Ori 5
Ijọba naa—Eeṣe Tí Ó Fi Pẹ́ Tobẹẹ Ní ‘Dídé’?
1. Lójú iwoye ohun tí ó wà ninu Romu 8:22, awọn ibeere wo ni wọn dide?
APOSTELI Paulu kọwe pe: “Nitori awa mọ̀ pe gbogbo ẹ̀dá ní o jumọ ń kerora ti o si ń rọbí pọ̀ títí di isinsinyi.” (Romu 8:22) Eeṣe tí eyi fi rí bẹẹ? Eeṣe tí Ọlọrun fi yọọda awọn ogun, ìwà-ọ̀daràn, àìsàn ati ipò òṣì tí ó ti wà fun 6,000 ọdun tí ó ti kọja ninu akọsilẹ ìtàn? Ki ni ṣẹlẹ, tí eniyan, tí a dá lati walaaye ní ibamu pẹlu ofin atọrunwa, fi nilati di eyi tí ìwà-àìlófin kó ìyọnu bá nisinsinyi? Eeṣe tí Baba wa ọrun kò tíì fi tún ipò-ọ̀ràn naa ṣe? Bi Ijọba naa bá jẹ́ ojútùú rẹ̀, eeṣe tí ó fi pẹ́ tobẹẹ ní ‘dídé’? Awa ha lè ní ireti nitootọ pe Ọlọrun yoo yí awọn ipò buburu wọnyi pada?
2. Labẹ ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun, ki ni ilẹ̀-ayé ìbá ti dà?
2 Labẹ iṣakoso onípò-àjùlọ, tabi ipò ọba-aláṣẹ, ti “Ọba ayeraye,” awọn ipò pípé ìbá ti gbilẹ̀ lori ilẹ̀-ayé lati igba ìṣẹ̀dá ní Edeni. Bi ọkunrin ati obinrin ekinni ti ń mú awọn ọmọ jade, tí idile eniyan sì ń pọ̀ sii ní ẹgbẹẹgbẹrun lọna araadọta ọkẹ ẹ̀ka idile, gbogbo ilẹ̀-ayé patapata porogodo ni ìbá ti di paradise ẹlẹwa kan, tí ó kún fun ẹ̀rín onídùnnú ati ifẹ aladuugbo ti awọn ẹya-iran eniyan alalaafia.—Fiwe Oniwasu 2:24.
3. (a) Ní àwòrán ta ni a dá eniyan? (b) Ki ni a paṣẹ fun tọkọtaya akọkọ lati ṣe? (c) Ibeere wo ni awa gbọdọ beere nisinsinyi?
3 Eyiini ni ohun tí Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ naa pète fun ilẹ̀-ayé yii nigba tí o dá eniyan ní jíjọ ọ̀nà-ìwàhíhù oun fúnraarẹ̀ tí ó sì dá obinrin lati ara ọkunrin naa. Nitori pe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀dá inu Bibeli sọ fun wa pe:
“Akọ ati abo ni o dá wọn. Ọlọrun si súre fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bí si i, ki ẹ sì ma rẹ̀, ki ẹ sì gbilẹ, kí ẹ sì ṣe ikawọ rẹ̀; kí ẹ sì maa jọba lori ẹ̀ja òkun, ati lori ẹyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alaaye gbogbo tí ń rákò lori ilẹ̀. . . . Ọlọrun si ri ohun gbogbo tí ó dá, si kiyesi i, daradara ni.” (Genesisi 1:26-31)
Eeṣe, nigba naa, tí awọn ìṣẹ̀dá Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé kò fi jẹ “daradara” lonii?
A PE IPÒ ỌBA-ALÁṢẸ ỌLỌRUN NÍJÀ
4. (a) Ofin Ọlọrun wo ni ó tayọlọla julọ, eesitiṣe? (b) Ta ni ó fẹ́ lati ṣe awọn ofin tí ó yatọ, bawo ni o ṣe ṣe eyi?
