ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 1/15 ojú ìwé 9-14
  • Ayọ Ainipẹkun Duro De Awọn Olufunni Oniwa-bi-Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayọ Ainipẹkun Duro De Awọn Olufunni Oniwa-bi-Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹbun Ọlọrun ti “Ọmọkunrin Ifẹ Rẹ̀”
  • Pipadanu Ti Isirẹli Padanu Ẹbun Titobi Lati Ọdọ Ọlọrun
  • Ayọ Fifunni
  • A Mu Ayọ Ainipẹkun Daju
  • Kí Nìdí Tí Ẹ̀bùn Yìí Fi Ṣe Iyebíye Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Bí Iṣẹ́ Tí Jésù Kristi Jẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Ju Gbogbo Ẹ̀bùn Lọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ṣé Ọmọ Ọlọ́run Ni Jésù Lóòótọ́?
    Jí!—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 1/15 ojú ìwé 9-14

Ayọ Ainipẹkun Duro De Awọn Olufunni Oniwa-bi-Ọlọrun

“Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹẹ gẹẹ ti ó fi fi Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀ funni, ki olukuluku ẹni ti o ba lo igbagbọ ninu rẹ̀ má baa parun ṣugbọn ki ó lè ni iye ainipẹkun.”—JOHANU 3:16, NW.

1, 2. (a) Ta ni Olufunni titobi julọ, ki sì ni ẹbun titobi julọ rẹ̀ fun araye? (b) Ni fifunni ni ẹbun titobi julọ rẹ̀, animọ wo ni Ọlọrun fihan?

JEHOFA ỌLỌRUN ni Olufunni titobi julọ ninu gbogbo olufunni. Ó jẹ́ nipa rẹ̀, Ẹlẹdaa ọrun ati ilẹ-aye, ni Kristẹni ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kọwe pe: “Gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pípé lati oke ni o ti wa, o si ń sọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹni ti kò lè sí iyipada tabi ojiji àyídà.” (Jakobu 1:17) Jehofa tún ni Olufunni ni ẹbun titobi julọ ti a tii fifunni rí. Nipa ẹbun rẹ̀ titobi julọ fun araye, a sọ pe: “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹẹ gẹẹ ti ó fi fi Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀ funni, ki olukuluku ẹni ti o ba lo igbagbọ ninu rẹ̀ má baa parun ṣugbọn ki ó lè ni ìyè ainipẹkun.”—Johanu 3:16, NW.

2 Ẹni ti o sọ awọn ọrọ wọnni kii ṣe ẹlomiran bikoṣe Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo ti Ọlọrun yẹn funraarẹ. Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo kan ti baba kan yoo mọriri yoo sì nífẹ̀ẹ́ iru baba bẹẹ lọna adanida gẹgẹ bi orisun iwalaaye rẹ̀ ati gbogbo ohun rere ti ó ti pese fun igbadun iwalaaye rẹ̀. Ṣugbọn ifẹ Ọlọrun ni a kò fi mọ sọdọ Ọmọkunrin yii nikan. Lati nasẹ iru ẹbun bẹẹ si awọn miiran ninu awọn iṣẹda rẹ̀ yoo fi lilo ti Ọlọrun ń lo ifẹ dé iwọn ara-ọtọ han. (Fiwe Roomu 5:8-10.) Eyi ni ó ṣe kedere sii nigba ti a ba ṣayẹwo ohun ti ọrọ naa “fifunni” tumọsi niti gidi ninu ayika ọrọ yii.

Ẹbun Ọlọrun ti “Ọmọkunrin Ifẹ Rẹ̀”

