ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 1/1 ojú ìwé 12-16
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Bíbélì Wọ Ilé Wa
  • Àwọn Tó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ìpinnu Tó Tọ́
  • Bá A Ṣe Ń Wàásù Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa
  • Mo Ṣe Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà, Mo Ṣẹ̀wọ̀n, Mò Tún Lọ Sáwọn Àpéjọ
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Àtohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Náà
  • Àwọn Ìpinnu Tí Mo Ṣe Àtàwọn Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun
  • Mò Ń Ṣe Ìwọ̀nba Tí Ọjọ́ Ogbó Jẹ́ Kí N Lè Ṣe
  • Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ibi Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Gbé Mi Dé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Ṣe Ni A Ṣe”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 1/1 ojú ìwé 12-16

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi

Gẹ́gẹ́ bí Paul Kushnir ṣe sọ ọ́

NÍ ỌDÚN 1897, bàbá àti ìyá mi àgbà ṣí kúrò lórílẹ̀-èdè Ukraine, wọ́n lọ sílẹ̀ Kánádà, wọ́n wá fìdí kalẹ̀ sítòsí ìlú Yorkton, ní ìpínlẹ̀ Saskatchewan. Ọmọ mẹ́rin ni wọ́n kó débẹ̀, ìyẹn ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin kan. Ọmọbìnrin wọn yìí, tó ń jẹ́ Marinka, ló bí mi ní ọdún 1923; èmi ló ṣe ìkeje nínú àwọn ọmọ tó bí. Kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn nǹkan ìgbàlódé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àmọ́ ọkàn àwọn èèyàn balẹ̀. Oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ wà, a láwọn aṣọ tó nípọn, ìjọba sì ń pèsè ohun tí ará ìlú nílò. Tẹ́nì kan bá níṣẹ́ ńlá kan tó fẹ́ ṣe, àwọn ará àdúgbò á wá ràn án lọ́wọ́. Nígbà òtútù ọdún 1925, ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sílé wa, orúkọ yìí la mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn. Wíwá tó wá yẹn mú ká ṣe àwọn ìpinnu kan tó ṣì ń múnú mi dùn di bí mo ti ń sọ̀rọ̀ yìí.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì Wọ Ilé Wa

Màmá mi gba àwọn ìwé kékeré bíi mélòó kan lọ́wọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, kò sì pẹ́ tó fi rí i pé òtítọ́ lohun tó wà níbẹ̀. Kíá ló tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1926. Nígbà tí màmá mi di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo wa nínú ìdílé wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tó yàtọ̀ wo ìgbésí ayé. Ilé wa wá di ibi tá a ti máa ń gbàlejò nígbà gbogbo. Ilé wa làwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, tá a máa ń pé ní arìnrìn-àjò ìsìn nígbà yẹn àtàwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mìíràn sábà máa ń dé sí. Lọ́dún 1928, alábòójútó arìnrìn-àjò kan fi “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka” hàn wá, ìyẹn “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” tí wọ́n ké kúrú. Ó yá ọ̀pọ̀lọ́ onírọ́bà kan táwa ọmọdé fi ń ṣeré, ọ̀pọ̀lọ́ yìí máa ń dún téèyàn bá tẹ̀ ẹ́. Tó bá ti tẹ ọ̀pọ̀lọ́ náà tó sì dún, àkókò tó láti lọ sórí àwòrán mìíràn nìyẹn. Inú wá dùn gan-an pé ọ̀pọ̀lọ́ onírọ́bà tá a fi ń ṣeré ló lò fún àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà!

