ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/1 ojú ìwé 26-29
  • Mo Dánìkan Wà Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Tì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Dánìkan Wà Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Tì
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣalábàápàdé Òtítọ́ Bibeli Lákọ̀ọ́kọ́
  • Nísinsìnyí Mo Dánìkan Wà Níti Gidi
  • Àjọṣepọ̀ Pẹ̀lú Ètò-Àjọ Náà
  • Àpéjọpọ̀ àti, Nígbẹ̀yìn Gbẹ́yín, Ìrìbọmi
  • Pípadà Sí Òkè-Ńlá Gambier
  • Iṣẹ́ Àyànfúnni Titun
  • Iṣẹ́-Ìsìn Alákòókò Kíkún Tí Ń Bá A Nìṣó
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Mo Rí Ìṣúra Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Tayọlọ́lá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/1 ojú ìwé 26-29

Mo Dánìkan Wà Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Tì

GẸ́GẸ́ BÍ ADA LEWIS ṢE SỌ Ọ́

Mo ti máa ń ní ìtẹ̀sí láti dá wà. Mo máa ń fẹ́ láti ṣe tinú mi—nígbà mìíràn àwọn mìíràn máa ń pè é ní oríkunkun—nínú ohun gbogbo tí mo bá ṣe. Mo mọ bí ó ṣe rọrùn tó, pẹ̀lú, láti jẹ́ ẹni tí kìí fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ìwà ànímọ́ yìí sì ti fa ìṣòro fún mi jálẹ̀ àwọn ọdún.

SÍBẸ̀, mo dúpẹ́ pé Jehofa Ọlọrun kò tí ì kọ̀ mí sílẹ̀ nítorí àwọn àlèébù tí ń bẹ nínú àkópọ̀ ànímọ́ mi. Nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti tún àkópọ̀ ànímọ́ mi ṣe mo sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́sin ire Ìjọba rẹ̀ fún nǹkan bí 60 ọdún. Láti ìgbà ọmọdé, mo ti jẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ẹṣin, ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ní ṣíṣàkóso ohun tí a lè pè ní ọkàn líle mi ti sábà rán mi létí bí a ṣe lè lo ìjánu láti ṣàkóso ẹṣin.

A bí mi sí ẹ̀bá erékùṣù rírẹwà kan tí ó jẹ́ aláwọ̀ búlúù ní Òkè-Ńlá Gambier ní South Australia ní 1908. Àwọn òbí mi ní oko tí a ti ń fún wàrà màlúù, èmi sì ni ọmọbìnrin tí ó dàgbà jùlọ nínú ọmọ mẹ́jọ. Bàbá wa kú nígbà tí gbogbo wa ṣì kéré. Ìyẹn fi ẹrù-iṣẹ́ bíbójútó oko náà lé mi lọ́wọ́, níwọ̀n bí àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjì ti níláti máa ṣiṣẹ́ níbi tí ó jìnnà sí ilé láti lè mú owó wọlé fún ìdílé náà. Ìgbésí-ayé ní oko náà jẹ́ èyí tí ń gba àkókò púpọ̀, iṣẹ́ tí ó nira ni.

Ṣíṣalábàápàdé Òtítọ́ Bibeli Lákọ̀ọ́kọ́

Ìdílé wa máa ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian, a sì jẹ́ mẹ́ḿbà tí ń ṣe ìsìn náà lójú méjèèjì. Mo di olùkọ́ni ní ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́ Sunday mo sì fi ọwọ́ dan-in dan-in mú ẹrù-iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ọmọdé ní ohun tí mo gbàgbọ́ pé ó jẹ́ ohun tẹ̀mí tí ó sì tọ̀nà níti ìwàrere.

Ní 1931 bàbá mi àgbà kú, àwọn ìwé mélòókan tí ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà J. F. Rutherford kọ sì wà lára àwọn ohun-ìní rẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ka Duru Ọlọrun àti Creation, bí mo sì ṣe ń kà á sí, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnu ń yà mí síi láti kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun púpọ̀ tí mo gbàgbọ́ ti mo sì ti fi ń kọ́ àwọn ọmọdé ni Bibeli kò tì lẹ́yìn.

