Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn—Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègbà Á?
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, ó ṣe kedere pé kò sí omijé ìbànújẹ́ tàbí ti ìrora. Kò sí ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn. Aráyé ni a fún ní ìbẹ̀rẹ̀ pípé. “Ọlọrun sì rí ohun gbogbo tí ó dá, sì kíyèsí i, dáradára ni.”—Genesisi 1:31.
Ṣùgbọ́n àwọn kan ṣàtakò pé, ‘Ìtàn Adamu àti Efa nínú ọgbà Edeni wulẹ̀ jẹ́ ìtàn olówe lásán.’ Ó baninínújẹ́ pé, èyí tẹnu púpọ̀ lára àwọn àlùfáà Kristẹndọm jáde. Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí ọlá-àṣẹ kan tí ó jẹ́rìí sí ìjótìítọ́ ọ̀rọ̀-ìtàn tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Edeni jù ti Jesu Kristi fúnraarẹ̀. (Matteu 19:4-6) Síwájú síi, ọ̀nà kanṣoṣo láti lóye ìdí tí Ọlọrun fi fàyègba ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn ni láti yẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ìjímìjí ọ̀rọ̀-ìtàn ènìyàn wọ̀nyí wò.
A fún Adamu, ọkùnrin àkọ́kọ́, ní iṣẹ́ tí ń tẹ́nilọ́rùn ti bíbójútó ọgbà Edeni. Pẹ̀lúpẹ̀lù, Ọlọrun gbé góńgó mímú kí ilé Edeni gbòòrò di ọgbà ìtura tí ó kárí-ayé ka iwájú rẹ̀. (Genesisi 1:28; 2:15) Láti lè ṣèrànwọ́ fún Adamu láti lè ṣàṣeparí iṣẹ́ bàǹtà-banta yìí, Ọlọrun pèsè Efa, olùbáṣègbéyàwó kan fún un, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n máa bí síi kí wọ́n sì máa gbilẹ̀ síi, kí wọ́n sì ṣe ìkáwọ́ ilẹ̀-ayé. Síbẹ̀ ohun mìíràn wà tí wọ́n nílò kí ète Ọlọrun fún ilẹ̀-ayé àti aráyé baà lè yọrísírere. Níwọ̀n bí a ti dá wọn ní àwòrán Ọlọrun, ènìyàn ní òmìnira ìfẹ́-inú; nítorí náà, ó pọndandan pé kí ìfẹ́-inú ènìyàn máṣe forígbárí pẹ̀lú ti Ọlọrun láé. Àìjẹ́bẹ́ẹ̀, rúdurùdu yóò wà lágbàáyé, ète Ọlọrun pé kí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn alálàáfíà kún ilẹ̀-ayé kì yóò sì ní ìmúṣẹ.
Ìtẹríba fún ìlànà Ọlọrun kò lè ṣàdéédé wá. Ń ṣe ni ó yẹ kí ó jẹ́ ohun tí ènìyàn fi òmìnira ìfẹ́-inú ṣe tìfẹ́tìfẹ́. Fún àpẹẹrẹ, a kà pé nígbà tí Jesu Kristi dojúkọ ìdánwò lílekoko, ó gbàdúrà pé: “Baba, bí iwọ bá fẹ́, mú ife yii kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́-inú mi ni kí ó ṣẹ, bíkòṣe tìrẹ.”—Luku 22:42, NW.
Bákan náà, ó kù sọ́wọ́ Adamu àti Efa láti fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n fẹ́ láti tẹríba fùn ìlànà Ọlọrun. Nítorí ète yìí, Jehofa Ọlọrun ṣètò fún ìdánwò ráńpẹ́ kan. Ọ̀kan lára àwọn igi tí ń bẹ nínú ọgbà náà ní a pè ní “igi ìmọ rere àti búburú.” Ó dúró fún ẹ̀tọ́ Ọlọrun láti pinnu àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n fún ìwa tí ó tọ́. Lọ́nà tí ó lè tètè yéni, Ọlọrun ka jíjẹ lára èso igi pàtó yìí léèwọ̀. Bí Adamu àti Efa bá ṣàìgbọràn, ikú ni yóò yọrísí fún wọn.—Genesisi 2:9, 16, 17.