3. Yatọ si “ọmọkunrin ifẹ rẹ̀,” awọn miiran wo ni wọn gbadun ifẹ Baba ti ọrun naa?

3 Fun akoko ti a kò sọ, Ọlọrun ti gbadun ibakẹgbẹ ara-ẹni pẹlu Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo yii—“Ọmọkunrin ifẹ rẹ̀”—ninu ilẹ akoso ti ọrun. (Kolose 1:13, NW) Ni gbogbo akoko yẹn, Baba ati Ọmọkunrin ti pọ ni ifẹ ati ifẹni fun araawọn ẹnikinni keji pupọpupọ debi pe kò si ifẹ tọtuntosi kankan ti ó dabi tiwọn. Awọn ẹ̀dá miiran ti Ọlọrun mu wá sí ààyè nipasẹ Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀ ni a tun nífẹ̀ẹ́ gẹgẹ bi awọn mẹmba idile atọrunwa ti Jehofa. Nipa bayii, ifẹ jọba lori gbogbo idile Ọlọrun. A sọ ọ lọna titọ ninu Iwe Mimọ pe “Ọlọrun jẹ́ ifẹ.” (1 Johanu 4:8, NW) Nitori naa idile atọrunwa naa, ni apapọ rẹ̀ yoo jẹ́ awọn wọnni ti Baba naa, Jehofa Ọlọrun fẹran.

4. Bawo ni fifun ti Ọlọrun funni ni Ọmọkunrin rẹ̀ ṣe ni ninu ju ipadanu ibakẹgbẹ ara-ẹni, nititori awọn wo sì ni?

4 Pẹkipẹki gan-an ni ìdè ti o wa laaarin Jehofa ati Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀ debi pe fifi iru ibakẹgbẹpọ timọtimọ bẹẹ du araawọn yoo jẹ ipadanu ńlá kan ninu araarẹ. (Kolose 1:15) Ṣugbọn ‘fífúnni’ ni Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo yii tumọsi ohun pupọ ju fifi ti Ọlọrun fi ibakẹgbẹ ara-ẹni pẹlu “Ọmọkunrin ifẹ rẹ̀” du araarẹ. Ó lọ ani de iwọn yiyọnda ti Jehofa yọnda Ọmọkunrin rẹ̀ lati di ẹni ti o la ikú kọja ti o sì tipa bẹẹ di ẹni ti a mu kuro láàyè gẹgẹ bi mẹmba idile agbaye Ọlọrun fun igba kukuru. Eyi jẹ́ iku nititori awọn wọnni ti wọn kò tíì figba kankan jẹ́ mẹmba idile Ọlọrun rí. Kò tun si ẹbun titobi kankan ti Jehofa lè ṣe nitori iran eniyan alaini ju Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀, ẹni ti Iwe Mimọ tun fihan gẹgẹ bii “olupilẹṣẹ ẹ̀dá Ọlọrun.”—Iṣipaya 3:14.

5. (a) Ki ni ipo iṣoro awọn ọmọ Adamu, ki si ni idajọ-ododo Ọlọrun beere fun ni apa ọdọ ọ̀kan lara awọn ọmọkunrin oluṣotitọ Rẹ̀? (b) Ki ni ẹbun Ọlọrun titobi julọ yoo beere fun ni ìhà ọdọ tirẹ?

5 Tọkọtaya ẹ̀dá eniyan akọkọ, Adamu ati Efa, kuna lati pa ipo wọn mọ gẹgẹ bii mẹmba idile Ọlọrun. Iyẹn ni ipo ti wọn ba araawọn lẹhin ti a lé wọn jade kuro ninu ọgba Edẹni nitori didẹṣẹ si Ọlọrun. Kii ṣe kiki pe wọn kii ṣe mẹmba idile Ọlọrun mọ ṣugbọn wọn tun wà labẹ idajọ iku. Nitori naa, iṣoro naa kii wulẹ ṣe ti mimu iru ọmọ wọn padabọsipo si ojurere Ọlọrun gẹgẹ bii mẹmba idile rẹ̀ ṣugbọn ti gbigbe idajọ iku atọrunwa naa kuro lori wọn. Ni ibamu pẹlu ọ̀nà iṣiṣẹ idajọ-ododo atọrunwa, eyi yoo beere pe ki ọ̀kan lara awọn ọmọkunrin ododo ti Ọlọrun niriiri iku gẹgẹ bi afidipo, tabi irapada kan. Fun idi yii, ibeere titobi naa ni pe: Ǹjẹ́ ẹni naa ti a yan yoo ha muratan lati la iru iku onifidipo bẹẹ kọja nititori awọn eniyan ẹlẹṣẹ? Siwaju sii, jíjẹ́ ki eyi ṣẹlẹ yoo beere iṣẹ iyanu kan ni ìhà ọdọ Ọlọrun Olodumare. Yoo tun beere ifihan ifẹ atọrunwa dé iwọn ti kò lẹgbẹ.—Roomu 8:32.

