ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 12/1 ojú ìwé 28-31
  • Bawo Ni Awa Ṣe Lè San Asanpada fun Jehofa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bawo Ni Awa Ṣe Lè San Asanpada fun Jehofa?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Asanpada Eyikeyii Ha Ṣeeṣe Bi?
  • Iwọ Ha Nilati San Idamẹwaa Bi?
  • Fifunni Ni Idamẹwaa Labẹ Ofin
  • Awọn Kristẹni Ha Gbọdọ San Idamẹwaa Bi?
  • Bọla fun Jehofa Pẹlu Awọn Ohun Ṣiṣeyebiye Rẹ
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìdá Mẹ́wàá?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ọrẹ Tí Ń Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Bí Àwọn kan Ṣe Ń Ṣe Ìtọrẹ Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Ẹ Mú Gbogbo Idamẹwaa Wá Sí Ile-Iṣura”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 12/1 ojú ìwé 28-31

Bawo Ni Awa Ṣe Lè San Asanpada fun Jehofa?

JEHOFA ỌLỌRUN fun wa ni apẹẹrẹ didara julọ ti fifunni. Oun ti jinki gbogbo ẹda eniyan pẹlu “ìyè ati èémí ati ohun gbogbo fun gbogbo eniyan.” (Iṣe 17:25) Ọlọrun mu ki oòrùn rẹ̀ ràn sara eniyan buburu ati eniyan rere bakan naa. (Matiu 5:45) Niti tootọ, ‘Jehofa nfun yin ni ojo lati ọrun wa, ati akoko eso, ó nfi ounjẹ ati ayọ kun ọkan yin.’ (Iṣe 14:15-17) Họwu, “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipe lati oke ni ó ti wá, o sì nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá”!—Jakobu 1:17.

Yatọ si gbogbo awọn ẹbun nipa ti ara lati ọdọ Ọlọrun, oun rán imọlẹ ati otitọ nipa tẹmi jade. (Saamu 43:3) Awọn aduroṣinṣin iranṣẹ Ọlọrun ni a bukun lọpọlọpọ pẹlu awọn ounjẹ tẹmi ti oun pese ni akoko ti ó tọ́ nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu.” (Matiu 24:45-47, NW) Awa lè jere lati inu awọn ipese Ọlọrun nipa tẹmi nitori oun ti mu ki ó ṣeeṣe fun awọn ẹ̀dá eniyan ẹlẹṣẹ ati ẹni kiku lati di onílàjà pẹlu rẹ̀. Bawo? Nipasẹ iku Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ti ó ti fi iwalaaye rẹ̀ funni gẹgẹ bi irapada fun ọpọlọpọ. (Matiu 20:28; Roomu 5:8-12) Iru ẹbun wo ni eyi jẹ́ lati ọdọ Ọlọrun onifẹẹ, Jehofa!—Johanu 3:16.

Asanpada Eyikeyii Ha Ṣeeṣe Bi?

Ọpọ ọrundun ṣaaju ki a to pese irapada naa, olorin kan ti a misi mọriri aanu, idasilẹ, ati iranlọwọ ti Ọlọrun fifunni lọna jijinlẹ debi ti oun fi sọ pe: “Ki ni emi yoo san fun Oluwa [“Jehofa,” NW] nitori gbogbo ore rẹ̀ si mi? Emi yoo mu ago igbala, emi yoo si maa ké pe orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW]. Emi yoo san ileri ifẹ mi fun Oluwa [“Jehofa,” NW], nitootọ ni oju gbogbo awọn eniyan rẹ̀.”—Saamu 116:12-14.

Bi awa ba fi tọkantọkan ṣe iyasimimọ si Jehofa, awa nkepe orukọ rẹ̀ ni igbagbọ ti a sì nsan awọn ẹ̀jẹ́ wa ti a jẹ́ fun un. Gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa, awa lè bukun Ọlọrun nipa sisọrọ daradara nipa rẹ̀ ni gbogbo ìgbà ati nipa pipolongo awọn ihin-iṣẹ Ijọba rẹ̀. (Saamu 145:1, 2, 10-13; Matiu 24:14) Ṣugbọn awa kò lè sọ Jehofa di ọlọ́rọ̀, ẹni ti ó ni gbogbo nǹkan, tabi san asanpada fun gbogbo awọn anfaani ti oun ti fun wa.—1 Kironika 29:14-17.