Alábòójútó arìnrìn-àjò kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Emil Zarysky sábà máa ń gbé ọkọ̀ àfiṣelé rẹ̀ wá nígbà tó bá wá bẹ ìjọ wa wò. Nígbà mìíràn, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kan tó ti dàgbà á tẹ̀ lé e wá, ọmọ rẹ̀ yìí sì máa ń fún àwa ọmọdé níṣìírí gan-an pé ká máa ronú láti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó bá yá. Ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà ló tún máa ń dé sílé wa. Nígbà kan, màmá mi mú ṣẹ́ẹ̀tì kan fún aṣáájú-ọ̀nà kan pé kó wọ̀ ọ́ kóun lè bá a rán ibi tó fàya lára èyí tó wọ̀ dé ọ̀dọ̀ wa. Àmọ́ ó ṣèèṣì di ṣẹ́ẹ̀tì náà mọ́ ẹrù rẹ̀ nígbà tó ń lọ. Nígbà tó yá, ó dá ṣẹ́ẹ̀tì náà padà, ó sì bẹ̀bẹ̀ pé ká máà bínú pé òun ò tètè dá a padà. Ó kọ̀wé pé: “Mi ò ní owó sítáǹbù tí mo lè lò láti fi dá a padà ni o.” Ì bá wù wá ká ní kò dá ṣẹ́ẹ̀tì náà padà! Mo lérò pé lọ́jọ́ kan èmi náà á lè ṣe bíi tàwọn aṣáájú-ọ̀nà wọ̀nyí tí kì í lépa ọrọ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé màmá mi jẹ́ ẹni tó lẹ́mìí àlejò ṣíṣe, èyí tó jẹ́ kí ìgbésí ayé wa dùn bí oyin tó sì jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará túbọ̀ pọ̀ sí i.—1 Pétérù 4:8, 9.

Dádì wa kò di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tiẹ̀, síbẹ̀ kò dí wa lọ́wọ́. Kódà lọ́dún 1930, ó fáwọn ará láyè láti ṣe àpéjọ ọlọ́jọ́ kan ní ibì kan tó máa ń kẹ́rù sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún méje péré ni mí nígbà yẹn, ayọ̀ tá a rí ní àpéjọ náà àti bó ṣe wà létòlétò wú mi lórí gan-an. Bàbá mi kú lọ́dún 1933. Bí màmá mi ṣe di opó nìyẹn tó wá ń dá nìkan tọ́mọ mẹ́jọ, síbẹ̀ kò dẹwọ́ nínú ìsapá rẹ̀ láti rí i pé òun fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́. Ó máa ń rí i dájú pé mo tẹ̀ lé òun lọ sí gbogbo ìpàdé. Lákòókò yẹn, ńṣe ló máa ń dà bíi pé àwọn ìpàdé náà ti gùn jù lójú mi, á wá máa wù mí kí n lọ máa báwọn ọmọ tó kù ṣeré níta, ìyẹn àwọn ọmọ táwọn òbí wọn gbà láyè láti máa ṣeré níta. Àmọ́ nítorí ọ̀wọ̀ tí mo ní fún màmá mi, màá fara balẹ̀ títí ìpàdé náà á fi parí. Nígbà tí màmá mi bá ń dáná lọ́wọ́, ó sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, á sì ní kí n sọ ibi tó wà nínú Bíbélì fóun. Lọ́dún 1933, ohun tá a kórè nínú oko wa pọ̀ gan-an, màmá mi sì ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan lára owó tá a rí níbẹ̀. Àwọn aládùúgbò wa kan tiẹ̀ bẹnu àtẹ́ lù ú pé ńṣe ló fowó ṣòfò, àmọ́ èrò rẹ̀ ni pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà á ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn.

Àwọn Tó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ìpinnu Tó Tọ́

Àwọn ọ̀dọ́ máa ń dàgbà dé àyè kan tí wọ́n ti ní láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ fi ọjọ́ ọ̀la wọn ṣe. Nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tórúkọ wọn ń jẹ́ Helen àti Kay dàgbà débi ṣíṣe irú ìpinnu tá a wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó máa ń dé sílé wa tá a sì máa ń ṣe lálejò dáadáa ni ọmọkùnrin kan tó rẹwà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Jazewsky. Màmá mi bẹ̀ ẹ́ pé kó dúró díẹ̀ kó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ oko wa. Nígbà tó yá, ó fẹ́ ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ Kay, àwọn méjèèjì sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ níbì kan tí kò jìnnà sọ́dọ̀ wa. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, wọ́n pè mí pé kí n wá bá wọn jáde òde ẹ̀rí fúngbà díẹ̀ lákòókò tá a wà lọ́lidé. Ìyẹn ló jẹ́ kí n lè mọ bí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ṣe rí gan-an.

