ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 11/1 ojú ìwé 24-25
  • Wá Ṣèbẹ̀wò Yíká Òkun Galili!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wá Ṣèbẹ̀wò Yíká Òkun Galili!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A7-E Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tó Ta Yọ Tí Jésù Ṣe ní Gálílì (Apá Kejì)
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Jésù Mú Kí Ìjì Dáwọ́ Dúró Lórí Òkun
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jẹnẹsarẹti—‘Agbayanu ati Ẹlẹ́wà’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 11/1 ojú ìwé 24-25

Àwọn Ìrísí Ìran Láti Ilẹ̀ Ìlérí

Wá Ṣèbẹ̀wò Yíká Òkun Galili!

IBI ààyè ilẹ̀ tí ó tètè máa ń wá sọ́kàn àwọn tí ń ka Bibeli ju Òkun Galili lọ kò pọ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ ha lè di ojú rẹ kí o sì fọkàn yàwòrán omi òkun tí kò níyọ̀ yìí, ní fífọkàndá àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì, bíi ibi ti Odò Jordani ń bá wọlé tí ó sì ń bá jáde tàbí ibi ti Kapernaumu àti Tiberia wà?

Wá àkókò láti farabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwòrán àgbókèèrèyà tí ó wà nísàlẹ̀ yìí, ni fífi í wéra pẹ̀lú amọ̀nà inú àkámọ́. Mélòó nínú àwọn ibi tí a kọ nọ́ḿbà sí ni o lè dá mọ̀? Bí èyí tí o mọ̀ nínú wọn bá ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni Bibeli rẹ yóò ṣe jẹ́ gidi sí ọ tí yóò sì nítumọ̀ tó. Fún ète yẹn, bá wa kálọ fún ìṣèbẹ̀wò yíká kúkúrú kan, tí ó kùn fún ẹ̀kọ́.

Àwòrán àgbókèèrèyà yìí ń wo apá ìhà àríwá ìlà oòrùn. Jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú #1. Apá ibo nínú òkun náà ni ìyẹn? Bẹ́ẹ̀ni, ìpẹ̀kun ìhà gúúsù, níbi ti odò Jordani ń bá jáde, tí yóò sì ṣàn gba àárín Samaria àti Gileadi kọjá lọ ṣàn sínú Òkun Òkú. Ìwọ lè túbọ̀ rí ìpẹ̀kun òkun yìí lọ́nà tímọ́tímọ́ síi ní apá òsì, a tún fihàn nínú 1993 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

Òkun Galili wà nísàlẹ̀ Àfonífojì Jíjìn Gìrìwò, nǹkan bíi igba mítà sísàlẹ̀ Òkun Meditareniani. Bí ó ti ń yẹ àwòrán àgbókèèrèyà náà wò, ṣàkíyèsí àwọn òkè-ńlá tí wọ́n yọrí láti èbúté ìlà-oòrùn rẹ̀ (láyìíká #7). Àwọn òkè kéékèèké àti òkè-ńlá tún yọrí ní èbúté tí ó wà nítòsí, tàbí ti ìwọ̀-oòrùn, tí ó tẹnumọ́ ọn pé òkun yìí wà nínú kòtò gìrìwò kan, bí òkun náà ti jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlélógún ní gígùn tí pátápinrá fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ kìlómítà méjìlá. Àlàfo àyè wà lórí àwọn èbúté náà fún abúlé àti àwọn ìlú-ńlá pàápàá, bíi Tiberia (#2). Padà rántí pé ogunlọ́gọ̀ kan nínú ọkọ̀ láti Tiberia sọdá òkun náà lọ sí ibi ti Jesu ti bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ́nà iṣẹ́-ìyanu.—Johannu 6:1, 10, 17, 23.