Ṣiṣe awọn itọrẹ fun ilọsiwaju awọn ire Ijọba naa kii ṣe ọna kan lati gbà san asanpada tabi sọ Jehofa di ọlọ́rọ̀. Bi o ti wu ki o ri, iru fifunni bẹẹ fun wa lanfaani lati fi ifẹ wa fun Ọlọrun han. Awọn itọrẹ ti a funni, ti kii ṣe lati inu awọn isunniṣe onimọtara-ẹni-nikan tabi fun awọn ifihan itagbangba tabi fun iyin, ṣugbọn pẹlu ẹmi ọlọlawọ ati lati gbe ijọsin tootọ leke, nmu idunnu ati ibukun Jehofa bá olufunni naa. (Matiu 6:1-4; Iṣe 20:35) Ẹnikan ni a lè mu ninipin-in ninu iru fifunni bẹẹ ati awọn idunnu ti nti ibẹ jade daloju nipa yiya ohun kan sọtọ deedee lati inu awọn ohun ìní ti araarẹ lati ṣe itilẹhin fun ijọsin tootọ ati lati ṣeranwọ fun awọn ẹni ti wọn yẹ fun un. (1 Kọrinti 16:1, 2) Njẹ a nilati ṣe eyi nipa sisan idamẹwaa bi?

Iwọ Ha Nilati San Idamẹwaa Bi?

Jehofa sọ nipasẹ wolii rẹ̀ Malaki pe: “Ẹ mu gbogbo idamẹwaa wá si ile iṣura, ki ounjẹ baa lè wà ni ile mi, ẹ sì fi eyi dán mi wò nisinsinyi, . . . bi emi ki yoo ba ṣí awọn ferese ọrun fun yin, ki nsi tú ibukun jade fun yin, tobẹẹ ti ki yoo sí àyè tó lati gba a.” (Malaki 3:10) Itumọ miiran kà pe: “Mu gbogbo idamẹwaa wá sinu ile ìkóǹkanpamọsi.”—An American Translation (Gẹẹsi).

Idamẹwaa jẹ́ apakan ninu mẹwaa ohunkohun. Ó jẹ́ ipin 10 ninu ọgọrun-un ti a funni tabi san gẹgẹ bi owo-ode. Sisan idamẹwaa ni a nṣe ni pataki fun awọn ete ti isin. Ó tumọsi fifunni ni idamẹwaa ohun ti nwọle fun ẹnikan lati ṣe igbeleke ijọsin.

Aburahamu (Abramu) babanla fun ọba ati alufaa naa Melikisedeki ti Salẹmu ni idamẹwaa awọn ikogun ti ogun ajaṣẹgun rẹ̀ lori Kedolaoma ati awọn onigbeja rẹ̀. (Jẹnẹsisi 14:18-20; Heberu 7:4-10) Lẹhin naa, Jakọbu bura lati fi idamẹwaa awọn ohun ìní rẹ̀ fun Ọlọrun. (Jẹnẹsisi 28:20-22) Ninu awọn ọran kọọkan, fifunni ni idamẹwaa jẹ́ ifinnufindọṣe, nitori ti awọn Heberu ijimiji wọnni kò ni ofin eyikeyii ti ó sọ ọ di aigbọdọmaṣe fun wọn lati san idamẹwaa.