Nígbà tó yá, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tóun náà ń jẹ́ John wá bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó iṣẹ́ oko náà débi tágbára wa mọ. Ìyẹn wá fún màmá mi láǹfààní láti lo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn fún ohun tá a wá ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lónìí. Kẹ̀kẹ́ ìkẹ́rù kan tí ẹṣin kan tó ti darúgbó ń fà ló lò fún iṣẹ́ náà. Orúkọ tí bàbá wa sọ ẹṣin olóríkunkun yìí ni Saul, àmọ́ màmá mi kà á sì ẹran tára ẹ̀ balẹ̀ tóun lè lò bó ṣe wu òun. Èmi àti John ń gbádùn iṣẹ́ oko tá a ń ṣe yẹn gan-an, àmọ́ gbogbo ìgbà tí màmá mi bá dé láti òde ẹ̀rí ló máa ń sọ àwọn ohun tó gbádùn lọ́hùn-ún fún wa, bí ọkàn wa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí kúrò nínú iṣẹ́ oko nìyẹn tá a sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́dún 1938, mo tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù gan-an, mo sì ṣèrìbọmi ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù February, ọdún 1940.

Nígbà tó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n fi mí ṣe ìránṣẹ́ ìjọ. Èmi ni mò ń bójú tó gbogbo àkọsílẹ̀ ìjọ, inú mi sì máa ń dùn gan-an tí mo bá ti rí i pé a pọ̀ sí i. Wọ́n ní kí n máa wàásù nílùú kan tí kò ju nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlógún sílé. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń fẹsẹ̀ rìn lọ síbẹ̀ nígbà òtútù, mo sì máa ń sun oorun ọjọ́ kan tàbí méjì ní yàrá tó wà lókè ilé ìdílé kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tí mo bá oníwàásù kan tó jẹ́ onísìn Luther sọ̀rọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà témi náà gbà bá a sọ̀rọ̀ nígbà yẹn ti ṣe ṣàkó jù, ó halẹ̀ mọ́ mi pé òun á ní kí ọlọ́pàá wá mú mi tí mi ò bá fi àwọn àgùntàn òun, ìyẹn àwọn ọmọ ìjọ òun sílẹ̀. Ńṣe lóhun tó sọ yẹn wá jẹ́ kí n túbọ̀ pinnu pé mi ò ní juwọ́ sílẹ̀.

Lọ́dún 1942, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Kay àti John ọkọ rẹ̀ ṣètò láti lọ sípàdé àgbègbè kan nílùú Cleveland, ní ìpínlẹ̀ Ohio, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Inú mi dùn gan-an nígbà tí wọ́n ní kí n bá wọn lọ. Ìpàdé àgbègbè yẹn jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí mo gbádùn jù lọ láyé yìí. Òun ló jẹ́ kí n pinnu ohun tí mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe. Nígbà tí Arákùnrin Nathan Knorr, tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ kárí ayé lákòókò náà sọ pé a nílò aṣáájú-ọ̀nà tó pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá. Ojú ẹsẹ̀ yẹn ni mo pinnu pé mo fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára wọn!

Ní oṣù January, ọdún 1943, òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò kan tó ń jẹ́ Henry wá bẹ ìjọ wa wò. Ó sọ àsọyé kan tó tani jí gan-an. Òtútù mú gan-an lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tó sọ àsọyé yìí, ẹ̀fúùfù kan tó ń fẹ́ wá láti ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn tún wá jẹ́ kí òtútù náà mú kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Nírú àkókò òtútù bẹ́ẹ̀, kò sẹ́ni tó máa ń jáde nílé, àmọ́ Henry múra tán láti jáde òde ẹ̀rí ní tiẹ̀. Òun àtàwọn kan wá wọ ọkọ̀ àfẹṣinfà kan tó nílé lórí, tí ààrò onígi wà nínú rẹ̀ lọ sí abúlé kan tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlá sí ọ̀dọ̀ wa. Èmi náà wá kọrí sí ọ̀dọ̀ ìdílé kan tó láwọn ọmọkùnrin márùn-ún. Wọ́n gbà kí n wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo wọn sì wá sínú òtítọ́ níkẹyìn.

