ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/1 ojú ìwé 12-16
  • A Mọ Ohun Tó Tọ́, A Sì Ṣe É

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Mọ Ohun Tó Tọ́, A Sì Ṣe É
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìṣòro Tó Dán Ìgbàgbọ́ Mi Wò
  • Bá A Ṣe Wọnú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò-Kíkún
  • Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì
  • A Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù Ní Pẹrẹu
  • Gbogbo Ìgbà La Máa Ń Rìnrìn Àjò
  • Àwọn Ìjọ Ṣe Ohun Tó Bá Ìlànà Ètò Jèhófà Mu
  • A Kọ́ Bẹ́tẹ́lì Tó Tóbi Sí I, Nǹkan sì Tún Yí Padà fún Wa
  • Gẹgẹ Bi Opó kan, Mo Rí Ìtùnú Tootọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/1 ojú ìwé 12-16

Ìtàn Ìgbésí Ayé

A Mọ Ohun Tó Tọ́, A Sì Ṣe É

GẸ́GẸ́ BÍ HADYN SANDERSON TI SỌ Ọ́

Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nígbà kan pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòhánù 13:17) Òótọ́ ni pé a lè mọ ohun tó tọ́, àmọ́ nígbà míì, àtiṣé e máa ń ṣòro! Àmọ́, lẹ́yìn tí mo ti lo ohun tó lé ní ọgọ́rin ọdún láyé, tí mo sì lo ogójì lára rẹ̀ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó dá mi lójú pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí. Ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run sọ máa ń mú ayọ̀ wá lóòótọ́. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.

LỌ́DÚN 1925, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ta, àwọn òbí mi lọ síbi àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì nílùú wa, ìyẹn Newcastle, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Àsọyé yẹn, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé” jẹ́ kó dá màmá mi lójú pé òun ti rí òtítọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí ìfẹ́ bàbá mi fi tutù. Ó ní màmá mi ò gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀sìn tuntun tó rí yìí, ó sì sọ pé òun á fi í sílẹ̀ bí kò bá jáwọ́. Màmá mi fẹ́ràn bàbá mi ó sì fẹ́ kí ìdílé wa wà níṣọ̀kan. Síbẹ̀, ó mọ̀ pé ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ó sì pinnu láti ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. (Mátíù 10:34-39) Bí bàbá mi ṣe fi wá sílẹ̀ nìyẹn, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo sì máa ń rí i lẹ́yìn ìgbà yẹn.

Nígbà tí n bá ronú padà sẹ́yìn, ńṣe ni jíjẹ́ tí màmá mi jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run máa ń jọ mí lójú. Ìpinnu tó ṣe yẹn mú kí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Beulah lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tó lárinrin nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ìpinnu yẹn tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé, tá a bá ti mọ ohun tó dára, a gbọ́dọ̀ sapá láti ṣe é.

Àwọn Ìṣòro Tó Dán Ìgbàgbọ́ Mi Wò

Gbágbáágbá làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún, dúró ti ìdílé wa. Ìyá ìyá mi kó wá sílé wa, òun náà sì di Ẹlẹ́rìí. Òun àti màmá mi jọ máa ń lọ sóde ìwàásù nígbà gbogbo, àwọn èèyàn sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn gan-an nítorí pé ìrísí wọn dára, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn.

Lákòókò tí mò ń sọ yìí, àwọn arákùnrin tó dàgbà lọ́jọ́ orí nínú ìjọ bójú tó mi gan-an, wọ́n sì kọ́ mi láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye. Kò pẹ́ rárá tí mo sì fi mọ bí wọ́n ṣe ń lo káàdì ìjẹ́rìí láti fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lọ́nà rírọrùn nínú ilé àwọn èèyàn. Mo tún ń lo ẹ̀rọ giramafóònù kékeré láti fi gbé àsọyé Bíbélì tí wọ́n gbà sílẹ̀ jáde káwọn èèyàn lè gbọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni mo sì máa ń kópa nínú títò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láwọn òpópónà ńlá nílùú wa, tí mo máa ń gbé àkọlé fífẹ̀ kan sọ́rùn. Èyí kò rọrùn fún mi rárá, nítorí pé ẹ̀rù àwọn èèyàn máa ń bà mí. Àmọ́ mo mọ ohun tó tọ́ mo sì pinnu láti ṣe é.