Ó bà mí lẹ́rù láti kẹ́kọ̀ọ́ pé ọkàn ẹ̀dá ènìyàn kì í ṣe àìleèkú, pé àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jùlọ kì yóò lọ sí ọ̀run nígbà tí wọ́n bá kú, àti pé kò sí ìjìyà ayérayé fún àwọn ẹni búburú nínú hẹ́ẹ̀lì oníná. Ìdààmú ọkàn bá mi láti tún rí i pé pípa sábáàtì Sunday ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́ kì í ṣe ohun àbéèrè fún lọ́wọ́ àwọn Kristian. Nítorí náà mo dojúkọ ṣíṣe ìpinnu tí ó lágbára: láti di àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ti Kristẹndọm mú tàbí láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni ní òtítọ́ Bibeli. Kò gbà mí ní àkókò púpọ̀ láti ṣe pinnu láti já gbogbo ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ mi pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian tì.

Nísinsìnyí Mo Dánìkan Wà Níti Gidi

Inú àwọn ìdílé mi, àwọn ọ̀rẹ́ mi, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi tẹ́lẹ̀rí ní ṣọ́ọ̀ṣì kò dùn nígbà tí mo sọ èrò mi jáde láti fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ tí n kò sì ní kọ́ni ní ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́ Sunday mọ́. Nígbà tí wọ́n sì rí i pé mo ń darapọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n fẹnu lásán pè ní àwọn ènìyàn Judge Rutherford, ìyẹn wulẹ̀ bu epo sí òfófó tí ń jó fòfò náà. A kò ta mí nù níti gidi, ṣùgbọ́n àwọn tí ó pọ̀ jùlọ lára ìdílé mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀rí kò yá mọ́ mi mọ́, kí n wulẹ̀ sọ díẹ̀ níbẹ̀.

Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ síi tí mo sì ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sínú àwọn ìwé náà tí mo ń kà, bẹ́ẹ̀ náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ríi pé ó yẹ láti wàásù ní gbangba. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń lọ láti ilé-dé-ilé gẹ́gẹ́ bí apákan iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn fún gbogbo ènìyàn. Ṣùgbọ́n nígbà yẹn kò sí Ẹlẹ́rìí kankan ní àgbègbè wa. Nítorí náà, kò sí ẹnì kankan tí ó fún mi ní ìṣírí tàbí tí ó fi bí a ṣe lè wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun hàn mí. (Matteu 24:14) Mo nímọ̀lára pé mo dánìkan wà níti gidi.

Síbẹ̀síbẹ̀, àṣẹ Bibeli láti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn ń dún gbọnmọ gbọnmọ ní etí mi, mo sì pinnu pé mo gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wàásù lọ́nà kan ṣá. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, mo pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sì kàn sí ilé àwọn aládùúgbò láti wulẹ̀ sọ ohun tí mo ti kọ́ láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ mi fún wọn kí n sì gbìyànjú láti fi àwọn nǹkan wọ̀nyí hàn wọ́n nínú Bibeli tiwọn. Ilé tí mo kọ́kọ́ wọ̀ ni ilé ọ̀gá mí àtijọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́ Sunday. Ìdáhùnpadà rẹ̀ tí ó tutù àti ọ̀rọ̀ òdì rẹ̀ nípa bí mo ṣe fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ dájúdájú kì í ṣe ìbẹ̀rẹ̀ tí ń fúnni ní ìṣírí. Ṣùgbọ́n mo nímọ̀lára ìtara àti okun inú tí ó ṣàjèjì bí mo ti fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ tí mo sì ń bá a lọ ní kíkàn sí àwọn ilé mìíràn.

Níti gidi kò sí àtakò kankan ní tààràtà, ṣùgbọ́n àìdágunlá ní gbogbogbòò ti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ mi tẹ́lẹ̀rí ní ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí mo bá kàn sí wọn ṣe mí ní kàyéfì. Sí ìyàlẹ́nu àti ìjákulẹ̀ mi, mo ní ìrírí àtakò tí ó lekoko jùlọ láti ọ̀dọ́ ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tí ó dàgbà jùlọ, èyí rán mi létí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Awọn òbí ati awọn arákùnrin ati awọn ẹbí ati awọn ọ̀rẹ́ pàápàá yoo fà yín lénilọ́wọ́, . . . ẹ̀yin yoo sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nitori orúkọ mi.”—Luku 21:16, 17.