Bá A Ṣe Ń Wàásù Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa nílẹ̀ Kánádà. A ní láti kó àwọn ìwé wa tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa mọ́, onírúurú ibi la sì kó wọn pa mọ́ sí nínú oko wa. Gbogbo ìgbà làwọn ọlọ́pàá máa ń wá sílé wa, àmọ́ wọn ò rí ohunkóhun. Bíbélì nìkan la máa ń lò nígbà tá a bá ń wàásù. Ńṣe la máa ń kóra jọ ní àwùjọ kéékèèké tá a bá fẹ́ ṣèpàdé. Wọ́n sì yan èmi àti John ẹ̀gbọ́n mi láti máa kó àwọn ìwé wa lọ sọ́dọ̀ àwọn ará ní bòńkẹ́lẹ́.

Nígbà ogun yẹn, ìjọ wa kópa nínú pípín ìwé pẹlẹbẹ kan kiri, èyí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní End of Nazism (Òpin Ètò Ìjọba Násì). Jákèjádò orílẹ̀-èdè làwọn ará ti pín ìwé tá à ń wí yìí. Òru ọ̀gànjọ́ la jáde síta. Ẹ̀rù bà mí gan-an bá a ti ń ya ilé lọ́kọ̀ọ̀kan tá a sì rọra ń fi ìwé náà sẹ́nu ọ̀nà wọn. Ohun tí mo ṣe tó bà mí lẹ́rù jù lọ láyé yìí nìyẹn. Ìgbà tá a pín gbogbo ìwé pẹlẹbẹ náà tán lọkàn mi tó balẹ̀! Gbogbo wa wá sáré padà sínú ọkọ̀, a ka ara wa láti rí i pé a pé, bá a ṣe yára wakọ̀ wa kúrò níbẹ̀ lọ́gànjọ́ òru yẹn nìyẹn.

Mo Ṣe Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà, Mo Ṣẹ̀wọ̀n, Mò Tún Lọ Sáwọn Àpéjọ

Ní ọjọ́ kìíní, oṣù May, ọdún 1943, mo dágbére fún màmá mi. Ogún dọ́là ló wà lápò mi, mo gbé àpótí kékeré tí mo kẹ́rù mi sí, mo sì forí lé ibi tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún mi láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Arákùnrin Tom Troop àti ìdílé rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ èèyàn àtàtà nílùú Quill Lake, ní ìpínlẹ̀ Saskatchewan gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, mo lọ sí ìpínlẹ̀ kan tó wà ní àdádó nílùú Weyburn, Saskatchewan. Ibi tí mo ti ń wàásù lójú pópó làwọn ọlọ́pàá ti mú mi ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù December, ọdún 1944. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi mí sọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan fún ọjọ́ díẹ̀, wọ́n mú mi lọ sí àgọ́ kan tí wọ́n ti ń lo àwọn èèyàn bí ẹrú ní ìlú Jasper, ìpínlẹ̀ Alberta. Àwọn mìíràn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá Jèhófà wà láyìíká ibẹ̀, ìyẹn àwọn òkè ńláńlá ilẹ̀ Kánádà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1945, àwọn aláṣẹ àgọ́ náà fún wa láyè láti lọ sípàdé kan tá a ṣe ní ìlú Edmonton, ìpínlẹ̀ Alberta. Arákùnrin Knorr ka ìròyìn kan tó wúni lórí gan-an nípa bí iṣẹ́ wa ṣe ń tẹ̀ síwájú kárí ayé. A wá ń fojú sọ́nà de ìgbà tí àkókò tí wọ́n dá fún wa láti lò ní àgọ́ náà máa pé ká lè láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù lẹ́ẹ̀kan sí i.

Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀, mo tún padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n sọ pé a fẹ́ ṣe Àpéjọ “Ìmúgbòòrò Gbogbo Orílẹ̀-Èdè” nílùú Los Angeles, ní ìpínlẹ̀ California. Arákùnrin kan tó wà níbi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún mi láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ṣètò ìjókòó ogún èèyàn sínú ọkọ̀ akẹ́rù rẹ̀. Nígbà tó sì di ọjọ́ kìíní, oṣù August, ọdún 1947, a gbéra, a sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò mánigbàgbé yìí. Ìrìn àjò ẹgbẹ̀rún méje ó lé igba [7,200] kìlómítà ni. A gba àwọn oko ọkà, àwọn aṣálẹ̀, àtàwọn ibi tó rẹwà gan-an kọjá, títí kan àwọn ọgbà ìtura Yellowstone àti Yosemite. Ọjọ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbáko ni gbogbo ìrìn àjò náà gbà wá, mi ò lè gbàgbé rẹ̀ láé!

Àgbàyanu ni àpéjọ àgbègbè ọ̀hún, kì í ṣohun téèyàn lè gbàgbé. Kí n bàa lè gbádùn rẹ̀ dáadáa, mo ṣe olùtọ́jú èrò níbẹ̀ lọ́sàn-án, mo sì ṣe iṣẹ́ ọlọ́dẹ lóru. Lẹ́yìn tí mo lọ sípàdé tó wà fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì, mo gba fọ́ọ̀mù, mo dáhùn àwọn ohun tí wọ́n béèrè níbẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, àmọ́ mi ò retí pé wọ́n máa pè mí. Lọ́dún 1948, mo yọ̀ǹda ara mi láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ Quebec tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà.—Aísáyà 6:8.

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Àtohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Náà

Lọ́dún 1949, inú mi dùn gan-an nígbà tí mo gba lẹ́tà tí wọ́n fi pè mí sí kíláàsì kẹrìnlá ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn mú kí ìgbàgbọ́ mi lágbára sí i, ó sì jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ṣáájú àkókò yẹn, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Kay àti John ọkọ rẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkànlá, wọ́n sì ti ń sìn ní ìhà Àríwá Rhodesia (tá a mọ̀ sí Zambia báyìí). Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ John náà kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1956. Ọdún méjìlélọ́gbọ̀n lóun àti Frieda aya rẹ̀ fi sìn ní orílẹ̀-èdè Brazil kí John tó kú.

Lọ́jọ́ tá a ń ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wa ní oṣù February, ọdún 1950, àwọn méjì ló tẹ wáyà sí mi, wọ́n sì fún mi níṣìírí gan-an. Ọ̀kan wá látọ̀dọ̀ màmá mi, èkejì sì wá látọ̀dọ̀ ìdílé Troop ní ìlú Quill Lake. Àkọlé wáyà tí ìdílé Troop fi ránṣẹ́ ni “Ìmọ̀ràn fún Akẹ́kọ̀ọ́yege,” ó sì kà pé: “Ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ òní jẹ́ fún ọ. Ọjọ́ tí wàá máa rántí pẹ̀lú ìdùnnú ni; á dáa fún ẹ, wàá sì láyọ̀ nígbèésí ayé rẹ.”

Wọ́n yàn mí sí ìpínlẹ̀ Quebec, àmọ́ wọ́n ní kí n ṣì wà ní Oko Society, ní ìpínlẹ̀ New York fúngbà díẹ̀, ibẹ̀ ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì wà nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Lọ́jọ́ kan, Arákùnrin Knorr bi mí bóyá màá fẹ́ lọ sórílẹ̀-èdè Belgium. Àmọ́, lọ́jọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ó bi mí bóyá máa fẹ́ láti lọ ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Netherlands. Nígbà tí mo gba lẹ́tà iṣẹ́ ìsìn náà, ohun tó wà níbẹ̀ ni pé kí n “lọ ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ka.” Ọ̀rọ̀ náà jọ mí lójú gan-an.

