ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 1/1 ojú ìwé 28-31
  • Mo Rí Ìṣúra Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Tayọlọ́lá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Rí Ìṣúra Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Tayọlọ́lá
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipò-Àtilẹ̀wá Ìdílé Mi
  • Rírí Ìṣúra Tòótọ́
  • Ìrìn-Àjò Ìwàásù Pẹ̀lú Baba Mi
  • Bíbá Onírúurú Àdánwò Pàdé
  • Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ ní Adelaide
  • Ẹ̀kọ́ Tí Mo Ti Ń Gbà Láti Kékeré
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Mo Dánìkan Wà Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Tì
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Títẹ̀ Lé Ipasẹ̀ Àwọn Òbí mi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Atànmọ́lẹ̀ fún Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 1/1 ojú ìwé 28-31

Mo Rí Ìṣúra Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Tayọlọ́lá

GẸ́GẸ́ BÍ FLORENCE WIDDOWSON TI SỌ Ọ́

Bí alẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ síí lẹ́, a pinnu láti pàgọ́ sẹ́bàá ọ̀sà kan. Kìí ṣe ibi tí ó dára láti pàgọ́ sí fún àwọn obìnrin méjì, ṣùgbọ́n a ronú pé kì yóò séwu fún alẹ́ ọjọ́ kan. Nígbà tí ọwọ́ mi dí fún pípàgọ́ náà, Marjorie ń gbọ́únjẹ alẹ́ wa.

MO ṢẸ̀ṢẸ̀ parí gbígbá èèkàn àgọ́ tí ó gbẹ̀yìn wọlẹ̀ ni nígbà tí mo tajúkán rí ohun kan tí ó rúnra wúrú lẹ́bàá gbòǹgbò igi dúdú kan. Mó késí Marjorie pé, “Ǹjẹ́ o rí i pé ohun kan rúnra wúrú nídìí igi yẹn?”

Ó dáhùnpadà, pẹ̀lú ìdàrúdàpọ̀ ọkàn díẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀kọ́.”

“Ó dára, ohun kan rúnra dájúdájú,” ni mo kígbe. “Gbé àgé fún mi!”

Ní gbígbà á, pẹ̀lú àáké ní èjìká mi, mo forílé ibi ọ̀sà náà. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí n dé ibi gbòǹgbò náà, ọkùnrin kan gba ẹ̀yìn rẹ̀ jáde!

“Omi tí ó wà nínú ọ̀sà ha dára fún mímu bí?” ni mo fi agbárakáká sọ.

“Bẹ́ẹ̀kọ́, kò dára láti mu,” ni ó dáhùn lọ́nà lílekoko, “ṣùgbọ́n bí o bá fẹ́ omi mímu, èmi yóò bá ọ wá díẹ̀.”

Mo yára kọ̀ ìfilọni rẹ̀, ara sì tù mí pẹ̀sẹ̀ bí ó ti yípadà bìrí tí ó sì lọ kúrò. Pẹ̀lú ìwárìrì, mó yára padà lọ sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún Marjorie. A tètè tú àgọ́ náà palẹ̀, a kó ẹrù wa, a sì fi ibẹ̀ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà a gbọ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ọkùnrin náà sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n ni.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùwá-ohun-iyebíye-kiri sábà máa ń pàgọ́ sórí àwọn pápá wúrà ti Australia nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní 1937, àwa jẹ́ irú olùwá-ohun-iyebíye-kiri kan tí ó yàtọ̀. A ń wá àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣeyebíye fún Ọlọrun kiri.

Ipò-Àtilẹ̀wá Ìdílé Mi

Ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún sẹ́yìn, baba mi ni alágbẹ̀dẹ tí ó wà ní àbúlé kékeré Porepunkah ní ìpínlẹ̀ Victoria. Níbẹ̀ ni a bí mi sí ní 1895, mo sì dàgbà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n ọkùnrin mẹ́rin nítòsí Odò Ovens, ní ìsàlẹ̀ Òkè Buffalo. Àwọn òbí mi a máa lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Union déédéé, èmi sì máa ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́-ìsinmi, níbi tí baba mi ti jẹ́ ọ̀gá olùṣàbójútó.

