ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 5/15 ojú ìwé 29-31
  • Òun Ni Ẹni Tí A Rán Ṣáájú Messia Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òun Ni Ẹni Tí A Rán Ṣáájú Messia Náà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Iṣẹ́ Tí A Rán An
  • Ohùn ní Aginjù
  • A Kìlọ̀ Fún “Onírúurú Ènìyàn Gbogbo”
  • A Fi Messia náà Hàn
  • Olóòótọ́ Títí dé Òpin
  • Jòhánù Arinibọmi Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Johanu Pa Ọ̀nà Mọ́
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 5/15 ojú ìwé 29-31

Òun Ni Ẹni Tí A Rán Ṣáájú Messia Náà

ÀMÙRÈ awọ fífẹ̀ kan pe àfiyèsí sí àwọ̀ ara rẹ̀ tí òòrùn ti sọ di dúdú. Pẹ̀lú ẹ̀wù tí a fi irun ràkúnmí ṣe tí ó wọ̀, ó rí bíi wòlíì gan-an nítòótọ́. Ọ̀pọ̀ tọ̀ ọ́ lọ nínú odò Jordani. Níbẹ̀ ni ọkùnrin tí ó fanimọ́ra yìí ti polongo tìgboyà tìgboyà pé òun ti ṣetán láti ṣe ìrìbọmi fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n bá ronúpìwàdà.

Ẹnu ya àwọn ènìyàn! Ta ni ọkùnrin yìí? Kí ni ète rẹ̀?

Jesu Kristi sọ nípa ẹni yìí pé: “Èéṣe tí ẹ fi jáde lọ? Ṣé lati rí wòlíì kan ni? Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún yín, ati èyí tí ó ju wòlíì kan lọ́pọ̀lọpọ̀. . . . Láàárín awọn wọnnì tí obìnrin bí a kò tí ì gbé ẹni kan dìde tí ó tóbi ju Johannu Oníbatisí lọ.” (Matteu 11:9-11) Èéṣe tí Johannu fi jẹ́ ẹni tí ó tayọ lọ́lá bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ó jẹ́ ẹni tí a rán ṣáájú Messia náà.

A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Iṣẹ́ Tí A Rán An

Ní èyí tí ó ju 700 ọdún ṣáájú ìbí Johannu, Jehofa kéde pé ẹni yìí yóò máa ké jáde láti aginjù: “Ẹ tún ọ̀nà Oluwa ṣe, ṣe òpópó títọ́ ní aginjù fún Ọlọrun wa.” (Isaiah 40:3; Matteu 3:3) Ní èyí tí ó ju 400 ọdún ṣáájú ìbí Johannu, Ọlọrun Olódùmarè polongo pé: “Wò ó, èmi óò rán wòlíì Elijah sí yín, kí ọjọ́ ńlá-ǹlà Olúwa, àti ọjọ́ tí ó ní ẹ̀rù tó dé.” (Malaki 4:5) Pé a bí Johannu Oníbatisí ni nǹkan bíi oṣù mẹ́fà ṣáájú Jesu kì í ṣe èèṣì rárá, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé ó wulẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà àbínibí ti ẹ̀dá. Gẹ́gẹ́ bí ìbí ọmọ tí a ṣèlérí rẹ̀ náà Isaaki, ìbí Johannu jẹ́ iṣẹ́ ìyanu, nítorí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì, Sekariah àti Elisabeti, ti dàgbà kọjá ọjọ́ orí ẹni tí ó lè bímọ.—Luku 1:18.

Ṣáájú ìlóyún Johannu pàápàá, àṣẹ tí a fi fún un, iṣẹ́ rẹ̀, àti ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ ni áńgẹ́lì Gabrieli ti ṣí payá. Pẹ̀lú okun àti ẹ̀mí Elijah, Johannu yóò yí àwọn aláìgbọràn padà kúrò ní ọ̀nà ikú yóò sì mú wọn gbaradì láti tẹ́wọ́gba Jesu gẹ́gẹ́ bíi Messia náà. Láti ìgbà tí a bá ti bíi, Johannu níláti jẹ́ Nasiri, tí a yà sọ́tọ̀ pátápátá fún Ọlọrun, kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan wáìnì tàbí ọtí líle. Nítòótọ́, oúnjẹ rẹ̀ ní aṣálẹ̀ ní nínú “awọn kòkòrò eéṣú ati oyin ìgàn.” (Marku 1:6; Numeri 6:2, 3; Luku 1:13-17) Bíi Samueli, láti ìgbà ọmọdé Johannu ni a ti yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́-ìsìn ológo ti Ọlọrun Gíga Jùlọ.—1 Samueli 1:11, 24-28.

