ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/15 ojú ìwé 11-13
  • Ìwé John Milton Tó Dàwátì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé John Milton Tó Dàwátì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí John Milton Ṣe Bẹ̀rẹ̀
  • “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nìkan”
  • Ìwé On Christian Doctrine
  • Ohun Tí Milton Gbà Gbọ́
  • Àṣìṣe Milton
  • Ǹjẹ́ ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Bí Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Ṣe Pa Dà Wá Sójú Táyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ṣé Ayé Máa Di Párádísè Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Mo Rí Ìṣúra Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Tayọlọ́lá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/15 ojú ìwé 11-13

Ìwé John Milton Tó Dàwátì

TÁ A bá ń sọ̀rọ̀ nípa pé kéèyàn kọ̀wé tó nípa tó lágbára lórí ọ̀pọ̀ èèyàn, òǹkọ̀wé bíi ti John Milton ṣọ̀wọ́n. Òun ló kọ ewì gígùn kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Paradise Lost [A Pàdánù Párádísè]. Ẹnì kan tó kọ ìtàn ìgbésí ayé John Milton ní, “ọ̀pọ̀ èèyàn ló gba tiẹ̀, àwọn díẹ̀ kórìíra ẹ̀, àmọ́ àwọn tí ò tíì gbọ́ nípa rẹ̀ ò tó nǹkan.” Dòní olónìí, àwọn ìwé tí Milton kọ wúlò púpọ̀ fáwọn tó ń kọ ìtàn, eré àti ewì nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Báwo ló ṣe di pé John Milton ní ipa tó lágbára bẹ́ẹ̀ lórí àwọn èèyàn? Kí nìdí tí àríyànjiyàn fi wà lórí ìwé àlàyé tó kọ gbẹ̀yìn náà On Christian Doctrine, débi tí wọn ò fi tẹ̀ ẹ́ jáde fún odindi àádọ́jọ [150] ọdún?

Bí John Milton Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Ilé ọlá ni wọ́n bí John Milton sí nílùú London lọ́dún 1608. Ó ní: “Àtìgbà kékeré mi ni bàbá mi ti ń ṣọ̀nà bí màá ṣe kẹ́kọ̀ọ́ láti di òǹkọ̀wé. Mo sì nífẹ̀ẹ́ sí i débi pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń kàwé di ààjìn òru látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún méjìlá.” Ó fakọ yọ nídìí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ó sì gboyè ẹlẹ́ẹ̀kejì ní Yunifásítì Cambridge lọ́dún 1632. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtàn ìgbà láéláé àtàwọn ìwé kan tí wọ́n kọ láyé ọjọ́un.

Milton fẹ́ láti di òǹkọ̀wé ewì, àmọ́ inú yánpọnyánrin ni ilẹ̀ England wà nígbà ayé rẹ̀, torí pé àwọn kan ń jà fitafita láti yí ètò ìjọba padà. Ìgbìmọ̀ kan tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin tí Oliver Cromwell jẹ́ alága rẹ̀ yan pàṣẹ pé kí wọ́n pa Ọba Charles Kìíní lọ́dún 1649. Milton wá kọ ìwé kan láti fi hàn pé ohun táwọn tó pa ọba ṣe yẹn kò burú, Milton sì di agbọ̀rọ̀sọ fún ìjọba Cromwell. Àní kí John Milton tó di gbajúmọ̀ òǹkọ̀wé ewì làwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n nítorí àwọn ìwé rẹ̀ tó dá lórí ìṣèlú àti ìwà ọmọlúwàbí.

Lẹ́yìn tí Ọba Charles Kejì gorí ìtẹ́ lọ́dún 1660 tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dá ètò ìjọba ti tẹ́lẹ̀ padà, ó di pé ẹ̀mí Milton wà nínú ewu torí pé ó ń ti Cromwell lẹ́yìn. Ni Milton bá lọ fara pa mọ́. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni pàtàkì láwùjọ ni wọn ò fi rí i pa. Àmọ́ gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn ò mú kí ìfẹ́ tó ní sí ọ̀rọ̀ ìsìn yingin.