4 Iṣẹda ní awọn ofin Ọlọrun gẹgẹ bi ìpìlẹ̀ rẹ̀. Eyi tí ó sì tayọ julọ ninu awọn wọnyi ni ofin ifẹ. Ọlọrun fúnraarẹ̀ jẹ́ “ifẹ.” (1 Johannu 4:8) Ṣugbọn nisinsinyi ẹnikan farahan tí ó fẹ́ lati ṣe awọn ofin ti o yàtọ̀ fun araye. “Ẹni” naa ni angẹli ‘ọmọkunrin Ọlọrun’ kan tí a kò lè fojúrí, laisi iyèméjì ọ̀kan lára awọn wọnni ‘tí ó hó ìhó ayọ̀’ nigba tí Jehofa dá ilẹ̀-ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀. (Jobu 38:7) Angẹli yii pa araarẹ̀ dà di satani kan, elénìní Ọlọrun. Ó fẹ́ ìdádúró-lómìnira, o ń wá ijọsin fun araarẹ̀ ó sì gbin ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀. (Efesu 2:1, 2; fiwe Luku 4:5-7.) O pète lati lò awọn obi wa eniyan akọkọ fun awọn góńgó onímọ̀tara ẹni-nìkan rẹ̀. Bawo ni ó ṣe ṣe eyi?
5, 6. (a) Aṣẹ tí ó rọrun wo ni Ọlọrun pa fun Adamu? (b) Iyọsini wo ni Satani lò, eeṣe tí ó fi tọ̀nà lati pè é ní “Eṣu”?
5 Ninu paradise ọgbà Edeni, Adamu ati Efa ni olùjàǹfààní iṣakoso ẹlẹ́mìí-ìṣore ti Jehofa. Ọlọrun pese ohun gbogbo tí ó pọndandan lati gbé wọn ró nipa ti ẹmi ati ti ara. Fun ire wọn lati maa báa niṣo, ó beere lọwọ wọn pẹlu pe ki wọn ṣe igbọran si oun gẹgẹ bi Oluwa Ọba-aláṣẹ wọn. Fun ète yii oun fun Adamu ní ofin rírọrùn kan, pe oun kò gbọdọ jẹ ninu “eso igi imọ rere ati buburu.” Eyi kàn Efa pẹlu, lẹhin ìṣẹ̀dá rẹ̀. Kii ṣe pe Ọlọrun fi ohunkohun dù wọn, nitori pe awọn igi miiran ninu ọgbà naa pese ọ̀kan-kò-jọ̀kan awọn eso àjẹgbádun tí ó kún fun oúnjẹ-afáralókun. Bi ó ti wù ki ó rí, bi wọn bá nilati ṣaigbọran si Ọlọrun ní jíjẹ lara èso kanṣoṣo yii, wọn yoo “kú.” Pẹlu ọgbọ́nwẹ́wẹ́, nipasẹ ejò kan, Satani ọlọ̀tẹ̀ naa kọ́kọ́ tọ Efa lọ, ó sì wi pe: “Ẹyin ki yoo kú ikúkíkú kan. Nitori Ọlọrun mọ̀ pe, ní ọjọ tí ẹyin bá jẹ ninu rẹ̀ [eso igi naa], nigba naa ni ojú yin yoo là, ẹyin yoo sì dabi Ọlọrun, ẹ ó mọ̀ rere ati buburu.”—Genesisi 2:17; 3:1-5.
6 Eyiini mú ki Ọlọrun dabi òpùrọ́ kan. Ṣugbọn niti gidi Satani ni òpùrọ́. Lọna ti ó tọ́, “baba eke” naa di ẹni tí a tún ń pè ní Eṣu, tí ó tumọsi “Abanijẹ́.” (Johannu 8:44) Níhìn-ín ni ìpèníjà taarata kan ti wà si ipò ọba-aláṣẹ Jehofa, Ipò ọba rẹ̀ lori awọn ẹda rẹ̀. Ó dọ́gbọ́n túmọ̀sí pe Ọlọrun ń fà ọwọ́ imọ sẹhin eyi tí wọn ní ẹ̀tọ́ sí, pe a kò lè gbẹkẹle iṣakoso Ọlọrun, pe yoo sànjù fun wọn lati tẹle awọn ọna ìdádúró lómìnira tiwọn funraawọn, ki wọn sì gbé awọn ọpa-idiwọn tiwọn funraawọn kalẹ nipa “rere ati buburu.”