6. Bawo ni Ọmọkunrin Ọlọrun ṣe kún oju iwọn aini ipo ti ó wémọ́ araye ẹlẹṣẹ, ki ni o sì sọ ninu ọran yii?

6 Ọmọkunrin akọbi Jehofa nikan ni ó lè kún oju iwọn awọn aini akanṣe ipo naa ti ó wémọ́ araye ẹlẹṣẹ. Ó jẹ́ aworan Baba rẹ̀ ọrun tobẹẹ gẹẹ ninu fifi ifẹni han fun awọn mẹmba idile ti Ọlọrun mu jade naa debi pe oun kò ni abaradọgba laaarin awọn ọmọkunrin Ọlọrun. Niwọn bi ó ti jẹ pe gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye ti ó kù ni a mú wá si ààyè nipasẹ rẹ̀, ó daju pe ifẹni rẹ fun wọn yoo pọ̀ yanturu ni. Siwaju sii, ifẹ jẹ́ animọ ṣiṣe pataki julọ ti Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo Jehofa, Jesu Kristi, nitori pe ‘ó jẹ́ itanṣan ogo [Ọlọrun] ati aworan deedee ti wíwà rẹ̀ gan-an.” (Heberu 1:3, NW) Ni fifi imuratan rẹ̀ lati fi ifẹ yii han dé iwọn titobi julọ nipa fifunni ni iwalaaye rẹ̀ nititori araye ẹlẹṣẹ, Jesu sọ fun awọn apọsiteli rẹ̀ mejila pe: “Ọmọkunrin eniyan paapaa wá, kii ṣe ki a ṣeranṣẹ fun un, bikoṣe ki ó ṣeranṣẹ ki o si fi ọkàn rẹ̀ funni ni irapada ni pàṣípààrọ̀ fun ọpọlọpọ.”—Maaku 10:45, NW; tun wo Johanu 15:13.

7, 8. (a) Ki ni ètè isunniṣe Jehofa ni rírán Jesu Kristi wá sinu aye araye? (b) Sẹnu iṣẹ wo ni Ọlọrun ran Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀?

7 Jehofa Ọlọrun ní idi akanṣe fun rírán Jesu wá sinu ayé araye ti a sọ dotoṣi yii. Ifẹ atọrunwa ni ète isunniṣe fun eyi, nitori pe Jesu funraarẹ sọ pe: “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹẹ gẹẹ ti ó fi fi Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀ funni, ki olukuluku ẹni ti ó bá lo igbagbọ ninu rẹ̀ má baa parun ṣugbọn ki ó lè ni ìyè ainipẹkun. Nitori Ọlọrun rán Ọmọkunrin rẹ̀ wá si ayé, kii ṣe fun un lati ṣedajọ ayé, bikoṣe ki a lè gba ayé là nipasẹ rẹ̀.”—Johanu 3:16, 17, NW.

8 Ó jẹ́ si ẹnu iṣẹ igbala ni Jehofa fi tifẹtifẹ ran Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀. Ọlọrun kò rán Ọmọkunrin rẹ̀ wá sihin-in ki ó baa lè dá ayé lẹjọ. Bi a bá ti rán Ọmọkunrin Ọlọrun ni iru iṣẹ idajọ bẹẹ, ireti ọjọ-ọla araye ni kì bá tí ṣeeṣe. Aṣẹ idajọ mimuna tí Jesu Kristi ìbá ti polongo sori idile eniyan ìbá ti jẹ́ ìdálẹ́bi iku. (Roomu 5:12) Nipa bayii, nipasẹ ifihan ifẹ atọrunwa alailẹgbẹ yii, Ọlọrun mu aṣẹ idajọ ikú tí idajọ ododo pọnbele ìbá ti beere fun baradọgba.

