ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 2/1 ojú ìwé 29-30
  • “Iṣeun-Ifẹ Rẹ̀ Ti Pọ̀ Jaburata”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Iṣeun-Ifẹ Rẹ̀ Ti Pọ̀ Jaburata”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ninu Ẹgbẹ́ Ọmọ-Ogun ati Lẹhin Naa
  • Igbesi-Aye Mi Yipada
  • Iṣẹ-Ojiṣẹ Alakooko Kikun
  • Sísìn Tọkàntọkàn Lójú Onírúurú Àdánwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ṣé O Lè Lọ Sìn Níbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ẹ Wo Báwọn Èèyàn Ṣe Ta Ẹ̀jẹ̀ Sílẹ̀ Lórúkọ Kristi
    Jí!—2005
  • Wíwá Tí A Wá Àìṣègbè Kiri
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 2/1 ojú ìwé 29-30

“Iṣeun-Ifẹ Rẹ̀ Ti Pọ̀ Jaburata”

GẸGẸ BI JOSÉ VERGARA OROZCO TI SỌ Ọ

Iwọ ha lero pe igbesi-aye rẹ ni a lè fi okun titun kún ni ẹni 70 ọdun bi? Temi ni a fikun. Iyẹn sì jẹ́ eyi ti ó lé ni ọdun 35 sẹhin. Nipasẹ iṣeun-ifẹ Jehofa, lati 1962, mo ti ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee, ati lati 1972, mo ti jẹ́ alaboojutoni Ijọ El Carrizal ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Ipinlẹ Jalisco, Mexico. Jẹ ki n sọ diẹ fun ọ nipa ipilẹ mi.

A BÍ mi ni Ipinlẹ Michoacán, ni Mexico, ni August 18, 1886. Baba mi jẹ́ mẹmba iru Ẹgbẹ́-Awo kan, nitori naa idile wa kò lọ si Ṣọọṣi Katoliki, bẹẹ ni a kò lọwọ ninu awọn ayẹyẹ onisin ti Katoliki eyikeyii tabi ní awọn ère isin eyikeyii ninu ile wa.

Nigba ti mo jẹ ẹni ọdun 16, baba mi lọ wá iṣẹ ṣe ni United States, ṣugbọn ó ṣeto pe ki ọkunrin kan maa kọ́ mi ni iṣẹ́-òwò. Bi o ti wu ki o ri, ni ọdun meji lẹhin naa, ọkunrin naa mu mi lọ si Mexico City fun idalẹkọọ ni ile-ẹkọ ologun. Lẹhin naa mo bẹrẹ iṣẹ igbesi-aye kan ninu ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ti Mexico.

Ninu Ẹgbẹ́ Ọmọ-Ogun ati Lẹhin Naa

Mo jà ninu Iyipada Afọtẹṣe ti Mexico ti o bẹrẹ ni 1910. Gbogbo awa ọdọmọkunrin ni ile-ẹkọ naa ti Francisco I. Madero lẹhin, ẹni ti o jẹ́ aṣaaju iyipada afọtẹṣe ti o lodi si ipo aṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ti Porfirio Díaz. A ti Madero lẹhin titi di igba iku rẹ̀ ni 1913, ati lẹhin naa, a ti Venustiano Carranza lẹhin, ẹni ti o ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aarẹ Orilẹ-ede Alailọba naa lati 1915 si 1920. Wọn ń pè wá ni Carranzistas.

Ni igba mẹrin ọtọọtọ, mo gbiyanju, laisi aṣeyọri, lati bọ́ ninu ẹgbẹ́ ọmọ-ogun naa. Nikẹhin mo sá kuro laigbaṣẹ mo sì di ìsáǹsá kan. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, baba mi, ẹni ti o ti pada si Mexico, ni a fisẹwọn. Ni ọjọ kan, ni dídíbọ́n lati jẹ́ ọmọ ibatan rẹ̀, mo bẹ̀ẹ́ wò ninu tubu. A jumọsọrọpọ nipa kikọwe sara awọn ègé bébà ki awọn oluṣọ ma baa lè gbọ́ wa. Lati ṣediwọ fun ẹnikẹni lati maṣe ṣàwárí ẹni ti emi jẹ́, mo jẹ bébà naa.

Lẹhin ti a dá baba mi silẹ kuro ninu tubu, ó bẹ̀ mi wò ó sì beere pe ki n lọ fi araami han fun awọn alaṣẹ. Mo ṣe bẹẹ, ati si iyalẹnu mi, olori ologun naa ti ń ṣe abojuto kò faṣẹ ọba mu mi. Kaka bẹẹ, ó damọran pe ki n ṣí lọ si United States. Mo tẹle amọran rẹ̀ mo sì gbé nibẹ lati 1916 si 1926.

Ni 1923, mo gbé obinrin ara Mexico kan niyawo ẹni ti o ń gbe ni United States pẹlu. Mo kọ́ iṣẹ́-òwò kan nipa iṣẹ-ikọle, a sì gba ọdọmọbinrin kekere kan ṣọmọ. Nigba ti o pa ọmọ oṣu 17, a pada si Mexico a sì ń gbe ni Jalpa, Tabasco. Lẹhin naa ‘ọ̀tẹ̀ Cristero’ bẹrẹ, ó sì wà lati 1926 si 1929.

Awọn Cristero fẹ ki n darapọ mọ wọn. Bi o ti wu ki o ri, idile mi yan lati sá lọ si Ipinlẹ Aguascalientes. Lẹhin gbigbe ni oniruuru ibi ninu orilẹ-ede alailọba naa Mexico, ni 1956 a fidikalẹ si Matamoros, Tamaulipas, nibi ti mo ti bẹrẹ si bojuto awọn iṣẹ-ikọle.