Fifunni Ni Idamẹwaa Labẹ Ofin

Gẹgẹ bi awọn eniyan Jehofa, awọn ọmọ Isirẹli gba awọn ofin lori idamẹwaa. O ṣe kedere pe eyi ní ìlò awọn idamẹwaa meji ti awọn ohun ti nwọle funni lọdọọdun nínú, bi o tilẹ jẹ́ pe awọn akẹkọọjinlẹ melookan ronu pe idamẹwaa ọdọọdun kanṣoṣo ni ó wà. Kò si idamẹwaa kankan ti a nsan laaarin ọdun Sabaati, niwọn bi kò ti si ohun ti nwọle funni ti a reti rẹ̀ nigba naa. (Lefitiku 25:1-12) Awọn idamẹwaa ni a funni ni afikun si awọn eso àkọ́so ti a sì fi rubọ si Ọlọrun.—Ẹkisodu 23:19.

Ìdá kan ninu mẹwaa awọn eso ilẹ naa ati awọn eso igi ati ohun ti o jọ ibisi ninu awọn ọ̀wọ́ ẹran ati agbo ẹran ni a mu wa sinu ibujọsin mímọ́ ti a sì fifun awọn ọmọ Lefi, ti wọn kò gba ogun eyikeyii ninu ilẹ naa. Ni tiwọn ẹ̀wẹ̀, awọn naa san idamẹwaa ohun ti wọn gbà lati ṣetilẹhin fun ipo alufaa Aroni. O han kedere pe awọn ọka naa ni a pa ti a sì fi awọn eso ajara ati ti igi olifi ṣe waini ati ororo ṣaaju sisan idamẹwaa. Bi ọmọ Isirẹli kan ba fẹ lati funni ni owo dipo awọn eso, oun lè ṣe bẹẹ, kiki ti oun ba fi idamarun-un iye owo rẹ̀ kun un.—Lefitiku 27:30-33; Numeri 18:21-30.

Idamẹwaa miiran ni ó jọ bi ẹni pe a tun nyasọtọ. Bi o ti yẹ ki ó ri, ohun ni idile kan yoo lò nigba ti awọn eniyan bá pejọ fun ajọdun. Ṣugbọn ki ni bi ọna ti o lọ sí Jerusalẹmu ba jìn pupọju ti kò fi rọrun lati kó awọn idamẹwaa naa dé ibẹ lọna rirọrun? Nigba naa, ọka naa, waini titun naa, ororo, ati awọn ẹran ni a o yipada si owo gidi eyi ti a lè fi irọrun mu rin. (Deutaronomi 12:4-18; 14:22-27) Ni opin ọdun kẹta ati ọdun kẹfa ti iyipo sabaati kọọkan ọlọdun meje, idamẹwaa naa ni a yasọtọ fun awọn ọmọ Lefi, awọn ajeji ti wọn jẹ́ awọn alejo, awọn opó, ati awọn ọmọ alaini baba.—Deutaronomi 14:28, 29; 26:12.

Labẹ Ofin, kò si ijiya kankan fun kikuna lati san idamẹwaa. Kaka bẹẹ, Jehofa fi awọn eniyan sabẹ iṣẹ aigbọdọmaṣe lilagbara niti ọna iwahihu lati pese awọn idamẹwaa. Nigba miiran wọn nilati sọ ọ gbangba niwaju rẹ̀ pe idamẹwaa ni a ti san ni ẹkunrẹrẹ. (Deutaronomi 26:13-15) Ohunkohun ti a ba pamọwọ lọna aitọ ni a fojuwo gẹgẹ bi ohun kan ti a ja Ọlọrun lole rẹ̀.—Malaki 3:7-9.

Sisan idamẹwaa kii ṣe iṣeto adẹrupani kan. Niti tootọ, nigba ti awọn ọmọ Isirẹli pa awọn ofin wọnyi mọ, wọn di ẹni ti o tubọ laasiki sii. Idamẹwaa naa ṣe igbeleke ijọsin tootọ laifi itẹnumọ alaiyẹ sori bi a o pese awọn ohun ti ara fun un. Nitori naa, iṣeto sisan idamẹwaa ṣiṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ Isirẹli lọna rere. Ṣugbọn sisan idamẹwaa ha wà fun awọn Kristẹni bi?

Awọn Kristẹni Ha Gbọdọ San Idamẹwaa Bi?