Orúkọ náà Johannu ni a tilẹ̀ yàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Orúkọ Heberu náà tí a sọ di “Johannu” túmọ̀ sí “Jehofa Ti Fi Ojú Rere Hàn; Jehofa Ti Jẹ́ Olóore Ọ̀fẹ́.”

Nígbà tí a kọ ọmọ náà nílà ní ọjọ́ kẹjọ, bàbá rẹ̀, Sekariah, ni a mí sí i látọ̀runwá láti polongo pé: “Níti iwọ, ọmọ kékeré, wòlíì Ẹni Gíga Jùlọ ni a óò pè ọ́, nitori tí iwọ yoo lọ ṣáájú níwájú Jehofa lati mú kí awọn ọ̀nà rẹ̀ wà ní sẹpẹ́, lati fi ìmọ̀ ìgbàlà fún awọn ènìyàn rẹ̀ nípasẹ̀ ìdáríjì awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nitori ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọrun wa. Pẹlu ìyọ́nú yii ojúmọ́ kan yoo bẹ̀ wá wò lati ibi gíga lókè.” (Luku 1:76-78) Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Johannu fún gbogbo ènìyàn ni ó níláti jẹ́ ohun àkọ́kọ́ pàtàkì nínú ìgbésí-ayé rẹ̀. Ní ìfiwéra pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ohun tí ó kù ni kò ṣe pàtàkì. Nítorí ìdí èyí, Ìwé Mímọ́ kárí 30 ọdún àkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé Johannu nínú ẹsẹ kanṣoṣo péré: “Ọmọ kékeré naa sì ń bá a lọ ní dídàgbà ati ní dídi alókunlágbára ninu ẹ̀mí, ó sì ń bá a lọ ní wíwà ninu awọn aṣálẹ̀ títí di ọjọ́ fífi ara rẹ̀ hàn ní gbangba wálíà fún Israeli.”—Luku 1:80.

Ohùn ní Aginjù

Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pontiu Pilatu jẹ́ gómìnà Judea, Johannu Oníbatisí fara hàn ní aginjù pẹ̀lú ìhìn-iṣẹ́ yíyanilẹ́nu yìí pé: “Ẹ ronúpìwàdà, nitori ìjọba awọn ọ̀run ti súnmọ́lé.” (Matteu 3:2; Marku 1:4; Luku 3:1, 2) Àwọn ènìyàn gbogbo ẹkùn náà ni a tají. Ìpolongo onígboyà náà nípa lórí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn tí ń yánhànhàn fún ìrètí kan tí ó dájú. Ìkéde Johannu tún pe ìrẹ̀lẹ̀ ẹnì kan níjà nítorí ó ń béèrè fún ìrònúpìwàdà àtọkànwá. Òtítọ́-inú àti ìdánilójú rẹ̀ sún ògìdìgbó àwọn aláìlábòsí àti olóòótọ́ ènìyàn láti kà á sí ẹnì kan tí Ọlọrun rán.

Òkìkí Johannu tàn kálẹ̀ kíákíá. Gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Jehofa, a tètè fi aṣọ àti ìfọkànsìn rẹ̀ dá a mọ̀. (Marku 1:6) Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi pàápàá rìnrìn-àjò láti Jerusalemu láti lọ wádìí ohun tí ó tanná ran gbogbo ọkàn-ìfẹ́ yìí. A ha níláti ronúpìwàdà bí? Èéṣe, àti nípa kí ni? Ta ni ọkùnrin yìí? Wọ́n fẹ́ láti mọ̀. Johannu ṣàlàyé pé: “‘Emi kọ́ ni Kristi naa.’ Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Kí wá ni? Iwọ ni Elijah bí?’ Ó sì wí pé: ‘Emi kọ́.’ ‘Iwọ ni Wòlíì Naa bí?’ Ó sì dáhùn pé: ‘Ó tì o!’ Nitori naa wọ́n wí fún un pé: ‘Ta ni ọ́? kí a lè fi ìdáhùn fún awọn wọnnì tí wọ́n rán wa níṣẹ́. Kí ni iwọ wí nipa ara rẹ?’ Ó wí pé: ‘Emi ni ohùn ẹni kan tí ń ké jáde ní aginjù, “Ẹ ṣe ọ̀nà Jehofa ní títọ́,” gan-an gẹ́gẹ́ bí Isaiah wòlíì ti wí.’ Wàyí o awọn wọnnì tí a rán jáde jẹ́ lati ọ̀dọ̀ awọn Farisi. Nitori naa wọ́n bi í léèrè wọ́n sì wí fún un pé: ‘Èéṣe tí o wá fi ń batisí bí iwọ fúnra rẹ kì í bá ṣe Kristi naa tabi Elijah tabi Wòlíì Naa?’”—Johannu 1:20-25.