Nígbà tó di ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù August, ọdún 1950, mo wọ ọkọ̀ òkun, mo sì rin ìrìn àjò ọjọ́ mọ́kànlá gbáko lọ sí orílẹ̀-èdè Netherlands. Àkókò yẹn ni mo fi ka Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun látòkèdélẹ̀, èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì nígbà yẹn. Ọjọ́ kárùn-ún, oṣù September, ọdún 1950 ni mo dé ìlú Rotterdam, níbi tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà níbẹ̀ ti gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo bí Ogun Àgbáyé Kejì ṣe ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ tó, àwọn arákùnrin ti ṣe gudugudu méje láti rí i pé àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni tún ti ń lọ bó ṣe yẹ. Bí mo ṣe ń gbọ́ gbogbo ohun tójú wọn rí àti bí wọn ò ṣe yẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wọn lákòókò inúnibíni líle koko yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn mi pé kò ní rọrùn fáwọn arákùnrin wọ̀nyí láti sìn lábẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́, kò pẹ́ rárá tí mo fi wá rí i pé kò sídìí kankan tó fi yẹ kí n máa bẹ̀rù.

Lóòótọ́, àwọn ohun kan wà tá a ní láti tètè bójú tó. Kété tí mo dé síbẹ̀ ni wọ́n ṣe ìpàdé àgbègbè kan, orí mi sì wú nígbà tí mo rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará tí wọ́n fi wọ̀ sí ibi àpéjọ ọ̀hún. Nígbà tá a fẹ́ ṣe ìpàdé àgbègbè tó tẹ̀ lé e, mo dámọ̀ràn pé kí wọ́n fàwọn ará sáwọn ilé àdáni. Àwọn ará gbà pé ìmọ̀ràn tó dáa ní, àmọ́ wọ́n ní ìyẹn ò lè ṣeé ṣe lórílẹ̀-èdè àwọn. Lẹ́yìn tá a jọ fikùnlukùn, gbogbo wá jọ gbà pé kí ìdajì àwọn ará wà ní ilẹ̀ àpéjọ náà, kí ìdajì wọn sì lọ gbé ilé àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nílùú tá a ti máa ṣe àpéjọ náà. Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi sọ ohun tá a ṣe yìí fún Arákùnrin Knorr nígbà tó wá sí ìpàdé àgbègbè náà. Àmọ́, kíá ni gbogbo ayọ̀ àṣeyọrí tá a rò pé a ṣe pòórá nígbà tí mo wá ka ìròyìn ìpàdé àgbègbè náà nínú Ilé Ìṣọ́, èyí tó kà pé: “Ó dá wa lójú pé nígbà míì, àwọn ará á lo ìgbàgbọ́, wọ́n á sì ṣètò láti fi àwọn tó wá sípàdé àgbègbè wọ̀ sí àwọn ilé àdáni, ìyẹn ibi tó gbéṣẹ́ jù lọ láti jẹ́rìí.” Ohun tá a sì ṣe gẹ́lẹ́ “nígbà míì” nìyẹn!

Lóṣù July, ọdún 1961, wọ́n pe àwọn aṣojú méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa pé kí wọ́n wá sípàdé kan tí àwọn àtàwọn aṣojú mìíràn láti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì yòókù máa jọ ṣe nílùú London. Ibẹ̀ ni Arákùnrin Knorr ti kéde pé a ó mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde láwọn èdè púpọ̀ sí i, títí kan èdè Dutch. Inú wa dùn gan-an nígbà tá a gbọ́ ìròyìn yẹn! A ò mọ ohunkóhun nípa bí iṣẹ́ náà ṣe máa rí. Ní ọdún méjì lẹ́yìn ìyẹn, lọ́dún 1963, mo wà lára àwọn tó kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé àgbègbè tá a ṣe ní New York, ibẹ̀ la ti mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Dutch.

Àwọn Ìpinnu Tí Mo Ṣe Àtàwọn Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun

Ní oṣù August, ọdún 1961, mo gbé Leida Wamelink níyàwó. Ọdún 1942 ni gbogbo ìdílé rẹ̀ wá sínú òtítọ́, ìyẹn lákòókò tíjọba Násì ń ṣenúnibíni sáwọn ará. Ọdún 1950 ni Leida bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sì wá sí Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1953. Bó ṣe máa ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú ìjọ jẹ́ kí n mọ̀ pé yóò jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ tó máa ṣeé fọkàn tán nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mò ń ṣe.