Mo ti di ọ̀gẹṣin tí ó ní ìrírí láti kékeré, nítorí náà mo pinnu pé ọ̀nà tí ó yá jùlọ láti dé ilé àwọn ènìyàn yóò jẹ́ nípa gígun ẹṣin. Èyí ràn mí lọ́wọ́ láti lọ jìnnà sí àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ ìgbèríko tí ó wà nítòsí. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀sán ọjọ́ kan ẹṣin mi fi ẹsẹ̀ kọ ó sì ṣubú lójú ọ̀nà tí ń yọ̀, mo sì fi eegun agbárí pa yánnayànna. Fún sáà kan, mo ń bẹ̀rù pé bóyá n kò ní lè yè é. Lẹ́yìn ìṣubú yẹn, bí ọ̀nà náà bá ni omi tàbí tí ó bá ń yọ̀, èmi yóò rin ìrìn-àjò pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́-ẹṣin dípò gígun ẹṣin.a

Àjọṣepọ̀ Pẹ̀lú Ètò-Àjọ Náà

Nígbà kan lẹ́yìn ìjàm̀bá mi, ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn oníwàásù alákòókò kíkún kan, tí a ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà nísinsìnyí, ṣe ìbẹ̀wò sí agbègbè Òkè-Ńlá Gambier. Nípa bẹ́ẹ̀, fún ìgbà àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe fún mi láti bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi sọ̀rọ̀ lójúkorojú. Kí wọ́n to padà, wọ́n fún mi ní ìṣírí láti kọ lẹ́tà sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society kí n sì béèrè nípa bí mo ṣe lè ṣàjọpín nínú ìwàásù fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ wà létòlétò.

Lẹ́yìn kíkọ lẹ́tà sí Society, mo gbà àwọn ìwé-ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, àti káàdì ìjẹ́rìí kan tí a tẹ̀ fún sísọ irú ẹni tí mo jẹ́ ní ẹnu ọ̀nà. Mo nímọ̀lára sísúnmọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi tẹ̀mí díẹ̀ síi nítorí rírí lẹ́tà gbà láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà padà tí wọ́n sì lọ sí ìlú kejì, mo nímọ̀lára dídánìkan wà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí jíjẹ́rìí déédéé káàkiri lójoojúmọ́—ní pàtàkì nípasẹ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin—mo di ẹni tí a mọ̀-bí-ẹní-mowó ní agbègbè náà. Ní àkókò kan náà, ó ṣeé ṣe fún mi láti bójútó iṣẹ́ oko mi. Nígbà yẹn ìdílé mi ti dáwọ́ àtakò dúró wọn kò sì sapá kankan láti dá sí mi. Fún ọdún mẹ́rin mo ṣiṣẹ́sìn lọ́nà yìí gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí ìhìnrere tí kò tì í ṣe ìrìbọmi, tí ó wà ní àdádó.

Àpéjọpọ̀ àti, Nígbẹ̀yìn Gbẹ́yín, Ìrìbọmi

Ní April 1938, Arákùnrin Rutherford ṣe ìbẹ̀wò sí Australia. Àtakò lílágbára tí àwọn àlùfáà ṣe yọrí sí fífagilé àdéhùn fún lílo Gbọ̀ngàn Ìlú Sydney. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó kù díẹ̀, a yọ̀ọ̀da fún wa láti lo Pápá Ìṣeré. Ètò tí a fi pá múni yípadà náà mú àǹfààní wá níti gidi, níwọ̀n bí àyè ti lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún síi ní Pápá Ìṣeré tí ó fẹ̀ síi náà. Nǹkan bí 12,000 ni ó wá, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àtakò sí ìpàdé wa tí àwọn àlùfáà ru sókè ni ó ru ọkàn-ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè.

Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀wò Arákùnrin Rutherford, a ṣe àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mélòókan ní ìgbèríko Sydney tí ó wà nítòsí. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín níbẹ̀ ni mo ti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn fún Jehofa Ọlọrun nípa ìrìbọmi nínu omi. O ha lè finúmòye ìdùnnú-ayọ̀ tí mo ní ìrírí rẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín láti péjọpọ̀ pẹ̀lú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin láti gbogbo kọ́ńtínẹ́ǹtì Australia gbígbòòrò bí?