Lẹ́yìn tí mo parí ẹ̀kọ́ mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní báńkì kan, èyí sì gba pé kí n máa rìnrìn àjò lọ sáwọn ẹ̀ka báńkì tó wà jákèjádò ìpínlẹ̀ New South Wales. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí lápá ibí yìí, ẹ̀kọ́ tí mo ti gbà ràn mí lọ́wọ́, kò jẹ́ kí iná ìgbàgbọ́ mi kú. Màmá mi máa ń kọ àwọn lẹ́tà tó ń fún mi níṣìírí sí mi, èyí sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi dúró digbí.

Àwọn lẹ́tà yẹn bọ́ sásìkò gan-an, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ogun Àgbáyé Kejì ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n sì pè mí fún iṣẹ́ ológun. Ẹni tó jẹ́ ọ̀gá báńkì náà máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì gan-an, ó sì tún jẹ́ ọ̀gá ológun kan nílùú náà. Nígbà tí mo ṣàlàyé fún un pé mi ò lè lọ́wọ́ sógun nítorí pé Kristẹni ni mí, ó sọ fún mi pé ọ̀kan ni màá mú nínú méjèèjì, yálà ki n fi ìsìn mi sílẹ̀ tàbí kí n fi iṣẹ́ báńkì sílẹ̀! Ìgbà tí mo lọ fara hàn níbi tí wọ́n ti ń gba àwọn èèyàn síṣẹ́ ológun ni iná wá jó dórí kókó. Ọ̀gá yẹn wà níbẹ̀, ńṣe ló sì tẹjú mọ́ mi bí mo ti ń lọ sídìí tábìlì tí wọ́n ti ń forúkọ àwọn èèyàn sílẹ̀. Nígbà tí mo kọ̀ tí mi ò fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà, ó hàn lójú àwọn aláṣẹ náà pé inú bí wọn gan-an. Àkókò yẹn ò rọrùn fún mi rárá, àmọ́ mo pinnu pé ohun tó tọ́ ni màá ṣe. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, mi ò gbọ̀n jìnnìjìnnì, mi ò sì yíhùn padà. Nígbà tó wá hàn sí mi lẹ́yìn náà pé àwọn èèyànkéèyàn kan ń wá mi, kíá ni mo palẹ̀ ẹrù mi mọ́ tí mo sì yára wọ ọkọ̀ ojú irin jáde kúrò nílùú náà!

Lẹ́yìn tí mo padà sílùú Newcastle, mo fojú ba ilé ẹjọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin méje mìíràn táwọn náà kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Adájọ́ náà dá ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára fún wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀wọ̀n kì í ṣe ibi tó dára, ṣíṣe ohun tó tọ́ mú èrè wá. Lẹ́yìn tí wọ́n dá wa sílẹ̀, Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hilton Wilkinson tá a jọ wà ní yàrá kan náà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n sọ pé kí n wá máa bá òun ṣiṣẹ́ níléeṣẹ́ fọ́tò yíyà òun. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ẹni tó wá di aya mi, ìyẹn Melody, tó ń ṣiṣẹ́ olùgbàlejò níbẹ̀. Kété tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.

Bá A Ṣe Wọnú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò-Kíkún

Lẹ́yìn témi àti Melody ṣègbéyàwó, a ṣí ṣọ́ọ̀bù fọ́tò tiwa sílùú Newcastle. Kò-pẹ́-kò-jìnnà, iṣẹ́ tí à ń rí gbà pọ̀ débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóbá fún ìléra wa àti àjọṣẹ wa pẹ̀lú Jèhófà. Àárín àkókò yẹn ni arákùnrin Ted Jaracz, tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà nígbà yẹn, tó sì ti di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí báyìí, bá wa sọ̀rọ̀ lórí bá a ṣe lè túbọ̀ kópa tó pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lẹ́yìn ìjíròrò yẹn, a pinnu láti gbé iléeṣẹ́ wa tà àti pé a ò ní lé nǹkan tara mọ́. Lọ́dún 1954, a ra ilé alágbèérìn kan a sì ṣí lọ sílùú Ballarat ní ìpínlẹ̀ Victoria, bá a ṣe di aṣáájú-ọ̀nà nìyẹn, ìyẹn àwọn oníwàásù alákòókò-kíkún.

