ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 1/1 ojú ìwé 24-25
  • Jẹnẹsarẹti—‘Agbayanu ati Ẹlẹ́wà’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹnẹsarẹti—‘Agbayanu ati Ẹlẹ́wà’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wá Ṣèbẹ̀wò Yíká Òkun Galili!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì​—Apẹja
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ṣiṣiṣẹsin Gẹgẹ Bi Awọn Apẹja Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Mẹ́rin Di Apẹja Èèyàn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 1/1 ojú ìwé 24-25

Awọn Irisi-Iran Lati Ilẹ Ileri

Jẹnẹsarẹti—‘Agbayanu ati Ẹlẹ́wà’

“Lẹbẹẹba Adagun Jẹnẹsarẹti ni ìtẹ́rẹrẹ ilẹ igberiko kan tí ó ni orukọ kan naa, ti ó jẹ́ agbayanu ni àbùdá rẹ̀ ati ni ẹwà rẹ̀. Ki a dupẹ lọwọ ilẹ ọlọ́ràá naa kò sí irugbin ti kò gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nibẹ, awọn olugbe ibẹ sì ń gbin ohun gbogbo: afẹfẹ ibẹ múlọ́ daradara tobẹẹ debi pe ó dara fun ọpọ julọ iru ẹ̀dá oriṣiriṣi. . . . Kii ṣe kiki pe ó ń mu awọn eso oniruuru ti ń yanilẹnu julọ jade; o ń pa ipese ti ń baa lọ mọ. . . . A ń bomirin in nipasẹ odò tooro kan ti ó ni agbara ìmúlẹ̀sọjí giga.”

Bayii ni opitan Josephus ṣe ṣapejuwe pẹtẹlẹ onigun mẹta ti ó wà ni ikangun ariwa iwọ-oorun ohun ti a mọ lọna wiwọpọ si Okun Galili. Aworan ti ó wà loke yii le fun ọ ni oye bi pẹtẹlẹ yii ti jẹ́ amesojade tó, ọ̀kan lara ilẹ ẹlẹ́tùlójú ni Galili.a Agbegbe yii ṣe pataki gan-an ni akoko igbaani debi pe onkọwe Ihinrere naa Luuku pe okun ti kò ni iyọ ti ó wà ni odikeji ni “adagun Jẹnẹsarẹti.”—Luuku 5:1.

Ó lo gbolohun yẹn nigba ti ó ń sọ pe Jesu wá si agbegbe yii ó sì ri awọn ọkunrin mẹrin ti wọn di apọsiteli. Wọn ha jẹ́ àgbẹ̀ ti ó ń wa atijẹ lati inu ilẹ ẹlẹ́tùlójú naa, ti ń gbin eso ajara, àsálà, olifi, tabi ọpọtọ bi? Bẹẹkọ, iru awọn eso bẹẹ pọ yanturu lori Pẹtẹlẹ Jẹnẹsarẹti, ṣugbọn awọn ọkunrin wọnyi jẹ́ apẹja, ó sì rọrun lati loye idi ti wọn fi jẹ bẹẹ.

Ó ṣeeṣe pe odo kekere naa ti ó la pẹtẹlẹ naa kọja ń gbé awọn eweko ti ó lè di ounjẹ fun awọn ẹja lọ sinu okun naa. Nitori naa awọn odo naa ń gbáyìn-ìn fun oniruuru ẹja, ti ó sì yọrisi ile-iṣẹ ẹja titobi kan. Peteru ati Anderu jẹ apẹjatà nibẹ, gẹgẹ bi Jakọbu ati Johanu, awọn ọmọkunrin Sebede apẹja ti jẹ́.—Matiu 4:18-22; Luuku 5:2-11.