9. Imọlara wo ni Dafidi onisaamu naa ni nipa fifunni Jehofa?

9 Ninu gbogbo nǹkan, Jehofa Ọlọrun fi ifẹ han ó sì ń ṣe e ni aṣehan gẹgẹ bi iha ti ó tayọ ninu animọ rẹ̀. A sì lè sọ lọna ti ó tọna pe Ọlọrun fi tifẹtifẹ fun awọn olujọsin rẹ̀ lori ilẹ-aye ni ohun ti ó pọ lapọto niti awọn ohun rere. Onisaamu naa Dafidi nimọlara lọna yẹn nipa ọran naa nigba ti ó sọ fun Ọlọrun pe: “Oore rẹ ti tobi tó, ti iwọ fi ṣúra de awọn ti ó bẹru rẹ: Oore ti iwọ ti ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ eniyan!” (Saamu 31:19) Ni ìgbà ijọba Dafidi lori orilẹ-ede Isirẹli—bẹẹni, jalẹ igbesi-aye rẹ̀ gẹgẹ bii mẹmba orilẹ-ede yẹn ti Ọlọrun yàn lọna akanṣe—oun niye igba niriiri oore Jehofa. Dafidi sì rii pe ó jẹ́ ọpọ yanturu.

Pipadanu Ti Isirẹli Padanu Ẹbun Titobi Lati Ọdọ Ọlọrun

10. Eeṣe ti Isirẹli igbaani kò fi dabi orilẹ-ede eyikeyii miiran lori ilẹ-aye?

10 Nipa níní Jehofa gẹgẹ bi Ọlọrun rẹ̀, Isirẹli igbaani kò dabi orilẹ-ede eyikeyii lori ilẹ-aye. Nipasẹ wolii Mose gẹgẹ bi alárinà, Jehofa mu àtọmọdọ́mọ Aburahamu, Isaaki, ati Jakọbu wa sinu ibatan onimajẹmu pẹlu araarẹ. Oun kò tii bá orilẹ-ede eyikeyii miiran lò ni iru ọna yii. Nitori naa, onisaamu ti a mísí naa polongo pe: “Ó fi ọrọ rẹ̀ hàn fun Jakọbu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Isirẹli. Kò ba orilẹ-ede kan ṣe bẹẹ rí; bi o sì ṣe ti idajọ rẹ̀ ni, wọn kò mọ̀ wọn. Ẹ fi iyin fun Oluwa.”—Saamu 147:19, 20.

11. Titi di ìgbà wo ni Isirẹli gbadun ipo olojurere rẹ̀ pẹlu Ọlọrun, bawo sì ni Jesu ṣe sọ iyipada ninu ipo ibatan wọn?

11 Orilẹ-ede Isirẹli ti ara ń baa lọ ninu ipo ibatan olojurere yii pẹlu Ọlọrun titi ti ó fi kọ̀ Jesu Kristi silẹ gẹgẹ bii Mesaya naa ni ọdun 33 ti Sanmani Tiwa. Ó jẹ́ ọjọ ibanujẹ gan-an fun Isirẹli nigba ti Jesu fẹnulé igbe ìkáàánú yii pe: “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, olùpa awọn wolii ati olùsọ okuta lu awọn wọnni ti a rán jade si i,—bawo ni o ti jẹ nigbakuugba tó ti emi ti fẹ́ kó awọn ọmọ rẹ jọpọ, ni ọna ti àgbébọ̀ adiẹ fi ń kó awọn òròmọdìẹ rẹ̀ jọpọ sabẹ iyẹ apa rẹ̀! Ṣugbọn ẹyin eniyan kò fẹ́ ẹ. Wò ó! A pa ile yin tì fun yin.” (Matiu 23:37, 38, NW) Awọn ọrọ Jesu fihan pe orilẹ-ede Isirẹli, bi o tilẹ jẹ pe Jehofa ṣe ojurere si i ni iṣaaju, ti padanu ẹbun akanṣe kan lati ọdọ Ọlọrun. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ?

