ti sọ̀rọ̀ yẹn, onírúurú orílẹ̀-èdè ti ṣàkóso ayé, wọ́n sì ti kúrò lójú ọpọ́n gẹ́gẹ́ bí agbára ayé. Àwọn èèyàn ti gbìyànjú onírúurú ètò ìjọba tí wọ́n hùmọ̀. Àmọ́ àjẹkún ìyà laráyé ń jẹ. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì wo sàkun gbogbo rẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, ó ní: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Wòlíì Jeremáyà pẹ̀lú kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àní àwọn ohun tí wọ́n ti gbé ṣe lágbo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí pàápàá ò lè já òótọ́ ọ̀rọ̀ táwọn òǹkọ̀wé Bíbélì yìí sọ ní koro. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ Bíbélì yìí.

Kí Ni Wàá Ṣe?

Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí Ọlọ́run yọ̀ǹda ti fi hàn pé irọ́ ni Sátánì pa nígbà tó sọ pé Jèhófà ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àní sẹ́, Jèhófà Ọlọ́run ni Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, kò sẹ́lòmíì. Ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni láti máa ṣàkóso lórí àwọn ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀, ìṣàkóso rẹ̀ ló sì dára jù. Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí lókè ọ̀run, tí wọ́n ti wà lábẹ́ àkóso Ọlọ́run fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún pàápàá gbà pé ìṣàkóso Ọlọ́run ló dára jù. Wọ́n ní: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”—Ìṣípayá 4:11.

Kí lèrò rẹ nípa ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀, pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso? Ǹjẹ́ o gbà pé ẹ̀tọ́ Ọlọ́run ni láti máa ṣàkóso rẹ? Tó o bá gbà bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Bó o ṣe lè ṣe èyí ni pé kó o máa fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti ìlànà tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò nínú ohun gbogbo. “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìfẹ́ tó ní fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀ ló mú kó fi òfin àti àṣẹ lélẹ̀ fún wọn. (1 Jòhánù 4:8) Jèhófà kì í fi ohun tó máa ṣe wá láǹfààní dù wá rárá. Nítorí náà, fọwọ́ pàtàkì mú ìmọ̀ràn tí Bíbélì gbani pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

O lè fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run lo fara mọ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti fífi ohun tó o bá kọ́ sílò

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

© Jeroen Oerlemans/Fọ́tò Panos

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́