Ní 1909, mama mi jìyà ìkọlù àìsàn ọkàn-àyà nígbà ìjì lílágbára kan ó sì kú sọ́wọ́ baba mi. Lẹ́yìn náà, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ 1914, ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin fi ilé sílẹ̀, àti ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n gbé e padà wá fún wa​—⁠ní òkú. Ó ti fi ọwọ́ araarẹ̀ pa araarẹ̀. Ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tí ó sọ pé ọ̀run àpáàdì dúró dè é mú ẹ̀dùn-ọkàn wa jinlẹ̀ síi, níwọ̀n bí wọ́n ti sọ pé ìfọwọ́ ara-ẹni pa ara-ẹni jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì.

Nígbà tí ó ṣe ní ọdún yẹn Ogun Àgbáyé Kìn-⁠ín-⁠ní bẹ́sílẹ̀, méjì nínú àwọn ẹ̀gbọ́n mi sì darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun ní ilẹ̀ òkèèrè. Ìròyìn amúnifòyà nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìjìyà sún àwa ọ̀dọ́bìnrin mẹ́fà, pẹ̀lú baba mi, láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bibeli náà Johannu.

Rírí Ìṣúra Tòótọ́

Ellen Hudson ní ẹ̀dà kan ìwé náà The Time Is at Hand, tí Charles Taze Russell kọ. Ìtara-ọkàn rẹ̀ fún un ní agbára ìdarí lórí àwa yòókù nínú àwùjọ náà. Nígbà tí ó kíyèsí i pé ìwé náà jẹ́ ọ̀kanṣoṣo nínú ọ̀wọ́ àwọn ìdìpọ̀ ìwé mẹ́fà tí a fún ní àkọlé náà Studies in the Scriptures, ó fi lẹ́tà kan ráńṣẹ́ sí International Bible Students Association ní Melbourne ó sì béèrè fún ìyókù nínú ọ̀wọ́ náà. Àwùjọ wa gbà láti lo ìdìpọ̀ àkọ́kọ́, The Divine Plan of the Ages, nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ronú nípa ayọ̀ baba mi àti tèmi láti ṣàwárí pé kò sí ọ̀run àpáàdì oníná. Ìbẹ̀rù náà pé ẹ̀gbọ́n mi ní a sémọ́ inú iná ọ̀run àpáàdì ni a mú kúrò. A kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ náà pé àwọn òkú kò mọ nǹkankan, bí ẹni pé wọ́n sùn fọnfọn, àti pé wọn kò gbé níbìkan tí wọ́n ti ń jìyà ìdálóró. (Oniwasu 9:​5, 10; Johannu 11:​11-⁠14) Àwọn kan nínú àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa pinnu láti tọ àwọn aládùúgbò wa lọ láti wàásù àwọn òtítọ́ tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. A rìn lọ sí àwọn ilé tí ń bẹ nítòsí, ṣùgbọ́n a lo kẹ̀kẹ́ ológeere àti kẹ̀kẹ́ àfẹṣinfà kan láti dé ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní àwọn àrọ́ko.

Mó kọ́kọ́ tọ́ ìjẹ́rìí ilé dé ilé wò ní Ọjọ́ Ìdágundúró Ráńpẹ́, ní November 11, 1918. Àwa mẹ́ta láti inú àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ wa rìnrìn-àjò 80 kìlómítà lọ sí ìlú Wangaratta láti pín ìwé-àṣàrò-kúkúrú náà Peoples Pulpit. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí a wà lẹ́nu iṣẹ́-àyànfúnni ìwàásù kan ní ọ̀kan nínú àwọn agbègbè àrọ́ko tí ó jìnnà sí ìlú, mo ní ìrírí náà tí mo mẹ́nukàn ní ìbẹ̀rẹ̀.