12. Awọn wo ni ‘awọn ọmọ Jerusalẹmu,’ ki ni yoo sì ti tumọsi fun Jesu lati kó wọn jọpọ?

12 Nipa lilo ede isọrọ naa “awọn ọmọ,” Jesu tọka si kiki awọn Juu nipa ti ara ti a kọ nila ti wọn gbe ni Jerusalẹmu ti wọn sì duro fun gbogbo orilẹ-ede awọn Juu. Fun Jesu lati kó ‘awọn ọmọ Jerusalẹmu’ jọpọ ìbá ti tumọ si pe ki oun mu “awọn ọmọ” wọnyi wá sinu majẹmu titun pẹlu Ọlọrun, pẹlu oun funraarẹ gẹgẹ bi Alárinà laaarin Jehofa ati awọn Juu nipa ti ara wọnyi. (Jeremaya 31:31-34) Eyi ìbá ti yọrisi idariji ẹṣẹ, nitori pe bẹẹ ni ifẹ Ọlọrun gbòòrò tó. (Fiwe Malaki 1:2.) Eyi nitootọ ìbá ti jẹ́ ẹbun titobi kan.

13. Pipa ti Isirẹli pa Ọmọkunrin Ọlọrun tì yọrisi ipadanu wo, ṣugbọn eeṣe ti ayọ Jehofa kò fi dinku?

13 Ni ibamu pẹlu Ọrọ alasọtẹlẹ rẹ̀, Jehofa duro di ìgbà ti ó ba ọgbọn mu tó ṣaaju ki ó tó nawọ ẹbun didi alábàápín majẹmu titun naa fun awọn ti kii ṣe Juu. Ṣugbọn nipa ṣíṣá Ọmọkunrin Ọlọrun funraarẹ, Mesaya naa tì, orilẹ-ede Isirẹli ti ara padanu ẹbun titobi yii. Nitori naa Jehofa mu ṣiṣa Ọmọkunrin rẹ̀ tì baradọgba nipa ninawọ ẹbun yii si awọn eniyan ti wọn rekọja orilẹ-ede Juu. Ni ọna yẹn, ayọ Jehofa gẹgẹ bi Olufunni Titobi ń baa lọ laidinku.

Ayọ Fifunni

14. Eeṣe ti Jesu Kristi fi jẹ́ ẹ̀dá ti o ni ayọ julọ ninu gbogbo agbaye?

14 Jehofa ni “Ọlọrun alayọ naa.” (1 Timoti 1:11, NW) Fifun awọn ẹlomiran jẹ́ ohun kan ti ń mu un layọ. Ati ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀ sọ pe: “Ayọ pupọ ń bẹ ninu fifunni ju eyi ti ó wà ninu ririgba lọ.” (Iṣe 20:35, NW) Ni ibamu pẹlu ilana yii, Jesu ti di alayọ julọ lara ẹ̀dá ti Ẹlẹdaa gbogbo agbaye. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ? O dara, tẹle Jehofa Ọlọrun funraarẹ, Jesu Kristi ti funni ni ẹbun titobi ju gbogbo rẹ̀ lọ nipa fifi ẹmi rẹ lélẹ̀ fun anfaani araye. Nitootọ, oun ni ‘alayọ Ọba alagbara giga’ naa. (1 Timoti 6:15) Jesu tipa bayii ṣapẹẹrẹ ohun ti ó sọ nipa ayọ pupọ sii ti fifunni.

15. Ki ni Jehofa kò ni dawọduro lae lati jẹ́ apẹẹrẹ rẹ̀, bawo sì ni awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye rẹ̀ ṣe lè niriiri iwọn kan ninu ayọ rẹ̀?

15 Nipasẹ Jesu Kristi, Jehofa Ọlọrun kò ni kuna lae lati jẹ́ Olufunni ọlọlawọ fun gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye rẹ̀ yoo sì maa figba gbogbo jẹ́ apẹẹrẹ wọn didara julọ ninu fifunni. Ani bi Ọlọrun ti ri idunnu ninu fifun awọn ẹlomiran ni awọn ẹbun rere, bẹẹ ni ó ti fi ẹmi ọlawọ sinu ọkan-aya awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye rẹ̀ ori ilẹ-aye. Ni ọna yẹn wọn fihan wọn sì ṣafarawe animọ rẹ̀ wọn sì niriiri iwọn kan ninu ayọ rẹ̀. (Jẹnẹsisi 1:26; Efesu 5:1) Lọna ti o yẹ rẹgi, Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ sọ fifunni di àṣà, awọn eniyan yoo si maa fifun yin. Wọn yoo dà si itan yin oṣuwọn rere, ti a kì mọ́lẹ̀, ti a mì papọ ti ó sì kún akunwọsilẹ. Nitori oṣuwọn ti ẹ ba fi ń wọ̀n jade, ni wọn yoo fi wọ̀n fun yin.”—Luuku 6:38.

