Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi?
KÒ DÌGBÀ tó o bá wò jìnnà kó o tó rí i pé ìwà ibi àti ìpọ́njú pọ̀ láyé. Bí ogun ṣe ń pa ọmọ ogun, bẹ́ẹ̀ ló ń pa aráàlú. Ìwà ọ̀daràn àti ìwà abèṣe gbòde kan. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣe ẹ̀tanú sí ọ láìpẹ́ yìí tàbí kí wọ́n ti rẹ́ ọ jẹ. Àwọn ohun tó o ti rí àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ lè ti mú kó o béèrè pé: ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi?’
Ìbéèrè yẹn kì í ṣe tuntun. Ní nǹkan bí egbèjìdínlógún [3,600] ọdún sẹ́yìn, Jóòbù tó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run béèrè pé: “Èé ṣe tí àwọn ẹni burúkú fi ń wà láàyè nìṣó?” (Jóòbù 21:7) Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ náà ni wòlíì Jeremáyà béèrè ní ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ìwà ibi àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀ kó ìdààmú ọkàn bá a. Ó ní: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ọ̀nà àwọn ẹni burúkú ni ó kẹ́sẹ járí, pé gbogbo àwọn tí ó ń ṣe àdàkàdekè ni ó jẹ́ aláìní ìdààmú-ọkàn?” (Jeremáyà 12:1) Jóòbù àti Jeremáyà mọ̀ pé olódodo ni Ọlọ́run. Síbẹ̀, kàyéfì ṣe wọ́n nípa ìdí tí ìwà ibi fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Bóyá ìyẹn tiẹ̀ ti tojú sú ìwọ náà.
Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run ló fa ìwà ibi àti ojú tó ń pọ́n ọmọ aráyé. Àwọn míì ń ṣe kàyéfì pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló lágbára jù, tó jẹ́ olódodo, tó sì nífẹ̀ẹ́, kí ló dé tí ò fòpin sí ìwà ibi àti ìpọ́njú tó ń bá ọmọ aráyé? Kí nìdí tó fi jẹ́ kí ìwà ibi wà títí di ìsinsìnyí?’ Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì míì.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
AP Photo/Adam Butler