Fun awọn akoko kan, sisan idamẹwaa wọpọ ni ilẹ akoso awọn Kristẹndọmu. Iwe The Encyclopedia Americana sọ pe: “Ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ . . . o di ohun ti ó wọpọ ni ọrundun kẹfa. Ajọ Council of Tours ni 567 ati Council of Macon keji ni 585 ṣalagbawi sisan idamẹwaa. . . . Aṣilo rẹ̀ di ohun ti ó wọpọ, ni pataki nigba ti ẹtọ lati gba awọn idamẹwaa di ohun ti a saba maa nfifun tabi tà fun awọn ọmọ ijọ. Bẹrẹ pẹlu Pope Gregory Keje, aṣa yii di ohun ti a polongo rẹ̀ ni alaibofinmu. Ọpọ awọn ọmọ ijọ wọnyi nigba naa gbe ọran ẹtọ wọn fun gbigba owo idamẹwaa wọnyi kalẹ fun ajọ awọn alufaa ile ajẹ́jẹ̀ẹ́ anikandagbe ati ti awọn katidira. Atunṣedọtun naa ni kò fopinsi sisan idamẹwaa rara, aṣa yii ni wọn sì nba lọ ninu Ṣọọṣi Roman Katoliki ati ni awọn orilẹ-ede Protẹstanti.” Sisan idamẹwaa ni a fopinsi tabi ṣe arọpo rẹ̀ ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ọpọ awọn ilẹ, awọn isin kereje ni wọn nlo aṣa naa nisinsinyi.

Nitori naa, nigba naa, njẹ a beere lọwọ awọn Kristẹni lati san idamẹwaa bi? Ninu iwe atọka awọn ẹsẹ Bibeli [concordance] rẹ̀, Alexander Cruden sọ pe: “Kii ṣe Olugbala wa, tabi awọn apọsiteli rẹ̀ ni wọn paṣẹ ohunkohun ninu ọran sisan idamẹwaa yii.” Niti tootọ, awọn Kristẹni ni a kò pa a laṣe fun lati san idamẹwaa. Ọlọrun funraarẹ ti fi opin si Ofin Mose, pẹlu awọn iṣeto sisan idamẹwaa rẹ̀, ni kikan an mọ opo igi idaloro Jesu. (Roomu 6:14; Kolose 2:13, 14) Kaka ti a bá fi beere fun fifunni ni iye pato kan lati mu awọn ọran inawo ijọ fuyẹ, nitori naa, awọn Kristẹni nṣe itọrẹ atinuwa.

Bọla fun Jehofa Pẹlu Awọn Ohun Ṣiṣeyebiye Rẹ

Amọ ṣaa o, bi Kristẹni kan ba finnufindọ yan lati funni ni idamẹwaa ohun ti nwọle fun un lati ṣe igbeleke ijọsin tootọ, ki yoo sí ipilẹ kan ti ó ba Iwe mimọ mu lati kọ ṣiṣe iru itọrẹ bẹẹ rẹ̀. Ninu lẹta kan ti ó pẹlu itọrẹ rẹ, ọmọde ọlọdun 15 kan ni Papua New Guinea kọwe pe: “Nigba ti emi ṣì kere, baba mi maa nsọ fun mi pe, ‘Nigba ti iwọ bá bẹrẹ si ni ṣiṣẹ, iwọ nilati fi akọso rẹ fun Jehofa.’ Emi ranti awọn ọrọ Owe 3:1, 9, eyi ti ó sọ pe awa nilati fi awọn akọso wa fun Jehofa lati bọla fun un. Nitori naa emi ṣeleri lati ṣe eyi, isinsinyi emi gbọdọ mu ileri mi ṣẹ. Emi layọ gidigidi lati fi owo yii ranṣẹ si yin lati ṣe iranwọ fun iṣẹ Ijọba naa.” Bibeli kò ké si awọn Kristẹni lati ṣe iru ileri kan bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, fifunni ọlọlawọ jẹ́ ọna rere kan lati fi itara mimuna wa han ninu ṣiṣe igbeleke ijọsin tootọ.