16. Fifunni wo ni Jesu tọka si ni Luuku 6:38?

16 Jesu gbe apẹẹrẹ titayọ kalẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ niti sisọ ipa-ọna fifunni dàṣà. Ó sọ pe idahunpada rere yoo wà fun iru fifunni bẹẹ lati ọdọ awọn ti wọn gbà á. Ni Luuku 6:38, Jesu kò tọka si kiki fifunni ni awọn ẹbun ohun ti ara. Oun kò sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati le ipa-ọna kan ti yoo sọ wọn dotoṣi niti ohun ti ara. Kaka bẹẹ, ó ń dari wọn si ipa-ọna kan ti yoo fun wọn ni òye aṣeyọri tẹmi.

A Mu Ayọ Ainipẹkun Daju

17. Ẹbun agbayanu wo ni Ọlọrun ti tú sori awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi?

17 Iru ẹbun agbayanu wo ni Jehofa, Olori gbogbo iṣẹda, ti fi jíǹkí awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi! Ó ti fun wa ni ihinrere Ijọba rẹ̀. A ni anfaani titobi ti jíjẹ́ olupolongo Ijọba Ọlọrun eyi ti a ti fidii rẹ̀ mulẹ ni ọwọ Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi tí ń jọba. (Matiu 24:14; Maaku 13:10) Pe a fi wa ṣe Ẹlẹ́rìí ọlọ́rọ̀ ẹnu ti Ọlọrun Ọga-Ogo jẹ́ ẹbun kan ti ó kọja afiwe, ọna ti ó sì dara julọ ti a lè gbà sọ fifunni daṣa ní ṣiṣafarawe Ọlọrun ni lati ṣajọpin ihin-iṣẹ Ijọba naa pẹlu awọn ẹlomiran ṣaaju ki opin eto igbekalẹ awọn nǹkan buburu yii tó dé.

18. Bi Ẹlẹ́rìí Jehofa, ki ni a gbọdọ fi fun awọn ẹlomiran?

18 Apọsiteli Pọọlu tọka si awọn inira ti oun nilati niriiri wọn nigba ti ó ń polongo ihin-iṣẹ Ijọba naa fun awọn miiran. (2 Kọrinti 11:23-27) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ode oni pẹlu nilati niriiri awọn inira ki wọn sì pa ohun tí wọn yànláàyò tì sẹgbẹẹkan ninu isapa lati fun awọn miiran ni ireti Ijọba naa. A lè má ni itẹsi lati lọ sẹnu ọna awọn eniyan, paapaa bi a ba ń tijú. Ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ọmọlẹhin Jesu, a kò lè yẹra fun, tabi yàgò fun anfaani fifun awọn ẹlomiran ni awọn ohun tẹmi nipa wiwaasu “ihinrere ijọba yii.” (Matiu 24:14) Ó yẹ ki a ni iṣarasihuwa kan naa ti Jesu ni. Nigba ti ó doju kọ iku, ó gbadura pe: “Baba mi, . . . kii ṣe bi ifẹ-inu mi, bikoṣe bi ifẹ-inu rẹ.” (Matiu 26:39, NW) Ninu ọran fifun awọn ẹlomiran ni ihinrere Ijọba naa, awọn iranṣẹ Jehofa gbọdọ ṣe ifẹ-inu Ọlọrun, kii ṣe tiwọn—ohun ti ó ń fẹ, kii ṣe ohun ti wọn lè fẹ́.