Bá a ti ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọ kékeré tó wà nílùú Ballarat, Jèhófà fi èrè sí iṣẹ́ náà. Láàárín ọdún kan àtààbọ̀, àwọn tó ń wá sípàdé pọ̀ sí i látorí èèyàn mẹ́tàdínlógún sí àádọ́rin èèyàn. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n ké sí wa pé ká wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká ní ìpínlẹ̀ South Australia. Odindi ọdún mẹ́ta la fi ń bẹ àwọn ìjọ wò nílùú Adelaide àtàwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń ṣe wáìnì àtàwọn ọtí olómi ọsàn nítòsí Odò Murray, a sì gbádùn iṣẹ́ ìsìn náà gan-an. Ìgbésí ayé wa ti yí padà pátápátá! Ńṣe ni inú wa ń dùn bá a ti ń sìn pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n. Èrè ńlá gbáà lèyí jẹ́ fún ṣíṣe ohun tá a mọ̀ pé ó tọ́!

Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì

Lọ́dún 1958, a sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Ọsirélíà pé a fẹ́ lọ sí Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Àtọ̀runwá” tí yóò wáyé nílùú New York lópin ọdún yẹn. Nígbà tí wọ́n máa fèsì, fọ́ọ̀mù tí wọ́n fi ń gbani wọlé sílé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì tá a mọ̀ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí wa. Níwọ̀n báwa méjèèjì sì ti lé lẹ́ni ọdún márùndínlógójì nígbà yẹn, a ronú pé a ti kọjá ọjọ́ orí ẹni tó lè lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Síbẹ̀, a fi fọ́ọ̀mù wa ránṣẹ́ wọ́n sì pè wá sí kíláàsì kejìlélọ́gbọ̀n. Ìgbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ti dé ìdajì ni wọ́n ti sọ ibi tá a ti máa lọ sìn fún wa. Ilẹ̀ Íńdíà ni! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù kọ́kọ́ bà wá, síbẹ̀ a fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, tayọ̀tayọ̀ la sì fi gbà láti lọ síbi tí wọ́n yàn wá sí náà.

Ọkọ̀ òkun la wọ̀, a sì gúnlẹ̀ sílùú Bombay (tó ti di Mumbai báyìí) láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kan lọ́dún 1959. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lébìrà sùn sílẹ̀ káàkiri níta gbangba ní èbútékọ̀ náà. Bẹ́ẹ̀ la sì ń gbọ́ àwọn òórùn kan tó ṣàjèjì. Nígbà tí oòrùn yọ, èyí jẹ́ ká mọ ohun tá a máa fara dà. A ò tíì rí irú ooru bẹ́ẹ̀ rí! Tọkọtaya míṣọ́nárì kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Lynton àti Jenny Dower tá a ti jọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà nílùú Ballarat ló wá pàdé wa. Wọ́n mú wa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Íńdíà tó wà nínú ilé kan térò pọ̀ sí tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí àárín ìlú. Àwọn ẹni mẹ́fà tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ló ń gbébẹ̀. Arákùnrin Edwin Skinner, tó ti ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Íńdíà látọdún 1926, gbà wá nímọ̀ràn pé ká ra àpò ìkẹ́rù ńlá méjì kan tí wọ́n fi aṣọ ṣe ká tó máa lọ síbi tí wọ́n yàn fún wa. A rí irú àpò yìí lọ́wọ́ àwọn èèyàn gan-an nígbà tá a wà nínú àwọn ọkọ̀ ojú irin ilẹ̀ Íńdíà, ó sì wúlò fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ìrìn àjò tá a tún rìn lẹ́yìn náà.

Lẹ́yìn tá a ti fi odindi ọjọ́ méjì rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú irin, a dé ibi tí wọ́n yàn fún wa, ìyẹn ìlú Tiruchchirappalli tó wà ní ìpínlẹ̀ Madras (tó ti di Tamil Nadu báyìí). A dara pọ̀ mọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mẹ́ta kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íńdíà tí wọ́n ń wàásù ní àgbègbè yìí, ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] sì ni iye àwọn èèyàn ibẹ̀. A ò láwọn nǹkan amáyédẹrùn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé gbogbo owó tá a ní lọ́wọ́ kò pé dọ́là mẹ́rin owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àmọ́ nígbà tówó yẹn tán, Jèhófà ò fi wá sílẹ̀. Ẹnì kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yá wa lówó láti fi gba ilé tá a lè máa ṣèpàdé nínú rẹ̀. Nígbà kan tá ò fi bẹ́ẹ̀ ní oúnjẹ, aládùúgbò wa kan gbé ọbẹ̀ ìbílẹ̀ wá fún wa. Mo gbádùn ọbẹ̀ náà gan-an, àmọ́ ọbẹ̀ náà ta débi pé, ńṣe ni òsúkè ń gbé mi!

A Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù Ní Pẹrẹu

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn díẹ̀ nílùú Tiruchchirappalli gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, èdè Tamil lọ̀pọ̀ jù lọ ń sọ. Fún ìdí yìí, a sapá gan-an láti kọ́ bá a ṣe lè lo èdè yẹn láti gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó rọrùn lóde ìwàásù. Ìsapá yìí jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ibẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa.

A gbádùn iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé gan-an. Àwọn ará Íńdíà máa ń ṣaájò àlejò gan-an, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló sì máa ń ní ká wọlé ká wá jẹ ìpápánu díẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oòrùn máa ń mú gan-an, a mọrírì aájò wọn yìí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó máa ń dára ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ara wa ná ká to sọ ohun tá a bá wá fún wọn. Àwọn tá a fẹ́ wàásù fún sábà máa ń bi èmi àtìyàwó mi pé: “Ibo lẹ ti wá? Ṣé ẹ bímọ? Kí ló dé tẹ́ ò bímọ?” Ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ lẹ́yìn náà ni pé àwọn lè júwe dókítà tó mọṣẹ́ dáadáa fún wa! Síbẹ̀, irú àwọn ìjíròrò yìí máa ń jẹ́ ká lè sọ irú ẹni tá a jẹ́ ká sì ṣàlàyé bí iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe ti ṣe pàtàkì tó.

Ẹlẹ́sìn Híńdù lọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí à ń wàásù fún, ohun tí wọ́n sì gbà gbọ́ yàtọ̀ gan-an sí tàwọn Kristẹni. Àmọ́ dípò ká jọ máa jiyàn lórí bí ẹ̀sìn Híńdù ṣe díjú, ńṣe la kàn máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn, èyí sì mú ọ̀pọ̀ àṣeyọrí wá. Láàárín oṣù mẹ́fà péré, àwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé nílé míṣọ́nnárì wa fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún èèyàn. Onímọ̀-ẹ̀rọ lọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Nallathambi. Nígbà tó yá, òun àtọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó ń jẹ́ Vijayalayan ran nǹkan bí àádọ́ta èèyàn lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Vijayalayan tún sìn fúngbà díẹ̀ lẹ́ka iléeṣẹ́ wa ní Íńdíà.

Gbogbo Ìgbà La Máa Ń Rìnrìn Àjò

Kò tíì pé oṣù mẹ́fà tá a délẹ̀ Íńdíà tí wọ́n ké sí mi pé kí n wá di alábòójútó àgbègbè, èmi sì ni wọ́n kọ́kọ́ dìídì yàn láti ṣe iṣẹ́ yìí lórílẹ̀-èdè náà. Èyí túmọ̀ sí pé màá máa lọ jákèjádò ilẹ̀ Íńdíà, màá máa ṣètò àwọn àpéjọ, màá sì máa bá àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ń sọ èdè mẹ́sàn-án ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Iṣẹ́ ńlá gbáà ni. A di aṣọ àtàwọn nǹkan èlò mìíràn tá a máa lò fún oṣù mẹ́fà sínú àpótí onípáànù mẹ́ta àti àpò aláṣọ tá a fi ń kó nǹkan, a sì wọ ọkọ̀ ojú irin kúrò nílùú Madras (tó ti di Chennai báyìí). Níwọ̀n bí agbègbè tá a ní láti bójú tó ti fẹ̀ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún kìlómítà, gbogbo ìgbà la máa ń wà lẹ́nu ìrìn àjò. Nígbà kan, a parí àpéjọ kan nílùú Bangalore lápá gúúsù orílẹ̀-èdè náà lọ́jọ́ Sunday. A sì lọ sílùú Darjeeling tó wà nísàlẹ̀ àwọn òkè Himalaya ní apá àríwá lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e láti lọ bójú tó àpéjọ àyíká mìíràn. Ìrìn àjò lọ sí ìlú Darjeeling yìí sì tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje kìlómítà, ọkọ̀ ojú irin márùn-ún la sì wọ̀ ká tó lè débẹ̀.

Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn-àjò, a máa ń fi sinimá The New World Society in Action han àwọn èèyàn, a sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Sinimá yìí jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé káàkiri ayé làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó máa ń wá wo sinimá yìí máa ń tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn. Nígbà kan, a fi sinimá náà han àwọn èrò kan tó kóra jọ lẹ́bàá ọ̀nà. Bí sinimá náà ti ń lọ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni òjò ṣú tó sì ń bolẹ̀ sí i. Nítorí pé àwọn èrò kan ti yarí fún wa nígbà kan tá a dá sinimá náà dúró lójijì, mo pinnu pé mi ò ní dá sinimá náà dúró lọ́tẹ̀ yìí àmọ́ màá jẹ́ kó yára kánkán. Inú wa dùn pé bí òjò náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kán sílẹ̀ ni fíìmù náà parí láìsí pé a dá a dúró.

Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilẹ̀ Íńdíà lèmi àti Melody rìnrìn àjò dé. Nítorí pé oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ lágbègbè kan, ìmúra wọn, èdè wọn, àti àyíká wọn, yàtọ̀ sí ti àgbègbè mìíràn, ńṣe ló dà bíi pé à ń ti orílẹ̀-èdè kan lọ sí òmíràn. Ọ̀kankòjọ̀kan mà làwọn ohun tí Jèhófà dá o! Bákan náà lọ̀rọ̀ ṣe rí tá a bá ń sọ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Íńdíà. Nígbà kan tá a wà nínú ẹgàn kan lórílẹ̀-èdè Nepal, kedere báyìí la rí ẹkùn ńlá kan. Ẹranko tó lẹ́wà gidi ni. Rírí tá a rí i jẹ́ kó túbọ̀ wù wá gan-an láti gbé nínú Párádísè, níbi tí àlàáfíà ti máa wà láàárín àwa èèyàn àtàwọn ẹranko.

Àwọn Ìjọ Ṣe Ohun Tó Bá Ìlànà Ètò Jèhófà Mu

Láwọn àkókò yẹn, àwọn ará nílẹ̀ Íńdíà kò tíì máa tẹ̀ lé ìlànà ètò Jèhófà dáadáa. Nínú àwọn ìjọ kan, ńṣe làwọn ọkùnrin máa ń jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú ìpàdé táwọn obìnrin sì máa ń lọ jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì. Ṣàṣà ìgbà nìpàdé máa ń bẹ̀rẹ̀ lákòókò tó yẹ. Níbì kan, aago ni wọ́n máa ń lù tí wọ́n fi máa ń pe àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run wá sípàdé. Láwọn àgbègbè mìíràn sì rèé, ìgbà táwọn ará bá rí i pé oòrùn ti débì kan pàtó lójú ọ̀run ní wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ máa dé sípàdé lọ́kọ̀ọ̀kan. Ìdákúrekú sì ni àpéjọ àyíká àti ìbẹ̀wò àwọn alábòójútó àyíká. Àwọn ará fẹ́ ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ wọ́n nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́.

Lọ́dún 1959, ètò Jèhófà dá Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sílẹ̀. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí, tó wáyé lápá ibi gbogbo láyé, ran àwọn alábòójútó àyíká, àwọn míṣọ́nnárì, àtàwọn alàgbà ìjọ lọ́wọ́ láti bójú tó iṣẹ́ wọn nínú ìjọ lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i. Nígbà tí ilé-ẹ̀kọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Íńdíà lóṣù December ọdún 1961, mo ṣe olùkọ́ níbẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àǹfààní tó wá látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í tàn dé àwọn ìjọ káàkiri orílẹ̀-èdè yẹn, kíákíá làwọn ìjọ sì tẹ̀ síwájú. Gbàrà táwọn ará ti mọ ohun tó dára, ẹ̀mí Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe é.