Ìbẹ̀rẹ̀ Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn
Lọ́jọ́ kan ọmọkùnrin Ọlọrun kan tí ó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí fi ìkùgbù gbé ìbéèrè dìde lòdìsí ọ̀nà tí Ọlọrun gbà ń ṣàkóso. Ní lílo ejò kan gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ, ó bi Efa pé: “[Ṣé] òótọ́ ni Ọlọrun wí pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ gbogbo èso igi ọgbà?” (Genesisi 3:1) Ó tipa báyìí gbin irúgbìn iyèméjì sínú Efa níti yálà ọ̀nà tí Ọlọrun gbà ń ṣàkóso tọ̀nà.a Ní fífèsì Efa dáhùn lọ́nà tí ó tọ́, èyí tí òun ti kọ́ láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀dá ẹ̀mí náà tako Ọlọrun ó sì parọ́ nípa ohun tí yóò jẹ́ àbájáde àìgbọràn, ní sísọ pé: “Ẹ̀yin kì yóò kú ikú kíkú kan. Nítorí Ọlọrun mọ̀ pé, ní ọjọ́ tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, nígbà náà ni ojú yín yóò là, ẹ̀yin óò sì dàbí Ọlọrun, ẹ óò mọ rere àti búburú.”—Genesisi 3:4, 5.
Ó baninínújẹ́ pé, a tan Efa jẹ láti bẹ̀rẹ̀ síí ronú pé àìgbọràn kì yóò yọrísí ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn, bíkòṣe ìgbésí-ayé tí ó sunwọ̀n síi. Bí ó ṣe túbọ̀ ń wo èso náà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrísí rẹ̀ túbọ̀ ń fà á lọ́kàn mọ́ra, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́. Lẹ́yìn èyí, àwíìyánnu rẹ̀ mú kí Adamu jẹ ẹ́ pẹ̀lú. Lọ́nà tí ó banilẹ́rù, Adamu yàn láti di ojúrere tí ó ní lọ́dọ̀ aya rẹ̀ mú dípò ti Ọlọrun.—Genesisi 3:6; 1 Timoteu 2:13, 14.
Nípa pípilẹ̀ ọ̀tẹ̀ yìí, ẹ̀dá ẹ̀mí náà sọ araarẹ̀ di alátakò Ọlọrun. Ó wá di ẹni tí a ń pè ní Satani, láti inú ọ̀rọ̀ Heberu náà tí ó túmọ̀sí “alátakò.” Ó tún parọ́ mọ́ Ọlọrun, ní sísọ araarẹ̀ di abanijẹ́. Nítorí ìdí èyí, a ń pè é ní Eṣu, láti inú ọ̀rọ̀ Griki tí ó túmọ̀sí “abanijẹ́.”—Ìfihàn 12:9.
Bí ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Mẹ́ta lára àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọrun ti ṣi ẹ̀bùn òmìnira ìfẹ́-inú wọn lò, ní yíyan ọ̀nà ìgbésí-ayé onímọtara-ẹni-nìkan ní ìṣàtakò sí Ẹlẹ́dàá wọn. Ìbéèrè náà wá dìde nísinsìnyí pé, Báwo ni Ọlọrun yóò ṣe yanjú ìṣọ̀tẹ̀ yìí lọ́nà tí ó tọ́ tí yóò lè tún fi ìyókù àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ olóye lọ́kàn balẹ̀, títíkan àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́ ní ọ̀run àti àwọn àtọmọdọ́mọ Adamu àti Efa ní ọjọ́-ọ̀la?
Ìhùwàpadà Ọlọrun Lọ́nà Ọgbọ́n
Àwọn kan lè jiyàn pé ìbá ti sàn jù kání Ọlọrun ti pa Satani, Adamu, àti Efa run lójúẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn kì bá tí yanjú àríyànjiyàn tí ìṣọ̀tẹ̀ náà gbé dìde. Satani ti gbé ìbéèrè dìde lòdìsí ọ̀nà tí Ọlọrun gbà ń ṣàkóso, ní dídábàá pé yóò sàn fún ẹ̀dá ènìyàn jù bí wọ́n bá wà lómìnira kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun. Bákan náà, àṣeyọrí rẹ̀ nínú dídẹ̀yìn àwọn ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́ kọ ìlànà Ọlọrun gbé àwọn ìbéèrè mìíràn dìde. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Adamu àti Efa dẹ́ṣẹ̀, èyí ha túmọ̀sí pé ohun kan wà tí ó kù díẹ̀ káàtó nínú ọ̀nà tí Ọlọrun gbà dá ènìyàn bí? Ọlọrun ha lè rí ẹnikẹ́ni lórí ilẹ̀-ayé tí yóò dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí i bí? Kí sì ni nípa tí àwọn áńgẹ́lì ọmọkùnrin Jehofa tí wọ́n rí ìṣọ̀tẹ̀ Satani? Wọn yóò ha gbárùkùti òdodo ìpò ọba-aláṣẹ Rẹ̀ bí? Ó hàn gbangba pé, a nílò àkókò tí ó pọ̀ tó láti fi yanjú àwọn àríyànjiyàn wọ̀nyí. Ìdí nìyẹn tí Ọlọrun fi fàyègba Satani láti wàláàyè títí di ọjọ́ wa.