19. Awọn wo ni Olùni “awọn ibi gbígbé ainipẹkun,” bawo sì ni a ṣe lè yan ọ̀rẹ́ pẹlu wọn?

19 Iru fifunni bẹẹ yoo ni akoko ati awọn ohun àmúṣọrọ̀ wa ninu, ṣugbọn nipa jíjẹ́ olufunni oniwa-bi-Ọlọrun, a ri i daju pe ayọ wa yoo jẹ́ alainipẹkun. Eeṣe? Nitori pe Jesu sọ pe: “Ẹ yan ọ̀rẹ́ fun araayin nipasẹ ọrọ̀ aiṣododo [“ọrọ̀ ti ayé,” New International Version (Gẹẹsi)], nigba ti iru bẹẹ bá kuna, ki wọn lè gbà yin si awọn ibi gbigbe ainipẹkun.” (Luuku 16:9, NW) Ó gbọdọ jẹ ilepa wa lati lo “awọn ọrọ̀ aiṣododo” lati yan ọ̀rẹ́ pẹlu awọn Olùni “awọn ibi gbígbé ainipẹkun.” Gẹgẹ bi Ẹlẹdaa, Jehofa ni ó ni ohun gbogbo, Ọmọkunrin akọbi rẹ̀ sì ṣajọpin ninu ipo jíjẹ́ oni-nǹkan yẹn gẹgẹ bi Ajogun ohun gbogbo. (Saamu 50:10-12; Heberu 1:1, 2) Lati yan ọ̀rẹ́ pẹlu wọn, a gbọdọ lo awọn ọrọ̀ ni ọna kan ti ń mú itẹwọgba wọn wá. Eyi kan níní iṣarasihuwa titọna ninu lilo awọn ohun ti ara fun ire awọn ẹlomiran. (Fiwe Matiu 6:3, 4; 2 Kọrinti 9:7.) A lè lo owo ni ọna bibojumu lati daabobo ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹlu Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi. Fun apẹẹrẹ, a ń ṣe eyi nipa fifi ọ̀yàyà lo awọn ohun ti a ní fun aranṣe awọn eniyan ti wọn wà ninu aini ati ni níná awọn ohun àmúṣọrọ̀ wa lati mu awọn ire Ijọba Ọlọrun tẹsiwaju.—Owe 19:17; Matiu 6:33.

20. (a) Eeṣe ti Jehofa ati Jesu fi lè mu wa wọnu “awọn ibi gbígbé ainipẹkun,” nibo sì ni ibi wọnyi lè jẹ́? (b) Anfaani wo ni yoo jẹ́ tiwa jalẹ ayeraye?

20 Nitori aileeku wọn, Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi lè jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa titilae wọn sì lè mú wa wọle sinu “awọn ibi gbígbé ainipẹkun.” Eyi rí bẹẹ yala iwọnyi yoo jẹ́ ni ọrun pẹlu gbogbo awọn angẹli mímọ́ tabi lori ilẹ-aye ninu Paradise ti a mú padabọsipo. (Luuku 23:43) Jesu Kristi ẹbun onifẹẹ ti Ọlọrun mú kí gbogbo eyi ṣeeṣe. (Johanu 3:16) Jehofa Ọlọrun yoo sì lo Jesu lati maa baa lọ lati fifun gbogbo ìṣẹ̀dá, si ayọ alailẹgbẹ Tirẹ funraarẹ. Nitootọ, jalẹ ayeraye awa funraawa yoo ni anfaani fifunni labẹ ipo ọba-alaṣẹ agbaye Jehofa Ọlọrun ati ipo ọba Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀, Oluwa ati Olugbala wa, Jesu Kristi. Eyi yoo yọri si ayọ ainipẹkun fun gbogbo awọn olufunni oniwa-bi-Ọlọrun.

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Ki ni ẹbun titobi julọ ti Ọlọrun yoo beere fun ni ìhà tirẹ̀?

◻ Sẹnu iṣẹ wo ni Ọlọrun ran Ọmọkunrin rẹ̀?

◻ Ta ni ẹ̀dá ti o ni ayọ julọ ni agbaye, eesitiṣe?

◻ Bawo ni awọn olufunni oniwa-bi-Ọlọrun yoo ṣe niriiri ayọ ainipẹkun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Iwọ ha mọriri ẹbun Ọlọrun ti Ọmọkunrin rẹ̀ gẹgẹ bi ẹbọ irapada kan bi?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Iwọ ha ń wá Ijọba Ọlọrun lakọọkọ nipa wiwaasu ihinrere ati nipa titi iṣẹ yẹn lẹhin pẹlu awọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́