ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/15 ojú ìwé 8-10
  • Bó o Ṣe Lè Gbin Ìfẹ́ Ọlọ́run Sọ́kàn Ọmọ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó o Ṣe Lè Gbin Ìfẹ́ Ọlọ́run Sọ́kàn Ọmọ Rẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ọmọ àti Òbí Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Wọn
  • Àpẹẹrẹ Òbí Lágbára Púpọ̀
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọmọ Wa Lọ́wọ́ Láti Mọ Ọlọ́run
  • Tó Bá Dọ̀rọ̀ Yíyan Ọ̀rẹ́
  • Èrè Tó Wà Nínú Títọ́ Ọmọ
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/15 ojú ìwé 8-10

Bó o Ṣe Lè Gbin Ìfẹ́ Ọlọ́run Sọ́kàn Ọmọ Rẹ

KÌ Í rọrùn rárá lóde òní láti dẹni tó ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 16:8) Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-5) Ní tòdodo, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn ò wọ́pọ̀ lónìí.

Kò yẹ ká fi àwọn ọmọ wa sílẹ̀, ká máa rò pé ńṣe ni wọ́n á kàn ṣàdédé nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ gbin ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run sọ́kàn wọn. Báwo la ṣe lè ṣe é?

Kí Ọmọ àti Òbí Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Wọn

Ká tó lè gbin ìfẹ́ Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wa, ìfẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wà lọ́kàn àwa alára. (Lúùkù 6:40) Ohun tí Bíbélì ń jẹ́ ká mọ̀ nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ.”—Diutarónómì 6:4-7.

Báwo la ṣe lè gbin ìfẹ́ Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wa? Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa náà.

Nígbà tí Jésù Kristi ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjì rìn lọ lójú ọ̀nà Ẹ́máọ́sì, ṣe ló kọ́kọ́ bi wọ́n ní ìbéèrè tó mú kí wọ́n sọ ohun tó jẹ́ ìdààmú ọkàn wọn kó tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìgbà tó gbọ́rọ̀ wọn tán ló tó fi Ìwé Mímọ́ tọ́ èrò wọn sọ́nà. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sọ pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀?” Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ìjíròrò táwọn tó ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ ti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fúnra wọn. (Lúùkù 24:15-32) Báwo la ṣe lè fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ wa?

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a bi àwọn òbí kan táwọn ọmọ wọn ti ń tójú bọ́ tàbí tí wọ́n ti dàgbà tí wọ́n sì ń ṣe dáadáa nínú ìjọ nípa bí wọ́n ṣe máa ń bá àwọn ọmọ wọn jíròrò tí àwọn ọmọ wọn fi ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fàlàlà. Bí àpẹẹrẹ, Glena tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò tó sì ní ọmọ mẹ́rin tó ti dàgbà, sọ pé: “Kí òbí àtọmọ máa bára wọn sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fàlàlà kì í ṣàdédé wáyé. Ńṣe lèmi àtìyàwó mi pinnu láti máa pa àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tì ká lè máa ráyè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wa dáadáa. Nígbà tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, a máa ń dìídì ya alẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún wọn nígbà míì, tá a ó jọ máa sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun tó bá wá sọ́kàn wọn. Bákan náà, tá a bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn nígbà tá a bá ń jẹun, a máa ń fòye mọ ohun tó kù díẹ̀ káàtó nínú ìṣe àti èrò wọn. A óò wá rọra tọ́ wọn sọ́nà. Àní ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àá ti tọ́ wọn sọ́nà tán kí wọ́n tiẹ̀ tó mọ̀ rárá.”

Ó yẹ kí òbí pẹ̀lú sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ọmọ. Jésù sọ pé: “Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere ọkàn-àyà rẹ̀, . . . nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Arákùnrin Toshiki táwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Àìmọye ìgbà ni mo máa ń sọ ìdí tí mo fi nígbàgbọ́ nínú Jèhófà fáwọn ọmọ mi. Mo máa ń sọ bí mo ṣe dẹni tó gbà tọkàntọkàn pé Jèhófà ń bẹ àti bí ìrírí mi nígbèésí ayé ṣe fi dá mi lójú pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì àti pé Bíbélì ni amọ̀nà tó dára jù nígbèésí ayé.” Bákan náà, Cindy tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Ìgbà gbogbo lọkọ mi máa ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ wa. Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ́ bó ṣe ń gbàdúrà látọkànwá, wọ́n máa ń mọ̀ pé ẹni gidi tó wà níbì kan ni Jèhófà.”

