Ìtàn Ìgbésí Ayé
Ẹ̀kọ́ Tí Mo Ti Ń Gbà Láti Kékeré
GẸ́GẸ́ BÍ HAROLD GLUYAS ṢE SỌ Ọ́
Ó ti lè ní àádọ́rin ọdún báyìí tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé. Ilé ìdáná màmá mi ni mo jókòó sí tí mò ń wo ìwé pélébé kan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ náà “Ceylon Tea” sí lára. Wọ́n tún ya àwòrán àwọn ọmọbìnrin sára páálí tíì náà, àwọn ọmọbìnrin náà ń ṣa ewé tíì nínú oko kan ní Ceylon (tá a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Sri Lanka báyìí). Ibi tí wọ́n ti ń ṣa ewé tíì yìí jìnnà gan-an sí ilé wa ní Gúúsù Ọsirélíà tó jẹ́ aṣálẹ̀, àwòrán náà sì mú kí n máa ronú nípa bí ibẹ̀ ṣe rí. Mò ń sọ lọ́kàn ara mi pé orílẹ̀-èdè Ceylon á lẹ́wà á sì dùn ún gbé! Mi ò mọ̀ nígbà yẹn pé mo ṣì máa lọ fi ọdún márùndínláàádọ́ta ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní erékùṣù rírẹwà yẹn.
OṢÙ April ọdún 1922 ni wọ́n bí mi, ayé ìgbà tiwa sì yàtọ̀ gan-an sí ti òde òní. Ìdílé wa ní oko ọkà kan nítòsí Kimba, àgbègbè àrọko kan tó jìnnà, tó wà láàárín kan ní ilẹ̀ Ọsirélíà, ó sì wà ní ìpẹ̀kun aṣálẹ̀ Ọsirélíà ní ìhà gúúsù. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń yọ wa lẹ́nu, bíi ọ̀dá, kòkòrò tó ń bá nǹkan jẹ́, ooru sì máa ń mú gan-an. Màmá mi máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára kó lè tọ́jú bàbá mi àtàwa ọmọ mẹ́fà nínú ilé wa kékeré tá a fi páànù ṣe.
Àmọ́, ibi téèyàn ti lómìnira láti ṣeré dáadáa ni mo ka àgbègbè àrọko tá à ń gbé yẹn sí. Mo rántí pé nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún mi nígbà tí mo bá rí agbo akọ màlúù tó lágbára bí wọ́n ṣe ń fa àwọn igi kéékèèké tó wà nínú oko tu dànù tí mo sì tún ń gbọ́ ariwo ìjì tó máa ń gba gbogbo àgbègbè àrọko náà kan. Nítorí náà, mo lè sọ pé ẹ̀kọ́ mi ti bẹ̀rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí n tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé kékeré tó jẹ́ ìrìn kìlómítà márùn-ún sí ilé wa. Tíṣà kan ṣoṣo péré ló ń kọ́ gbogbo ọmọ ilé ìwé náà.
Àwọn òbí mi kì í fọ̀rọ̀ ìsìn ṣeré rárá, àmọ́ wọn ò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì rí láyé wọn, olórí ohun tó sì fà á ni pé abúléko tá à ń gbé jìnnà sílùú ibi tí ṣọ́ọ̀ṣì wà. Síbẹ̀ náà, làwọn ọdún 1930, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ àsọyé Bíbélì tí Judge Rutherford máa ń sọ, èyí tí ilé iṣẹ́ rédíò tó wà nílùú Adelaide máa ń gbé jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Oníwàásù tó kàn ń gbé nílùú Adelaide ni mo pe Judge Rutherford, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni màmá mi máa ń jókòó de ọ̀rọ̀ Judge Rutherford, á sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lórí rédíò ayé àtijọ́ oníbátìrì tá à ń lò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé rédíò náà kì í gbé ohùn rẹ̀ jáde ketekete.
Lọ́sàn-án ọjọ́ kan tí oòrùn mú janjan, ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan tó ti gbó dúró níwájú ilé wa, àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n múra dáadáa sì jáde látinú ọkọ̀ náà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Màmá mi fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ wọn, ó tún fún wọ́n ní ọrẹ owó nítorí ìwé mélòó kan tí wọ́n fún un, lójú ẹsẹ̀ ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé náà. Àwọn ìwé náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi tó fi sọ fún bàbá mi láìpẹ́ sígbà yẹn pé kó fi mọ́tò gbé òun lọ sọ́dọ̀ àwọn ará àdúgbò kóun lè máa sọ nǹkan tóun ń kọ́ fún wọn.