Ní 1919, mò lọ sí àpéjọpọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan ní Melbourne. Níbẹ̀, ní April 22, 1919, mo ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ mi fún Jehofa nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi. Àsè ńlá tẹ̀mí náà mú ìmọrírì mi jinlẹ̀ síi fún ìṣúra tẹ̀mí ti Ìjọba àwọn ọ̀run àti fún ètò-àjọ Jehofa ti orí ilẹ̀-ayé.​—⁠Matteu 13:⁠44.

Nkò padà sílé lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà ṣùgbọ́n mo tẹ́wọ́gba ìkésíni kan láti darapọ̀ mọ́ Jane Nicholson, oníwàásù alákòókò kíkún, fún wíwàásù fún oṣù kan. Ibi iṣẹ́-àyànfúnni wa ni àdúgbò àwùjọ àwọn tí ń ṣọ̀gbìn tí wọ́n sì ń sin màlúù lọ́nà Odò King. Ní kìkì ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, agbègbè olókè-ńlá yìí ni ibi tí a lò fún ìgbékalẹ̀ àwòrán sinimá náà The Man From Snowy River.

Ní 1921 a gba àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli dídára náà Duru Ọlọrun. Nígbà tí baba mi bẹ̀rẹ̀ síí lò ó gẹ́gẹ́ bí ìwé-ẹ̀kọ́ fún kíláàsì ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́-ìsinmi rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn òbí kọ̀ wọ́n sì sọ pé kí ó kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní kánmọ́. Lẹ́yìn náà a gba ìwé-kékeré náà Hell, pẹ̀lú àwọn ìbéèrè ojú-ewé àkọ́kọ́ rẹ̀ tí ń ru ìtọpinpin sókè, “Kí Ni Ó Jẹ́? Àwọn Wo Ni Wọ́n Wà Níbẹ̀? Wọ́n Ha Lè Jáde Bí?” Ẹ̀rí Bibeli ṣíṣekedere tí a gbékalẹ̀ lórí kókó-ẹ̀kọ́ náà ru ìmọ̀lára baba mi sókè gan-⁠an tí ó fi bẹ̀rẹ̀ síí pín àwọn ẹ̀dà rẹ̀ kiri lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti ilé dé ilé. Ó fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn sóde ní abúlé wa àti ní àwọn àrọ́ko tí ó wà nítòsí.

Ìrìn-Àjò Ìwàásù Pẹ̀lú Baba Mi

Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, baba mi ra ọkọ̀-ìrìnnà kan láti mú ìhìnrere Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní àwọn agbègbè mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí alágbẹ̀dẹ, ẹṣin mọ́ ọn lára ju, nítorí náà mo di awakọ̀ ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀, a kọ́kọ́ ń gbé òrumọ́jú ní àwọn òótẹ̀lì. Láìpẹ́ èyí jásí ọ̀kan tí ó gbówólórí jù, a sì bẹ̀rẹ̀ síí pàgọ́ kiri.

Baba mi ṣe ìjókòó iwájú ọkọ̀ náà kí ó baà lè ṣeétẹ́ pẹrẹsẹ kí èmi sì lè sùn nínú ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́. A pàtíbàbà kékeré kan fún baba mi láti sùn sí. Lẹ́yìn pípàgọ́ fún àwọn ọ̀sẹ̀ mélòókan, a ó padà lọ sí Porepunkah, níbi ti baba mi yóò ti ṣí ṣọ́ọ̀bù àgbẹ̀dẹ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi. Ohun ìyanu ni ó máa ń jẹ́ fún wa pé nígbà gbogbo ni ọ̀pọ̀ àwọn oníbàárà tí ń sanwó iṣẹ́ wọn máa ń wà láti mówó tí yóò kájú àwọn ìnáwó wa fún ìrìn-àjò ìwàásù tí yóò tẹ̀lé e wọlé.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí ìfẹ́-inú lọ́nà títọ́ dáhùnpadà lọ́nà rere sí àwọn ìbẹ̀wò wa wọ́n sì gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Ìjọ méje ni ó wà nísinsìnyí pẹ̀lú Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn ní agbègbè náà tí àwùjọ wa kékeré láti Porepunkah ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́, ta ni lè kẹ́gàn “ọjọ́ ohun kékeré”?​—⁠Sekariah 4:⁠10.

