ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 2/15 ojú ìwé 29
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Johanu Ha Ṣàìní Ìgbàgbọ́ Bí?
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jòhánù Fẹ́ Gbọ́rọ̀ Látẹnu Jésù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Òun Ni Ẹni Tí A Rán Ṣáájú Messia Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ta Ni Jòhánù Arinibọmi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 2/15 ojú ìwé 29

Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Ó ha yẹ ki a pari-ero lati inu Matiu 11:11 pe Jesu mọ ṣaaju pe Johanu Arinibọmi yoo ku ṣaaju bi?

Bẹẹni, Jesu lọna ti o han gbangba mọ pe Johanu ki yoo laaja lati di Kristẹni ẹni ami ororo kan, nitori Jesu sọ pe: “Loootọ ni mo wi fun yin, ninu awọn ti a bi ninu obinrin, kò si ẹni ti o ti i dide ju Johanu Bamtisi lọ; ṣugbọn ẹni ti o kere julọ ni ijọba ọrun o pọ̀ ju u lọ.”—Matiu 11:11.

Nigba ti angẹli Geburẹli kede bíbọ̀ ìbí Johanu, ó sọtẹlẹ pe Johanu yoo, fi “ẹmi ati agbara Elija, . . . mura silẹ fun Jehofa awọn eniyan ti a ti pese silẹ.” Johanu ni o nilati jẹ́ ẹni ti a rán ṣaaju kan, ni mimura awọn eniyan silẹ fun Mesaya Jehofa. Ṣugbọn kò si ohunkohun ninu ikede atọrunwa yẹn ti o fihan pe Johanu funraarẹ yoo di ọmọ-ẹhin Mesaya naa ti ń bọ̀, bẹẹ ni kò si idamọran eyikeyii si iyẹn ninu gbolohun ọrọ alasọtẹlẹ ti baba Johanu, Sekaraya sọ.—Luuku 1:17, 67-79, NW.

Nipa bayii, lẹhin ti o bamtisi Jesu, Johanu ń baa lọ lati waasu ati lati bamtisi, ni rírọ̀ mọ́ iṣẹ ayanfunni rẹ̀ lati mura awọn eniyan kan silẹ. Johanu mọ lọna iyanu pe Jesu yoo pese bamtisimu pẹlu ẹmi mímọ́, ṣugbọn Johanu kò sọ pe oun funra oun yoo gba ẹmi mímọ́, ni didi Kristẹni ẹni ami ororo kan. (Matiu 3:11) Johanu tun mọ pe oun yoo maa lọsilẹ, nigba ti Jesu yoo maa pọ sii.—Johanu 3:22-30.

Nigba ti Jesu sọ ohun ti a kà ni Matiu 11:11, Johanu ni a ti fi sinu ẹwọn ṣaaju akoko yẹn. Jesu sọ ọ di mímọ̀ ṣaaju pe wolii ti a fi sẹwọn yii kere ju ẹni kekere julọ ti yoo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ọba ati alufaa ninu awọn ọrun ni ọjọ-ọla. Sibẹ Jesu tun jọ bii pe ó mọ pe Johanu ni yoo kú laipẹ, ni kikọja lọ kuro ninu iran ayé ṣaaju ki ọna “titun” naa si iwalaaye ti ọrun tó ṣí silẹ. (Heberu 10:19, 20) Iyẹn tumọ si pe Johanu ki yoo laaja titi Pẹntikọsi 33 C.E., nigba ti ìfàmì ororo yan awọn ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu ẹmi bẹrẹ. Fun idi yii, àlàyé ọrọ Jesu ni Matiu 11:11 ni a lè gbà daradara lati jẹ́ itọka kan pe oun mọ pe Johanu ki yoo lọ si ọrun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́