Pípadà Sí Òkè-Ńlá Gambier

Nígbà tí mo padà sí ilé, mo nímọ̀lára dídánìkan wà gidigidi, síbẹ̀ mo túbọ̀ ní ìpinnu ju ti ìgbàkigbà rí lọ láti ṣe ohun tí mo lè ṣe nínú iṣẹ́ Ìjọba náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà mo di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú ìdílé Agnew—Hugh, aya rẹ̀, àti àwọn ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Wọ́n ń gbé ní ìlú Millicent, 50 kìlómítà péré láti Òkè-Ńlá Gambier, èmi yóò sì rin ìrìn-àjò 50 kìlómítà ní àlọ àti 50 kìlómítà ní àbọ̀ pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́-ẹṣin láti lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn. Nígbà tí wọ́n tẹ́wọ́gba òtítọ́, ìdánìkanwà mi ni a mú kúrò.

Kò pẹ́ kò jìnnà, a di ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí a ṣètò fún jíjẹ́rìí. Lẹ́yìn náà, ó dùnmọ́ni pé, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí ní ọkàn-ìfẹ́ ó sì darapọ̀ mọ́ mi nínú ìrìn-àjò 100 kìlómítà ní àlọ àti àbọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwùjọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Láti ìgbà náà wá, Màmá ti máa ń fúnni ní ìṣírí ó sì jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tó ọdún díẹ̀ kí ó tó ṣe ìrìbọmi. Èmi kò nímọ̀lára ìdánìkanwà mọ́!

Ẹgbẹ́ àwùjọ wa kékeré ní aṣáájú-ọ̀nà mẹ́rin, àwọn ọmọbìnrin Agnew mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—Crystal, Estelle, àti Betty—àti èmi. Lẹ́yìn náà, ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ 1950, gbogbo àwọn ọmọbìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lọ sí Watchtower Bible School of Gilead. A yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì sí India àti Sri Lanka, níbi tí gbogbo wọn ti ń ṣiṣẹ́sìn títí di ẹnu àìpẹ́ yìí, nígbà tí Estelle níláti padà sí Australia nítorí ìṣòro ìlera lílekoko.

Ní January 1941 a fòfin de ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Australia, nítorí náà kíá ni a gbé ìgbésẹ̀. A kó gbogbo ohun tí a ń lò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́—ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ẹ̀rọ tí ń lu rẹ́kọ́ọ̀dù, àwọn àwíyé Bibeli tí a ti gbohùn wọn sílẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—sínú àpótí onírin ńlá kan. Lẹ́yìn náà a gbé àpótí onírin náà sínú ahéré kan a sì fi kẹ̀kẹ́-ẹṣin kó koríko gbígbẹ bò ó.

Láìka ìfòfindè náà sí, a ń bá ìwàásù ilé-dé-ilé wa nìṣó, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìṣọ́ra, a ń lo Bibeli nìkan nígbà tí a bá ń bá onílé sọ̀rọ̀. Èmi yóò fi ìwé ìròyìn àti ìwé pẹlẹbẹ pamọ́ sábẹ́ gàárì ẹṣin mi èmi yóò sì mu wọn jáde kìkì nígbà tí mo bá rí ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ tí a fi hàn sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ní June 1943, a mú ìfòfindè náà kúrò, a sì ní àǹfààní náà lẹ́ẹ̀kan síi láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni ní gbangba.

Iṣẹ́ Àyànfúnni Titun

Ní 1943, mo yọ̀ọ̀da ara mi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, àti ní ọdún tí ó tẹ̀lé e mo fi Òkè-Ńlá Gambier sílẹ̀ fún iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn. Lákọ̀ọ́kọ́, a késí mi láti ṣiṣẹ́sìn fún àkókò kúkúrú ní ọ́fíìsì ẹ̀ka Society ní Strathfield. Lẹ́yìn èyí mo gba, àwọn iṣẹ́ àyànfúnni, léraléra ní àwọn ìlú kéékèèké ní gúúsù New South Wales àti ìwọ̀-oòrùn Victoria. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àyànfúnni mi nípa tẹ̀mí tí ó mú èrè wá jùlọ jẹ́ pẹ̀lú ijọ ńlá ní ìlù-ńlá Melbourne. Níwọ̀n bí mo ti wá láti orílẹ̀-èdè kékeré, mo kọ́ ohun púpọ̀ nípasẹ̀ ṣíṣiṣẹ́sìn níbẹ̀.