Kristẹni kan lè yan lati maṣe fi òté lé iye pato kan ninu awọn itọrẹ ti oun nṣe lati mu ijọsin Jehofa Ọlọrun tẹsiwaju. Lati ṣakawe eyi: Nigba ti wọn wà ni apejọpọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan, awọn arabinrin agbalagba meji njiroro nipa itọrẹ ti o ṣeeṣe ki wọn ṣe fun iṣẹ Ijọba naa. Nipa ti riri ounjẹ ni ilẹ apejọpọ naa, ọkan ninu awọn arabinrin naa, ti ó jẹ ẹni ọdun 87, beere nipa iye ti ó ṣeeṣe ki eyi tó ki oun baa lè fi iye naa gan-an tọrẹ. Arabinrin keji, ti ó jẹ ẹni 90 ọdun, sọ pe: ‘Ṣaa fi kiki ohun ti iwọ lero pe o tó silẹ—ati iye diẹ kun un.’ Iru iṣarasihuwa rere wo ni arabinrin agbalagba yii fihan!

Niwọn bi awọn eniyan Jehofa ti ya gbogbo ohun ti wọn ni si mimọ fun un patapata, wọn layọ lati ṣe awọn itọrẹ niti owo ati awọn iranlọwọ miiran lati ṣe itilẹhin fun ijọsin tootọ. (Fiwe 2 Kọrinti 8:12.) Niti tootọ, ọna ti awọn Kristẹni ngba funni pese awọn anfaani fun wọn lati fi imọriri wọn jijinlẹ fun ijọsin Jehofa han. Iru fifunni bẹẹ ni a kò fi mọ si ọrẹ idamẹwaa kan, awọn ipo miiran lè wà ninu eyi ti ẹnikọọkan lè di ẹni ti a sun lati fi pupọ sii funni lati mu ire Ijọba naa tẹsiwaju.—Matiu 6:33.

Apọsiteli Pọọlu sọ pe: “Ki olukuluku eniyan ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu ni ọkan rẹ̀; kii ṣe àfèkunṣe, tabi ti alaigbọdọmaṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ.” (2 Kọrinti 9:7) Bi iwọ ba fi inudidun ati ọlawọ ṣe itilẹhin fun ijọsin tootọ, iwọ yoo ṣe rere, nitori owe ọlọgbọn naa sọ pe: “Fi ohun ìní rẹ bọwọ fun Oluwa [“Jehofa,” NW], ati lati inu gbogbo akọbi ibisi oko rẹ: bẹẹ ni àká rẹ yoo kún fun ọpọlọpọ, ati àgbá rẹ yoo si kún fun ọti waini titun.”—Owe 3:9, 10.

Awa kò lè sọ Ọga-ogo Julọ naa di ọlọ́rọ̀. Tirẹ ni gbogbo awọn wura ati fadaka, awọn ẹranko igbo ni ẹgbẹẹgbẹrun wọn lori oke, ati awọn ohun iyebiye lailonka. (Saamu 50:10-12) Awa kò lè san asanpada fun Ọlọrun fun awọn ohun ti oun ti fi ṣanfaani fun wa lae. Ṣugbọn awa lè fi imọriri jijinlẹ fun un han ati fun anfaani ti a ni fun ṣiṣe iṣẹ-isin mimọ ọlọwọ si ogo rẹ̀. Awa sì lè ni idaniloju pe awọn ibukun ọlọraa nṣan sọdọ awọn wọnni ti wọn nfi tinutinu funni lati ṣe igbeleke ijọsin tootọ ati lati bọla fun Jehofa, Ọlọrun onifẹẹ ati ọlọlawọ naa.—2 Kọrinti 9:11.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

BI AWỌN KAN ṢE NṢE ITILẸHIN FUN IṢẸ IJỌBA NAA

◻ AWỌN ỌRẸ FUN IṢẸ YIKA-AYE: Ọpọlọpọ fi sọtọ tabi ṣeto fun iye owo kan ti wọn lè fi sinu awọn apoti ọrẹ ti o ni àkọlé naa: “Awọn Ọrẹ fun Iṣẹ Society Yika Ayé—Matiu 24:14.” Loṣooṣu ni ijọ nfi awọn owo wọnyi ranṣẹ yala si orile-iṣẹ agbaye ni Brooklyn, New York, tabi si ẹka ile-iṣẹ ti ó sunmọ wọn julọ.