Bí o ti ń tọ etí èbúté náà lọ láti Tiberia, ìwọ yóò kọjá ẹkùn-ilẹ̀ ẹlẹ́tùlójú ti Gennesareti (#3).a Ní àyíká yìí Jesu ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó sì ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé lórí èbúté tí ó wà nítòsí, ni ó ti késí Peteru àti àwọn mẹ́ta mìíràn láti di “apẹja ènìyàn,” gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn nínú àwòrán lókè. (Matteu 4:18-22) Bí o ti ń rìnrìn-àjò nìṣó, ìwọ yóò dé Kapernaumu (#4), tí ó jẹ́ ibùdó ìgbòkègbodò fún Jesu, a tilẹ̀ pè é ní “ìlú òun tìkáraarẹ̀.” (Matteu 4:13-17; 9:1, 9-11; Luku 4:16, 23, 31, 38-41) Bí o ti ń bá a lọ síhà ìlà-oòrùn láyìíká òkun náà, ìwọ yóò la (#5) kọjá níbi tí Jordani apá òkè ti ń ṣàn sínú òkun (nísàlẹ̀). Nígbà náà ni ìwọ yóò dé agbègbè Betsaida (#6).

A tilẹ̀ lè lo ìwọ̀nba ibi ààyè ilẹ̀ wọ̀nyí láti ṣàkàwé bí ìmọ̀ rẹ nípa Òkun Galili ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀lé, àti láti fojú-inú-wo, àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli. Lẹ́yìn ti Jesu ti bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní agbègbè Betsaida tí ogunlọ́gọ̀ kan sì fẹ́ láti fi jọba, ó rán àwọn aposteli nínú ọkọ̀ lọ síhà Kapernaumu. Nígbà ìrìn-àjò wọn lórí òkun, ẹ̀fúùfù ìjì ṣàdéédéé fẹ́ wá láti orí àwọn òkè-ńlá ó sì ru ìgbì sókè, ní dída jìnnìjìnnì bo àwọn aposteli. Ṣùgbọ́n Jesu tọ̀ wọ́n wá ó ń rìn lórí òkun, ó dá ìjì náà dúró, ó sì mú kí ó ṣeéṣe fún wọn láti gúnlẹ̀ sẹ́bàá Gennesareti láìséwu. (Matteu 14:13-34) Àwọn tí wọ́n ti Tiberia wá tún kọjá wá sí Kapernaumu lẹ́ẹ̀kan síi.—Johannu 6:15, 23, 24.

Bí o ti ń báa lọ láyìíká apá ìlà-oòrùn òkun náà, ìwọ yóò kọjá ohun kan tí ó ṣeéṣe kí a ti tọ́kasí gẹ́gẹ́ bí “ilẹ̀ àwọn ará Gergesene [tàbí, Gadara].” Padà rántí pé níhìn-ín Jesu lé ẹ̀mí-èṣù jáde lára àwọn ọkùnrin méjì. Àwọn ẹ̀mí wọ̀nyẹn lọ́nà ìwà-ìkà wọnú agbo àwọn ẹ̀lẹ́dẹ̀ ńlá kan lọ, èyí tí ó túpùú gba orí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta lọ sínú òkun. Lẹ́yìnwá ìgbà náà ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà jẹ́rìí ní àwọn ìlú-ńlá ìtòsí tí ń sọ èdè Griki ní Dekapoli. Jesu dé agbègbè yìí ó sì kúrò níbẹ̀ nípasẹ̀ ọkọ̀ ojú-omi rékọjá Òkun Galili.—Matteu 8:28–9:1; Marku 5:1-21.

Bí o bá ti wá sí ìparí ìṣèbẹ̀wò yíká rẹ síhà apá ìsàlẹ̀ òkun náà, ìwọ yóò kọjá nítòsí ibi odò ńlá kan (tí a ń pè ní Yarmuk) tí ń mú omi tí ó pọ̀ tó wá sí Odò Jordani ti ìsàlẹ̀.

Bibeli kò tọ́ka ibi tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nítòsí Òkun Galili ti wáyé ní pàtó, bíi ìfarahàn Jesu lẹ́yìn àjíǹde nígbà tí Peteru àti àwọn aposteli yòókù ń pẹja (nísàlẹ̀). Ìwọ ha rò pé nítòsí Kapernaumu ni bí? Lọ́nàkọnà ṣá, ìmọ̀ rẹ nípa òkun pàtàkì yìí ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fojú-inú wo ṣíṣeéṣe náà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Jẹnẹsarẹti—‘Agbayanu ati Ẹlẹ́wà’” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti January 1, 1992.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

1

2

3

4

5

6

7

N

S

E

W

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwés 24, 25]

Garo Nalbandian

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́