7. Ní ọna wo ni awọn tọkọtaya eniyan fi kùnà labẹ ìdánwò?
7 Bawo ni obinrin naa ṣe dahunpada si ọ̀rọ̀ abanijẹ́ yii? Oun kuna lati pa ọkàn-àyà rẹ̀ mọ́, tí ó sì yọ̀ọ̀da fun ifẹ-ọkan àìtọ́ lati ta gbòǹgbò nibẹ. Ifẹ-ọkan yii wá gbilẹ̀, tobẹẹ tí a fi tàn án jẹ sinu mímọ̀ọ́mọ̀ dẹṣẹ nipa ṣiṣaigbọran si Ọlọrun. Ninu eyi oun tún ṣaika ipò ori ọkọ rẹ̀ sí, ẹni tí oun ìbá ti bá forikori. Bawo sì ni ọkunrin naa ṣe huwapada? “A kò tan Adamu jẹ,” ṣugbọn ó yàn lati faramọ Efa, tí ó si mọ̀ọ́mọ̀ darapọ mọ́ ọn ninu ipa ọna ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀. Ọjọ onibanujẹ wo ni eyi jẹ́ fun awọn obi wa akọkọ, ati fun gbogbo ẹ̀yà-ìran eniyan lodidi!—Genesisi 3:6, 7; 1 Timoteu 2:14; fiwe Jakọbu 1:14, 15.
8. (a) Ìdájọ́ tí ó tọ́ wo ni Ọlọrun dá fun Adamu ati Efa? (b) Wọn ha ní ọkàn kan tí yoo lọ si ọrun tabi si hẹẹli ìdálóró nigba iku bi? (c) Ọba wo ni ó bẹrẹsi ṣakoso lori wa, eesitiṣe?
8 Adamu ati Efa ti fi àìkàsí tí ó burú lékenkà hàn fun ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun. Nitori naa nisinsinyi, ní ibamu pẹlu ofin rẹ̀, Ọlọrun kede ìdájọ́ iku, ní sísọ fun Adamu pe:
“Erupẹ sa ni iwọ, iwọ yoo si pada di erupẹ.” (Genesisi 3:19)
Níhìn-ín Ọlọrun kò ní in lọ́kàn pe ara Adamu nikan ni yoo kú, nigba tí “ọkàn” kan tabi “ẹmi” kan ninu lọ́hùn-ún yoo fi ara silẹ lati maa walaaye niṣoo ni ọrun kan tabi hẹẹli kan. Bẹẹkọ, nitori pe Adamu fúnraarẹ̀ jẹ́ “ọkàn” kan. Gẹgẹ bi akọsilẹ ìṣẹ̀dá ti wí, ninu Genesisi 2:7 pe: “Oluwa Ọlọrun si fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ eniyan; ó sì mí ẹmi ìyè si ihò imú rẹ̀; eniyan si di alaaye ọkàn.” Nigba tí ó yá, Adamu ati Efa kú—gẹgẹ bi awọn ọkàn. Nitori pe gbogbo ẹya-iran eniyan jẹ́ ọmọ Adamu alábàwọ́n-ẹ̀ṣẹ̀, gbogbo wa ni ó ti jogún ẹṣẹ ati iku. “Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, oun yoo kú.” (Esekieli 18:4, 20) Bẹẹni, gẹgẹ bi awọn eniyan tí o jẹ́ ọkàn, gbogbo wa ni ó ń kú. Iku ti wá ṣakoso gẹgẹ bi ọba lori wa.—Romu 5:12, 14; 6:12; Oniwasu 3:19, 20; 9:5, 10; Orin Dafidi 6:5; 115:17.