Ní 1931, èmi àti baba mi wakọ̀ lọ sí nǹkan bíi 300 kìlómítà gba ọ̀nà gbágungbàgun kọjá láti lọ sí ìpàdé àkànṣe kan, níbi tí a ti gba orúkọ wa titun, “Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Orúkọ aláìlẹ́gbẹ́, tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu yìí dùn mọ́ àwa méjèèjì nínú. (Isaiah 43:​10-⁠12) Ó fi wa hàn yàtọ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe kedere gan-⁠an ju orúkọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ fìyàtọ̀ hàn náà “International Bible Students” [Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-Èdè], èyí tí a fi mọ̀ wá títí di ìgbà náà.

Ní ọjọ́ kan nígbà tí a ń wàásù ní ìlú Bethanga, mo pàdé òjíṣẹ́ àdúgbò ti Church of England kan. Ó bínú ó sì bẹ̀rẹ̀ síí lọ káàkiri sí àwọn ibi tí a ti fìwé sóde, ní fífi dandangbọ̀n béèrè pé kí àwọn ènìyàn fi àwọn ìwé wọn lé òun lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìgbà náà ó dáná sun àwọn ìwé ní gbangba ní àárín ìlú. Ṣùgbọ́n ìwà-àìdáa tí ó hù já jó o lójú.

Lẹ́yìn tí mo ti fi ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tó ẹ̀ka ọ́fíìsì Society létí, lẹ́tà ìkìlọ̀ kan tí ó dẹ́bi fún ohun tí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ná ṣe ni a tẹ̀jáde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ṣètò fún àwọn ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n kún fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti pín lẹ́tà náà kiri jákèjádò agbègbè náà. Nígbà tí èmi àti baba mi padà ṣèbẹ̀wò sí ìlú náà, a fi ìwé púpọ̀ síi ju ti tẹ́lẹ̀rí lọ sóde. Àwọn ènìyàn ìlú náà nífẹ̀ẹ́-ìtọpinpin láti mọ̀ nípa ohun tí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a “kàléèwọ̀” náà ní nínú!

Ẹni àkọ́kọ́ tí ó tẹ́wọ́gba òtítọ́ Bibeli ní àríwá ìlà-oòrùn Victoria nítorí ìwàásù wa ni Milton Gibb. Láàárín ìbẹ̀wò kan sí òmíràn, ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ gbogbo ìtẹ̀jáde Society tí a bá fisílẹ̀ fún un ní àkọ́yé. Nígbà ìpadàbẹ̀wò wa kan, ó mú ẹnu yà wá nípa sísọ pé: “Mo ti di ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ báyìí.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpinnu rẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, mo ṣàlàyé pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́, Milton. Ìwọ kò lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.”

“Ó dára, nígbà náà, mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rutherford [ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà].”

Mo tún ṣàlàyé lẹ́ẹ̀kan síi pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́, kìí ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rutherford, ṣùgbọ́n mo nírètí pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi.”

Milton Gibb wulẹ̀ jásí ọ̀kan nínú àwọn ìṣúra iyebíye ti mo ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìwà-ohun-ìṣúra-iyebíye nítorí wọn ni. Òun àti méjì nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Kristian alàgbà, àwọn mẹ́ḿbà mìíràn nínú ìdílé rẹ̀ sì ń ṣe déédéé nínú ìjọ.