Àǹfààní Bíbá Àwọn Èèyàn Dáadáa Kẹ́gbẹ́
Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ipò nǹkan tí kò bára dé ní abúléko tá à ń gbé yìí mú ká kó lọ sílùú Adelaide tó wà ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà síbi tá a wà. Ìdílé wa bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí Ìjọ Adelaide tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ṣíṣí tá a ṣí kúrò ni kò jẹ́ kí n lọ sílé ìwé mọ́. Mo kúrò ní iléèwé nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, ìyẹn lẹ́yìn tí mo parí ìpele kìíní ní ilé ìwé girama. Mo jẹ́ èèyàn kan tí kì í ka nǹkan sí, èyí ì bá sì ti mú kí n pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn arákùnrin rere, ìyẹn àwọn aṣáájú ọ̀nà tàbí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, tí wọ́n fẹ́ràn mi.
Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin onítara wọ̀nyí mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tẹ̀mí. Inú mi máa ń dùn láti wà lọ́dọ̀ wọn, bí wọ́n sì ṣe ń ṣiṣẹ́ kára wù mí gan-an. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ṣe ìfilọ̀ kan ní àpéjọ àgbègbè tá a ṣe ní Adelaide lọ́dún 1940 pé káwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, mi ò mọ̀gbà tí mo lọ forúkọ sílẹ̀. Mi ò tíì ṣèrìbọmi lákòókò náà, mi ò sì tíì fi bẹ́ẹ̀ mọ bá a ṣe ń wàásù. Síbẹ̀ náà, ní ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ní kí n lọ bá àwọn aṣáájú ọ̀nà mélòó kan tó wà ní Warrnambool, ìyẹn ìlú kan tó wà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà sí ìlú Adelaide, lágbègbè ìpínlẹ̀ Victoria.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo kọ́kọ́ ń ṣiyèméjì níbẹ̀rẹ̀, kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìsìn pápá, inú mi sì dùn pé ìfẹ́ yẹn ò tutù látìgbà yẹn. Ní tòótọ́, ìgbà yẹn jẹ́ àkókò ìyípadà ńlá fún mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí. Mo wá mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn sún mọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Mo sì wá rí ọ̀nà tí àpẹẹrẹ rere irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè gbà mú kéèyàn máa ṣe dáadáa béèyàn ò tiẹ̀ kàwé púpọ̀, mo tún rí i bí àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ ṣe lè ṣe wá láǹfààní títí ọjọ́ ayé wa.
Àdánwò fún Mi Lókun
Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ni Ìjọba fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Nítorí pé mi ò mọ ohun tí ǹ bá ṣe, ni mo bá lọ béèrè lọ́wọ́ àwọn ará pé kí ni kí n ṣe, wọ́n sọ fún mi pé kò sófin tó ní kéèyàn máà bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Bí èmi àtàwọn aṣáájú ọ̀nà mìíràn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti ojúlé dé ojúlé nìyẹn, tá à ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ṣókí látinú Bíbélì. Èyí fún mi lókun láti kojú àdánwò tí ń bẹ níwájú.
Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn ìgbà yẹn ni mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, wọ́n sì sọ pé kí n wá wọṣẹ́ ológún. Èyí jẹ́ kí n láǹfààní láti gbèjà ìgbàgbọ́ mi níwájú àwọn ọ̀gá sójà bíi mélòó kan àti níwájú adájọ́. Lákòókò tí mò ń wí yìí, nǹkan bí ogún arákùnrin ló wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nílùú Adelaide nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi sọ èmi náà sẹ́wọ̀n pẹ̀lú wọn. Wọ́n lò wá bí ẹrú, à ń fọ́ òkúta, a sì ń tún ojú ọ̀nà ṣe. Èyí mú kí n ní àwọn ànímọ́ bíi ìfaradà àti ìforítì. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ìwà ọmọlúwàbí wa àti ìṣòtítọ́ wa mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fi ọ̀wọ̀ wa wọ̀ wá.
Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ ní nǹkan bí oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo wá ń jẹ́ oúnjẹ tó dára, mo sì padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣùgbọ́n, ó ṣọ̀wọ́n láti rẹ́ni bá ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lákòókò náà, nítorí èyí wọ́n ní kí èmi nìkan lọ máa wàásù lábúlé kan tó jìnnà rere ní Gúúsù orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Mo gbà pé máa lọ, mo sì wọ ọkọ̀ òkun lọ sí ilẹ̀ Yorke tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po, mo sì kó àwọn nǹkan tí màá máa lò fún iṣẹ́ ìwàásù dání àti kẹ̀kẹ́ kan. Nígbà tí mo débẹ̀, ìdílé kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì júwe ilé àgbàwọ̀ kan fún mi níbi tí obìnrin onínúure kan ti mú mi bí ọmọ. Lójú mọmọ, màá gun kẹ̀kẹ́ gba ojú ọ̀nà eléruku láti lọ wàásù làwọn ìlú kékeré tó wà káàkiri ilẹ̀ tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po náà. Kí n sì lè wàásù láwọn ibi tó jìnnà rere, mo máa ń sún mọ́jú làwọn hòtẹ́ẹ̀lì kékeré tàbí ilé àgbàwọ̀ nígbà míì. Lọ́nà yìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà ni mo gun kẹ̀kẹ́ lọ, mo sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí alárinrin. Mi ò ráhùn pé èmi nìkan ló ń dá ṣe iṣẹ́ ìsìn, bí mo sì ṣe ń rí ọwọ́ Jèhófà lára mi, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń sún mọ́ ọn.
Bí Mo Ṣe Borí Èrò Pé Mi Ò Tóótun
Ní ọdún 1946, mo gba lẹ́tà tí wọ́n fi ní kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ fáwọn ará (alábòójútó àyíká là ń pè é nísinsìnyí). Iṣẹ́ náà gba pè kí n máa bẹ àwọn ìjọ wo ní àyíká kan. Ká sòótọ́, iṣẹ́ náà ò rọrùn rárá. Lọ́jọ́ kan, mo gbọ́ tí arákùnrin kan sọ pé, “Harold ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ, àmọ́ tó bá jẹ́ iṣẹ́ ìwàásù ni, ó mọ̀ nípa ẹ̀ gan-an.” Ìṣírí ńlá ni ọ̀rọ̀ arákùnrin yìí jẹ́ fún mi. Mo mọ àwọn ibi tó kù sí fún mi tó bá di pé ká sọ̀rọ̀ tàbí ká ṣe ètò nǹkan, síbẹ̀ mo gbà pé iṣẹ́ ìwàásù ni olórí iṣẹ́ àwa Kristẹni.
Ní ọdún 1947, inú wa dùn gan-an nígbà tí arákùnrin Nathan Knorr àti arákùnrin Milton Henschel wá sọ́dọ̀ wa láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn téèyàn máa wá láti orílé-iṣẹ́ lẹ́yìn tí Arákùnrin Rutherford ti wá lọ́dún 1938. A ṣe àpéjọ àgbègbè ńlá kan nílùú Sydney nígbà ìbẹ̀wò náà. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, èmi náà nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ táwọn míṣọ́nárì máa ń gbà nílé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, ìyẹn Watchtower Bible School of Gilead ní Gúúsù Lansing, nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwa kan lára àwọn tó wá sí àpéjọ náà rò pé bóyá ó máa gba pé kéèyàn kàwé gan-an kí wọ́n tó lè ní kó wá sílé ẹ̀kọ́ náà. Àmọ́, Arákùnrin Knorr sọ pé tá a bá lè ka àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ tá a sì lè rántí kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀, á jẹ́ pé a lè ṣe dáadáa nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì nìyẹn.
Èrò mi ni pé bí mi ò ṣe kàwé púpọ̀ yẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n pè mí sílé ẹ̀kọ́ náà. Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, ẹnu yà mi nígbà tí wọ́n ní kí n kọ̀wé pé mo fẹ́ wá sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gbà mí sílé ẹ̀kọ́ náà, mo lọ sí kíláàsì kẹrìndínlógún lọ́dún 1950. Lílọ tí mo lọ sílé ẹ̀kọ́ náà jẹ́ nǹkan àgbàyanu tó mú kí ń túbọ̀ nígboyà sí i. Ó jẹ́ kí n mọ̀ dájú pé kì í ṣe kéèyàn kàwé ni olórí ohun tó máa mú kéèyàn ṣe àṣeyọrí. Dípò ìyẹn, kéèyàn tẹra mọ́ nǹkan, kó sì jẹ́ onígbọràn ni olórí ohun tó máa mú kó ṣe àṣeyọrí. Àwọn olùkọ́ wá gbà wá nímọ̀ràn pé ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe. Ìmọ̀ràn wọn tí mo tẹ̀ lé mú kí n tẹ̀ síwájú dáadáa, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti lè fojú sí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ dáadáa.