“Ohun Tí Bíbélì Sọ Nìkan”

Milton sọ bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn nínú ìwé tó kọ, ó ní: “Àti kékeré ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun tí wọ́n fi àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ.” Milton wá ka Ìwé Mímọ́ sí atọ́nà kan ṣoṣo tó ṣeé gbára lé lórí ọ̀rọ̀ ìsìn àti bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà. Àmọ́, nígbà tó ṣàyẹ̀wò onírúurú ìwé ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ìgbà ayé rẹ̀, inú rẹ̀ ò dùn rárá sóhun tó rí. Ó kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Mi ò rò pé ó bójú mu pé kí n gba irú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ gbọ́ tàbí kí n gbà pé ó máa jẹ́ kí n rí ìgbàlà.” Ó pinnu pé “ohun tí Bíbélì sọ nìkan lòun máa fi wo” ohun tóun gbà gbọ́ láti mọ̀ “bóyá ó tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà.” Ó wá to àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe kókó sábẹ́ àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ pàtàkì pàtàkì, ó sì máa ń lo ọ̀rọ̀ àwọn ẹsẹ náà tó bá ń ṣàlàyé.

Lónìí, ohun tí wọ́n fi ń rántí John Milton jù ni ìwé rẹ̀ tó pè ní Paradise Lost [A Pàdánù Párádísè]. Ìwé ewì yìí ló fi sọ ìtàn Bíbélì nípa béèyàn ṣe pàdánù ìjẹ́pípé, tó daláìpé. (Jẹ́nẹ́sísì, orí kẹta) Ìwé yìí, tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ lọ́dún 1667, ló sọ Milton dolókìkí lẹ́nu iṣẹ́ ìwé kíkọ, pàápàá láwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì láyé. Nígbà tó ṣe, ó kọ ewì míì tó fi ń bá àlàyé ewì tó kọ́kọ́ kọ nìṣó. Ó pè é ní Paradise Regained [A Rí Párádísè Gbà Padà]. Àwọn ewì yìí sọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ìran èèyàn nípilẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn, ìwàláàyè pípé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n tún sọ bí Ọlọ́run yóò ṣe tipasẹ̀ Kristi mú Párádísè bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Paradise Lost, Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì sàsọtẹ́lẹ̀ ìgbà tí Kristi yóò “san èrè fáwọn olóòótọ́ tí yóò sì fún wọn ní ayọ̀ àìnípẹ̀kun, yálà lọ́run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, nítorí pé ayé á ti di Párádísè, ayọ̀ ibẹ̀ á ju ti Édẹ́nì lọ fíìfíì, èèyàn á sì máa gbébẹ̀ títí láé.”

Ìwé On Christian Doctrine

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Milton tún fẹ́ láti kọ ìwé míì tó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ẹ̀kọ́ àti ìgbésí ayé Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ríran mọ́ rárá nígbà tó fi máa di ọdún 1652, ó ṣiṣẹ́ kára lórí ìwé tó ṣe gbẹ̀yìn yìí títí tó fi kú lọ́dún 1674, akọ̀wé rẹ̀ ló sì ràn án lọ́wọ́. Milton pe ìwé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ẹ̀kọ́ Kristẹni yìí, tó sọ pé ó dá lé Ìwé Mímọ́ nìkan, ní A Treatise on Christian Doctrine Compiled From the Holy Scriptures Alone. Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé náà, ó ní: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kọ̀wé lórí ẹ̀kọ́ Kristẹni . . . ló jẹ́ pé àlàyé etí ìwé ni wọ́n fi ẹsẹ Bíbélì ṣe, bẹ́ẹ̀ orí Bíbélì ló yẹ káwọn ẹ̀kọ́ wọn dá lé. Àmọ́ èmi gbìyànjú gan-an láti fọ̀rọ̀ Bíbélì kúnnú ìwé tí mo kọ yìí fọ́fọ́, ibi gbogbo nínú Bíbélì ni mo sì ti fa ọ̀rọ̀ yọ.” Òótọ́ ni Milton sọ torí pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ìgbà tí ìwé rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tàbí tó tọ́ka sí i.

Milton máa ń sọ ohun tó gbà gbọ́ kó tó di pé ó ṣe ìwé yìí. Àmọ́ nígbà tó ṣèwé yìí tán, kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé ó mọ̀ pé àlàyé Bíbélì tóun ṣe nínú ìwé náà yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fara mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, kò rí ojúure ìjọba mọ́ nígbà tí wọ́n dá ìjọba ti tẹ́lẹ̀ padà tí ọba míì sì gorí ìtẹ́. Bóyá ìdí nìyẹn tó fi ń dúró dìgbà tó lè tẹ ìwé náà jáde láìsí wàhálà. Lẹ́yìn tó kú, akọ̀wé rẹ̀ mú ìwé tó fèdè Látìn kọ yẹn lọ síléeṣẹ́ ìtẹ̀wé, àmọ́ wọn ò gbà láti tẹ̀ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ẹni pàtàkì kan nínú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbẹ́sẹ̀ lé ìwé náà, ó sì fi pa mọ́. Odindi àádọ́jọ [150] ọdún lẹ́yìn náà ni wọ́n tó rí ìwé náà.