Bíbá Onírúurú Àdánwò Pàdé

Láìka ìfòfindè tí a gbékarí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Australia sí ní January 1941, a ń wàásù nìṣó, ní lílo kìkì Bibeli nìkan. Nígbà náà ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tàbí iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mi, bá ìdíwọ́ pàdé nígbà tí a késí mi padà sílé láti bójútó baba mi tí ara rẹ̀ kò yá gan-⁠an. Lẹ́yìn náà èmi pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀sí ṣàìsàn tí mo sì nílò iṣẹ́-abẹ kan tí ó léwu. Ó gba àkókò díẹ̀ kí ara mi tó mókun, ṣùgbọ́n mo nírìírí òtítọ́ inú ìlérí Ọlọrun pe: “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” (Heberu 13:⁠5) Kristian arábìnrin kan fún mi ní ìdánilójú, ní wíwí pé: “Rántí, Flo, ìwọ kò dá wà rárá. Ìwọ àti Jehofa jẹ́ iye tí ó pọ̀ jùlọ nígbà gbogbo.”

Lẹ́yìn náà ni àìsàn ti baba mi ṣe kẹ́yìn fún ọ̀sẹ̀ 13 wáyé. Ní July 26, 1946, ó dolóògbé. Ó ti gbádùn ìgbésí-ayé kíkún, òun sì ní ìrètí ti ọ̀run. (Filippi 3:14) Ó wá jẹ́ pé ní ẹni ọdún 51, mo dá wà ní èmi nìkan, níwọ̀n bí mo ti wà pẹ̀lú baba mi fún apá tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé mi. Lẹ́yìn náà ni mo pàdé ọkọ mi ọjọ́-iwájú. A ṣègbéyàwó ní 1947 a sì bẹ̀rẹ̀ síí ṣe aṣáájú-ọ̀nà papọ̀. Ṣùgbọ́n sáà-àkókò aláyọ̀ yìí kò tọ́jọ́, níwọ̀n bí àrùn arọnilọ́wọ́rọnilẹ́sẹ̀ ti kọlù ú ní 1953 tí ó sì di aláìlera.

Ọ̀rọ̀-sísọ ọkọ mi ni èyí nípa lé lórí lọ́nà kan tí kò dára, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dí ohun tí kò ṣeéṣe rárá láti lè bá a sọ̀rọ̀pọ̀. Apá tí ó ṣòro jùlọ nínú àbójútó rẹ̀ nìyẹn. Ìgalára ọpọlọ tí ń bẹ nínú gbígbìyànjú láti lóye ohun tí ó ń tiraka láti sọ jẹ́ èyí tí ó ga nítòótọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé ní agbègbè àdádó níbi tí kò ti sí ìjọ tí ó wà nítòsí, Jehofa kò kọ̀ wá sílẹ̀ ní àwọn ọdún apinnilẹ́mìí wọ̀nyẹn. Mo ń rí i pé kò sí èyíkéyìí tí ó fò mí ru nínú àwọn ìsọfúnni ti ètò-àjọ náà tí ó dé kẹ́yìn, àti ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí nínú àwọn ìwé-ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! Ní December 29, 1957, ọkọ mi ọ̀wọ́n kú.

Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ ní Adelaide

Mo tún dá wà lẹ́ẹ̀kan síi. Kí ni mo níláti ṣe? Ǹjẹ́ a óò tún tẹ́wọ́gbà mí gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lẹ́ẹ̀kan síi lẹ́yìn àlàfo nǹkan bíi ọdún márùn-⁠ún? A tẹ́wọ́gbà mí, nítorí náà mo ta ilé mi mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lákọ̀tun ní Adelaide, olú-ìlú South Australia. Àìní wà fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà níbẹ̀ nígbà náà, a sì yàn mí sí Ìjọ Prospect.