Nínú iṣẹ́ àyànfúnni mi ní ẹkùn Gippsland ti àgbègbè Victoria, èmi àti aṣáájú-ọ̀nà alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi, Helen Crawford, darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli púpọ̀ àti, ní àkókò díẹ̀ síi, a rí ìdásílẹ̀ ìjọ kan. Àgbègbè náà ní agbègbè ìpínlẹ̀ ìgbèríko tí ó gbòòrò, a sì ní ọkọ̀ kan tí ó ti gbó tí kò ṣeé gbáralé, fún rírin ìrìn-àjò. Nígbà mìíràn a máa ń wa ọkọ̀ náà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń tì í. Ẹ wo bí mo ṣe yánhànhàn fún ẹṣin tó! Nígbà mìíràn, mo lè fi pẹ̀lú òtítọ́ inú sọ pé: “Mo lè fi ohunkóhun (yàtọ̀ sí Ìjọba náà) sílẹ̀ nítorí ẹṣin!” Nínú àwọn ìlú tí ó pọ̀ jùlọ ní àgbègbè yẹn lónìí, àwọn ìjọ tí ó lágbára àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàtà wà níbẹ̀.

Ní 1969, iṣẹ́ àyànfúnni gbé mi lọ sí Canberra, olú-ìlú Australia. Ibí yìí jẹ́ ibi ìpèníjà tí ó sì fúnni ní onírúurú àǹfààní láti jẹ́rìí, níwọ̀n bí a ti sábà máa ń kàn sí àwọn òṣìṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ọ́fíìsì aṣojú ilẹ̀ òkèèrè. Mo ṣì ń ṣiṣẹ́sìn níhìn-ín, ṣùgbọ́n ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí mo ti darí àfiyèsí ìjẹ́rìí mi sí agbègbè ilé-iṣẹ́ ìlú-ńlá náà.

Ní 1973, mo ní àǹfààní lílọ sí àwọn àpéjọpọ̀ ńlá ní United States. Apá pàtàkì mìíràn nínú ìgbésí-ayé mi ni jíjẹ́ àyànṣaṣojú àpéjọpọ̀ ní 1979 tí mo si rin ìrìn-àjò lọ sí Israeli àti Jordani. Ṣíṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ilẹ̀ gan-an tí a mẹ́nu kàn nínú Bibeli tí mo sì ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé níbẹ̀ jẹ́ ìrírí tí ń rùmọ̀lára sókè nítòótọ́. Ó ṣeé ṣe fún mi láti ní ìrírí bí yóò ti rí láti léfòó lórí Òkun Òkú, pẹ̀lú omi oníyọ̀ rẹ̀ tí a kò lè rí ìsàlẹ̀ rẹ̀, àti nígbà ìbẹ̀wò wa sí Petra ní Jordani, mo ní àǹfààní lẹ́ẹ̀kan síi láti gun ẹṣin. Èyí rán mi létí àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn nígbà tí ẹṣin tí mu kí ó ṣeé ṣe fún mi láti dé àwọn agbègbè tí ó wà káàkiri àti ìgbèríko pẹ̀lú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà.

Iṣẹ́-Ìsìn Alákòókò Kíkún Tí Ń Bá A Nìṣó

Ọkàn-ìfẹ́ mi láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún láìka pé ọjọ́ ogbó ti ń dé sí ni a ti ń mú gbóná nípasẹ̀ àwọn ìpèsè àkànṣe bí Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà àti ìpàdé àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí a ń ṣe papọ̀ pẹ̀lú àwọn àpéjọ àyíká, bákan náà sì ni ìṣírí tí kò dáwọ́ dúró tí mo ń rí gbà lọ́wọ́ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Mo lè sọ nítòótọ́ pé Jehofa ti fi pẹ̀lú inúrere rí sí i pé àwọn àkókò tí mo fi dánìkanwà ti di ohun àtijọ́.

Mo ti di ẹni ọdún 87 báyìí, mo sì ti lo nǹkan bí 60 ọdún ní ṣiṣẹ́sin Jehofa, mo ní ọ̀rọ̀ ìṣírí kan fún àwọn ẹlòmíràn tí àwọn pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ tí wọ́n sì fẹ́ láti wà lómìnira pé: Ẹ máa juwọ́sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà Jehofa nígbà gbogbo. Ǹjẹ́ kí Jehofa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso sísọ̀rọ̀ láìfi sábẹ́ ahọ́n sọ, ǹjẹ́ kí ó sì máa rán wa létí nígbà gbogbo pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè nímọ̀lára ìdánìkanwà, òun kì yóò pa wá tì láé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kẹ̀kẹ́-ẹṣin jẹ́ ọkọ̀ ẹlẹ́sẹ̀ méjì, tí ó fúyẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́