Lọ́dún 1823, ṣàdédé ni akọ̀wé kan rí ìwé gbajúmọ̀ òǹkọ̀wé ewì yìí, níbi tí wọ́n fi bébà wé e pa mọ́ sí. Ọba George Kẹrin tó wà lórí ìtẹ́ ilẹ̀ England nígbà yẹn wá pàṣẹ pé kí wọ́n tú u sédè Gẹ̀ẹ́sì látèdè Látìn tí wọ́n fi kọ ọ́, kí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde fáwọn èèyàn. Nígbà tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún méjì lẹ́yìn náà, ó dá awuyewuye sílẹ̀ lágbo àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àtàwọn òǹkọ̀wé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni bíṣọ́ọ̀bù kan sọ pé ayédèrú ìwé ni. Ó ní òun ò gbà pé Milton tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sẹ́ni tó já fáfá jù lọ lára àwọn òǹkọ̀wé ewì ẹ̀sìn ní England, lè ta ko àwọn ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbé gẹ̀gẹ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹni tó túmọ̀ ìwé àlàyé náà, On Christian Doctrine, ti róye pé báwọn èèyàn ṣe máa ṣe tí wọ́n bá rí ìwé náà nìyẹn, ló bá kọ àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé sínú rẹ̀ láti fi jẹ́ kéèyàn rí ọgọ́rùn-ún márùn-ún nǹkan tí ìwé náà fi jọ ìwé Paradise Lost, kó bàa lè dájú pé Milton ló ṣe ìwé náà.a

Ohun Tí Milton Gbà Gbọ́

Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Milton, orílẹ̀-èdè England ti gba àtúnṣe táwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ń ṣe sí ìsìn Kristẹni, kò sì bá ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe mọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbà pé póòpù kọ́ ló yẹ kó máa pàṣẹ ohun tó yẹ kéèyàn gbà gbọ́ àti irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, pé Bíbélì nìkan ló yẹ kó sọ ọ́. Àmọ́, nínú ìwé On Christian Doctrine, Milton fi hàn pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àti àṣà àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì pàápàá kò bá Bíbélì mu. Ó fi Bíbélì ṣàlàyé pé ẹ̀kọ́ nípa kádàrá tí ṣọ́ọ̀ṣì John Calvin fi ń kọ́ni kò tọ̀nà, pé Ọlọ́run fún èèyàn lómìnira láti yan ohun tó wù ú. Bákan náà, Milton gbé fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo Jèhófà tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run lárugẹ nípa lílò ó láìmọye ìgbà nínú ìwé rẹ̀.

Milton fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé ọkàn máa ń kú. Ó sọ̀rọ̀ nípa Jẹ́nẹ́sísì 2:7 nínú ìwé tó kọ, ó ní: “Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn tán, Ìwé Mímọ́ sọ pé: eniyan si di alààyè ọkàn. . . . Èèyàn ò pín sí méjì, kò sì sí nǹkan míì nínú rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá kan lọ́tọ̀ tàbí tó ṣeé yà sọ́tọ̀. Ọ̀rọ̀ ò rí bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rò pé ohun méjì, ìyẹn ọkàn àti ara, ló para pọ̀ di èèyàn, tí wọ́n si ń sọ pé ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó yàtọ̀ síra ni wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, èèyàn fúnra rẹ̀ lódindi ni ọkàn.” Lẹ́yìn náà, Milton béèrè pé: “Ṣé èèyàn lódindi ló máa ń kú ni, àbí ara rẹ̀ nìkan?” Ó wá sọ ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì tó fi hàn pé èèyàn lódindi ló máa ń kú láìjẹ́ pé ohun kan jáde kúrò nínú rẹ̀, ó sì fi kún un pé: “Àmọ́ àlàyé tó dájú jù lọ pé ọkàn ń kú lohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ nínú Ìsík[íẹ́lì 18:]20, pé: ọkan ti o ba ṣẹ̀ yoo kú.” Milton tún mẹ́nu kan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Lúùkù 20:37 àti Jòhánù 11:25 láti fi hàn pé àjíǹde tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú nìkan ni ìrètí táwọn òkú ní láti tún padà wà láàyè.