ÀRÍYÀNJIYÀN NIPA ÌWÀTÍTỌ́ ENIYAN
9. Àríyànjiyàn miiran wo ni a tún gbé dide ní Edeni?
9 Bi ó ti wù ki ó rí, kii ṣe kiki ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun nikan ni a penija nipasẹ ìṣọ̀tẹ̀ naa ní Edeni. Àríyànjiyàn miiran ni a gbé dide. Niwọn bi awọn eniyan akọkọ gan-an tí Ọlọrun fi sori ilẹ̀-ayé ti di alaiṣootọ labẹ ìdánwò, ohun kan ha ṣaidara tó ninu ìṣẹ̀dá Ọlọrun bi? A ha lè fi tootọ-tootọ sọ pe gbogbo iṣẹ rẹ̀ jẹ́ “pípé” bi?
10. (a) Ìṣẹ̀dá Ọlọrun ha ní àbùkù bi, eeṣe tí o fi dahun bẹẹ? (b) Bawo ni awọn eniyan ṣe lè fi araawọn hàn pe wọn jẹ́ “aworan Ọlọrun”?
10 Ọlọrun lè ti pa Adamu ati Efa run lẹsẹkẹsẹ ki ó sì dá eniyan meji miiran. Ṣugbọn eyiini kò ha ní jẹ́ fifaramọ ọn pe ìṣẹ̀dá rẹ̀ akọkọ jẹ́ alábùkù bi? Kii ṣe alábùkù. Ó wulẹ jẹ́ nitori pe awọn obi wa akọkọ yàn lati lò agbára ominira yíyàn ti wọn ni niti ọna ìwàhíhù lọna àìtọ́ ni. Bi wọn bá ti jẹ́ ẹ̀rọ robọti tí ó nilati ṣe ohun ti o tọ́ labẹ ipò gbogbo, nigba naa wọn yoo ti kù sibikan niti ọ̀nà ìwàhíhù. Wọn kìbá ti jẹ́ “aworan Ọlọrun.” Jehofa maa ń figba gbogbo ṣe awọn nǹkan ní pípé, lọna tí ó tọ́, nitori pe oun jẹ́ ifẹ. Oun bẹẹ gẹgẹ ń fẹ́ ki awọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye di ẹni tí ifẹ sún lati ṣe ohun tí ó tọ́.—Genesisi 1:26, 27; 1 Johannu 5:3.
11. Imọlẹ wo ni Deuteronomi 32:4, 5 tàn sori ipo-ọran naa lọ́hùn-ún?
11 A kọwe rẹ̀ nipa Jehofa pe: “Apata naa, pípé ni iṣẹ rẹ̀; nitori pe ẹ̀tọ́ ni gbogbo ọna rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati aláìṣègbè, ododo ati otitọ ni oun.” Awọn ẹ̀dá rẹ̀, iran eniyan, lè jẹ́ olùṣòtítọ́, olododo ati aduroṣinṣin pẹlu. Nitori naa oun yọọda fun Adamu ati Efa lati mú awọn ọmọ jade. Àní bi ó tilẹ jẹ́ pe awọn wọnyi jogun awọn animọ ti o kun fun ẹṣẹ lati ọ̀dọ̀ awọn obi wọn, sibẹ awọn kan yoo wà lara wọn tí yoo fi ifẹ àìyẹsẹ̀ hàn fun Ẹlẹ́dàá wọn tí wọn yoo sì fẹ̀rí ìwàtítọ́ wọn hàn si i, àní ninu ara àìpé wọn ati lójú awọn idanwo ati inunibini kíkorò tí ó lè dé si wọn. Ṣugbọn awọn miiran ninu araye yoo ‘gbégbèésẹ̀ lọna ìparun’ tí wọn yoo sì fi araawọn hàn pe wọn kii ṣe awọn ọmọ Ọlọrun. Eyiini yoo jẹ́ yíyàn tiwọn funraawọn, àbùkù naa ni a ó sì kà si wọn lọ́rùn, kìí ṣe sí Ọlọrun.—Deuteronomi 32:4, 5.