Igbesi-Aye Mi Yipada

Igba yii ni igbesi-aye mi bẹrẹ sii yipada. Ọmọbinrin mi, ẹni ti o ti ṣegbeyawo nisinsinyi ti o sì ń gbé lodikeji ààlà ni Brownsville, Texas, U.S.A., maa ń ṣebẹwo sọdọ wa lemọlemọ. Ni ọjọ kan o sọ pe: “Dadi, ọpọlọpọ idile ń pade ninu gbọngan ipade ilu nisinsinyi gan-an. Ẹ jẹ ki a lọ ki a sì mọ ohun ti ó dá lé lori.” Ó jẹ́ apejọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ọmọbinrin mi, ọkọ rẹ̀, ọmọ-ọmọ mi, aya mi, ati emi lọ si gbogbo ọjọ mẹrẹẹrin apejọ naa.

Lati ọdun yẹn lọ, ni a ti ń lọ si ipade Kristẹni ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Mo tẹsiwaju nipa tẹmi ni Mexico, nigba ti ọmọbinrin mi ṣe bẹẹ ni United States. Laipẹ mo ń sọ awọn otitọ Bibeli ti mo ń kọ fun awọn alajọṣiṣẹ mi. Mo ń gba iwe irohin mẹwaa ninu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! kọọkan, eyi ti mo pin kiri laaarin awọn alajọṣiṣẹ mi. Marun-un ninu awọn ti ń ṣiṣẹ ninu ọfiisi ati mẹta lara awọn ẹnjinnia ati pẹlu awọn oṣiṣẹ diẹ miiran di Ẹlẹ́rìí.

Óò, ó tutu gan-an ni December 19, 1959, yẹn, nigba ti mo gba iribọmi ninu odo! Olukuluku ti o gba iribọmi ni ọjọ yẹn ni aisan ṣe nitori omi ti o tutu rekọja ààlà. Ọmọbinrin mi gba iribọmi ṣaaju mi, ati niti aya mi, bi o tilẹ jẹ pe oun kò gba iribọmi, ó dé ori koko mímọ otitọ Bibeli, ó sì fọwọsowọpọ gan-an.

Iṣẹ-Ojiṣẹ Alakooko Kikun

Mo nimọlara kíkún fún imoore si Ọlọrun fun gbogbo iṣeun-ifẹ rẹ̀, nitori naa ni February 1962, nigba ti mo jẹ́ ẹni ọdun 75, mo bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna. Ọdun diẹ lẹhin naa, ni 1968, aya mi kú, mo fẹ lati ṣiṣẹsin nigba naa ni orilẹ-ede miiran, ṣugbọn nitori ọjọ-ori mi, awọn arakunrin kò ro pe iyẹn bọgbọnmu. Bi o ti wu ki o ri, ni 1970, a yàn mi si Colotlán ni Ipinlẹ Jalisco gẹgẹ bi aṣaaju-ọna, nibi ti ijọ kekere kan wà.

Ni September 1972, alaboojuto ayika damọran pe ki n ṣí lọ si ilu El Carrizal, eyi ti o sunmọ Colotlán. Ni November ọdun yẹn, ijọ kan ni a fidii rẹ̀ mulẹ nibẹ, a sì yan mi sipo gẹgẹ bi alagba kan. Ani bi o tilẹ jẹ pe o jẹ́ ilu ti ó dádó gan-an, iye ti o tó 31 ń wá si awọn ipade ijọ.

Laika ọjọ-ori mi si, mo ṣì ń gbekankanṣiṣẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ, ni gbigbiyanju kára lati ran awọn eniyan lọwọ lati ronu lori awọn igbagbọ wọn. Fun apẹẹrẹ, ninu aṣa kíka Adura Àfìlẹ̀kẹ̀gbà awọn Katoliki olootọ-inu ń ṣatunka Mo Ki Ọ Maria pe: ‘Mo Ki Ọ, Maria, ẹni ti o kun fun aanu; Oluwa wà pẹlu rẹ.’ Adura naa fikun pe: ‘Maria Mímọ́, Iya Ọlọrun.’ Mo beere lọwọ wọn pe: ‘Bawo ni iyẹn ṣe lè ri bẹẹ? Bi Ọlọrun ba jẹ́ ẹni ti o gba Maria là, bawo ni Oun lakooko kan naa ṣe lè jẹ́ ọmọkunrin rẹ̀?’

Mo jẹ́ ẹni ọdun 105 nisinsinyii mo sì ti ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba ati gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee ni El Carrizal, Jalisco, fun ohun ti o sunmọ 20 ọdun. Mo nimọlara pe o ti jẹ́ ifẹ Jehofa pe ki n ti gbe fun ọpọlọpọ ọdun wọnyi, niwọn bi o ti jẹ́ pe ni ọna yii mo lè san asanpada fun akoko ti mo padanu nigba ti emi ko ṣiṣẹsin In.

Ohun kan ti mo ti kọ́ ni pe a gbọdọ maa ni igbọkanle nigba gbogbo pe Onidaajọ Gigajulọ wa ń ṣọ́ wa lati ori ìtẹ́ ododo rẹ̀ ó sì ń pese fun awọn aini wa. Gẹgẹ bi Saamu 117:2 (NW) ti wi: “Siha ọdọ wa ni iṣeun-ifẹ rẹ̀ ti pọ̀ jaburata.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́