Níti Adamu àti Efa, ní ọjọ́ tí wọ́n ṣàìgbọràn, Ọlọrun dájọ́ ikú fún wọn. Bí ikú ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn, tí a lóyún wọn lẹ́yìn tí Adamu àti Efa ti dẹ́ṣẹ̀, jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn aláìpé.—Romu 5:14.
Satani bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú àríyànjiyàn náà. Ó ti lo àkókò tí a yọ̀ọ̀da fún un láti gbìyànjú láti mú kí àwọn àtọmọdọ́mọ Adamu wá sábẹ́ ìdarí rẹ̀. Ó ti kẹ́sẹjárí bákan náà nínú títan ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì jẹ láti darapọ̀ mọ́ ọn nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ọmọkùnrin áńgẹ́lì Ọlọrun ti fi tòótọ́tòótọ́ gbárùkùti òdodo ìṣàkóso Jehofa.—Genesisi 6:1, 2; Juda 6; Ìṣípayá 12:3, 9.
Àríyànjiyàn tí ń bẹ lójú ọpọ́n jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun ní ìforígbárí pẹ̀lú ti Satani, àríyànjiyàn kan tí ń lọ lọ́wọ́ nígbà ayé Jobu. Ọkùnrin olùṣòtítọ́ yìí fi ẹ̀rí hàn nípa ìwà rẹ̀ pé òun faramọ́ ìṣàkóso òdodo Ọlọrun ju ìdádúró lómìnira ti Satani lọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọrun bí Abeli, Enoku, Noa, Abrahamu, Isaaki, Jakobu, àti Josefu ti ṣe ṣáájú. Jobu di kókó-ọ̀rọ̀ ìjíròrò tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run níwájú àwọn olùṣòtítọ́ áńgẹ́lì Ọlọrun. Ní kínkín ìṣàkóso òdodo Rẹ̀ lẹ́yìn, Ọlọrun wí fún Satani pé: “Ìwọ ha kíyèsí Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tíí ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúróṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, tí ó sì kórìíra ìwà búburú.”—Jobu 1:6-8.
Ní kíkọ̀ láti gbà pé òun ti fìdírẹmi, Satani jẹ́wọ́ pé Jobu ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun kìkì nítorí àwọn ìdí onímọ̀tara-ẹni-nìkan, níwọ̀n bí Ọlọrun ti fi aásìkí nípa ti ara bùkún Jobu jìngbìnnì. Nítorí náà Satani tẹnumọ́ ọn pé: “Ǹjẹ́ nawọ́ rẹ nísinsìnyí, kí o sì fi tọ́ ohun gbogbo ohun tí ó ní; bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” (Jobu 1:11) Satani tilẹ̀ lọ síwájú síi, ní gbígbé ìbéèrè dìde lòdìsí ìwàtítọ́ gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọrun. Ó tẹnumọ́ ọn pé, “Ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òhun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀.” (Jobu 2:4) Ìkòlójú lọ́nà tí ń banijẹ́ yìí kò kan Jobu nìkan ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ olùjọsìn Ọlọrun ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀-ayé. Satani ń dọ́gbọ́n sọ pé bí ìwàláàyè wọn bá wà nínú ewu wọn yóò yááfì ipò-ìbátan wọn pẹ̀lú Jehofa.
Jehofa Ọlọrun ní ìgbọ́kànlé tí ó kúnrẹ́rẹ́ nínú ìwàtítọ́ Jobu. Ní fífi ẹ̀rí ìyẹn hàn, ó fàyègba Satani láti mú ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn wá sórí Jobu. Nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ rẹ̀ kìí wulẹ̀ ṣe pé Jobu wẹ orúkọ tirẹ̀ mọ́ nìkan ni ṣùgbọ́n, èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, ó gbárùkùti òdodo ipò ọba-aláṣẹ Jehofa. Ó mú Eṣu ní elékèé.—Jobu 2:10; 42:7.
Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu Kristi ni àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ tí ó dára jùlọ lábẹ́ ìdánwò. Ọlọrun ti tàtaré ìwàláàyè áńgẹ́lì Ọmọkùnrin yìí láti ọrún sínú ilé-ọlẹ̀ wúńdíá kan. Nítorí náà Jesu kò jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó dàgbà di ọkùnrin pípé kan, alábàádọ́gba rẹ́gí pẹ̀lú ọkùnrin àkọ́kọ́ náà kí ó tó di pé ìyẹn pàdánù ìjẹ́pípé rẹ̀. Satani sọ Jesu di ohun ìfojúsùn àkànṣe, ní mímú ọ̀pọ̀ ìdẹwò àti àdánwò wá sórí rẹ̀, ní fífi ikú akótìjúbáni ṣe àṣekágbá rẹ̀. Ṣùgbọ́n Satani kùnà láti ba ìwàtítọ́ Jesu jẹ́. Lọ́nà pípé pérépéré, Jesu gbárùkùti òdodo ìṣàkóso Bàbá rẹ̀. Ó tún fi ẹ̀rí hàn pé Adamu ọkùnrin pípè náà kò ní àwíjàre kankan fún dídarapọ̀ mọ́ Satani nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀. Adamu kì bá ti jẹ́ olùṣòtítọ́ lábẹ́ ìdánwò rẹ̀ tí ó kéré ní ìfiwéra.
Ohun Mìíràn Wo Ni A Tún Ti Fi Ẹ̀rí Rẹ̀ Hàn?
Nǹkan bíi 6,000 ọdún ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn ti kọjá láti ìgbà ìṣọ̀tẹ̀ Adamu àti Efa. Láàárín àkókò yìí Ọlọrun ti fàyègba aráyé láti fi onírúurú àkóso yíyàtọ̀síra dánrawò. Àkọsílẹ̀ bíbanilẹ́rù nípa ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn ti fi ẹ̀rí hàn pé ènìyàn kò tóótun láti ṣàkóso araarẹ̀. Níti gàsíkíá, rúgúdù tí gbilẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ilẹ̀-ayé. Ìdádúró lómìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí Satani ṣe ṣalágbàwí rẹ̀, kún fún àjálù-ibi.
Kò tíì sí ìdí kankan fún Jehofa láti fi ẹ̀rí ohunkóhun hàn fún araarẹ̀. Ó mọ̀ pé ọ̀nà tí òun ń gbà ṣàkóso jẹ́ òdodo ó sì jẹ́ fún ire dídára jùlọ ti àwọn ẹ̀dá òun. Bí ó ti wù kí ó rí, láti lè dáhùn gbogbo ìbéèrè tí ìṣọ̀tẹ̀ Satani gbé dìde lọ́nà tí ó tẹ́nilọ́rùn, ó ti fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye ní àǹfààní láti fi yíyàn wọn hàn fún ìṣàkóso òdodo rẹ̀.
Àwọn èrè fún nínífẹ̀ẹ́ Ọlọrun àti jíjẹ́ olùṣòtítọ́ sí i tẹ̀wọ̀n fíìfíì ju sáà ìjìyà fún ìgbà díẹ̀ lọ́wọ́ Eṣu. Ọ̀ràn Jobu ṣe àkàwé èyí. Jehofa Ọlọrun wo Jobu sàn kúrò nínú àìsàn tí Eṣu ti mú wá sórí rẹ̀. Síwájú síi, Ọlọrun “bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.” Ní àkótań, lẹ́yìn 140 ọdún tí a fikún ọjọ ayé rẹ̀, “Jobu kú, ó gbò, ó sì kún fún ọjọ́.”—Jobu 42:10-17.
Kristian òǹkọ̀wé Bibeli náà Jakọbu pe àfiyèsí sí èyí, ní sísọ pé: “Ẹ ti gbọ́ nipa ìfaradà Jobu ẹ sì ti rí àbárèbábọ̀ tí Jehofa mú wá, pé Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú.”—Jakọbu 5:11, NW, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé.