12, 13. (a) Bawo ni Satani ṣe ṣáátá Ọlọrun niti ọran Jobu? (b) Èsì wo ni Jobu pese, ati pẹlu iyọrisi wo fun un?
12 Pé Satani Eṣu rinkinkin mọ́ àríyànjiyàn yii nipa ìwàtítọ́ eniyan niwaju Ọlọrun ni a fihan ninu iwe Jobu ninu Bibeli. Ọkunrin naa Jobu, tí ó gbé ayé ní nǹkan bii 2,500 ọdun lẹhin iṣubu Adamu, jẹ́ “oloootọ, tí ó sì duroṣinṣin, ẹni tí ó bẹru Ọlọrun, tí ó sì koriira iwa-buburu.” Satani ṣáátá Ọlọrun pe iṣotitọ Jobu kii ṣe ojulowo, pe ó ṣiṣẹsin Ọlọrun kìkì nitori ohun tí ó lè rí gbà ninu rẹ̀. Nitori naa Ọlọrun yọọda fun Satani lati dán Jobu wò. Jobu jìyà àdánù nlanla niti awọn dúkìá; awọn ọmọ rẹ̀ mẹwaa ni a pa ninu ìjábá; oun fúnraarẹ̀ ni a pọ́nlójú pẹlu àrùn akoninírìíra kan lẹhin naa, ati nikẹhin iyawo rẹ̀ fi i ṣe ẹlẹya, wi pe: “Iwọ dì ìwàtítọ́ rẹ mú sibẹ! Bú Ọlọrun ki o sì kú.” Tẹle eyi, Jobu nilati wọ̀jà pẹlu awọn ìpẹ̀gàn tí ó kún fun ọ̀rọ̀ òdì tí kò báradé lati ọ̀dọ̀ awọn olùtùnú eke mẹta.—Jobu 1:6–2:13.
13 La gbogbo awọn idanwo wọnyi já, Jobu di ipinnu rẹ̀ mu ṣinṣin:
“Titi emi o fi ku, emi ki yoo ṣi ìwà òtítọ́ mi kuro lọdọ mi.”
Oun jẹ́ oloootọ si Ọlọrun, nipa bayii ó pese ìfèsìpadà alagbara fun awọn ẹ̀sùn Satani. Nitori naa Jehofa san èrè-ẹ̀san fun Jobu nipa fifun un ní ìlọ́po meji ohun gbogbo tí ó ti ní tẹlẹ. A sì tún bukun fun un niti pe o ní ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta lẹẹkan sii—tí awọn tí a mẹnukan kẹ́hìn wọnyi sì jẹ́ arẹwa julọ ní gbogbo ilẹ naa.—Jobu 27:5; 42:10-15.
14. Bawo ni awọn miiran bakan naa ṣe dahun ẹ̀sùn Satani, apẹẹrẹ didarajulọ wo ni ó sì wà nipa eyi?
14 Bi ó ti wù ki ó rí, Jobu wulẹ jẹ́ ọkanṣoṣo péré lara ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn olùṣòtítọ́ iranṣẹ Ọlọrun tí wọn ti mú ọkàn-àyà Rẹ̀ yọ̀ nitori pipese idahun fun ẹ̀sùn eke Satani pe awọn olufẹ Jehofa ń ṣe igbọran tí wọn sì ń ṣiṣẹsin in kiki fun awọn idi onimọtara-ẹni-nikan. Apẹẹrẹ didarajulọ fun eyi ni ti Jesu, Ọmọkunrin Ọlọrun fúnraarẹ̀, ẹni tí, nigba tí ó wà lori ilẹ̀-ayé, “farada igi oró, o tẹmbẹlu itiju,” gbogbo rẹ̀ fun ìdùnnú ti bibaa nìṣó lati ṣiṣẹsin pẹlu àìmọ̀tara-ẹni-nìkan ninu iṣẹ́ tí Ọlọrun fun un.—Heberu 12:2, NW.