Kí ló dun àwọn kan jù nínú ìwé Milton yìí? Òun ni àlàyé rírọrùn tó fi Bíbélì ṣe. Àlàyé yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn dájú pé Kristi Ọmọ Ọlọ́run rẹlẹ̀ sí Bàbá rẹ̀, ìyẹn Ọlọ́run. Lẹ́yìn tó fa ọ̀rọ̀ Jòhánù 17:3 àti Jòhánù 20:17 yọ, ó béèrè pé: “Tí Bàbá bá jẹ́ Ọlọ́run Kristi àti Ọlọ́run wa, tó sì jẹ́ pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, ta ló tún lè jẹ́ Ọlọ́run yàtọ̀ sí Bàbá?”

Milton tún sọ pé: “Ọmọ alára àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi hàn nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ àti gbogbo ìwé tí wọ́n kọ pé gbogbo nǹkan ni Bàbá fi ju Ọmọ lọ.” (Jòhánù 14:28) Ó ní: “Ṣebí Kristi ló fúnra rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 26:39 pé: Baba mi, bó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá; àmọ́, kì í ṣe bí èmi ti fẹ́, bí kò ṣe bí ìwọ ti fẹ́. . . . Tó bá jẹ́ pé òun ni Ọlọ́run, kí nìdí tí kò fi gbàdúrà sí ara rẹ̀, tó jẹ́ pé Bàbá rẹ̀ ló gbàdúrà sí? Tó bá jẹ́ pé bó ṣe jẹ́ èèyàn yẹn, òun kan náà tún ni Ọlọ́run Olódùmarè, kí ló dé tó tún ń béèrè ohun tó lè fúnra rẹ̀ ṣe? . . . Bí Ọmọ ṣe ń gbé Bàbá ga níbi gbogbo tó sì ń jọ́sìn Bàbá nìkan, bẹ́ẹ̀ ló kọ́ àwa náà pé ká máa ṣe.”

Àṣìṣe Milton

John Milton wọ́nà láti mọ òtítọ́. Síbẹ̀, ó ní kùdìẹ̀-kudiẹ ẹ̀dá èèyàn, ó sì ṣeé ṣe káwọn nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀ sí i nípa lórí èrò rẹ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ lẹ́yìn tó gbé ọmọ baálẹ̀ kan níyàwó nìyẹn já a jù sílẹ̀ tó sì padà sílé àwọn òbí rẹ̀. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ló sì lò níbẹ̀. Lákòókò yẹn, Milton kọ àwọn ìwé kan láti fi hàn pé àgbèrè nìkan kọ́ ló lè fa ìkọ̀sílẹ̀. Ó ní tí ìwà tọkọtaya ò bá bára mu, wọ́n lè kọra wọn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ àgbèrè nìkan ni Jésù sọ pé ó lè fa ìkọ̀sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Milton sọ èrò rẹ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀ yìí nínú ìwé On Christian Doctrine.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Milton ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiẹ̀, ìwé On Christian Doctrine tó ṣe sọ èrò Bíbélì nípa ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì. Dòní olónìí, táwọn èèyàn bá ń ka ìwé rẹ̀, wọ́n máa ń rí i pé ó yẹ káwọn gbé ìgbàgbọ́ àwọn yẹ̀ wò bóyá ó bá Bíbélì mu tàbí kò bá a mu.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtumọ̀ ìwé On Christian Doctrine tí ilé ẹ̀kọ́ Yunifásítì Yale tẹ̀ lọ́dún 1973 jẹ́ ìtumọ̀ tó túbọ̀ péye látinú èyí tí Milton fúnra rẹ̀ fi èdè Látìn kọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Milton máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda The Early Modern Web ní Oxford

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ewì tí Milton kọ nípa bá a ṣe pàdánù Párádísè ló sọ ọ́ di olókìkí

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda The Early Modern Web ní Oxford

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ìwé tí Milton kọ gbẹ̀yìn dàwátì fún àádọ́jọ ọdún gbáko

[Credit Line]

Àwòrán nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Rare Books and Special Collections, Thomas Cooper Library, University of South Carolina

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwòrán nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Rare Books and Special Collections, Thomas Cooper Library, University of South Carolina

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́