Àpẹẹrẹ Òbí Lágbára Púpọ̀

Àpẹẹrẹ àwa òbí lágbára púpọ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu wa lọ, torí ó máa ń jẹ́ káwọn ọmọ wa rí bí àwa òbí wọn ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó. Àwọn èèyàn mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run jinlẹ̀ lọ́kàn Jésù Kristi nígbà tí wọ́n rí bó ṣe ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Jésù sọ pé: “Nítorí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe.”—Jòhánù 14:31.

Ní ilẹ̀ Wales, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Gareth sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn ọmọ wa rí i pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé à ń sapá láti ṣe nǹkan lọ́nà tó fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ mi rí i pé mo máa ń gba àṣìṣe mi bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ṣe. Báyìí, àwọn ọmọ mi náà máa ń gbìyànjú láti gba àṣìṣe wọn.”

Òbí míì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ọsirélíà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Greg sọ pé: “A fẹ́ káwọn ọmọ wa rí i pé òtítọ́ ló ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa. Nígbà tá a bá ń gbèrò bá a ṣe máa ṣe iṣẹ́ tàbí eré àṣenajú, ohun tá a kọ́kọ́ máa ń gbé yẹ̀ wò ni ipa tó máa ní lórí ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Inú wa dùn gan-an ni pé ọmọbìnrin wa ọlọ́dún mọ́kàndínlógún náà ń ṣe bẹ́ẹ̀ bó ṣe ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.”

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọmọ Wa Lọ́wọ́ Láti Mọ Ọlọ́run

Èèyàn ò lè nífẹ̀ẹ́ tàbí kó fọkàn tán ẹni tí ò mọ̀ dáadáa. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fẹ́ káwọn Kristẹni ìlú Fílípì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí i, ó kọ̀wé sí wọn pé: “Èyí sì ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” (Fílípì 1:9) Lórílẹ̀-èdè Peru, òbí kan tó ń jẹ́ Falconerio, tó ń tọ́ ọmọ mẹ́rin, sọ pé: “Kíkà tí mò ń ka Bíbélì pẹ̀lú àwọn ọmọ mi tí mo sì ń bá wọn kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ń mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i. Mo rí i pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run máa ń jó àjórẹ̀yìn tí mi ò bá bá wọn kẹ́kọ̀ọ́.” Ní ilẹ̀ Ọsirélíà, òbí kan tó ń jẹ́ Gary sọ pé: “Mo sábà máa ń fi ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń nímùúṣẹ han àwọn ọmọ mi. Mo tún máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Ṣíṣe tá à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé ló ń mú kí ìgbàgbọ́ wọn máa lágbára sí i.”

Ẹ̀kọ́ máa wọ àwọn ọmọ lọ́kàn dáadáa táwọn òbí ò bá fọwọ́ líle mú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tí wọn kì í sì í kanra mọ́ àwọn ọmọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti fọwọ́ pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún. Èyí á jẹ́ káwọn ọmọ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. (Jákọ́bù 3:18) Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Shawn àti Pauline tí wọ́n ní ọmọ mẹ́rin sọ pé: “Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa, a máa ń gbìyànjú láti má ṣe sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sáwọn ọmọ wa, kódà nígbà tí wọn ò bá jókòó jẹ́ẹ́. Oríṣiríṣi ọ̀nà la máa ń gbà darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì a máa ń sọ fáwọn ọmọ wa pé kí wọ́n yan kókó tá a máa kọ́. A máa ń lo àwọn fídíò tí ètò Jèhófà ṣe. Nígbà míì, a lè tún apá kan fídíò kan wò tàbí ká dá a dúró díẹ̀ láti jíròrò ohun tá a ti wò ká tó tún máa wò ó lọ.” Ìyá kan tó ń jẹ́ Kim ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yìí kan náà sọ pé: “Mo máa ń fara balẹ̀ múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé sílẹ̀ kí n lè bi àwọn ọmọ mi ní ìbéèrè tó máa mú wọn ronú jinlẹ̀. A máa ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gan-an ni. A máa ń rẹ́rìn-ín dáadáa.”