A DAHUN ÌPÈNÍJÀ OLÙṢÁÁTÁ NAA
15. Eeṣe tí a fi lè sọ pe ìhà ti Jehofa ninu ìpèníjà naa ni a ti fẹ̀rí rẹ̀ hàn?
15 Nisinsinyi, akoko tí a yànkalẹ̀ naa ti fẹrẹẹ pari tán. Lakooko nǹkan bii 6,000 ọdun Jehofa ti ń fi iha tirẹ̀ hàn pẹlu ẹ̀rí ní idahun si ìpèníjà naa. Oun ti fihan pe oun lè pese oun sì ti pese awọn ọkunrin ati obinrin lori ilẹ̀-ayé tí wọn pà ìwàtítọ́ mọ́ laika inunibini eyikeyii tabi àdánwò mímúná miiran tí Satani ń mú wá sori wọn sí. Eṣu ti lo gbogbo ìpète buburu tí oun lè ronu kàn lodisi wọn, ṣugbọn òfo ni o jásí. Awọn iranṣẹ Ọlọrun olùṣòtítọ́ ti mú ọkàn-àyà Baba wọn yọ̀, nitori pe wọn ti pese èsì fun un si ẹni naa tí “ń gan” Ọlọrun, eyiini ni, elénìní nla naa, Satani.—Owe 27:11.
16. (a) Ninu iṣẹgun wo ni awọn kan ninu awọn aduroṣinṣin iranṣẹ Ọlọrun ti ní ìpín nisinsinyi? (b) Eeṣe tí awọn ọmọ-abẹ Ijọba naa lè fi ní igbẹkẹle ninu awọn olùṣàkóso wọn?
16 Lẹsẹkan naa, ni ibamu pẹlu ọna igbaṣe nǹkan rẹ̀, Jehofa ti ń yàn lara awọn aduroṣinṣin wọnyi awọn eniyan tí yoo ṣakoso pẹlu Kristi ninu Ijọba ọrun. Bi ó tilẹ jẹ́ pe Satani ti fi wọn sùn “niwaju Ọlọrun wa ní ọ̀sán ati ní òru,” wọn ti ṣẹgun rẹ̀ “nitori ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹran ẹ̀mí wọn àní titi dé iku.” Gẹgẹ bi Àwòfiṣàpẹẹrẹ wọn, Jesu Kristi, wọn ti ń fẹ́ lati fi ifẹ wọn gigajulọ hàn fun Ọlọrun ati aládùúgbò nipa fifi ẹ̀mí wọn paapaa lélẹ̀. Ìgbọ́kànlé wo ni yoo ṣeeṣe fun araye lati ní ninu Ijọba ọrun naa tí o parapọ̀ jẹ́ Kristi ati 144,000 awọn ọba olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀—gbogbo wọn tí a dánwò tí wọn sì jẹ́ olùpa ìwàtítọ́ mọ́!—Ìfihàn 12:10, 11; 14:1-5; 20:4; Johannu 15:13.