Àwọn àpéjọ àgbáyé pàápàá tún fún àwọn ará níṣìírí ó sì mú kí wọ́n túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Èyí tó jẹ́ mánigbàgbé jù lára àwọn ìpàdé àgbègbè yẹn ni Àpéjọ Àgbáyé ti “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” tó wáyé nílùú New Delhi lọ́dún 1963. Láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ Íńdíà làwọn Ẹlẹ́rìí ti rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà wá sí àpéjọ yìí, ọ̀pọ̀ wọn ló sì jẹ́ pé gbogbo owó tí wọ́n ní nípamọ́ ni wọ́n ná sórí ìrìn àjò náà. Ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́tàlélọ́gọ́rin [583] làwọn tó wá sí àpéjọ náà láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n mìíràn. Èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Íńdíà máa pàdé àwọn arákùnrin tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n sì jọ fara rora.

Lọ́dún 1961, wọ́n ní kí èmi àti Melody wá di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Bombay, mo sì sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lẹ́yìn náà. Àwọn àǹfààní mìíràn tún yọjú lẹ́yìn èyí. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi sìn gẹ́gẹ́ bí Alábòójútó Tó Ń Bẹ Ẹ̀ka Wò jákèjádò àwọn apá ibì kan nílẹ̀ Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Nítorí pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gba iṣẹ́ ìwàásù láyè ní ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ní láti “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí [wọ́n] jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.”—Mátíù 10:16.

A Kọ́ Bẹ́tẹ́lì Tó Tóbi Sí I, Nǹkan sì Tún Yí Padà fún Wa

Nígbà tá a kọ́kọ́ dé sílẹ̀ Íńdíà lọ́dún 1959, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ó lé mẹ́rìnlá [1,514] akéde ló ń wàásù lórílẹ̀-èdè yẹn. Lónìí, wọ́n ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24,000] lọ. Láti lè bójú tó pípọ̀ táwọn akéde ń pọ̀ sí i yìí, ẹ̀ẹ̀mejì la ti kọ́ ilé Bẹ́tẹ́lì tuntun tá a sì kó lọ sínú wọn nílùú Bombay tàbí nítòsí rẹ̀. Àmọ́ nígbà tó tún di oṣù March ọdún 2002, ìdílé Bẹ́tẹ́lì tún ṣí lọ síbòmíràn. Lọ́tẹ̀ yìí, Bẹ́tẹ́lì tuntun tó tóbi tí wọ́n kọ́ sí tòsí ìlú Bangalore ni wọ́n kó lọ, ní gúúsù ilẹ̀ Íńdíà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, igba ó lé ogójì [240] làwọn tó ń gbénú Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n kọ́ lọ́nà ti ìgbàlódé yìí, díẹ̀ lára wọn sì ń túmọ̀ àwọn ìwé tá a fi ń ṣàlàyé Bíbélì sí ogún èdè.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú èmi àti Melody ti wà lọ́nà láti kó lọ sí Bẹ́tẹ́lì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sílùú Bangalore yìí, àmọ́ a ní láti padà sílẹ̀ Ọsirélíà tipátipá lọ́dún 1999 nítorí àìlera ara. Bẹ́tẹ́lì ti ìlú Sydney la ti ń sìn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kúrò ní ilẹ̀ Íńdíà, ìfẹ́ tá a ní sáwọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àtàwọn tá a ti ràn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ kò dín kù rárá. Nígbà tá a bá gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ wọn, inú wa máa ń dùn gan-an ni!

Nígbà témi àti Melody bá ronú padà sí ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún tá a ti ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún bọ̀, a mọ̀ pé Jèhófà ti bù kún wa gan-an. Ìgbà kan wà tí à ń ya fọ́tò káwọn èèyàn lè máa rántí bí wọ́n ṣe rí, àmọ́ iṣẹ́ tó ń mú kí Ọlọ́run máa rántí àwọn èèyàn tá à ń ṣe báyìí sàn jùyẹn lọ fíìfíì. Ìpinnu tá a ṣe láti fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wa ti mú ká gbádùn àwọn ohun tó ṣeyebíye gan-an! Ní tòótọ́, ayọ̀ ló máa ń já sí béèyàn bá ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́!

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÍŃDÍÀ

New Delhi

Darjeeling

Bombay (Mumbai)

Bangalore

Madras (Chennai)

Tiruchchirappalli

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Hadyn àti Melody lọ́dún 1942

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìdílé Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Íńdíà lọ́dún 1975

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́