Àkókò ti tó fún Satani àti ayé rẹ̀ báyìí. Láìpẹ́, Ọlọrun yóò yí gbogbo ìjìyà tí ọ̀tẹ̀ Satani ti mú wá sórí aráyé padà. Àní àwọn òkú ni a óò jí dìde. (Johannu 11:25) Nígbà náà, àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ bíi Jobu yóò ní àǹfààní jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun lórí paradise orí ilẹ̀-ayé. Àwọn ìbùkún ọjọ́-ọ̀la wọ̀nyí tí Ọlọrun yóò tújáde sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dá a láre láé àti títíláé gẹ́gẹ́ bí Ọba-Aláṣẹ tí ó ‘jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni tí ó sì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú’ nítòótọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Philip Mauro, agbẹjọ́rò àti òǹṣèwé kan ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, tí ó yẹ ìbéèrè yìí wò nínú ìjíròrò rẹ̀ nípa “Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ìwà-Ibi,” parí èrò pé èyí ni “okùnfà gbogbo ìdààmú aráyé.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
ÀWỌN ỌLỌRUN ONÍKÀ TI ÀWỌN ÈNÌYÀN
ÀWỌN ọlọrun ìgbàanì ni a máa ń fihàn lọ́pọ̀ ìgbà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti aṣèfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Láti tù wọ́n lójú, àwọn òbí tilẹ̀ sun àwọn ọmọ wọn nínú iná lóòyẹ̀. (Deuteronomi 12:31) Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò-orí abọ̀rìṣà sì tún ki àṣejù bọ̀ ọ́ nípa kíkọ́ni pé Ọlọrun kò ní àwọn ìmọ̀lára bí ìbínú tàbí àánú.
Ojú-ìwòye onímìísí ẹ̀mí-èṣù ti àwọn ọlọ́gbọ́n èrò-orí wọ̀nyí nípa lórí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ ti Ọlọrun, àwọn Ju. Ju ọlọ́gbọ́n èrò-orí náà Philo, alájọgbáyé Jesu fi ìtẹnumọ́ kéde pé Ọlọrun “kò ní ìmí-ẹ̀dùn kankan rárá.”
Àní àwọn ẹ̀ya-ìsìn Ju tí wọ́n mógìírí jùlọ àwọn Farisi pàápàá kò bọ́ lọ́wọ́ agbára ìdarí ọgbọ́n èrò-orí Griki. Wọ́n tẹ́wọ́gba ẹ̀kọ́ Plato pé ọkàn àìlèkú kan tí a sémọ́ inú ara ẹ̀dá ni ó parapọ̀ di ènìyàn. Síwájú síi, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn ọ̀rúndún kìn-ín-ní Josephus ti sọ, àwọn Farisi gbàgbọ́ pé ọkàn àwọn ènìyàn búburú “ń jìyà ìdálóró ayérayé.” Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli kò fúnni ní ìdí kankan fún irú ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀.—Genesisi 2:7; 3:19; Oniwasu 9:5; Esekieli 18:4.
Àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu ńkọ́? Wọ́n ha yọ̀ọ̀da kí ọgbọ́n èrò-orí àwọn abọ̀rìṣà nípa lé wọn lórí bí? Ní mímọ ewu yìí dájú, aposteli Paulu kìlọ̀ fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹni kan lè wà tí yoo gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ọgbọ́n èrò-orí ati ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹlu òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹlu àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé tí kò sì sí ní ìbámu pẹlu Kristi.”—Kolosse 2:8, NW; wo 1 Timoteu 6:20 pẹ̀lú.
Ó mà ṣe o, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian alábòójútó ti ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta fi ojú tín-ín-rín ìkìlọ̀ yẹn wọ́n sì kọ́ni pé Ọlọrun kò ní ìmọ̀lára kankan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Látòkè-délẹ̀, àwọn ànímọ́-ìwà Ọlọrun ní a lóye gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti tẹnumọ́ wọn nínú ìrònú àwọn Ju àti ti ọlọ́gbọ́n èrò-orí ti àkókò náà . . . Èròǹgbà náà pé Ọlọrun Bàbá lè ní ìmọ̀lára bí àánú . . . ní a ti kà sí aláìṣètẹ́wọ́gbà ní gbogbogbòò títí di nǹkan bí apá ìparí ọ̀rúndún ogún.”
Nípa báyìí, Kristẹndọm tẹ́wọ́gba ẹ̀kọ́ èké ti ọlọrun oníkà tí ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nípa mímú kí wọ́n jìyà ìdálóró tí wọ́n mọ̀ lára títí láé. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, Jehofa Ọlọrun sọ ní kedere nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” kìí ṣe ìdálóró tí a mọ̀ lára títí ayérayé.—Romu 6:23, NW.
[Àwọn Credit Line]
Òkè: Acropolis Museum, Greece
Ìyọ̀ọ̀da Onínúure ti The British Museum
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ète Ọlọrun láti sọ ilẹ̀-ayé di paradise bíi ti Edeni gbọ́dọ̀ ní ìmúṣẹ!