17. Awọn wo ni yoo jogun ilẹ-akoso ayé ti Ijọba naa?
17 Awọn miiran, gẹgẹ bi Jobu, tí wọn kú ní olùṣòtítọ́ si Ọlọrun ṣaaju akoko Kristian, ni a fun ní imudaniloju “ajinde tí ó daraju” sinu “ayé titun.” (Heberu 11:35; 2 Peteru 3:13) Wọn di apakan “agutan miiran” ti “oluṣọ-agutan rere” naa Jesu Kristi, pẹlu ireti ìyè ainipẹkun ninu paradise ilẹ̀-ayé. Pẹlupẹlu, awọn ẹni-bi-agutan wọnni tí wọn fi inurere hàn si awọn ẹni-ami-ororo “arakunrin” Kristi ní akoko “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” ni a kesi lati jogun ilẹ̀-ayé yii tii ṣe apakan agbegbe Ijọba naa. (Johannu 10:11, 16; Matteu 24:3, NW; 25:31-46) A ó gbà wọn là nigba tí awọn angẹli ọrun bá tú afẹfẹ “ipọnju nla” naa sori ilẹ̀-ayé wa. Iwọ ha fẹ́ lati jẹ́ ọ̀kan lára awọn “ogunlọgọ nla” olulaaja naa nigba tí Ijọba Ọlọrun bá “dé” lati tẹ awọn orilẹ-ede buruku rẹ́? Iwọ lè jẹ́ bẹẹ! Nitori pe, gẹgẹ bi olùpa iwàtítọ́ mọ́ kan, iwọ pẹlu lè fihan pe ọna Ọlọrun nikanṣoṣo ní ó lè ṣamọna si igbadun iwalaaye pipẹtiti.—Ìfihàn 7:1-3, 9, 13, 14.
18. (a) Eeṣe tí ki yoo fi pọndandan mọ́ lae lati dá ipò ọba-aláṣẹ Jehofa láre? (b) Awọn wo ni ó ní ireti mímọ́lẹ̀yòò nisinsinyi? (Orin Dafidi 37:11, 29)
18 Gbàrà tí Ijọba Ọlọrun bá ti tẹ̀ Satani ati eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi rẹ̀ oníwà-ìbàjẹ́ rẹ́, kò tún ní pọndandan mọ́ lae lati dá ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun láre. Awọn àríyànjiyàn tí ọlọ̀tẹ̀ naa Satani gbé dide ni a ó ti dahun rẹ̀ lẹẹkanṣoṣo ati fun gbogbo ayeraye. (Nahumu 1:9) Níhìn-ín gan-an, ní ilẹ̀-ayé yii, ẹ̀tọ́, ododo, ìtayọlọ́lá iṣakoso tí a gbeka ori ofin ifẹ ti Ọlọrun, ni a ó ti fẹri rẹ̀ han, Ijọba naa yoo sì ti “dé” lati yà orukọ atobilọla ti Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ si mímọ́. Fun awọn ‘ẹ̀dá tí ń kerora’ tí wọn ń ṣiṣẹsin Ọlọrun nisinsinyi ninu ìwàtítọ́, ẹ wò iru ireti dídán tí Ijọba Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ jade! Iwọ ha ń gbadura tọkantọkan fun ‘dídé’ rẹ̀ bi?—Romu 8:22-25.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 44]
EEṢE TÍ ỌLỌRUN FI FÀYÈGBÀ IWA-IBI FUN ÌGBÀ PÍPẸ́ TOBẸẸ?
● Lati fìdí ẹ̀tọ́, ododo, ìlọ́lájù ati ìwàpẹ́títí ipò ọba-aláṣẹ agbaye Jehofa múlẹ̀
● Lati fihan fun gbogbo igba pe iṣakoso eniyan eyikeyii laisi Ọlọrun ń yọrisi kìkì ìkárísọ ati ìjábá
● Lati pese fun idagbasoke awọn ileri Ijọba Ọlọrun, ati àṣàyàn ati dídán awọn ajogún Ijọba naa wò
● Lati fi àyè silẹ fun fífẹ̀rí hàn, gẹgẹ bi ninu ile-ẹjọ ofin kan, pe awọn iranṣẹ Ọlọrun lè pa ìwàtítọ́ mọ́ laika àdánwò eyikeyii lati ọ̀dọ̀ Satani sí
● Lati fihan pe igbọran, tí a gbeka ori ofin ifẹ ti Ọlọrun, ni ipa-ọna kanṣoṣo tí ń ṣamọna si igbadun iwalaaye pipeṭiti
● Lati dahun ìpèníjà Satani jálẹ̀jálẹ̀ ati lati fìdí irufẹ akọsilẹ ofin ṣíṣekedere bẹẹ múlẹ̀ tí ó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí kò fi ní pọndandan mọ́ lae lati dá orukọ ati ipò ọba-aláṣẹ Jehofa láre.