A Ṣí Láti Orílẹ̀-Èdè Ọsirélíà Lọ Sí Ilẹ̀ Ceylon
Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n rán èmi àtàwọn arákùnrin méjì láti Ọsirélíà lọ sí orílẹ̀-èdè Ceylon (tó ń jẹ́ Sri Lanka báyìí). A dé Colombo tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè náà ní oṣù September 1951. Ooru mú gan-an, ojú ọjọ́ sì máa ń mú kéèyàn làágùn, oríṣiríṣi nǹkan tá ò rí rí, tá ò sì gbọ́ rí la bá pàdé, a sì tún ń gbóòórùn oríṣiríṣi nǹkan. Bá a ṣe sọ̀ kalẹ̀ látinú ọkọ̀ òkun náà, ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn lórílẹ̀-èdè náà kí mi káàbọ̀, ló bá fún mí níwèé pélébé kan tí wọ́n fi ń sọ fáwọn aráàlú nípa àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí yóò wáyé ní gbàgede ìlú lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e. Ẹnu yà mí nígbà tí mo rí i pé orúkọ mi ni wọ́n kọ́ sórí ìwé pélébé náà pé ó máa sọ àsọyé náà! Ẹ wò ó, ọkàn mi ò balẹ̀. Àmọ́, àwọn ọdún tí mo ti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ti jẹ́ kí n mọ́ bá a ṣe ń tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fúnni. Torí náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo sọ àsọyé náà láìsí ìṣòro kankan. Àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàwọn arákùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó ń gbé ilé míṣọ́nnárì ní Colombo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Sinhala tó ṣòro kọ́, a sì tún jọ ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Àwa nìkan ló máa ń dá ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà, inú wa sì dùn pé àwọn tó ń gbé nílùú yẹn máa ń bọ̀wọ̀ féèyàn, wọ́n sì tún lẹ́mìí àlejò ṣíṣe. Kò pẹ́ tí iye àwọn tó ń wá sípàdé bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i.
Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa arábìnrin arẹwà kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sybil. Mo bá arábìnrin náà pàdé nínú ọkọ̀ òkun tí mo wọ̀ nígbà tí mò ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ó fẹ́ lọ ṣe ìpàdé àgbáyé ní New York. Nígbà tó ṣe, arábìnrin náà lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti kíláàsì kọkànlélógún, wọ́n sì rán an lọ sí orílẹ̀-èdè Hong Kong lọ́dún 1953. Mo pinnu láti máa kọ lẹ́tà sí i, bá a sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa nìyẹn títí di ọdún 1955 nígbà tí Sybil wá bá mi ní Ceylon, níbi tá a ti ṣègbéyàwó.
Ìlú Jaffna ni ibi tí wọ́n kọ́kọ́ rán wa lọ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya míṣọ́nnárì, ìlú náà wà nípẹ̀kun àríwá orílẹ̀-èdè Sri Lanka. Láàárín àwọn ọdún 1950, rògbòdìyàn ìṣèlú bẹ̀rẹ̀ sí í pín ẹ̀ya Sinhala àti ti Tamil, èyí ló sì wá mú kí wọ́n máa bá ara wọn jagun ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ó mà múnú ẹni dùn gan-an o láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ Sinhala àti Tamil tí wọ́n ń dáàbò bo ara wọn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù lákòókò tí nǹkan ò rọgbọ yẹn! Àwọn àdánwò wọ̀nyẹn sọ ìgbàgbọ́ àwọn ará dọ̀tun, ó sì mú kó túbọ̀ lágbára sí i.
Iṣẹ́ Ìwàásù àti Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Ní Sri Lanka
Ó gba sùúrù gan-an kí àgbègbè táwọn onísìn Híńdù àti Mùsùlùmí ń gbé tóó mọ́ wa lára. Síbẹ̀ náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí àwọn àṣà àti ànímọ́ wọn tó fani mọ́ra. Nítorí pé àwọn àjèjì kì í sábà wọ bọ́ọ̀sì ìgboro, tá a bá lọ wọ̀ ọ́, ńṣe làwọn èèyàn máa ń fi wá ṣèran wò. Sybil wá pinnu pé tí wọ́n bá tẹjú mọ́ òun, ẹ̀rín lòun máa rín sí wọn. Inú wa máa ń dùn gan-an pé àwọn èèyàn tó fẹ́ mọ irú ẹni tá a jẹ́ yìí máa ń rẹ́rìn ín sí wa padà!