Niye ìgbà ẹja pipa ni a ń ṣe nipa titu àwọ̀n jade lati inu ọkọ àfàjẹ̀wà kan. Ohun ti Peteru ati Anderu ń ṣe niyẹn nigba ti Jesu tọ̀ wọn lọ. Àwọ̀n gigun kan, tabi àwọ̀n ńlá, ni a nà jade yika ni obiripo. Ilefoo onigi di igun oke mú, ọ̀rìn ti ó wà ni apa isalẹ mu ki àwọ̀n nà siha apa isalẹ okun. Ọpọ iye ẹja ni a lè mu ninu iru àwọ̀n kan bẹẹ. Lẹhin naa a fà á sinu ọkọ àjẹ̀ tabi wọ́ ọ sinu omi ti kò jìn, lati tú u jade ni etikun. Ẹja ti ó yẹ fun jijẹ ni a o yà sọtọ kuro lara awọn eyi tí kò yẹ. Ṣakiyesi ipeye kulẹkulẹ naa ni Luuku 5:4-7 ati Johanu 21:6-11. Iwọ ha ranti pe Jesu mẹnukan ọ̀nà ẹja pipa yii ninu apejuwe rẹ̀ ti àwọ̀n? (Matiu 13:47, 48) Ni afikun, Matiu 4:21 tẹnumọ ọn pe niye ìgbà awọn apẹja nilati lo akoko gigun ni titun àwọ̀n wọn ti ó já lara apata tabi nipasẹ awọn ẹja ṣe.

Bi iwọ ba rinrin-ajo lẹbaa etikun Jẹnẹsarẹti yii, ó ṣeeṣe ki iwọ ri awọn ọgangan bii melookan ti a sọ pe ó jẹ ibi ti awọn iṣẹlẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ Jesu ti ṣẹlẹ. Ọkan jẹ́ oke alawọ ewe lori eyi ti Jesu ti sọ Iwaasu rẹ̀ ori Oke, gẹgẹ bi itan atọwọdọwọ ti wi. Ibi aye yii kò forigbari pẹlu awọn akọsilẹ Ihinrere, nitori Jesu wà lẹbaa Pẹtẹlẹ Jẹnẹsarẹti nigba ti ó ń ṣe iwaasu naa.—Matiu 5:1–7:29; Luuku 6:17–7:1.

Ọgangan miiran ti a fidaniloju sọ pe ó jẹ́ otitọ kò ba otitọ Bibeli mu. Iwọ yoo ri ṣọọṣi kan ti a lerope a kọ́ si ibi ti Jesu ti bọ́ 4,000 lati inu ìṣù akara meje ati awọn ẹja wẹ́wẹ́ diẹ. (Matiu 15:32-38; Maaku 8:1-9) Dipo gbigbe eyi sori Pẹtẹlẹ Jẹnẹsarẹti, akọsilẹ Maaku mẹnukan “agbegbe Dẹkapoli,” eyi ti ó wà lodikeji okun ni eyi ti ó ju ibusọ meje lọ.—Maaku 7:31.

Matiu ati Maaku sọ pe lẹhin ṣiṣe iṣẹ iyanu yii, Jesu rin irin-ajo nipasẹ ọkọ àjẹ̀ lọ si Magadani, tabi Dalimanuta. (Matiu 15:39; Maaku 8:10) Awọn ọmọwe so ẹkùn yii pọ mọ Magidala (Migidala), eyi ti ó wà ni guusu Pẹtẹlẹ Jẹnẹsarẹti gan-an siha Tiberia. Ni ibamu pẹlu The Macmillan Bible Atlas, Magidala jẹ́ “olokiki fun ile-iṣẹ ẹja sísìn rẹ̀.” Ọpọ yanturu ẹja pipa ni apa adagun yii dajudaju lè mu ki iru ile-iṣẹ kan bẹẹ gbeṣẹ ki ó sì mu èrè wá.

Lọna ti ó runi lọkan soke, ọ̀dá kan ti ó ṣẹlẹ ni 1985/86 mu bèbè omi Okun Galili lọ silẹ, ni fifi pẹrẹsẹ isalẹ adagun naa han. Nitosi Pẹtẹlẹ Jẹnẹsarẹti, awọn ọkunrin meji ri afọku ọkọ àjẹ̀ igbaani kan. Awọn awalẹpitan lè hú ọkọ ẹja pipa onigi yii ti ó pẹ́ sẹhin si nǹkan bi akoko ti Jesu bẹ Adagun Pẹtẹlẹ Jẹnẹsarẹti wò.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo aworan alawọ meremere titobi ninu 1992 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Garo Nalbandian

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́