Ó lé díẹ̀ lọ́dún kan lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ni wọ́n pè mí sí Brooklyn pé kí n wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ sí i fún oṣù mẹ́wàá gbáko. Wọn ò ṣètò pé káwọn aya tẹ̀ lé àwọn ọkọ wọn wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara Leida ó fi bẹ́ẹ̀ yá, tìfẹ́tìfẹ́ ló fi gbà pé kí n lọ. Nígbà tó yá, àìsàn Leida wá pọ̀ sí i. A kọ́kọ́ fẹ́ máa bá iṣẹ́ wa lọ ní Bẹ́tẹ́lì àmọ́ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a pinnu pé ohun tó máa dára jù ni pé ká lọ máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún níta. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò nìyẹn. Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn ìyẹn tí ìyàwó mi fi ṣe iṣẹ́ abẹ kan tó le gan-an. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn àwọn ará, ìṣòro náà ò ga jù fún wa, kódà ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n tún sọ mí di ìránṣẹ́ àgbègbè.

Ọdún méje gbáko la fi gbádùn ìṣẹ́ ìsìn arìnrìn-àjò tó fún wa lókun gan-an. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé a tún ní láti ṣe ìpinnu kan tó lágbára nígbà tí wọ́n pè mí pé kí n wá kọ́ àwọn ará ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. A gbà láti lọ, àmọ́ kò rọrùn fún wa rárá, nítorí pé à ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn arìnrìn-àjò tá à ń ṣe yẹn gan-an. Pípín tí wọ́n pín ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà sí kíláàsì mẹ́tàdínláàádọ́ta, tí kíláàsì kọ̀ọ̀kan sì ń lo ọ̀sẹ̀ méjì méjì, fún mi láǹfààní láti bá àwọn alàgbà ìjọ ṣàjọpín àwọn ìbùkún tẹ̀mí.

Àárín ìgbà yẹn ni mò ń ṣètò láti lọ wó màmá mi lọ́dún 1978. Àmọ́ lójijì la rí wáyà kan gbà tó sọ fún wa pé màmá mi ti kù lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù April, ọdún 1977. Ohun tó bà mí nínú jẹ́ jù lọ ni pé mi ò ní lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kóríyá tó máa ń sọ fún mi mọ́, mi ò sì ní lè sọ fún un bí mo ṣe mọrírì gbogbo àwọn ohun tó ti ṣe fún mi.

Nígbà tí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ náà parí, wọ́n ní ká di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, ọdún mẹ́wàá gbáko ni mo fi jẹ́ olùṣekòkárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka wa. Nígbà tó yá, Ìgbìmọ̀ Olùdarí yan olùṣekòkárí tuntun, tó lágbára àtiṣe iṣẹ́ náà jù mi lọ. Mo dúpẹ́ gan-an fún ìyẹn.

Mò Ń Ṣe Ìwọ̀nba Tí Ọjọ́ Ogbó Jẹ́ Kí N Lè Ṣe

Èmi àti Leida ti di ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin báyìí. Mo ti gbádùn iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fun ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún báyìí, èmi àti aya mi ọ̀wọ́n la sì jọ gbádùn ọdún márùnlélógójì tó kẹ́yìn níbẹ̀. Ojú tó fi wo gbogbo ìtìlẹ́yìn tó ṣe fún mi ní gbogbo ibi iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wa ni pé, ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá tóun ṣe fún Jèhófà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú ìjọ.—Aísáyà 46:4.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá rán ara wa létí àwọn ohun pàtàkì tá a ti gbé ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nígbèésí ayé wa. A ò kábàámọ̀ rárá nípa ohun tá a ti ṣe nínú ìṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó sì dá wa lójú pé ìpinnu tá a ṣe níbẹ̀rẹ̀ ayé wa jẹ́ ìpinnu tó dára jù lọ. A múra tán láti máa sin Jèhófà títí lọ, a ó sì máa fi gbogbo okun wa bọlá fún un.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Èmi àti Bill, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àti ẹṣin wa tó ń jẹ́ Saul

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa, lóṣù August ọdún 1961

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Èmi àti Leida lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́