Lọ́jọ́ kan, àwọn ẹ̀ṣọ́ dá wa dúró lójú ọ̀nà. Lẹ́yìn tí ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ náà béèrè lọ́wọ́ wa ibi tá a ti ń bọ̀ àti ibi tá à ń lọ, ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn nǹkan tí ò kàn án.
Ó bi mi pé, “Ta lobìnrin yìí?”
Mo ní “ìyàwó mi ni.”
Ó ní “Ó ti tó ìgbà wo tẹ́ ẹ ti fẹ́ra yín?”
Mo sọ pé “ọdún kẹjọ rèé tá a ti fẹ́ra wa.”
Ó ní “Ǹjẹ́ ẹ lọ́mọ kankan?”
Mo ni “Rárá, a ò lọ́mọ kankan.”
Ó ní “Mo gbé, ẹ ò tíì lọ́mọ! Ṣé ẹ ti lọ rí dókítà?”
Bí wọ́n ṣe ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wa yẹn kọ́kọ́ yà wá lẹ́nu, àmọ́ nígbà tó yá, a wá rí i pé ìfẹ́ àtọkànwá táwọn ará àdúgbò yẹn ní séèyàn ló mú kí wọ́n máa béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tó dára jù lọ tí wọ́n ní. Tẹ́nì kan bá dúró sí gbàgede ìlú fún ìṣẹ́jú mélòó kan, ó lè ṣàdédé rí ẹnì kan tó máa wá bá a tá sì wá bi í pé bóyá kóun ràn án lọ́wọ́.
Àwọn Ìyípadà Àtàwọn Nǹkan Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Sẹ́yìn
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, oríṣiríṣi iṣẹ́ la ṣe yàtọ̀ sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì tá a ṣe lórílẹ̀-èdè Sri Lanka. Mo ṣe alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè, mo tún fìgbà kan wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Nígbà tó di ọdún 1996, mo lè lẹ́ni àádọ́rin ọdún. Ó lé lọ́dún márùndínláàádọ́ta tí mo fi ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Sri Lanka. Ogún èèyàn ló wà nípàdé àkọ́kọ́ ti mo lọ nílùú Colombo. Àmọ́, àwọn tó ń wá sípàdé ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [3,500] báyìí! Èmi àti Sybil ń wo ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àti ọmọ ọmọ wa nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló ṣì wà láti ṣe káàkiri orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ pé àwọn tó kéré sí wa lọ́jọ́ orí ni wọ́n ní okun àti agbára láti ṣe é. Nítorí èyí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ pé ká padà sí orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, a sì fara mọ́ ọn. Èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn tọkọtaya tí wọ́n tóótun tí wọ́n sì kéré sí wa lọ́jọ́ orí láti lọ rọ́pò wa ní orílẹ̀-èdè Sri Lanka gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì.
Mo ti lé lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gọ́rin báyìí, inú èmi àti Sybil sì dùn pé ara wa ṣì le láti máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe lọ ní Adelaide, ìyẹn ìlú tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń mú kí ọpọlọ wa jí pépé ká sì mọ ọwọ́ yí padà. Ó sì tún ti ràn wá lọ́wọ́ láti mú ara wa ba onírúurú ipò mu lórílẹ̀-èdè tá a wà yìí.
Ọwọ́ Jèhófà ò kúrò lára wa, ó ń pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa nípa tara, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin nínú ìjọ tá a wà fẹ́ràn wa gan-an, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n fún mi ní iṣẹ́ tuntun kan. Wọ́n ní kí n máa ṣe akọ̀wé ìjọ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, mo wá rí i pé bí mo ṣe ń sapá láti máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ kò dáwọ́ dúró. Nígbà tí mo ronú kan àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn látọdún wọ̀nyẹn, gbogbo ìgbà lẹ́nu máa ń yà mi pé èmi ọmọ kékeré tí kì í ka nǹkan sí, tó jẹ́ ọmọ oko nígbà yẹn lọ́hùn-ún ló wá gba ẹ̀kọ́ àtàtà yìí, ìyẹn ẹ̀kọ́ tí mo ti ń gbà láti kékeré.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwa rèé lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1955
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Èmi àti arákùnrin Rajan Kadirgamar tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ rèé lóde ẹ̀rí lọ́dún 1957
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi àti Sybil rèé lónìí