Níwọ̀n bí mo ti ń kọminú nípa wíwakọ̀ láàárín àwọn ọkọ̀ tí ń lọ tí ń bọ̀ nínú ìlú, mo ta ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ mi mo sì bẹ̀rẹ̀ síí lo kẹ̀kẹ́ ológeere lẹ́ẹ̀kan síi. Mo lò ó títí tí mo fi di ẹni ọdún 86, ní dídi ẹni tí a mọ̀ sí “ìyá oníkẹ̀kẹ́ búlúù” ní agbègbè náà. Nígbà tí ó yá ojora mi túbọ̀ pọ̀ síi láàárín àwọn ọkọ̀ tí ń lọ tí ń bọ̀; ó dàbí ẹni pé táyà iwájú kẹ̀kẹ́ mi ń gbọ̀npẹ̀pẹ̀ léraléra. Ìrírí adámọlẹ́kun tí ó gbẹ̀yìn wáyé ní ọ̀sán ọjọ́ kan nígbà tí mo ṣubú sínú igbó-ọgbà kan. ‘Ó tó gẹ́ẹ́,’ ni mo sọ fún araàmi, nítorí náà mo padà síí fẹsẹ̀rìn lẹ́ẹ̀kan síi.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, nígbà tí mo lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan, ẹsẹ̀ mi bẹ̀rẹ̀ síí yẹ̀, nígbà tí ó sì yá wọ́n ṣe iṣẹ́-abẹ méjì fún mi níbi ìdèpọ̀-oríkèé ìgbaròkó mi. Mo ń ṣe dáradára lẹ́yìn iṣẹ́-abẹ náà títí di ìgbà tí ajá ńlá kan gbé mi lulẹ̀. Èyí mú kí ìtọ́jú síwájú síi pọndandan, láti ìgbà náà wá ni mo sì ti nílò ohun tí mo lè fi máa rìn káàkiri. Èrò-inú mi ṣì jípépé gan-⁠an. Ṣe ni ó rí bí ọ̀rẹ́ mi kan ti sọ ọ́: “Ó dàbí ẹní pé ara rẹ̀ tí ń gbó kò lè ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú èrò-inú rẹ tí ó ṣì jẹ́ ti èwe.”

Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mo ti ríi tí àwọn ìjọ tí ó wà ní Adelaide ń dàgbà, ń gbòòrò, tí wọ́n sì ń bí àwọn ìjọ mìíràn. Lẹ́yìn náà, ní 1983, nígbà tí mo di ẹni ọdún 88, mo kúrò ní Adelaide láti lọ gbé pẹ̀lú ìdílé kan ní Kyabram ní ìpínlẹ̀ Victoria, níbi tí mo ti lo ọdún mẹ́wàá tí ó kún fún ayọ̀, mò ṣi ń gbìyànjú láti jáde lọ sínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá; àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ máa ń fi ọkọ̀ gbé mi káàkiri láti bẹ àwọn tí ń gba ìwé-ìròyìn lọ́wọ́ mi déédéé wò. Àwọn ènìyàn yẹn máa ń fi inúrere wá sídìí ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ náà kí n baà lè bá wọn sọ̀rọ̀.

Ní ríronúpadà sẹ́yìn sí àkókò ìwàláàyè mi tí ó ti ju ọdún 98 lọ, mo ń fi ìkúdùn rántí ọ̀pọ̀ àwọn adúróṣinṣin àti olùṣòtítọ́ tí a ti jọ yin Jehofa papọ̀, ní pàtàkì baba mi àgbàyanu. Ó dàbí ẹni pé èmi ni mo gbé pẹ́ láyé ju gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ mi nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ẹ sì wo ìdùnnú-ayọ̀ náà tí ń dúró dè mí nígbà tí a bá tún mú mi wà papọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìrètí ẹ̀bùn-eré-ìje ìyè nínú Ìjọba Ọlọrun ní ọ̀run, ìṣúra kan tí ìníyelórí rẹ̀ tayọlọ́lá ni nítòótọ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Mo ṣèrìbọmi ní April 22, 1919

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Mo ṣì láyọ̀ láti máa ṣiṣẹ́sin Jehofa bí mo ti ń súnmọ́ 100 ọdún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́