Tó Bá Dọ̀rọ̀ Yíyan Ọ̀rẹ́

Ìfẹ́ Jèhófà àti ìmọrírì fún ìjọsìn tòótọ́ máa túbọ̀ gbilẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ tó bá jẹ́ pé àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń bá kẹ́gbẹ́. Ó lè gba ìsapá ká tó lè ṣètò báwọn ọmọ wa ṣe máa rí àwọn tó lè ṣe wọ́n láǹfààní, tí wọ́n á jọ máa sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì jọ máa ṣeré. Àmọ́ àǹfààní ẹ̀ pọ̀! Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ṣàǹfààní tá a bá wá báwọn ọmọ wa á ṣe máa rìn mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn àwọn tí wọ́n ti pinnu láti fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ pé bíbá tí wọ́n bá àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ onítara kẹ́gbẹ́ ló ràn wọ́n lọ́wọ́. Arábìnrin kan tó di míṣọ́nnárì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn òbí mi máa ń pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà pé kí wọ́n wá jẹun nílé wa. Ó hàn gbangba pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ń fún wọn láyọ̀ gan-an, ìyẹn sì mú kémi náà fẹ́ láti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún bíi tiwọn.”

Irú àwọn táwọn ọmọ wa ń bá kẹ́gbẹ́ lè ní ipa rere tàbí búburú lórí wọn. Ewu ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tó wà lóde yìí gba pé kí òbí fi ọgbọ́n kọ́ ọmọ. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Káwa òbí tó lè kọ́ àwọn ọmọ wa láti yẹra fún àwọn tí ò mọ Jèhófà tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a ní láti jẹ́ olùkọ́ olóye. (Òwe 13:20) Òbí kan tó ń jẹ́ Shawn, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “A jẹ́ káwọn ọmọ wa mọ̀ pé a ò ní kí wọ́n má bá àwọn ọmọ iléèwé wọn ṣeré rárá o, àmọ́ kí wọ́n má ṣe bá wọn ṣe wọléwọ̀de lẹ́yìn àkókò ilé ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ wa mọ ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n máa lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tó máa ń wáyé lẹ́yìn àkókò ilé ẹ̀kọ́ tàbí ìdíje eré ìdárayá tí wọ́n máa ń ṣe níléèwé.”

Èrè Tó Wà Nínú Títọ́ Ọmọ

Tá a bá kọ́ àwọn ọmọ wa bí wọ́n á ṣe máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, a ó tipa bẹ́ẹ̀ mú kó máa wù wọ́n láti fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run hàn. Arákùnrin Mark tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “A fẹ́ káwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì rí i pé wọ́n lè sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn nígbàkigbà, pé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tí wọ́n bá gbápò tí wọ́n lọ sóde ẹ̀rí. Nítorí náà, tá a bá ń lọ najú, yálà ní ọgbà ìtura, létíkun, tàbí nínú igbó, a máa ń mú Bíbélì àtàwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì dání, a sì máa ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a gbà gbọ́. Ó máa ń dùn mọ́ àwọn ọmọ wa gan-an ni tá a bá jọ ń wàásù nírú ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Wọ́n máa ń dá sí ìjíròrò náà wọ́n sì máa ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́.”

Àpọ́sítélì Jòhánù àgbàlagbà ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé nípa wọn pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi [nípa tẹ̀mí] ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Táwa náà bá gbin ìfẹ́ Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wa, a óò ní irú ayọ̀ yẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ó gba ìsapá kí òbí àtọmọ tó lè jọ máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fàlàlà nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run hàn

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Green Chimneys Farm

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́