Ìrònúpìwàdà àti ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó pọdandan fún àwọn wọnnì tí yóò wọ Ìjọba náà. Nítorí náà, Johannu dáhùn pé: ‘Èmi ń fi omi batisí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronúpìwàdà, ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó lókunlágbára jù mí lọ ń bọ̀ tí yóò batisí yín pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ àti iná. Èéṣe, okùn sálúbàtà ẹni tí èmi kò yẹ lati tú. Kí ẹ sì ṣọ́ra! Ó ń gbé ṣọ́bìrì ìfẹ́kà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ lati kó àlìkámà jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pamọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni oun yóò fi iná jó tí yóò sì parun.’ (Luku 3:15-17; Ìṣe 1:5) Nítòótọ́, ẹ̀mí mímọ́ ni a óò fi jíǹkí àwọn ọmọlẹ́yìn Messia náà, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò ní ìrírí iná ìparun.

A Kìlọ̀ Fún “Onírúurú Ènìyàn Gbogbo”

Ọ̀pọ̀ àwọn Júù aláìlábòsí ọkàn ni ọ̀rọ̀ Johannu nípa lé lórí gidigidi tí wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àìṣòótọ́ wọn sí májẹ̀mú Òfin ní gbangba. Wọ́n fi ẹ̀rí ìrònúpìwàdà wọn hàn ní gbangba nípa yíyọ̀ọ̀da kí Johannu ṣe ìrìbọmi fún wọn ní Odò Jordani. (Matteu 3:5, 6) Ní ìyọrísí rẹ̀, ọkàn-àyà wọn wà ní ipò tí ó tọ́ láti tẹ́wọ́gba Messia náà. Ní pípa òùngbẹ wọn fún ìmọ̀ nípa òdodo tí Ọlọrun béèrè fún, Johannu fi tayọ̀ tayọ̀ tọ́ wọn sọ́nà gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó tilẹ̀ kọ́ wọn bí wọn yóò ṣe gbàdúrà.—Luku 11:1.

Aposteli Johannu kọ̀wé nípa ẹni yìí, tí a rán ṣáájú Messia náà pé: “Ọkùnrin yii wá fún ẹ̀rí, lati lè jẹ́rìí nipa ìmọ́lẹ̀ naa, kí onírúurú ènìyàn gbogbo baà lè gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.” (Johannu 1:7) Nítorí náà bí ó ṣe di pé onírúurú ènìyàn gbogbo ni ó wá láti tẹ́tísílẹ̀ sí Johannu Oníbatisí nìyẹn bí ó “ti wàásù ní gbangba fún gbogbo awọn ènìyàn Israeli nipa ìbatisí ní àmì-ìṣàpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà.” (Ìṣe 13:24) Ó kìlọ̀ fún àwọn agbowó-orí lòdìsí dídi ẹni tí ń lọ́nilọ́wọ́gbà. Ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ogun lòdìsí híhalẹ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tàbí fífi ẹ̀sùn èké kanni. Ó tún sọ fún àwọn ẹlẹ́mìí-ìsìn, àwọn àgàbàgebè Farisi àti àwọn Sadusi pe: “Ẹ̀yin àmújáde-ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ni fi tó yín létí lati sá kúrò ninu ìrunú tí ń bọ̀? Nitori bẹ́ẹ̀ nígbà naa ẹ mú èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà jáde; kí ẹ má sì ṣe kùgbù lati wí fún ara yín pé, ‘Awa ní Abrahamu gẹ́gẹ́ bí baba.’ Nitori mo wí fún yín pé Ọlọrun lè gbé awọn ọmọ dìde fún Abrahamu lati inú awọn òkúta wọnyi.”—Matteu 3:7-9; Luku 3:7-14.

Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn aṣáájú ìsìn ní ọjọ́ Johannu kọ̀ láti gbà á gbọ́ wọ́n sì fi èrú fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ní ẹ̀mí-èṣù. Wọ́n kọ ọ̀nà òdodo tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn agbowó-orí àti àwọn aṣẹ́wó tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n gba gbólóhùn ẹ̀rí Johannu gbọ́ ronúpìwàdà a sì ṣe ìrìbọmi fún wọn. Láìpẹ́, wọ́n tẹ́wọ́gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bíi Messia náà.—Matteu 21:25-32; Luku 7:31-33.

A Fi Messia náà Hàn

Fún oṣù mẹ́fà—láti ìgbà ìrúwé sí ìbẹ̀rẹ̀ 29 C.E—olùṣòtítọ́ ẹlẹ́rìí Ọlọrun náà Johannu darí àfiyèsí àwọn Júù sí Messia náà tí ń bọ̀. Ó ti tó àkókò fún Messia Ọba náà láti fara hàn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé, ó sọ̀kalẹ̀ wá sí odò Jordani kan náà ó sì béèrè kí a ṣe ìrìbọmi fún òun. Ní àkọ́kọ́ Johannu kọ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà ó faramọ́ ọn. Ronúwòye ìdùnnú-ayọ̀ rẹ̀ nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ sọ̀kalẹ̀ lé Jesu lórí tí a sì gbọ́ ohun Jehofa tí ń sọ ìtẹ́wọ́gbà Ọmọkùnrin Rẹ̀ jáde.—Matteu 3:13-17; Marku 1:9-11.

Johannu ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó dá Jesu mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Messia náà, ó sì fi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ han Ẹni Àmì-Òróró yìí. Johannu sọ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ọlọrun tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” Ó tún polongo pé: “Èyí ni ẹni naa nipa ẹni tí mo wí pé, Lẹ́yìn mi ọkùnrin kan ń bọ̀ tí ó ti lọ jìnnà níwájú mi, nitori tí ó wà ṣáájú mi. Emi pàápàá kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ìdí tí mo fi wá ń batisí ninu omi ni pé kí a lè fi í hàn kedere fún Israeli.”—Johannu 1:29-37.

Iṣẹ́ Johannu ń bá a lọ ní àsìkò kan náà pẹ̀lú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu fún nǹkan bí oṣù mẹ́fà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lóye iṣẹ́ tí ẹnìkejì ń ṣe. Johannu wo ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọkọ Ìyàwó ó sì láyọ̀ láti rí i pé Kristi ń pọ̀ síi nígbà tí òun àti iṣẹ́ òun ń dínkù.—Johannu 3:22-30.

Jesu mọ Johannu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a rán ṣáájú òun, ẹni tí Elijah ṣàpẹẹrẹ. (Matteu 11:12-15; 17:12) Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, Jesu sọ pé: “Òfin ati awọn Wòlíì wà títí di ìgbà Johannu. Lati ìgbà naa lọ ni a ti ń polongo ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere, onírúurú ènìyàn gbogbo sì ń fi ìsapá tẹ̀síwájú síhà rẹ̀.”—Luku 16:16.

Olóòótọ́ Títí dé Òpin

A fi àṣẹ ọba mú Johannu a sì fi í sẹ́wọ̀n nítorí pé ó fi ìgboyà kéde òtítọ́. Òun kò sá fún ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ láti túdìí àṣírí Ọba Herodu pàápàá. Ní ríré òfin Ọlọrun kọjá, ọba náà ń gbé ìgbésí-ayé onípanṣágà pẹ̀lú Herodia, aya ẹ̀gbọ́n òun fúnra rẹ̀. Johannu fi ìgboyà sọ̀rọ̀ kí ọkùnrin náà baà lè ronúpìwàdà kí ó sì rí àánú Ọlọrun gbà.

Ẹ wo àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí Johannu jẹ́! Bí ó tilẹ̀ ná an ní òmìnira ara rẹ̀, ó fi ẹ̀rí ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jehofa Ọlọrun àti ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ hàn. Lẹ́yìn wíwà ní ẹ̀wọ̀n fún ọdún kan, Johannu ni a bẹ́ lórí gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rìkíṣí tí Èṣù mí sí tí ẹni ibi náà Herodia dásílẹ̀, ẹni tí ń “di kùnrùngbùn” sí i. (Marku 6:16-19; Matteu 14:3-12) Ṣùgbọ́n ẹni tí a rán ṣáájú Messia náà di ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jehofa mu a óò sì jí i dìde láìpẹ́ kúrò nínú òkú láti gbádùn ìwàláàyè nínú ayé titun Ọlọrun tí òdodo ń gbé.—Johannu 5:28, 29; 2 Peteru 3:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́