◻ AWỌN Ẹ̀BÙN: Awọn itọrẹ owo ti a fínnúfíndọ̀ ṣe ni a lè firanṣẹ ni taarata si Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201, tabi si ẹka ile-iṣẹ agbegbe adugbo ti Society. Ẹṣọ okuta iyebiye tabi awọn nǹkan iyebiye miiran ni a lè fi tọrẹ pẹlu. Lẹta ṣoki kan ti o sọ pe iru eyi jẹ́ ẹbun patapata nilati ba awọn ọrẹ wọnyi wa.

◻ IṢETO IDAWO ONIPO AFILELẸ: Owo ni a lè fifun Watch Tower Society lati maa lò bii ohun afunniṣọ titi fi di igba iku olutọrẹ naa, pẹlu ipese pe ti ọran ìlò ara ẹni kan bá dide, a o da a pada fun ẹni ti o fi tọrẹ.

◻ OWÓ ÌDÍYELÓFÒ: Watch Tower Society ni a lè darukọ gẹgẹ bi olujanfaani ilana eto idiyelofo iwalaaye tabi ninu iwewee owo asanfunni ifẹhinti. Society ni a gbọdọ fi iru awọn iṣeto bẹẹ tó leti.

◻ AWỌN OWO AFIPAMỌ SI BANKI: Awọn owo afipamọ si banki, awọn iwe ẹ̀rí owo idokowo, tabi owo ifẹhinti ẹnikọọkan ti a fipamọ ni a lè fi sikaawọ tabi mu ki o ṣee san nigba iku fun Watch Tower Society, ni ibamu pẹlu awọn ohun abeere fun ti banki adugbo naa. Society ni a gbọdọ fi iru awọn iṣeto bẹẹ tó leti.

◻ AWỌN IWE Ẹ̀TỌ́ LORI OWO IDOKOWO ATI IWE Ẹ̀TỌ́ LORI OWO TI A FI YANI: Awọn iwe ẹ̀tọ́ lori owo idokowo ati iwe ẹ̀tọ́ lori owo ti a fi yani ni a lè fi tọrẹ fun Watch Tower Society yala gẹgẹ bi ẹbun patapata kan tabi labẹ iṣeto kan nibi ti a o ti maa baa lọ ni sisan owo ti ó wọle wá lori eyi fun olutọrẹ naa.

◻ ILE TABI ILẸ: Awọn ile tabi ilẹ ti ó ṣeeta ni a lè fi tọrẹ fun Watch Tower Society yala nipa ṣiṣe e ni ẹbun patapata kan tabi nipa pipa a mọ gẹgẹ bi ohun ìní olutọrẹ naa nigba ti ó bá ṣì walaaye, ẹni ti ó ṣì lè maa baa lọ lati gbe ninu rẹ nigba aye rẹ. Ẹni kan nilati kàn si Society ṣaaju fifi iwe aṣẹ sọ ile tabi ilẹ eyikeyii di ti Society.

◻ AWỌN IWE ÌHÁGÚN ATI OHUN ÌNI IFISIKAAWỌ: Dukia tabi owo ni a lè fisilẹ bi ogun fun Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania nipasẹ iwe ìhágún ti a muṣẹ labẹ ofin, tabi ti a lè darukọ Society gẹgẹ bi olujanfaani iru iwe adehun fifi ohun ìní sikaawọ ẹni bẹẹ. Awọn ohun ìní ifisikaawọ ti eto-ajọ isin kan njafaani ninu rẹ̀ le pese awọn anfaani melookan ninu ọran owo ori. Ẹ̀dà kan ninu iwe ìhágún tabi iwe ohun ìní ifisikaawọ ni a nilati fi ranṣẹ si Society.

Fun isọfunni siwaju sii nipa awọn koko ọran bẹẹ, kọwe si Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State. Nigeria.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́